Monday, October 27
Kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn bí ara wọn.—Éfé. 5:28.
Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí ọkọ nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀, kó máa pèsè àwọn nǹkan tó nílò fún un, kó máa ṣìkẹ́ ẹ̀, kó sì máa ṣe ohun táá jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ní àròjinlẹ̀, kó o máa bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin, kó o sì jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá di ọkọ rere. Lẹ́yìn tó o bá láya, ó ṣeé ṣe kó o bímọ. Tó o bá fẹ́ jẹ́ bàbá rere, ẹ̀kọ́ wo lo lè kọ́ lára Jèhófà? (Éfé. 6:4) Jèhófà sọ fún Jésù Ọmọ ẹ̀ ní gbangba pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, òun sì tẹ́wọ́ gbà á. (Mát. 3:17) Torí náà, tó o bá bímọ, rí i dájú pé gbogbo ìgbà lò ń sọ fáwọn ọmọ ẹ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. Tí wọ́n bá ṣe ohun tó dáa, gbóríyìn fún wọn látọkànwá. Àwọn bàbá tó bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà máa ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ báyìí de ojúṣe yìí, bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa fìfẹ́ bójú tó àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìdílé àtàwọn ará ìjọ, kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, o sì mọyì wọn.—Jòh. 15:9. w23.12 28-29 ¶17-18
Tuesday, October 28
[Jèhófà] ló ń mú kí nǹkan lọ bó ṣe yẹ láwọn àkókò rẹ.—Àìsá. 33:6.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá, a máa ń níṣòro, a sì máa ń ṣàìsàn bíi tàwọn yòókù. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń fara da àtakò àti inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn tó kórìíra àwa èèyàn Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń gbà wá tá a bá níṣòro, ó ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́. (Àìsá. 41:10) Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè láyọ̀, ká ṣe ìpinnu tó tọ́, ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí i kódà nígbà tí ìṣòro bá mu wá lómi. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa ní àlàáfíà tí Bíbélì pè ní “àlàáfíà Ọlọ́run.” (Fílí. 4:6, 7) Àlàáfíà yìí jẹ́ ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní torí pé ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Àlàáfíà yìí “kọjá gbogbo òye,” ó sì ju gbogbo ohun téèyàn lè rò lọ. Ṣé ìgbà kan wà tó o ní ìdààmú ọkàn, àmọ́ tọ́kàn ẹ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ lẹ́yìn tó o gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn? “Àlàáfíà Ọlọ́run” ló mú kíyẹn ṣeé ṣe. w24.01 20 ¶2; 21 ¶4
Wednesday, October 29
Jẹ́ kí n yin Jèhófà; kí gbogbo ohun tó wà nínú mi yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.—Sm. 103:1.
Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń yin orúkọ ẹ̀ tọkàntọkàn. Ọba Dáfídì mọ̀ pé tá a bá ń yin orúkọ Jèhófà, Jèhófà náà là ń yìn yẹn. Tá a bá gbọ́ orúkọ Jèhófà, ó máa ń jẹ́ ká rántí àwọn ìwà rere tó ní àti àwọn ohun rere tó máa ń ṣe. Ó wu Dáfídì pé kó ya orúkọ Bàbá ẹ̀ sí mímọ́, kó sì máa yìn ín. Ó sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn pẹ̀lú “gbogbo ohun tó wà nínú” ẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwọn ọmọ Léfì ló máa ń ṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n bá fẹ́ yin Jèhófà. Síbẹ̀, wọ́n gbà pé kò sí báwọn ṣe lè yin Jèhófà tó bó ṣe yẹ káwọn yìn ín. (Neh. 9:5) Ó dájú pé bí wọ́n ṣe fìrẹ̀lẹ̀ yin Jèhófà, tí wọ́n sì ṣe é tọkàntọkàn máa múnú ẹ̀ dùn gan-an. w24.02 9 ¶6