ÀKỌSÍLẸ̀ LÚÙKÙ
1 Bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ti gbìyànjú láti kó ìròyìn àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ jọ, èyí tí a gbà gbọ́* délẹ̀délẹ̀ láàárín wa,+ 2 bí àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀,+ tí wọ́n sì jẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà ṣe fi àwọn nǹkan yìí lé wa lọ́wọ́,+ 3 èmi náà pinnu, torí mo ti wádìí ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ lọ́nà tó péye, pé kí n kọ ọ́ ránṣẹ́ sí ọ lẹ́sẹẹsẹ, ìwọ Tìófílọ́sì+ ọlọ́lá jù lọ, 4 kí o lè mọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí àwọn ohun tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́ ọ ṣe jẹ́ òótọ́ tó.+
5 Láyé ìgbà Hẹ́rọ́dù,*+ ọba Jùdíà, àlùfáà kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sekaráyà nínú ìpín Ábíjà.+ Ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Áárónì ni ìyàwó rẹ̀, Èlísábẹ́tì ni orúkọ rẹ̀. 6 Àwọn méjèèjì jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n sì ń rìn láìlẹ́bi ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo àṣẹ àti àwọn ohun tí òfin Jèhófà* béèrè. 7 Àmọ́ wọn ò ní ọmọ, torí Èlísábẹ́tì yàgàn, àwọn méjèèjì sì ti lọ́jọ́ lórí gan-an.
8 Bó ṣe ń ṣiṣẹ́ àlùfáà nínú iṣẹ́ tí a yàn fún ìpín rẹ̀+ níwájú Ọlọ́run, 9 gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn àlùfáà,* òun ló kàn láti sun tùràrí+ nígbà tó wọnú ibi mímọ́ Jèhófà.*+ 10 Gbogbo èrò tó pọ̀ rẹpẹtẹ sì ń gbàdúrà níta ní wákàtí tí wọ́n ń sun tùràrí. 11 Áńgẹ́lì Jèhófà* fara hàn án, ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún pẹpẹ tùràrí. 12 Àmọ́ ìdààmú bá Sekaráyà nítorí ohun tó rí, ẹ̀rù sì bà á gidigidi. 13 Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, Sekaráyà, torí a ti ṣojúure sí ọ, a sì ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ, Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ máa bí ọmọkùnrin kan fún ọ, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jòhánù.+ 14 Inú rẹ máa dùn, o sì máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn máa yọ̀ nígbà tí o bá bí i,+ 15 torí ẹni ńlá ló máa jẹ́ lójú Jèhófà.*+ Àmọ́ kò gbọ́dọ̀ mu wáìnì rárá tàbí ọtí líle èyíkéyìí,+ ẹ̀mí mímọ́ sì máa kún inú rẹ̀, àní kí wọ́n tó bí i,*+ 16 ó sì máa mú kí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà* Ọlọ́run wọn.+ 17 Bákan náà, ó máa lọ ṣáájú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí àti agbára Èlíjà,+ kó lè yí ọkàn àwọn bàbá pa dà sí àwọn ọmọ+ àti àwọn aláìgbọràn sí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ ti àwọn olódodo, kó lè ṣètò àwọn èèyàn tí a ti múra sílẹ̀ fún Jèhófà.”*+
18 Sekaráyà sọ fún áńgẹ́lì náà pé: “Báwo ni màá ṣe mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí? Torí mo ti dàgbà, ìyàwó mi sì ti lọ́jọ́ lórí gan-an.” 19 Áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Èmi ni Gébúrẹ́lì,+ tó ń dúró nítòsí, níwájú Ọlọ́run,+ a rán mi láti bá ọ sọ̀rọ̀, kí n sì kéde ìhìn rere yìí fún ọ. 20 Àmọ́ wò ó! o ò ní lè sọ̀rọ̀, wàá sì ya odi títí di ọjọ́ tí àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, torí pé o ò gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́, èyí tó máa ṣẹ ní àkókò tí a yàn fún wọn.” 21 Àmọ́ àwọn èèyàn ṣì ń dúró de Sekaráyà, ó sì yà wọ́n lẹ́nu pé ó pẹ́ gan-an nínú ibi mímọ́. 22 Nígbà tó jáde, kò lè bá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n sì fòye mọ̀ pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ohun* kan tó ju agbára ẹ̀dá lọ nínú ibi mímọ́. Ó ń fi ara ṣàpèjúwe fún wọn, síbẹ̀ kò lè sọ̀rọ̀. 23 Nígbà tí àwọn ọjọ́ tó fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́* pé, ó lọ sílé rẹ̀.
24 Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara pa mọ́ fún oṣù márùn-ún, ó sọ pé: 25 “Ohun tí Jèhófà* ṣe sí mi ní àwọn ọjọ́ yìí nìyí. Ó ti yíjú sí mi kó lè mú ẹ̀gàn mi kúrò láàárín àwọn èèyàn.”+
26 Nígbà tó pé oṣù mẹ́fà, Ọlọ́run rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì+ sí ìlú kan ní Gálílì tí wọ́n ń pè ní Násárẹ́tì, 27 sí wúńdíá kan+ tó jẹ́ àfẹ́sọ́nà* ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù ní ilé Dáfídì, orúkọ wúńdíá náà ni Màríà.+ 28 Nígbà tí áńgẹ́lì náà wọlé, ó sọ fún un pé: “Mo kí ọ o, ìwọ ẹni tí a ṣojúure sí gidigidi, Jèhófà* wà pẹ̀lú rẹ.” 29 Àmọ́ ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì náà rú obìnrin náà lójú gan-an, ó sì fẹ́ mọ ohun tí irú ìkíni yìí túmọ̀ sí. 30 Áńgẹ́lì náà wá sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, Màríà, torí o ti rí ojúure Ọlọ́run. 31 Wò ó! o máa lóyún,* o sì máa bí ọmọkùnrin kan,+ kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.+ 32 Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá,+ wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ,+ Jèhófà* Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀,+ 33 ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”+
34 Àmọ́ Màríà sọ fún áńgẹ́lì náà pé: “Báwo ló ṣe máa ṣẹlẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé mi ò bá ọkùnrin lò pọ̀?”+ 35 Áńgẹ́lì náà dá a lóhùn pé: “Ẹ̀mí mímọ́ máa bà lé ọ,+ agbára Ẹni Gíga Jù Lọ sì máa ṣíji bò ọ́. Ìdí nìyẹn tí a fi máa pe ẹni tí o bí ní mímọ́,+ Ọmọ Ọlọ́run.+ 36 Wò ó! Èlísábẹ́tì mọ̀lẹ́bí rẹ náà ti lóyún ọmọkùnrin kan, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, oyún rẹ̀ sì ti pé oṣù mẹ́fà báyìí, ẹni táwọn èèyàn ń pè ní àgàn; 37 torí pé kò sí ìkéde kankan tí kò ní ṣeé ṣe* fún Ọlọ́run.”+ 38 Màríà wá sọ pé: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!* Kó ṣẹlẹ̀ sí mi bí o ṣe kéde rẹ̀.” Ni áńgẹ́lì náà bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
39 Màríà wá gbéra ní àkókò yẹn, ó sì yára rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ olókè, sí ìlú kan ní Júdà, 40 ó wọ ilé Sekaráyà, ó sì kí Èlísábẹ́tì. 41 Ó ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Èlísábẹ́tì gbọ́ tí Màríà kí i, ọmọ inú rẹ̀ sọ, ẹ̀mí mímọ́ sì kún inú Èlísábẹ́tì, 42 ó sì ké jáde pé: “Ìbùkún ni fún ọ láàárín àwọn obìnrin, ìbùkún sì ni fún èso inú rẹ! 43 Báwo ló ṣe jẹ́ pé èmi ni àǹfààní yìí tọ́ sí, pé kí ìyá Olúwa mi wá sọ́dọ̀ mi? 44 Torí wò ó! bí mo ṣe gbọ́ tí o kí mi, ayọ̀ mú kí ọmọ tó wà ní inú mi sọ kúlú. 45 Aláyọ̀ náà ni obìnrin tó gbà gbọ́, torí pé gbogbo ohun tí a sọ fún un látọ̀dọ̀ Jèhófà* ló máa ṣẹ délẹ̀délẹ̀.”
46 Màríà wá sọ pé: “Ọkàn* mi gbé Jèhófà* ga,+ 47 ẹ̀mí mi ò sì yéé yọ̀ gidigidi torí Ọlọ́run Olùgbàlà mi,+ 48 torí pé ó ti ṣíjú wo ipò tó rẹlẹ̀ tí ẹrúbìnrin rẹ̀ wà.+ Torí, wò ó! láti ìsinsìnyí lọ, gbogbo ìran máa kéde pé aláyọ̀ ni mí,+ 49 torí pé Ẹni tó lágbára ti ṣe àwọn ohun ńláńlá fún mi, mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀+ 50 àti pé láti ìran dé ìran, ó ń ṣàánú àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.+ 51 Ó ti fi apá rẹ̀ ṣe ohun tó lágbára; ó ti tú àwọn tó jẹ́ agbéraga nínú èrò ọkàn wọn ká.+ 52 Ó ti rẹ àwọn ọkùnrin alágbára sílẹ̀ látorí ìtẹ́,+ ó sì gbé àwọn tó rẹlẹ̀ ga;+ 53 ó ti fi àwọn ohun rere tẹ́ àwọn tí ebi ń pa lọ́rùn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,+ ó sì ti mú kí àwọn tó lọ́rọ̀ lọ lọ́wọ́ òfo. 54 Ó ti wá ran Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó rántí àánú rẹ̀,+ 55 bó ṣe sọ fún àwọn baba ńlá wa, fún Ábúráhámù àti ọmọ* rẹ̀,+ títí láé.” 56 Màríà dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ fún nǹkan bí oṣù mẹ́ta, ó sì pa dà sí ilé rẹ̀.
