LÚÙKÙ
OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ
-  1  - 
- Ó kọ̀wé sí Tìófílọ́sì (1-4) 
- Gébúrẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa bí Jòhánù Arinibọmi (5-25) 
- Gébúrẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa bí Jésù (26-38) 
- Màríà lọ kí Èlísábẹ́tì (39-45) 
- Màríà gbé Jèhófà ga (46-56) 
- Wọ́n bí Jòhánù, wọ́n sì sọ ọ́ lórúkọ (57-66) 
- Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀ (67-80) 
 
-  2  - 
- Wọ́n bí Jésù (1-7) 
- Àwọn áńgẹ́lì yọ sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn (8-20) 
- Ìdádọ̀dọ́ àti ìwẹ̀mọ́ (21-24) 
- Síméónì rí Kristi (25-35) 
- Ánà sọ̀rọ̀ ọmọ náà (36-38) 
- Wọ́n pa dà sí Násárẹ́tì (39, 40) 
- Jésù ọmọ ọdún méjìlá wà nínú tẹ́ńpìlì (41-52) 
 
-  3  - 
- Ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Jòhánù (1, 2) 
- Jòhánù ń wàásù pé kí wọ́n ṣèrìbọmi (3-20) 
- Jésù ṣèrìbọmi (21, 22) 
- Ìlà ìdílé Jésù Kristi (23-38) 
 
-  4  - 
- Èṣù dán Jésù wò (1-13) 
- Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní Gálílì (14, 15) 
- Wọn ò tẹ́wọ́ gba Jésù ní Násárẹ́tì (16-30) 
- Nínú sínágọ́gù ní Kápánáúmù (31-37) 
- Ó wo ìyá ìyàwó Símónì àtàwọn míì sàn (38-41) 
- Àwọn èrò rí Jésù ní ibi tó dá (42-44) 
 
-  5  - 
- Wọ́n rí ẹja kó lọ́nà ìyanu; àwọn ọmọ ẹ̀yìn àkọ́kọ́ (1-11) 
- Ó wo adẹ́tẹ̀ sàn (12-16) 
- Jésù wo alárùn rọpárọsẹ̀ sàn (17-26) 
- Jésù pe Léfì (27-32) 
- Ìbéèrè nípa ààwẹ̀ (33-39) 
 
-  6  - 
- Jésù ni “Olúwa Sábáàtì” (1-5) 
- Ó wo ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ rọ sàn (6-11) 
- Àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12-16) 
- Jésù ń kọ́ni, ó sì ń woni sàn (17-19) 
- Àwọn aláyọ̀ àtàwọn tí a káàánú wọn (20-26) 
- Nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá (27-36) 
- Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́ mọ́ (37-42) 
- Èso igi la fi ń mọ̀ ọ́n (43-45) 
- Ilé tí wọ́n kọ́ dáadáa; ilé tí ìpìlẹ̀ rẹ̀ ò lágbára (46-49) 
 
-  7  - 
- Ìgbàgbọ́ ọ̀gágun (1-10) 
- Jésù jí ọmọkùnrin opó Náínì dìde (11-17) 
- Ó yin Jòhánù Arinibọmi (18-30) 
- Ó dá ìran ọlọ́kàn líle lẹ́bi (31-35) 
- Ó dárí ji obìnrin kan tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ (36-50) 
 
-  8  - 
- Àwọn obìnrin tó ń tẹ̀ lé Jésù (1-3) 
- Àpèjúwe afúnrúgbìn (4-8) 
- Ìdí tí Jésù fi ń lo àwọn àpèjúwe (9, 10) 
- Ó ṣàlàyé àpèjúwe afúnrúgbìn (11-15) 
- A kì í bo fìtílà mọ́lẹ̀ (16-18) 
- Ìyá Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ (19-21) 
- Jésù mú kí ìjì dáwọ́ dúró (22-25) 
- Jésù lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde sínú ẹlẹ́dẹ̀ (26-39) 
- Ọmọbìnrin Jáírù; obìnrin kan fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè Jésù (40-56) 
 
