ORIN 89
Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún
- 1. Aláyọ̀ làwọn tó ń gbọ́rọ̀ Ọlọ́run, - Tí wọ́n ń fetí sẹ́kọ̀ọ́ Jésù Kristi; - Ìbàlẹ̀ ọkàn, ìdùnnú, àlàáfíà, - Yóò jẹ́ tàwọn tó bá jónígbọràn. - (ÈGBÈ) - Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún, - Tí Ọlọ́run bá ń sọ̀rọ̀. - Tó o bá fẹ́ máa múnú Jèhófà dùn, - Ìgbọràn ṣe pàtàkì. 
- 2. Tá a bá jẹ́ onígbọràn sí Ọlọ́run, - Ìgbésí ayé wa yóò dára gan-an. - Ó máa dà bí ilé orí àpáta - Tó lágbára, tó sì fìdí múlẹ̀. - (ÈGBÈ) - Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún, - Tí Ọlọ́run bá ń sọ̀rọ̀. - Tó o bá fẹ́ máa múnú Jèhófà dùn, - Ìgbọràn ṣe pàtàkì. 
- 3. Tí a bá fetí sí ohùn Jèhófà, - Tá à ń tẹ̀ lé àṣẹ àti ‘lànà rẹ̀, - A máa dà bí igi tá a gbìn sétídò, - Tó ń so èso rẹ̀ lákòókò tó yẹ. - (ÈGBÈ) - Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún, - Tí Ọlọ́run bá ń sọ̀rọ̀. - Tó o bá fẹ́ máa múnú Jèhófà dùn, - Ìgbọràn ṣe pàtàkì. 
(Tún wo Diu. 28:2; Sm. 1:3; Òwe 10:22; Mát. 7:24-27; Lúùkù 6:47-49.)