57 Nígbà tí ó tó àkókò tí Èlísábẹ́tì máa bímọ, ó bí ọmọkùnrin kan. 58 Àwọn aládùúgbò àti àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ gbọ́ pé Jèhófà* ti ṣàánú rẹ̀ gidigidi, wọ́n sì bá a yọ̀.+ 59 Ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá láti dádọ̀dọ́* ọmọ kékeré náà,+ wọ́n sì fẹ́ sọ ọ́ ní Sekaráyà, orúkọ bàbá rẹ̀. 60 Àmọ́ ìyá rẹ̀ fèsì pé: “Rárá o! Jòhánù la máa pè é.” 61 Ni wọ́n bá sọ fún un pé: “Kò sí mọ̀lẹ́bí rẹ kankan tó ń jẹ́ orúkọ yìí.” 62 Torí náà, wọ́n fara ṣàpèjúwe fún bàbá rẹ̀ láti béèrè orúkọ tó fẹ́ sọ ọ́. 63 Ó wá ní kí wọ́n fún òun ní wàláà kan, ó sì kọ ọ́ pé: “Jòhánù ni orúkọ rẹ̀.”+ Ni ẹnu bá ya gbogbo wọn. 64 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹnu rẹ̀ là, ahọ́n rẹ̀ ṣí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀,+ ó ń yin Ọlọ́run. 65 Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tó ń gbé àdúgbò wọn, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn gbogbo nǹkan yìí ní gbogbo ilẹ̀ olókè ní Jùdíà. 66 Gbogbo àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà sì fi sọ́kàn, wọ́n ń sọ pé: “Kí ni ọmọ kékeré yìí máa dà?” Torí ọwọ́ Jèhófà* wà lára rẹ̀ lóòótọ́.
67 Ẹ̀mí mímọ́ wá kún inú Sekaráyà bàbá rẹ̀, ó sì sọ tẹ́lẹ̀, ó ní: 68 “Ẹ yin Jèhófà,* Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ torí ó ti yíjú sí àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ti gbà wọ́n sílẹ̀.+ 69 Ó ti gbé ìwo ìgbàlà*+ kan dìde fún wa ní ilé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀,+ 70 bó ṣe gbẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ nígbà àtijọ́ sọ̀rọ̀,+ 71 nípa ìgbàlà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó kórìíra wa;+ 72 láti ṣàánú lórí ọ̀rọ̀ àwọn baba ńlá wa, kó sì rántí májẹ̀mú mímọ́ rẹ̀,+ 73 ohun tó búra fún Ábúráhámù baba ńlá wa,+ 74 pé lẹ́yìn tí a bá ti gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, òun máa fún wa ní àǹfààní láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un láìbẹ̀rù, 75 pẹ̀lú ìdúróṣinṣin àti òdodo níwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ wa. 76 Àmọ́ ní tìrẹ, ọmọ kékeré, wòlíì Ẹni Gíga Jù Lọ la ó máa pè ọ́, torí o máa lọ níwájú Jèhófà* láti múra àwọn ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,+ 77 láti fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìmọ̀ ìgbàlà nípa dídárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n,+ 78 torí ojú àánú Ọlọ́run wa. Pẹ̀lú àánú yìí, ojúmọ́ kan máa mọ́ wa láti ibi gíga, 79 láti fún àwọn tó jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú ní ìmọ́lẹ̀,+ kó sì darí ẹsẹ̀ wa ní ọ̀nà àlàáfíà.”
80 Ọmọ kékeré náà wá dàgbà, ó sì di alágbára nínú ẹ̀mí, ó wà ní aṣálẹ̀ títí di ọjọ́ tó fi ara rẹ̀ han Ísírẹ́lì ní gbangba.
2 Nígbà yẹn, Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pàṣẹ pé kí gbogbo èèyàn tó ń gbé láyé lọ forúkọ sílẹ̀. 2 (Ìgbà tí Kúírínọ́sì jẹ́ gómìnà Síríà ni ìforúkọsílẹ̀ àkọ́kọ́ yìí wáyé.) 3 Gbogbo èèyàn sì lọ forúkọ sílẹ̀, kálukú lọ sí ìlú rẹ̀. 4 Jósẹ́fù+ náà gòkè lọ láti Gálílì, ó gbéra ní ìlú Násárẹ́tì lọ sí Jùdíà, sí ìlú Dáfídì, tí wọ́n ń pè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ torí pé ó jẹ́ ará ilé àti ìdílé Dáfídì. 5 Ó lọ forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú Màríà, tí a ti fún un pé kó fi ṣe aya bí a ṣe ṣèlérí,+ tí kò sì ní pẹ́ bímọ.+ 6 Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ó tó àkókò fún un láti bímọ. 7 Ó sì bí ọmọkùnrin rẹ̀, àkọ́bí,+ ó wá fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran,+ torí pé kò sí àyè fún wọn ní ibi táwọn èèyàn ń dé sí.
8 Ní agbègbè yẹn kan náà, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń gbé níta, wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru. 9 Lójijì, áńgẹ́lì Jèhófà* dúró síwájú wọn, ògo Jèhófà* tàn yòò yí wọn ká, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 10 Àmọ́ áńgẹ́lì náà sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù, torí, ẹ wò ó! mò ń kéde ìhìn rere ayọ̀ ńláǹlà fún yín, èyí tí gbogbo èèyàn máa ní. 11 Torí lónìí, a bí olùgbàlà kan+ fún yín ní ìlú Dáfídì,+ òun ni Kristi Olúwa.+ 12 Àmì tí ẹ máa rí nìyí: Ẹ máa rí ọmọ jòjòló kan tí wọ́n fi ọ̀já wé, tí wọ́n tẹ́ sínú ibùjẹ ẹran.” 13 Lójijì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun ọ̀run+ wá bá áńgẹ́lì náà, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń sọ pé: 14 “Ògo ni fún Ọlọ́run ní ibi gíga lókè àti àlàáfíà fún àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà* ní ayé.”
15 Torí náà, nígbà tí àwọn áńgẹ́lì náà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ara wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ká lọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀, ohun tí Jèhófà* jẹ́ ká mọ̀.” 16 Wọ́n yára lọ, wọ́n sì rí Màríà àti Jósẹ́fù àti ọmọ jòjòló náà nínú ibùjẹ ẹran tí wọ́n tẹ́ ẹ sí. 17 Nígbà tí wọ́n rí èyí, wọ́n sọ ohun tí a ti sọ fún wọn nípa ọmọ kékeré yìí. 18 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tó gbọ́ ohun tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà sọ fún wọn, 19 àmọ́ Màríà bẹ̀rẹ̀ sí í pa gbogbo ọ̀rọ̀ yìí mọ́, ó sì ń parí èrò nínú ọkàn rẹ̀.+ 20 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà wá pa dà lọ, wọ́n ń fògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì ń yìn ín torí gbogbo ohun tí wọ́n gbọ́, tí wọ́n sì rí, bí a ṣe sọ fún wọn gẹ́lẹ́.
21 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ, nígbà tí àkókò tó láti dádọ̀dọ́ rẹ̀,*+ wọ́n sọ ọ́ ní Jésù, orúkọ tí áńgẹ́lì náà pè é kí wọ́n tó lóyún rẹ̀.+
22 Bákan náà, nígbà tí àkókò tó láti wẹ̀ wọ́n mọ́ bó ṣe wà nínú Òfin Mósè,+ wọ́n gbé e wá sí Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè fún Jèhófà,* 23 bí a ṣe kọ ọ́ sínú Òfin Jèhófà* pé: “Gbogbo àkọ́bí ọkùnrin* ni ká pè ní mímọ́ fún Jèhófà.”*+ 24 Wọ́n sì rúbọ bí Òfin Jèhófà* ṣe sọ: “ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.”+
25 Wò ó! ọkùnrin kan wà ní Jerúsálẹ́mù tó ń jẹ́ Síméónì, olódodo àti ẹni tó ní ìfọkànsìn ni ọkùnrin yìí, ó ń dúró de ìgbà tí a máa tu Ísírẹ́lì nínú,+ ẹ̀mí mímọ́ sì wà lára rẹ̀. 26 Bákan náà, a ti ṣí i payá fún un látọ̀run wá nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ pé kò ní rí ikú kó tó rí Kristi Jèhófà.* 27 Ẹ̀mí darí rẹ̀, ó sì wá sínú tẹ́ńpìlì, bí àwọn òbí ọmọ náà ṣe gbé Jésù ọmọ kékeré náà wọlé láti ṣe ohun tí wọ́n máa ń ṣe lábẹ́ Òfin fún un,+ 28 ó gba ọmọ náà, ó sì gbé e dání, ó yin Ọlọ́run, ó sì sọ pé: 29 “Ní báyìí, Olúwa Ọba Aláṣẹ, ò ń jẹ́ kí ẹrú rẹ lọ ní àlàáfíà+ bí o ṣe kéde, 30 torí ojú mi ti rí ohun tí o máa fi gbani là,+ 31 èyí tí o pèsè níṣojú gbogbo èèyàn,+ 32 ìmọ́lẹ̀+ láti mú ìbòjú kúrò lójú àwọn orílẹ̀-èdè+ àti ògo àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì.” 33 Ohun tó ń sọ nípa ọmọ náà sì ń ya bàbá àti ìyá rẹ̀ lẹ́nu. 34 Bákan náà, Síméónì súre fún wọn, ó sì sọ fún Màríà, ìyá ọmọ náà pé: “Wò ó! A ti yan ọmọ yìí kí ọ̀pọ̀ ní Ísírẹ́lì lè ṣubú,+ kí ọ̀pọ̀ sì tún dìde,+ kó sì lè jẹ́ àmì tí wọ́n máa sọ̀rọ̀ lòdì sí + 35 (àní, a máa fi idà gígùn kan gún ọ*),+ kí a lè mọ ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń rò lọ́kàn.”