-  9  - 
- Ó fún àwọn Méjìlá náà ní ìtọ́ni nípa iṣẹ́ ìwàásù (1-6) 
- Ìdààmú bá Hẹ́rọ́dù torí Jésù (7-9) 
- Jésù bọ́ 5,000 èèyàn (10-17) 
- Pétérù pè é ní Kristi (18-20) 
- Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú Jésù (21, 22) 
- Ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn (23-27) 
- A yí Jésù pa dà di ológo (28-36) 
- Ó wo ọmọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu sàn (37-43a) 
- Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀  (43b-45) 
- Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù (46-48) 
- Ẹni tí kò bá ta kò wá, tiwa ló ń ṣe (49, 50) 
- Àwọn ará abúlé kan ní Samáríà kọ Jésù (51-56) 
- Bí a ṣe lè tẹ̀ lé Jésù (57-62) 
 
- 10  - 
- Jésù rán 70 èèyàn jáde (1-12) 
- Àwọn ìlú tí kò ronú pìwà dà gbé (13-16) 
- Àwọn 70 náà pa dà dé (17-20) 
- Jésù yin Baba rẹ̀ torí ó ṣojúure sí àwọn onírẹ̀lẹ̀ (21-24) 
- Àpèjúwe ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere (25-37) 
- Jésù lọ sọ́dọ̀ Màtá àti Màríà (38-42) 
 
- 11  - 
- Bí o ṣe lè gbàdúrà (1-13) 
- Ó fi ìka Ọlọ́run lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde (14-23) 
- Ẹ̀mí àìmọ́ pa dà wá (24-26) 
- Ayọ̀ tòótọ́ (27, 28) 
- Àmì Jónà (29-32) 
- Fìtílà ara (33-36) 
- Àwọn ẹlẹ́sìn tó ń ṣe àgàbàgebè gbé (37-54) 
 
- 12  - 
- Ìwúkàrà àwọn Farisí (1-3) 
- Bẹ̀rù Ọlọ́run, má bẹ̀rù èèyàn (4-7) 
- Fi hàn pé o wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi (8-12) 
- Àpèjúwe ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó jẹ́ òmùgọ̀ (13-21) 
- Ẹ yéé ṣàníyàn (22-34) 
- Ṣíṣọ́nà (35-40) 
- Ìríjú olóòótọ́ àti ìríjú aláìṣòótọ́ (41-48) 
- Kì í ṣe àlàáfíà, ìpínyà ni (49-53) 
- Ó yẹ kí wọ́n ṣàyẹ̀wò àkókò (54-56) 
- Yíyanjú ọ̀rọ̀ (57-59) 
 
- 13  - 
- Ẹ ronú pìwà dà àbí kí ẹ pa run (1-5) 
- Àpèjúwe igi ọ̀pọ̀tọ́ tí kò so èso (6-9) 
- Ó ṣèwòsàn fún obìnrin tí ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀ ní Sábáàtì (10-17) 
- Àpèjúwe hóró músítádì àti ìwúkàrà (18-21) 
- Ó gba ìsapá láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé (22-30) 
- Hẹ́rọ́dù, “kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yẹn” (31-33) 
- Jésù dárò lórí Jerúsálẹ́mù (34, 35) 
 
- 14  - 
- Ó wo ọkùnrin kan tí ara rẹ̀ wú sàn ní Sábáàtì (1-6) 
- Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tí o bá jẹ́ àlejò (7-11) 
- Pe àwọn tí kò lè san án pa dà fún ọ (12-14) 
- Àpèjúwe àwọn àlejò tó ṣàwáwí (15-24) 
- Ohun tó máa ná ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn (25-33) 
- Iyọ̀ tí ò lágbára mọ́ (34, 35) 
 
