ORIN 76
Báwo Ló Ṣe Máa Ń Rí Lára Rẹ?
- 1. Báwo ló ṣe máa ń rí - tó o bá ń ṣiṣẹ́ ìwàásù, - tó ò ń gbìyànjú láti dé - ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn? - Àwa gbẹ́kẹ̀ lé Jáà, - yóò bù kún iṣẹ́ tá a ṣe, - Torí Ó mọ àwọn tó - jẹ́ ọlọ́kàn tútù. - (ÈGBÈ) - Inú wa dùn, ayọ̀ wa kún - pé a ti ṣohun tá a lè ṣe. - Kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ‘ṣẹ́ - tá à ń ṣe lójoojúmọ́. 
- 2. Báwo ló ṣe máa ń rí - tó o bá báwọn kan sọ̀rọ̀ - tí wọ́n tẹ́tí gbọ́rọ̀ rẹ, - tó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn? - Àwọn mí ì kọ̀ jálẹ̀, - Wọn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. - Síbẹ̀, à ń láyọ̀ pé à ń - wàásù orúkọ Jáà. - (ÈGBÈ) - Inú wa dùn, ayọ̀ wa kún - pé a ti ṣohun tá a lè ṣe. - Kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ‘ṣẹ́ - tá à ń ṣe lójoojúmọ́. 
- 3. Báwo ló ṣe máa ń rí - tó o bá ń ṣiṣẹ́ Jèhófà, - tó fi sí ìkáwọ́ wa, - tó sì ń tì wá lẹ́yìn? - À ń wá àwọn èèyàn - tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. - À ń sọ̀rọ̀ tútù lẹ́nu - bá a ṣe ń wàásù fún wọn. - (ÈGBÈ) - Inú wa dùn, ayọ̀ wa kún - pé a ti ṣohun tá a lè ṣe. - Kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ‘ṣẹ́ - tá à ń ṣe lójoojúmọ́. 
(Tún wo Ìṣe 13:48; 1 Tẹs. 2:4; 1 Tím. 1:11.)