36 Wòlíì obìnrin kan wà, Ánà lorúkọ rẹ̀, ọmọbìnrin Fánúẹ́lì ni, láti ẹ̀yà Áṣérì. Obìnrin yìí ti lọ́jọ́ lórí gan-an, ọdún méje ló sì lò nílé ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn ìgbéyàwó,* 37 ó ti di opó, ó sì ti di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84) báyìí. Kì í pa wíwá sí tẹ́ńpìlì jẹ, ó máa ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tọ̀sántòru, ó máa ń gbààwẹ̀, ó sì máa ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀. 38 Ní wákàtí yẹn gan-an, ó wá sí tòsí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó ń sọ̀rọ̀ ọmọ náà fún gbogbo àwọn tó ń dúró de ìdáǹdè Jerúsálẹ́mù.+
39 Torí náà, lẹ́yìn tí wọ́n ṣe gbogbo nǹkan bó ṣe wà nínú Òfin Jèhófà,*+ wọ́n pa dà sí Gálílì, wọ́n lọ sí Násárẹ́tì ìlú wọn.+ 40 Ọmọ kékeré náà wá ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ọgbọ́n kún inú rẹ̀, Ọlọ́run sì ń ṣojúure sí i.+
41 Ó jẹ́ àṣà àwọn òbí rẹ̀ láti máa lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún kí wọ́n lè lọ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá.+ 42 Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá (12), wọ́n gòkè lọ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe nígbà àjọyọ̀ náà.+ 43 Nígbà tí wọ́n parí àjọyọ̀ náà, tí wọ́n sì ń pa dà sílé, ọmọdékùnrin náà, Jésù, ṣì wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn òbí rẹ̀ ò sì mọ̀. 44 Wọ́n rò pé ó wà láàárín àwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò, torí náà, wọ́n ti rin ìrìn ọjọ́ kan kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í wá a kiri láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn ojúlùmọ̀. 45 Àmọ́ nígbà tí wọn ò rí i, wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì fara balẹ̀ wá a. 46 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n rí i nínú tẹ́ńpìlì, ó jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, ó ń fetí sí wọn, ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè. 47 Àmọ́ léraléra ni ẹnu ń ya gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí òye tó ní àti bó ṣe ń dáhùn.+ 48 Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ rí i, ẹnu yà wọ́n, ìyá rẹ̀ wá sọ fún un pé: “Ọmọ, kí ló dé tí o fi ṣe báyìí sí wa? Wò ó, èmi àti bàbá rẹ ti dààmú gan-an bá a ṣe ń wá ọ kiri.” 49 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń wá mi? Ṣé ẹ ò mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?”+ 50 Ṣùgbọ́n ohun tó ń sọ fún wọn ò yé wọn.
51 Ó wá tẹ̀ lé wọn sọ̀ kalẹ̀, wọ́n pa dà sí Násárẹ́tì, ó sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.*+ Bákan náà, ìyá rẹ̀ rọra fi gbogbo ọ̀rọ̀ yìí sọ́kàn.+ 52 Ọgbọ́n Jésù wá ń pọ̀ sí i, ó ń dàgbà sí i, ó sì ń rí ojúure Ọlọ́run àti èèyàn.
3 Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún àkóso Tìbéríù Késárì, nígbà tí Pọ́ńtíù Pílátù jẹ́ gómìnà Jùdíà, tí Hẹ́rọ́dù*+ sì jẹ́ alákòóso agbègbè* Gálílì, tí Fílípì arákùnrin rẹ̀ jẹ́ alákòóso agbègbè ilẹ̀ Ítúréà àti Tírákónítì, tí Lísáníà sì jẹ́ alákòóso agbègbè Ábílénè, 2 nígbà ayé Ánásì olórí àlùfáà àti Káyáfà,+ Jòhánù+ ọmọ Sekaráyà gbọ́ ìkéde látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nínú aginjù.+
3 Ó wá lọ sí gbogbo ìgbèríko tó yí Jọ́dánì ká, ó ń wàásù pé kí àwọn èèyàn ṣèrìbọmi láti fi hàn pé wọ́n ti ronú pìwà dà, kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà,+ 4 bí a ṣe kọ ọ́ sínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Àìsáyà pé: “Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé: ‘Ẹ ṣètò ọ̀nà Jèhófà!* Ẹ mú àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ́.+ 5 Gbogbo àfonífojì gbọ́dọ̀ ga sókè, kí gbogbo òkè ńlá àti òkè kéékèèké tẹ́jú; àwọn ọ̀nà tó wọ́ gbọ́dọ̀ tọ́, kí àwọn ọ̀nà tó rí gbágungbàgun sì dán; 6 gbogbo ẹran ara* sì máa rí ìgbàlà Ọlọ́run.’”*+
7 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn èrò tó ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ṣèrìbọmi pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, ta ló kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ sá fún ìbínú tó ń bọ̀?+ 8 Torí náà, ẹ so èso tó yẹ ìrònúpìwàdà. Ẹ má bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ara yín pé, ‘A ní Ábúráhámù ní baba.’ Torí mò ń sọ fún yín pé Ọlọ́run lè gbé àwọn ọmọ dìde fún Ábúráhámù látinú àwọn òkúta yìí. 9 Ó dájú pé àáké ti wà níbi gbòǹgbò àwọn igi báyìí. Torí náà, gbogbo igi tí kò bá so èso tó dáa la máa gé lulẹ̀, tí a sì máa jù sínú iná.”+
10 Àwọn èrò náà wá ń bi í pé: “Kí wá ni ká ṣe?” 11 Ó sọ fún wọn pé: “Kí ẹni tó ní aṣọ méjì* fún ẹni tí kò ní lára aṣọ rẹ̀, kí ẹni tó sì ní ohun tó máa jẹ ṣe ohun kan náà.”+ 12 Kódà, àwọn agbowó orí wá, kí wọ́n lè ṣèrìbọmi,+ wọ́n sì sọ fún un pé: “Olùkọ́, kí ni ká ṣe?” 13 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má gbà* ju iye owó orí lọ.”+ 14 Bákan náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ológun ń bi í pé: “Kí ni ká ṣe?” Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe fòòró ẹnikẹ́ni* tàbí kí ẹ fẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni,+ àmọ́ ẹ jẹ́ kí àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbà* tẹ́ yín lọ́rùn.”
15 Àwọn èèyàn náà ń fojú sọ́nà, gbogbo wọn sì ń ronú nípa Jòhánù lọ́kàn wọn pé, “Àbí òun ni Kristi náà?”+ 16 Jòhánù dá wọn lóhùn, ó sọ fún gbogbo wọn pé: “Ní tèmi, mò ń fi omi batisí yín, àmọ́ ẹni tó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, ẹni tí mi ò tó tú okùn bàtà rẹ̀.+ Ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ àti iná batisí yín.+ 17 Ṣọ́bìrì tó fi ń fẹ́ ọkà wà lọ́wọ́ rẹ̀, kó lè gbá ibi ìpakà rẹ̀ mọ́ tónítóní, kó sì kó àlìkámà* jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí rẹ̀, àmọ́ ó máa fi iná tí kò ṣeé pa sun ìyàngbò.”*
18 Ó tún gba àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyànjú míì, ó sì ń kéde ìhìn rere fún àwọn èèyàn. 19 Àmọ́ torí pé Jòhánù ti bá Hẹ́rọ́dù alákòóso agbègbè náà wí nípa Hẹrodíà ìyàwó arákùnrin rẹ̀ àti nípa gbogbo ohun burúkú tí Hẹ́rọ́dù ṣe, 20 ó tún fi èyí kún gbogbo ohun tó ṣe yẹn: Ó ti Jòhánù mọ́nú ẹ̀wọ̀n.+
21 Nígbà tí gbogbo àwọn èèyàn náà ṣèrìbọmi, Jésù náà ṣèrìbọmi.+ Bó ṣe ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀,+ 22 ẹ̀mí mímọ́ bà lé e, ẹ̀mí náà rí bí àdàbà, ohùn kan sì dún láti ọ̀run pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, àyànfẹ́; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”+
23 Nǹkan bí ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún+ ni Jésù+ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀, bí wọ́n sì ṣe rò, ó jẹ́ ọmọ
Jósẹ́fù,+
ọmọ Hélì,
24 ọmọ Mátátì,
ọmọ Léfì,
ọmọ Mélíkì,
ọmọ Jánááì,
ọmọ Jósẹ́fù,
25 ọmọ Mátátíà,
ọmọ Émọ́sì,
ọmọ Náhúmù,
ọmọ Ésílì,
ọmọ Nágáì,
26 ọmọ Máátì,
ọmọ Mátátíà,
ọmọ Séméínì,
ọmọ Jósẹ́kì,
ọmọ Jódà,
27 ọmọ Jóánánì,
ọmọ Résà,
ọmọ Serubábélì,+
ọmọ Ṣéálítíẹ́lì,+
ọmọ Nẹ́rì,
28 ọmọ Mélíkì,
ọmọ Ádì,
ọmọ Kósámù,
ọmọ Élímádámù,
ọmọ Éérì,
29 ọmọ Jésù,
ọmọ Élíésérì,
ọmọ Jórímù,
ọmọ Mátátì,
ọmọ Léfì,
30 ọmọ Símíónì,
ọmọ Júdásì,
ọmọ Jósẹ́fù,
ọmọ Jónámù,
ọmọ Élíákímù,
31 ọmọ Méléà,
ọmọ Ménà,
ọmọ Mátátà,
ọmọ Nátánì,+
ọmọ Dáfídì,+
ọmọ Óbédì,+
ọmọ Bóásì,+
ọmọ Sálímọ́nì,+
ọmọ Náṣónì, +
33 ọmọ Ámínádábù,
ọmọ Áánì,
ọmọ Hésírónì,
ọmọ Pérésì,+
ọmọ Júdà,+
ọmọ Ísákì,+
ọmọ Ábúráhámù,+
ọmọ Térà,+
ọmọ Náhórì,+
ọmọ Réù,+
ọmọ Pélégì, +
ọmọ Ébérì,+
ọmọ Ṣélà,+
36 ọmọ Káínánì,
ọmọ Ápákíṣádì,+
ọmọ Ṣémù,+
ọmọ Nóà,+
ọmọ Lámékì,+
ọmọ Énọ́kù,
ọmọ Járédì,+
ọmọ Máháláléélì,+
ọmọ Káínánì,+
ọmọ Sẹ́ẹ̀tì,+
ọmọ Ádámù,+
ọmọ Ọlọ́run.
