ORIN 159
Jèhófà Ni Ìyìn àti Ògo Yẹ!
- 1. Jèhófà ta ló dà bí rẹ? - Ta ni mo lè fi ọ́ wé? - Títóbi rẹ ga ju ọ̀run, - Ògo àtagbára rẹ pọ̀. - Kí ni mo jẹ́ Ọlọ́run mi, - Tí o fi ń fiyè sí mi? - Kí ni màá fi san oore rẹ, - Fún ìfẹ́ tó ò ń fi hàn sí mi? - (ÈGBÈ) - Ẹnu mi yóò máa kọ orin sí ọ. - Jèhófà jọ̀ọ́ gbóhùn mi. - Ọlọ́run mi Ọba Ayérayé, - Ògo àtìyìn yẹ ọ́; - Màá yìn ọ́ títí ayé. 
- 2. Mo fayé mi fún ọ Bàbá, - Mo fẹ́ máa múnú rẹ dùn. - Màá fayọ̀ wàásù ọ̀rọ̀ rẹ, - Màá ròyìn àwọn oore rẹ. - Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún mi - Pé mo jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ. - Ìwọ ni ibi ààbò mi, - Títí láé ní màá ṣèfẹ́ rẹ. - (ÈGBÈ) - Ẹnu mi yóò máa kọ orin sí ọ. - Jèhófà jọ̀ọ́ gbóhùn mi. - Ọlọ́run mi Ọba Ayérayé, - Ògo àtìyìn yẹ ọ́; - Màá yìn ọ́ títí ayé. 
- 3. Àwọn ohun tí o ṣẹ̀dá - Sáyé àtojú ọ̀run - Jẹ́ kí n rí i pé o nífẹ̀ẹ́ mi, - Àti pé ọgbọ́n rẹ pọ̀ gàn-an. - Àgbàyanu ni iṣẹ́ rẹ, - Ó ń jẹ́ kí orí mi wú! - Ta ni ǹbá tún fì ìyìn fún, - Bí kò ṣèwọ Ẹlẹ́dàá mi? - (ÈGBÈ) - Ẹnu mi yóò máa kọ orin sí ọ. - Jèhófà jọ̀ọ́ gbóhùn mi. - Ọlọ́run mi Ọba Ayérayé, - Ògo àtìyìn yẹ ọ́; - Màá yìn ọ́ títí ayé. 
(Tún wo Sm. 96:1-10; 148:3, 7.)