ORIN 28
Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
	(Sáàmù 15)
- 1. Ta lọ̀rẹ́ rẹ, Baba, - Táá máa gbé ilé rẹ; - Ẹni tí Ìwọ gbẹ̀rí rẹ̀ jẹ́, - Tó sì mọ̀ ọ́ dunjú? - Àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ, - Tí wọ́n sì nígbàgbọ́; - Àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin, - Tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. 
- 2. Ta ni yóò dọ̀rẹ́ rẹ, - Tó sì lè sún mọ́ ọ; - Táá mú kó o láyọ̀, kínú rẹ dùn, - Tíwọ sì mọ̀ dunjú? - Àwọn olódodo - Tó ń gbórúkọ rẹ ga; - Àwọn tó máa ń ṣègbọràn sí ọ, - Tó máa ń sọ òtítọ́. 
- 3. Gbogbo àníyàn wa - La gbé síwájú rẹ. - Ojoojúmọ́ lò ń fà wá mọ́ra; - Ò ń fìfẹ́ ṣìkẹ́ wa. - A fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ - Títí ayérayé. - Kò sọ́rẹ̀ẹ́ míì tó dáa jù ọ́ lọ; - Kò sọ́rẹ̀ẹ́ míì bíi rẹ. 
(Tún wo Sm. 139:1; 1 Pét. 5:6, 7.)