4 Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí mímọ́ kún inú Jésù, ó sì kúrò ní Jọ́dánì, ẹ̀mí wá darí rẹ̀ káàkiri nínú aginjù+ 2 fún ogójì (40) ọjọ́, Èṣù sì dán an wò.+ Kò jẹ nǹkan kan láwọn ọjọ́ yẹn, torí náà, lẹ́yìn àwọn ọjọ́ náà, ebi bẹ̀rẹ̀ sí í pa á. 3 Ni Èṣù bá sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún òkúta yìí pé kó di búrẹ́dì.” 4 Àmọ́ Jésù dá a lóhùn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè.’”+
5 Ó wá mú un gòkè, ó sì fi gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí à ń gbé hàn án lójú ẹsẹ̀.+ 6 Èṣù wá sọ fún un pé: “Gbogbo àṣẹ yìí àti ògo wọn ni màá fún ọ, torí a ti fi lé mi lọ́wọ́,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì wù mí ni màá fún. 7 Torí náà, tí o bá jọ́sìn níwájú mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, gbogbo rẹ̀ máa jẹ́ tìẹ.” 8 Jésù dá a lóhùn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘Jèhófà* Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’”+
9 Lẹ́yìn náà, ó mú un lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó mú un dúró lórí ògiri orí òrùlé* tẹ́ńpìlì, ó sì sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ láti ibí yìí,+ 10 torí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó máa pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ, pé kí wọ́n pa ọ́ mọ́’ 11 àti pé, ‘Wọ́n á fi ọwọ́ wọn gbé ọ, kí o má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbá òkúta.’”+ 12 Jésù dá a lóhùn pé: “A sọ ọ́ pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà* Ọlọ́run rẹ wò.’”+ 13 Torí náà, lẹ́yìn tí Èṣù dán an wò tán, ó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ títí di ìgbà míì tó wọ̀.+
14 Jésù wá pa dà sí Gálílì+ nínú agbára ẹ̀mí. Ìròyìn rere nípa rẹ̀ sì tàn káàkiri gbogbo ìgbèríko tó wà ní àyíká. 15 Bákan náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, gbogbo èèyàn sì ń bọlá fún un.
16 Lẹ́yìn náà, ó lọ sí Násárẹ́tì,+ níbi tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, ó wọnú sínágọ́gù,+ ó sì dìde dúró láti kàwé, bó ṣe máa ń ṣe ní ọjọ́ Sábáàtì. 17 Torí náà, wọ́n fún un ní àkájọ ìwé wòlíì Àìsáyà, ó ṣí àkájọ ìwé náà, ó sì rí ibi tí wọ́n kọ ọ́ sí pé: 18 “Ẹ̀mí Jèhófà* wà lára mi, torí ó ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn aláìní. Ó rán mi láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú, pé àwọn afọ́jú máa pa dà ríran, láti mú kí àwọn tí wọ́n tẹ̀ rẹ́ máa lọ lómìnira,+ 19 láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.”*+ 20 Ló bá ká àkájọ ìwé náà, ó dá a pa dà fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó; gbogbo àwọn tó wà nínú sínágọ́gù sì tẹjú mọ́ ọn. 21 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún wọn pé: “Òní ni ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ yìí ṣẹ.”+
22 Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́rìí rẹ̀ ní rere, ẹnu ń yà wọ́n torí àwọn ọ̀rọ̀ tó tuni lára tó ń ti ẹnu rẹ̀ jáde,+ wọ́n sì ń sọ pé: “Ọmọ Jósẹ́fù nìyí, àbí òun kọ́?”+ 23 Ló bá sọ fún wọn pé: “Ó dájú pé ẹ máa fi ọ̀rọ̀ yìí bá mi wí pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ sàn. Tún ṣe àwọn ohun tí a gbọ́ pé ó wáyé ní Kápánáúmù ní ìlú rẹ níbí.’”+ 24 Torí náà, ó sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé kò sí wòlíì tí wọ́n máa ń tẹ́wọ́ gbà ní ìlú rẹ̀.+ 25 Bí àpẹẹrẹ, mò ń sọ fún yín ní tòótọ́ pé: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ opó ló wà ní Ísírẹ́lì nígbà ayé Èlíjà, nígbà tí a sé ọ̀run pa fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà, tí ìyàn sì mú gidigidi ní gbogbo ilẹ̀ náà.+ 26 Síbẹ̀, a kò rán Èlíjà sí ìkankan nínú àwọn obìnrin yẹn, àfi opó tó wà ní Sáréfátì nílẹ̀ Sídónì nìkan.+ 27 Bákan náà, ọ̀pọ̀ adẹ́tẹ̀ ló wà ní Ísírẹ́lì nígbà ayé wòlíì Èlíṣà; síbẹ̀ a ò wẹ ìkankan nínú wọn mọ́,* àfi Náámánì ará Síríà.”+ 28 Ni inú bá bí gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nínú sínágọ́gù gan-an,+ 29 wọ́n dìde, wọ́n yára mú un lọ sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì mú un lọ sí téńté òkè tí wọ́n kọ́ ìlú wọn sí, kí wọ́n lè taari rẹ̀ sísàlẹ̀. 30 Àmọ́ ó kọjá láàárín wọn, ó sì ń bá tirẹ̀ lọ.+
31 Ó wá sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Kápánáúmù, ìlú kan ní Gálílì. Ó ń kọ́ wọn ní ọjọ́ Sábáàtì,+ 32 bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ sì yà wọ́n lẹ́nu,+ torí pé ó ń sọ̀rọ̀ tàṣẹtàṣẹ. 33 Ọkùnrin kan wà nínú sínágọ́gù náà tó ní ẹ̀mí kan, ẹ̀mí èṣù àìmọ́, ó sì kígbe pé:+ 34 “Áà! Kí ló pa wá pọ̀, Jésù ará Násárẹ́tì?+ Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́ gan-an, Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run ni ọ́.”+ 35 Àmọ́ Jésù bá a wí, ó ní: “Dákẹ́, kí o sì jáde kúrò nínú rẹ̀.” Torí náà, lẹ́yìn tí ẹ̀mí èṣù náà gbé ọkùnrin náà ṣánlẹ̀ láàárín wọn, ó jáde kúrò nínú rẹ̀ láìṣe é léṣe. 36 Ni ẹnu bá ya gbogbo wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ara wọn pé: “Irú ọ̀rọ̀ wo nìyí? Torí ó ń fi àṣẹ àti agbára lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́, wọ́n sì ń jáde!” 37 Ìròyìn rẹ̀ wá ń tàn káàkiri ṣáá dé gbogbo ìgbèríko tó wà ní àyíká.
38 Lẹ́yìn tó kúrò nínú sínágọ́gù, ó wọ ilé Símónì. Akọ ibà ń ṣe ìyá ìyàwó Símónì, wọ́n sì ní kó ràn án lọ́wọ́.+ 39 Torí náà, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ obìnrin náà, ó sì bá ibà náà wí, ibà náà sì lọ. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin náà dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
40 Àmọ́ nígbà tí oòrùn ń wọ̀, gbogbo àwọn tí èèyàn wọn ń ṣàìsàn, tí wọ́n ní oríṣiríṣi àrùn, mú wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Bó ṣe ń gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó ń wò wọ́n sàn.+ 41 Àwọn ẹ̀mí èṣù tún jáde lára ọ̀pọ̀ èèyàn, wọ́n ń kígbe, wọ́n sì ń sọ pé: “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”+ Àmọ́ ó bá wọn wí, kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀,+ torí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi.+
42 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó kúrò lọ sí ibì kan tó dá.+ Àmọ́ àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí í wá a,* wọ́n dé ibi tó wà, wọ́n sì gbìyànjú láti dá a dúró kó má bàa kúrò lọ́dọ̀ wọn. 43 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Mo tún gbọ́dọ̀ kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú míì, torí pé nítorí èyí la ṣe rán mi.”+ 44 Torí náà, ó ń wàásù nínú àwọn sínágọ́gù Jùdíà.