- 15  - 
- Àpèjúwe àgùntàn tó sọ nù (1-7) 
- Àpèjúwe ẹyọ owó tó sọ nù (8-10) 
- Àpèjúwe ọmọ tó sọ nù (11-32) 
 
- 16  - 
- Àpèjúwe ìríjú aláìṣòdodo (1-13) 
- Òfin àti Ìjọba Ọlọ́run (14-18) 
- Àpèjúwe ọkùnrin ọlọ́rọ̀ àti Lásárù (19-31) 
 
- 17  - 
- Ìkọ̀sẹ̀, ìdáríjì àti ìgbàgbọ́ (1-6) 
- Àwọn ẹrú tí kò dáa fún ohunkóhun (7-10) 
- Ó wo adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá sàn (11-19) 
- Dídé Ìjọba Ọlọ́run (20-37) 
 
- 18  - 
- Àpèjúwe opó tí kò juwọ́ sílẹ̀ (1-8) 
- Farisí àti agbowó orí (9-14) 
- Jésù àti àwọn ọmọdé (15-17) 
- Alákòóso kan tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ béèrè ìbéèrè (18-30) 
- Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ (31-34) 
- Alágbe kan tó fọ́jú pa dà ríran (35-43) 
 
- 19  - 
- Jésù lọ sọ́dọ̀ Sákéù (1-10) 
- Àpèjúwe mínà mẹ́wàá (11-27) 
- Jésù gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnú ìlú (28-40) 
- Jésù sunkún lórí Jerúsálẹ́mù (41-44) 
- Jésù fọ tẹ́ńpìlì mọ́ (45-48) 
 
- 20  - 
- Wọ́n béèrè àṣẹ tí Jésù fi ń ṣe nǹkan (1-8) 
- Àpèjúwe àwọn tó ń dáko, tí wọ́n sì pààyàn (9-19) 
- Ọlọ́run àti Késárì (20-26) 
- Ìbéèrè nípa àjíǹde (27-40) 
- Ṣé ọmọ Dáfídì ni Kristi? (41-44) 
- Ó kìlọ̀ fún wọn nípa àwọn akọ̀wé òfin (45-47) 
 
- 21  - 
- Ẹyọ owó méjì tí opó aláìní fi sílẹ̀ (1-4) 
- ÀMÌ OHUN TÓ MÁA ṢẸLẸ̀ (5-36) - 
- Ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, àìtó oúnjẹ (10, 11) 
- Àwọn ọmọ ogun máa yí Jerúsálẹ́mù ká (20) 
- Àkókò tí a yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè (24) 
- Ọmọ èèyàn ń bọ̀ (27) 
- Àpèjúwe igi ọ̀pọ̀tọ́ (29-33) 
- Ẹ wà lójúfò (34-36) 
 
- Jésù ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì (37, 38) 
 
- 22  - 
- Àwọn àlùfáà gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù (1-6) 
- Wọ́n múra Ìrékọjá tó gbẹ̀yìn sílẹ̀ (7-13) 
- Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀ (14-20) 
- “Èmi àti ẹni tó máa dà mí jọ wà lórí tábìlì” (21-23) 
- Wọ́n bára wọn jiyàn gidigidi nípa ẹni tó tóbi jù (24-27) 
- Jésù bá wọn dá májẹ̀mú ìjọba (28-30) 
- Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Pétérù máa sẹ́ òun (31-34) 
- Ìdí tó fi yẹ kí wọ́n múra sílẹ̀; idà méjì (35-38) 
- Àdúrà Jésù lórí Òkè Ólífì (39-46) 
- Wọ́n mú Jésù (47-53) 
- Pétérù sẹ́ Jésù (54-62) 
- Wọ́n fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́ (63-65) 
- Wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (66-71) 
 
- 23  
- 24  - 
- Jésù jíǹde (1-12) 
- Lójú ọ̀nà tó lọ sí Ẹ́máọ́sì (13-35) 
- Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn (36-49) 
- Jésù pa dà sí ọ̀run (50-53)