ORIN 3
Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. A ní ìrètí iyebíye - tí à ń sọ fáráyé. - Ìrètí tó ń mórí wa wú, - lo fún wa, Jèhófà. - Ṣùgbọ́n tíṣòro bá ti pọ̀ jù, - ṣe nìbẹ̀rù máa ń bò wá. - Ìrètí wa tó lágbára - sì lè wá máa kú lọ. - (ÈGBÈ) - Agbára wa àti - Olùpèsè wa; - A gbọ́kàn lé ọ, Jèhófà. - À ń wàásù, à ń kọ́ni, - ọkàn wa balẹ̀ - Torí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé. 
- 2. Jọ̀ọ́, Jèhófà Olùtùnú wa, - Jẹ́ ká máa rántí pé, - Gbogbo ìgbà tá a níṣòro - lo máa ń tù wá nínú. - Èyí ló sì mú ká lókun gan-an - tírètí wa fi ń sọjí; - Tá a fi lè fìgboyà sọ̀rọ̀ - nípa orúkọ rẹ. - (ÈGBÈ) - Agbára wa àti - Olùpèsè wa; - A gbọ́kàn lé ọ, Jèhófà. - À ń wàásù, à ń kọ́ni, - ọkàn wa balẹ̀ - torí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé. 
(Tún wo Sm. 72:13, 14; Òwe 3:5, 6, 26; Jer. 17:7.)