5 Nígbà kan tí àwọn èrò ń fún mọ́ ọn, tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ adágún omi Jẹ́nẹ́sárẹ́tì.*+ 2 Ó sì rí ọkọ̀ ojú omi méjì tó gúnlẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ adágún náà, àmọ́ àwọn apẹja ti jáde kúrò nínú wọn, wọ́n sì ń fọ àwọ̀n wọn.+ 3 Ó wọnú ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, èyí tó jẹ́ ti Símónì, ó sì sọ fún un pé kó wa ọkọ̀ náà lọ síwájú díẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀. Ó wá jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èrò náà látinú ọkọ̀ ojú omi náà. 4 Nígbà tó sọ̀rọ̀ tán, ó sọ fún Símónì pé: “Wa ọkọ̀ lọ síbi tí omi ti jìn, kí ẹ sì rọ àwọ̀n yín sísàlẹ̀ láti kó ẹja.” 5 Àmọ́ Símónì fèsì pé: “Olùkọ́, gbogbo òru la fi ṣiṣẹ́ kára, a ò sì rí nǹkan kan mú,+ ṣùgbọ́n torí ohun tí o sọ, màá rọ àwọ̀n náà sísàlẹ̀.” 6 Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja ni wọ́n kó.* Kódà, àwọ̀n wọn bẹ̀rẹ̀ sí í fà ya.+ 7 Torí náà, wọ́n ṣẹ́wọ́ sí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, nínú ọkọ̀ ojú omi kejì, pé kí wọ́n wá ran àwọn lọ́wọ́, wọ́n wá, wọ́n sì rọ́ ẹja kún inú ọkọ̀ méjèèjì, débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì. 8 Nígbà tí Símónì Pétérù rí èyí, ó wólẹ̀ síbi orúnkún Jésù, ó ní: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Olúwa, torí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.” 9 Ìdí ni pé ẹnu ya òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gan-an torí bí ẹja tí wọ́n kó ṣe pọ̀ tó, 10 bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí lára Jémíìsì àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè,+ tí àwọn àti Símónì jọ ń ṣiṣẹ́. Àmọ́ Jésù sọ fún Símónì pé: “Má bẹ̀rù mọ́. Láti ìsinsìnyí lọ, wàá máa mú àwọn èèyàn láàyè.”+ 11 Wọ́n wá dá àwọn ọkọ̀ ojú omi náà pa dà sórí ilẹ̀, wọ́n pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.+
12 Ní àkókò míì, nígbà tó wà nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú náà, wò ó! ọkùnrin kan wà tí ẹ̀tẹ̀ bò! Nígbà tó tajú kán rí Jésù, ó wólẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé: “Olúwa, tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.”+ 13 Torí náà, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó ní: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí o mọ́.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà pòórá lára rẹ̀.+ 14 Ó wá pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé kó má sọ fún ẹnikẹ́ni, ó ní: “Àmọ́ lọ, kí o fi ara rẹ han àlùfáà, kí o sì ṣe ọrẹ láti wẹ̀ ọ́ mọ́, bí Mósè ṣe sọ,+ kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.”+ 15 Àmọ́ ìròyìn rẹ̀ ń tàn káàkiri ṣáá, èrò rẹpẹtẹ sì máa ń kóra jọ kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, kó sì lè wò wọ́n sàn.+ 16 Ṣùgbọ́n ó sábà máa ń lọ sí àwọn ibi tó dá láti gbàdúrà.
17 Lọ́jọ́ kan, bó ṣe ń kọ́ni, àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ Òfin tí wọ́n wá láti gbogbo abúlé Gálílì àti Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù jókòó níbẹ̀; agbára Jèhófà* sì wà lára rẹ̀ láti wo àwọn èèyàn sàn.+ 18 Wò ó! àwọn ọkùnrin kan fi ibùsùn gbé ọkùnrin kan tó ní àrùn rọpárọsẹ̀, wọ́n sì ń gbìyànjú láti gbé e wọlé, kí wọ́n lè gbé e síwájú Jésù.+ 19 Torí náà, nígbà tí wọn ò rí ọ̀nà gbé e wọlé torí àwọn èrò náà, wọ́n gun orí òrùlé, wọ́n sì fi ibùsùn náà sọ̀ ọ́ kalẹ̀ gba àárín ohun tí wọ́n fi bo ilé náà, wọ́n gbé e sọ̀ kalẹ̀ sí àárín àwọn tó wà níwájú Jésù. 20 Nígbà tó rí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní, ó sọ pé: “Ọkùnrin yìí, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+ 21 Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó, wọ́n ń sọ pé: “Ta lẹni tó ń sọ̀rọ̀ òdì yìí? Ta ló lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini yàtọ̀ sí Ọlọ́run nìkan?”+ 22 Àmọ́ Jésù fòye mọ ohun tí wọ́n ń rò, ó sì dá wọn lóhùn pé: “Kí lẹ̀ ń rò lọ́kàn yín? 23 Èwo ló rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ àbí láti sọ pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn’? 24 Àmọ́ kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ èèyàn ní àṣẹ ní ayé láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini—” ó sọ fún ọkùnrin tó ní àrùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “Mò ń sọ fún ọ, Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sílé rẹ.”+ 25 Ló bá dìde níwájú wọn, ó gbé ohun tó ti ń dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó ń yin Ọlọ́run lógo. 26 Ẹnu ya gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, wọ́n ń sọ pé: “A ti rí àwọn nǹkan àgbàyanu lónìí!”
27 Lẹ́yìn náà, ó jáde lọ, ó sì rí agbowó orí kan tó ń jẹ́ Léfì, tó jókòó sí ọ́fíìsì àwọn agbowó orí, ó sì sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.”+ 28 Ló bá fi ohun gbogbo sílẹ̀, ó dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e. 29 Léfì wá gbà á lálejò, ó se àsè rẹpẹtẹ fún un nílé rẹ̀, àwọn agbowó orí àti àwọn míì tó ń bá wọn jẹun* sì pọ̀ gan-an níbẹ̀.+ 30 Ni àwọn Farisí àti àwọn tó jẹ́ akọ̀wé òfin lára wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n ń sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, tí ẹ sì ń bá wọn mu?”+ 31 Jésù fún wọn lésì pé: “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀.+ 32 Kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè kí wọ́n ronú pìwà dà, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”+
33 Wọ́n sọ fún un pé: “Léraléra ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù máa ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ń jẹ, wọ́n sì ń mu.”+ 34 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ ò lè mú kí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó gbààwẹ̀ tí ọkọ ìyàwó bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, àbí ẹ lè ṣe bẹ́ẹ̀? 35 Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó+ kúrò lọ́dọ̀ wọn ní tòótọ́; wọ́n máa wá gbààwẹ̀ láwọn ọjọ́ yẹn.”+
36 Ó tún sọ àpèjúwe kan fún wọn pé: “Kò sí ẹni tó máa gé lára aṣọ àwọ̀lékè tuntun, kó sì rán ègé náà mọ́ ara aṣọ tó ti gbó. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ègé aṣọ tuntun náà máa ya kúrò, aṣọ tí wọ́n gé lára aṣọ tuntun náà kò sì ní bá èyí tó ti gbó mu.+ 37 Bákan náà, kò sí ẹni tó máa rọ wáìnì tuntun sínú àpò awọ tó ti gbó. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, wáìnì tuntun náà máa bẹ́ àpò awọ náà, ó máa dà nù, àpò náà sì máa bà jẹ́. 38 Àmọ́ inú àpò awọ tuntun la gbọ́dọ̀ rọ wáìnì tuntun sí. 39 Kò sẹ́ni tó máa fẹ́ mu wáìnì tuntun lẹ́yìn tó ti mu wáìnì tó ti pẹ́, torí ó máa sọ pé, ‘Èyí tó ti pẹ́ yẹn dáa.’”
6 Ní sábáàtì kan, ó ń gba oko ọkà kọjá, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń ya àwọn erín ọkà* jẹ,+ wọ́n sì ń fi ọwọ́ ra á.+ 2 Ni àwọn kan nínú àwọn Farisí bá sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe ohun tí kò bófin mu lọ́jọ́ Sábáàtì?”+ 3 Àmọ́ Jésù fún wọn lésì pé: “Ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe rí ni, nígbà tí ebi ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀?+ 4 Bó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tó gba àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú,* tó sì jẹ ẹ́, tó tún fún àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹ, èyí tí kò bófin mu fún ẹnì kankan láti jẹ, àfi àwọn àlùfáà nìkan?”+ 5 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ọmọ èèyàn ni Olúwa Sábáàtì.”+
6 Ní sábáàtì míì,+ ó wọ inú sínágọ́gù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni. Ọkùnrin kan sì wà níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ.+ 7 Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí wá ń ṣọ́ Jésù lójú méjèèjì, wọ́n ń wò ó bóyá ó máa ṣe ìwòsàn ní Sábáàtì, kí wọ́n lè rí ọ̀nà láti fẹ̀sùn kàn án. 8 Àmọ́ ó mọ ohun tí wọ́n ń rò,+ torí náà, ó sọ fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé: “Dìde, kí o dúró ní àárín.” Ó dìde, ó sì dúró síbẹ̀. 9 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Mò ń bi yín, Ṣé ó bófin mu ní Sábáàtì láti ṣe rere tàbí láti ṣe ibi, láti gba ẹ̀mí* là tàbí láti pa á run?”+ 10 Lẹ́yìn tó wo gbogbo wọn yí ká, ó sọ fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. 11 Àmọ́ wọ́n bínú gidigidi láìronú jinlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn sọ ohun tí wọ́n lè ṣe sí Jésù.
12 Nígbà yẹn, ó lọ sórí òkè lọ́jọ́ kan láti gbàdúrà,+ ó sì fi gbogbo òru gbàdúrà sí Ọlọ́run.+ 13 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì yan méjìlá (12) lára wọn, ó tún pè wọ́n ní àpọ́sítélì,+ àwọn ni: 14 Símónì, tó tún pè ní Pétérù, Áńdérù arákùnrin rẹ̀, Jémíìsì, Jòhánù, Fílípì,+ Bátólómíù, 15 Mátíù, Tọ́másì,+ Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì, Símónì tí wọ́n ń pè ní “onítara,” 16 Júdásì ọmọ Jémíìsì àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ẹni tó di ọ̀dàlẹ̀.
17 Wọ́n jọ sọ̀ kalẹ̀, ó wá dúró síbì kan tó tẹ́jú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì pọ̀ gan-an níbẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn èèyàn láti gbogbo Jùdíà, Jerúsálẹ́mù àti agbègbè etí òkun ní Tírè àti Sídónì, tí wọ́n wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì rí ìwòsàn àwọn àrùn wọn. 18 Àwọn tí ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú pàápàá rí ìwòsàn. 19 Gbogbo èrò náà sì fẹ́ fọwọ́ kàn án, torí pé agbára ń jáde lára rẹ̀,+ ó sì ń wo gbogbo wọn sàn.
20 Ó wá gbójú sókè wo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé:
“Aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ aláìní, torí pé tiyín ni Ìjọba Ọlọ́run.+
21 “Aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ebi ń pa báyìí, torí pé ẹ máa yó.+
“Aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sunkún báyìí, torí pé ẹ máa rẹ́rìn-ín.+
22 “Aláyọ̀ ni yín nígbàkigbà tí àwọn èèyàn bá kórìíra yín+ àti nígbàkigbà tí wọ́n bá ta yín nù,+ tí wọ́n pẹ̀gàn yín, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn yín* pé * ẹni burúkú ni yín nítorí Ọmọ èèyàn. 23 Ẹ yọ̀ ní ọjọ́ yẹn, kí ẹ sì fò sókè tayọ̀tayọ̀, torí, ẹ wò ó! èrè yín pọ̀ ní ọ̀run, torí àwọn ohun yẹn kan náà ni àwọn baba ńlá wọn máa ń ṣe sí àwọn wòlíì.+
24 “Àmọ́, ó mà ṣe fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀ o,+ torí pé ẹ̀ ń rí ìtùnú gbà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.+
25 “Ó mà ṣe fún ẹ̀yin tí ẹ yó báyìí o, torí ebi máa pa yín.
“Ó mà ṣe fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rẹ́rìn-ín báyìí o, torí ẹ máa ṣọ̀fọ̀, ẹ sì máa sunkún.+
26 “Ó mà ṣe fún yín o, nígbàkigbà tí gbogbo èèyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín dáadáa,+ torí ohun tí àwọn baba ńlá wọn ṣe sí àwọn wòlíì èké nìyí.
27 “Àmọ́ mò ń sọ fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fetí sílẹ̀ pé: Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ máa ṣe rere sí àwọn tó kórìíra yín,+ 28 ẹ máa súre fún àwọn tó ń gégùn-ún fún yín, kí ẹ máa gbàdúrà fún àwọn tó ń fi ìwọ̀sí lọ̀ yín.+ 29 Tí ẹnì kan bá gbá ọ ní etí* kan, yí ìkejì sí i; tí ẹnì kan bá sì gba aṣọ àwọ̀lékè rẹ, má ṣe lọ́ra láti fún un ní aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú.+ 30 Gbogbo àwọn tó bá ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ rẹ ni kí o fún,+ ẹni tó bá sì ń mú àwọn nǹkan rẹ lọ, má sọ pé kó dá a pa dà.
31 “Bákan náà, bí ẹ ṣe fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ máa ṣe sí wọn.+
32 “Tí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ yín, àǹfààní kí ló jẹ́ fún yín? Torí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wọn.+ 33 Tí ẹ bá sì ń ṣe rere sí àwọn tó ń ṣe rere sí yín, àǹfààní kí ló jẹ́ fún yín? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. 34 Bákan náà, tí ẹ bá ń yá* àwọn tí ẹ retí pé wọ́n máa san án pa dà ní nǹkan, àǹfààní kí ló jẹ́ fún yín?+ Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá máa ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní nǹkan kí wọ́n lè rí ohun kan náà gbà pa dà. 35 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ẹ máa ṣe rere, kí ẹ sì máa yáni ní nǹkan láìretí ohunkóhun pa dà;+ èrè yín máa wá pọ̀, ẹ sì máa jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, torí ó máa ń ṣoore fún àwọn aláìmoore àti àwọn ẹni burúkú.+ 36 Ẹ máa jẹ́ aláàánú, bí Baba yín ṣe jẹ́ aláàánú.+
37 “Bákan náà, ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, ó sì dájú pé a ò ní dá yín lẹ́jọ́;+ ẹ yéé dáni lẹ́bi, ó sì dájú pé a ò ní dá yín lẹ́bi. Ẹ máa dárí jini,* a sì máa dárí jì yín.*+ 38 Ẹ sọ ọ́ di àṣà láti máa fúnni, àwọn èèyàn sì máa fún yín.+ Wọ́n máa da òṣùwọ̀n tó dáa, tí a kì mọ́lẹ̀, tí a mì pọ̀, tó sì kún àkúnwọ́sílẹ̀, sórí itan yín. Torí òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni la máa fi díwọ̀n pa dà fún yín.”
39 Ó tún sọ àpèjúwe kan fún wọn pé: “Afọ́jú kò lè fi afọ́jú mọ̀nà, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀? Inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa ṣubú sí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+ 40 Akẹ́kọ̀ọ́* ò ga ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, àmọ́ gbogbo ẹni tí a bá kọ́ lọ́nà tó pé máa dà bí olùkọ́ rẹ̀. 41 Kí ló wá dé tí ò ń wo pòròpórò tó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, àmọ́ tí o ò kíyè sí igi ìrólé tó wà nínú ojú tìrẹ?+ 42 Báwo lo ṣe lè sọ fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, jẹ́ kí n bá ọ yọ pòròpórò tó wà nínú ojú rẹ,’ nígbà tó jẹ́ pé ìwọ fúnra rẹ ò rí igi ìrólé tó wà nínú ojú tìrẹ? Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ, ìgbà yẹn lo máa wá ríran kedere láti yọ pòròpórò tó wà nínú ojú arákùnrin rẹ.
43 “Torí kò sí igi rere tó máa ń mú èso jíjẹrà jáde, kò sì sí igi jíjẹrà tó máa ń mú èso rere jáde.+ 44 Torí èso igi kọ̀ọ̀kan la fi ń mọ̀ ọ́n.+ Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn kì í kó èso ọ̀pọ̀tọ́ jọ látorí igi ẹ̀gún, wọn kì í sì í gé èso àjàrà lára igi ẹlẹ́gùn-ún. 45 Ẹni rere máa ń mú ohun rere jáde látinú ìṣúra rere tó wà nínú ọkàn rẹ̀, àmọ́ ẹni burúkú máa ń mú ohun burúkú jáde látinú ìṣúra burúkú rẹ̀; torí lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.+
46 “Kí ló wá dé tí ẹ̀ ń pè mí ní ‘Olúwa! Olúwa!’ àmọ́ tí ẹ ò ṣe àwọn ohun tí mo sọ?+ 47 Gbogbo ẹni tó bá wá sọ́dọ̀ mi, tó ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi, tó sì ń ṣe é, màá fi irú ẹni tó jẹ́ hàn yín:+ 48 Ó dà bí ọkùnrin kan tó ń kọ́ ilé kan, tó walẹ̀ jìn, tó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí àpáta. Nígbà tó yá, tí àkúnya omi dé, odò ya lu ilé náà, àmọ́ kò lágbára tó láti mì í, torí wọ́n kọ́ ọ dáadáa.+ 49 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́, tí kò sì ṣe nǹkan kan,+ ó dà bí ọkùnrin kan tó kọ́ ilé kan sórí ilẹ̀ láìsí ìpìlẹ̀. Odò ya lu ilé náà, ó sì wó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ilé náà sì bà jẹ́ gan-an.”
7 Nígbà tó parí gbogbo ọ̀rọ̀ tó fẹ́ bá àwọn èèyàn náà sọ, ó wọ Kápánáúmù. 2 Ẹrú ọ̀gágun kan, tí ọ̀gá rẹ̀ fẹ́ràn gan-an ń ṣàìsàn gidigidi, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.+ 3 Nígbà tí ọ̀gágun náà gbọ́ nípa Jésù, ó rán àwọn kan lára àwọn àgbààgbà àwọn Júù sí i, kí wọ́n sọ fún un pé kó wá, kó lè mú ẹrú òun lára dá. 4 Wọ́n wá bá Jésù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ taratara, wọ́n ní: “Ó yẹ lẹ́ni tí o lè ṣe é fún, 5 torí ó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wa, òun ló sì kọ́ sínágọ́gù wa.” 6 Torí náà, Jésù tẹ̀ lé wọn. Àmọ́ nígbà tó sún mọ́ ilé ọ̀gágun náà, ọ̀gágun náà ti rán àwọn ọ̀rẹ́ pé kí wọ́n sọ fún un pé: “Ọ̀gá, má ṣèyọnu, torí mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè wá sábẹ́ òrùlé rẹ̀.+ 7 Ìdí nìyẹn tí mi ò fi ka ara mi sí ẹni tó yẹ láti wá sọ́dọ̀ rẹ. Àmọ́, sọ̀rọ̀, kí o sì jẹ́ kí ara ìránṣẹ́ mi yá. 8 Torí èmi náà wà lábẹ́ àṣẹ, mo sì ní àwọn ọmọ ogun tó wà lábẹ́ àṣẹ mi, tí mo bá sọ fún eléyìí pé, ‘Lọ!’ á lọ, tí mo bá sọ fún ẹlòmíì pé, ‘Wá!’ á wá, tí mo bá sì sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe báyìí!’ á ṣe é.” 9 Nígbà tí Jésù gbọ́ àwọn nǹkan yìí, ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà yà á lẹ́nu, ó wá yíjú sí àwọn èrò tó ń tẹ̀ lé e, ó sì sọ pé: “Mò ń sọ fún yín pé, mi ò tíì rí ẹnì kankan ní Ísírẹ́lì pàápàá tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tó báyìí.”+ 10 Nígbà tí àwọn tí ọkùnrin náà rán wá pa dà sílé, wọ́n rí i pé ara ẹrú náà ti yá.+
11 Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, ó rìnrìn àjò lọ sí ìlú kan tó ń jẹ́ Náínì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti èrò rẹpẹtẹ sì ń bá a rìnrìn àjò. 12 Bó ṣe sún mọ́ ẹnubodè ìlú náà, wò ó! wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, òun nìkan ṣoṣo ni ìyá rẹ̀ bí.*+ Yàtọ̀ síyẹn, opó ni obìnrin náà. Èrò rẹpẹtẹ tún tẹ̀ lé e látinú ìlú náà. 13 Nígbà tí Olúwa tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é,+ ó sì sọ fún un pé: “Má sunkún mọ́.”+ 14 Ló bá sún mọ́ wọn, ó fọwọ́ kan àga ìgbókùú* náà, àwọn tó gbé e sì dúró. Ó wá sọ pé: “Ọ̀dọ́kùnrin, mo sọ fún ọ, dìde!”+ 15 Ọkùnrin tó ti kú náà wá dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, Jésù sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.+ 16 Ẹ̀rù ba gbogbo wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo, wọ́n ní: “A ti gbé wòlíì ńlá kan dìde láàárín wa”+ àti pé, “Ọlọ́run ti yíjú sí àwọn èèyàn rẹ̀.”+ 17 Ìròyìn yìí nípa rẹ̀ sì tàn káàkiri gbogbo Jùdíà àti gbogbo ìgbèríko tó wà ní àyíká.
18 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù wá ròyìn gbogbo nǹkan yìí fún un.+ 19 Torí náà, Jòhánù pe méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì rán wọn sí Olúwa pé kí wọ́n bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tó Ń Bọ̀,+ àbí ká máa retí ẹlòmíì?” 20 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, àwọn ọkùnrin náà sọ pé: “Jòhánù Arinibọmi rán wa sí ọ láti béèrè pé, ‘Ṣé ìwọ ni Ẹni Tó Ń Bọ̀, àbí ká máa retí ẹlòmíì?’” 21 Ní wákàtí yẹn, ó ṣe ìwòsàn fún ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn,+ àwọn tó ní àrùn tó le àti àwọn tó ní ẹ̀mí burúkú, ó sì mú kí ọ̀pọ̀ afọ́jú pa dà ríran. 22 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ ti rí, tí ẹ sì ti gbọ́ fún Jòhánù: Àwọn afọ́jú ti ń ríran báyìí,+ àwọn arọ ń rìn, à ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn,+ à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń sọ ìhìn rere fún àwọn aláìní.+ 23 Aláyọ̀ ni ẹni tí kò rí ohunkóhun tó máa mú kó kọsẹ̀ nínú mi.”+
24 Nígbà tí àwọn tí Jòhánù rán wá lọ tán, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn èrò náà nípa Jòhánù pé: “Kí lẹ jáde lọ wò ní aginjù? Ṣé esùsú* tí atẹ́gùn ń gbé kiri ni?+ 25 Kí wá lẹ jáde lọ wò? Ṣé ọkùnrin tó wọ aṣọ àtàtà* ni?+ Ṣebí inú ilé àwọn ọba ni àwọn tó wọ aṣọ tó rẹwà, tí wọ́n sì ń gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ máa ń wà? 26 Ká sòótọ́, kí wá lẹ jáde lọ wò? Ṣé wòlíì ni? Àní mo sọ fún yín, ó ju wòlíì lọ dáadáa.+ 27 Ẹni yìí la kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi ṣáájú rẹ,* ẹni tó máa ṣètò ọ̀nà rẹ dè ọ́.’+ 28 Mò ń sọ fún yín, nínú àwọn tí obìnrin bí, kò sí ẹni tó tóbi ju Jòhánù lọ, àmọ́ ẹni kékeré nínú Ìjọba Ọlọ́run tóbi jù ú lọ.”+ 29 (Nígbà tí gbogbo èèyàn àti àwọn agbowó orí gbọ́ èyí, wọ́n kéde pé olódodo ni Ọlọ́run, torí Jòhánù ti ṣe ìrìbọmi fún wọn.+ 30 Àmọ́ àwọn Farisí àti àwọn tó mọ Òfin dunjú kò ka ìmọ̀ràn* tí Ọlọ́run fún wọn sí,+ torí pé kò tíì ṣe ìrìbọmi fún wọn.)
31 “Ta ni màá wá fi àwọn èèyàn ìran yìí wé, ta ni wọ́n sì jọ?+ 32 Wọ́n dà bí àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n jókòó nínú ọjà, tí wọ́n sì ń ké pe ara wọn, tí wọ́n ń sọ pé: ‘A fun fèrè fún yín, àmọ́ ẹ ò jó; a pohùn réré ẹkún, àmọ́ ẹ ò sunkún.’ 33 Bákan náà, Jòhánù Arinibọmi wá, kò jẹ búrẹ́dì, kò sì mu wáìnì,+ àmọ́ ẹ sọ pé, ‘Ẹlẹ́mìí èṣù ni.’ 34 Ọmọ èèyàn wá, ó ń jẹ, ó sì ń mu, àmọ́ ẹ sọ pé: ‘Wò ó! Ọkùnrin alájẹkì, ti kò mọ̀ ju kó mu wáìnì lọ, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀!’+ 35 Síbẹ̀ náà, a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo* nípasẹ̀ gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀.”*+
36 Ọkàn lára àwọn Farisí ń rọ̀ ọ́ ṣáá pé kó wá bá òun jẹun. Torí náà, ó wọ ilé Farisí náà, ó sì jókòó* sídìí tábìlì. 37 Wò ó! obìnrin kan tí wọ́n mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìlú náà gbọ́ pé ó ń jẹun* nínú ilé Farisí náà, ó sì mú orùba* alabásítà tí wọ́n rọ òróró onílọ́fínńdà sí wá.+ 38 Ó dúró sẹ́yìn níbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sunkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wá ń fi irun orí rẹ̀ nù ún kúrò. Bákan náà, obìnrin náà rọra fi ẹnu ko ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì da òróró onílọ́fínńdà náà sí i. 39 Nígbà tí Farisí tó pè é wá rí èyí, ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Tó bá jẹ́ pé wòlíì ni ọkùnrin yìí lóòótọ́, ó máa mọ obìnrin tó ń fọwọ́ kàn án yìí àti irú ẹni tó jẹ́, pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”+ 40 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Símónì, mo fẹ́ sọ nǹkan kan fún ọ.” Ó fèsì pé: “Olùkọ́, sọ ọ́!”
41 “Ọkùnrin méjì jẹ ayánilówó kan ní gbèsè; ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) owó dínárì,* àmọ́ èkejì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta (50). 42 Nígbà tí wọn ò ní ohunkóhun tí wọ́n máa fi san án pa dà fún un, ó dárí ji àwọn méjèèjì pátápátá. Torí náà, èwo nínú wọn ló máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jù?” 43 Símónì dá a lóhùn pé: “Mo rò pé ẹni tó dárí púpọ̀ jì ni.” Ó sọ fún un pé: “Bí o ṣe dájọ́ yẹn tọ́.” 44 Ó wá yíjú sí obìnrin náà, ó sì sọ fún Símónì pé: “Ṣé o rí obìnrin yìí? Mo wọ ilé rẹ; o ò fún mi ní omi láti fọ ẹsẹ̀ mi. Àmọ́ obìnrin yìí fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ mi, ó sì fi irun rẹ̀ nù ún kúrò. 45 O ò fẹnu kò mí lẹ́nu, àmọ́ obìnrin yìí, láti wákàtí tí mo ti wọlé, kò yéé rọra fi ẹnu ko ẹsẹ̀ mi. 46 O ò da òróró sí orí mi, àmọ́ obìnrin yìí da òróró onílọ́fínńdà sí ẹsẹ̀ mi. 47 Torí èyí, mò ń sọ fún ọ, bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tiẹ̀ pọ̀,* a dárí wọn jì í,+ torí ó ní ìfẹ́ púpọ̀. Àmọ́ ẹni tí a dárí díẹ̀ jì ní ìfẹ́ díẹ̀.” 48 Ó wá sọ fún un pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+ 49 Àwọn tó jókòó sídìí tábìlì pẹ̀lú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ láàárín ara wọn pé: “Ta ni ọkùnrin yìí tó tún lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini?”+ 50 Àmọ́ ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ ti gbà ọ́ là;+ máa lọ ní àlàáfíà.”
8 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó ń rin ìrìn àjò láti ìlú dé ìlú àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.+ Àwọn Méjìlá náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀, 2 bákan náà ni àwọn obìnrin kan tó ti lé ẹ̀mí burúkú kúrò lára wọn, tó sì ti wo àìsàn wọn sàn: Màríà tí wọ́n ń pè ní Magidalénì, tí ẹ̀mí èṣù méje jáde lára rẹ̀; 3 Jòánà+ ìyàwó Kúsà, ọkùnrin tí Hẹ́rọ́dù fi ṣe alábòójútó; Sùsánà; àti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin míì, tí wọ́n ń fi àwọn ohun ìní wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.+
4 Nígbà tí èrò rẹpẹtẹ ti kóra jọ pẹ̀lú àwọn tó ń lọ bá a láti ìlú dé ìlú, ó fi àpèjúwe kan sọ̀rọ̀,+ ó ní: 5 “Afúnrúgbìn kan jáde lọ fún irúgbìn rẹ̀. Bó ṣe ń fún irúgbìn, díẹ̀ lára rẹ̀ já bọ́ sí etí ọ̀nà, wọ́n tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ṣà á jẹ.+ 6 Àwọn kan já bọ́ sórí àpáta, lẹ́yìn tí wọ́n sì rú jáde, wọ́n gbẹ dà nù torí pé omi ò rin ibẹ̀.+ 7 Àwọn míì já bọ́ sáàárín ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún tí wọ́n sì jọ dàgbà fún wọn pa.+ 8 Àmọ́ àwọn míì já bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, lẹ́yìn tí wọ́n sì rú jáde, wọ́n so èso ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100).”+ Bó ṣe sọ àwọn nǹkan yìí, ó gbóhùn sókè, ó ní: “Kí ẹni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”+
9 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í ní ohun tí àpèjúwe yìí túmọ̀ sí.+ 10 Ó sọ pé: “Ẹ̀yin la yọ̀ǹda fún pé kí ẹ lóye àwọn àṣírí mímọ́ Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́ àpèjúwe+ ló jẹ́ fún àwọn yòókù, kó lè jẹ́ pé, bí wọ́n tiẹ̀ ń wò, lásán ni wọ́n á máa wò àti pé bí wọ́n tiẹ̀ ń gbọ́, kó má ṣe yé wọn.+ 11 Ìtumọ̀ àpèjúwe náà nìyí: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni irúgbìn náà.+ 12 Àwọn ti etí ọ̀nà ni àwọn tó gbọ́, tí Èṣù wá lẹ́yìn náà, tó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò nínú ọkàn wọn, kí wọ́n má bàa gbà gbọ́, kí wọ́n sì rí ìgbàlà.+ 13 Àwọn ti orí àpáta ni àwọn tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gbà á, àmọ́ àwọn yìí kò ní gbòǹgbò. Wọ́n gbà gbọ́ fúngbà díẹ̀, àmọ́ ní àsìkò ìdánwò, wọ́n yẹsẹ̀.+ 14 Ní ti àwọn tó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, àwọn yìí ló gbọ́, àmọ́ torí pé àníyàn, ọrọ̀+ àti adùn ayé yìí + pín ọkàn wọn níyà, a fún wọn pa pátápátá, wọn ò sì mú kí ohunkóhun dàgbà.+ 15 Ní ti èyí tó wà lórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, àwọn yìí ló jẹ́ pé, lẹ́yìn tí wọ́n fi ọkàn tó tọ́, tó sì dáa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà,+ wọ́n fi sọ́kàn, wọ́n sì ń fi ìfaradà so èso.+
16 “Kò sí ẹni tó máa tan fìtílà, tó máa wá fi nǹkan bò ó tàbí kó gbé e sábẹ́ ibùsùn, àmọ́ orí ọ̀pá fìtílà ló máa gbé e sí, kí àwọn tó bá wọlé lè rí ìmọ́lẹ̀.+ 17 Torí kò sí nǹkan tí a fi pa mọ́ tí kò ní hàn kedere, kò sí ohun tí a rọra tọ́jú tí a ò ṣì ní mọ̀, tí kò sì ní hàn sí gbangba.+ 18 Torí náà, ẹ kíyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀, torí ẹnikẹ́ni tó bá ní, a máa fi kún ohun tó ní,+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tí kò bá ní, a máa gba ohun tó rò pé òun ní pàápàá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”+
19 Ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀+ wá a wá, àmọ́ wọn ò ráyè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ torí èrò wà níbẹ̀.+ 20 Torí náà, wọ́n sọ fún un pé: “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró níta, wọ́n fẹ́ rí ọ.” 21 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn yìí tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é.”+
22 Lọ́jọ́ kan, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká sọdá sí òdìkejì adágún.” Torí náà, wọ́n ṣíkọ̀.+ 23 Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń lọ lórí omi, ó sùn lọ. Ìjì líle kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í jà lórí adágún náà, omi wá ń rọ́ wọnú ọkọ̀ wọn, wọ́n sì wà nínú ewu.+ 24 Torí náà, wọ́n lọ jí i, wọ́n ní: “Olùkọ́, Olùkọ́, a ti fẹ́ ṣègbé!” Ló bá dìde, ó bá ìjì àti omi tó ń ru gùdù náà wí, wọ́n sì rọlẹ̀, wọ́n pa rọ́rọ́.+ 25 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò nígbàgbọ́ ni?” Àmọ́ ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n ń sọ fúnra wọn pé: “Ta lẹni yìí gan-an? Torí ó ń pàṣẹ fún ìjì àti omi pàápàá, wọ́n sì ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.”+
26 Wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté tó wà ní agbègbè àwọn ará Gérásà,+ èyí tó wà ní òdìkejì Gálílì. 27 Bí Jésù ṣe sọ̀ kalẹ̀, ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu pàdé rẹ̀ látinú ìlú náà. Ó pẹ́ tí kò ti wọṣọ, kì í sì í gbé inú ilé, àárín àwọn ibojì* ló ń gbé.+ 28 Bó ṣe rí Jésù, ó kígbe, ó sì wólẹ̀ síwájú rẹ̀, ó wá ké jáde pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ? Mo bẹ̀ ọ́, má ṣe dá mi lóró.”+ 29 (Torí Jésù ti ń pàṣẹ fún ẹ̀mí àìmọ́ náà pé kó jáde lára ọkùnrin náà. Ẹ̀mí náà ti gbá ọkùnrin náà mú lọ́pọ̀ ìgbà,*+ léraléra sì ni wọ́n fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, tí wọ́n sì ń ṣọ́ ọ, àmọ́ ó máa ń já àwọn ìdè náà, ẹ̀mí èṣù náà á sì mú kó lọ sí àwọn ibi tó dá.) 30 Jésù bi í pé: “Kí lorúkọ rẹ?” Ó sọ pé: “Líjíónì,” torí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí èṣù ti wọ inú rẹ̀. 31 Wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ pé kó má pàṣẹ fún àwọn láti lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.+ 32 Ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀+ tó pọ̀ ń jẹun níbẹ̀ lórí òkè náà, torí náà, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó gba àwọn láyè láti wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ó sì gbà wọ́n láyè.+ 33 Ni àwọn ẹ̀mí èṣù náà bá jáde lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ọ̀wọ́ ẹran náà rọ́ kọjá ní etí òkè* sínú adágún, wọ́n sì kú sínú omi. 34 Àmọ́ nígbà tí àwọn darandaran rí ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá lọ, wọ́n sì ròyìn rẹ̀ nínú ìlú àti ní ìgbèríko.
35 Torí náà, àwọn èèyàn jáde lọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Wọ́n wá bá Jésù, wọ́n sì rí ọkùnrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde lára rẹ̀, ó ti wọṣọ, orí rẹ̀ sì ti wálé, ó jókòó síbi ẹsẹ̀ Jésù, ni ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n. 36 Àwọn tí wọ́n rí i ròyìn fún wọn nípa bí ara ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà ṣe yá. 37 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láti agbègbè àwọn ará Gérásà ní àyíká ibẹ̀ wá sọ fún Jésù pé kó kúrò lọ́dọ̀ àwọn, torí pé ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Torí náà, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kó lè máa lọ. 38 Àmọ́ ọkùnrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde lára rẹ̀ ń bẹ̀ ẹ́ ṣáá pé òun fẹ́ bá a lọ, ṣùgbọ́n ó ní kí ọkùnrin náà máa lọ, ó ní:+ 39 “Pa dà sílé, kí o sì máa ròyìn ohun tí Ọlọ́run ṣe fún ọ.” Torí náà, ó lọ, ó ń kéde ohun tí Jésù ṣe fún un káàkiri gbogbo ìlú náà.
40 Nígbà tí Jésù pa dà dé, àwọn èrò náà tẹ́wọ́ gbà á tinútinú, torí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀.+ 41 Àmọ́ wò ó! ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jáírù wá; ọkùnrin yìí ni alága sínágọ́gù. Ó wólẹ̀ síbi ẹsẹ̀ Jésù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé kó wá sí ilé òun,+ 42 torí pé ọmọbìnrin kan ṣoṣo tó bí,* tó jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlá (12), ń kú lọ.
Bí Jésù ṣe ń lọ, àwọn èrò ń fún mọ́ ọn. 43 Obìnrin kan wà tó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀+ fún ọdún méjìlá (12), kò sì tíì rí ìwòsàn lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni.+ 44 Obìnrin náà sún mọ́ ọn láti ẹ̀yìn, ó sì fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì dáwọ́ dúró lójú ẹsẹ̀. 45 Jésù wá sọ pé: “Ta ló fọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn ń sọ pé àwọn kọ́, Pétérù sọ pé: “Olùkọ́, àwọn èrò ń há ọ mọ́, wọ́n sì ń fún mọ́ ọ.”+ 46 Àmọ́ Jésù sọ pé: “Ẹnì kan fọwọ́ kàn mí, torí mo mọ̀ pé agbára+ jáde lára mi.” 47 Nígbà tí obìnrin náà rí i pé òun ò lè fara pa mọ́ mọ́, ó wá, jìnnìjìnnì bò ó, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sọ ohun tó mú kí òun fọwọ́ kàn án níwájú gbogbo èèyàn àti bí ara òun ṣe yá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 48 Àmọ́ ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà.”+
49 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, aṣojú alága sínágọ́gù wá, ó ní: “Ọmọbìnrin rẹ ti kú; má yọ Olùkọ́ lẹ́nu mọ́.”+ 50 Nígbà tí Jésù gbọ́ èyí, ó dá a lóhùn pé: “Má bẹ̀rù, ṣáà ti ní ìgbàgbọ́, ara ọmọ náà sì máa yá.”+ 51 Nígbà tó dé ilé náà, kò jẹ́ kí ẹnì kankan bá òun wọlé àfi Pétérù, Jòhánù, Jémíìsì pẹ̀lú bàbá àti ìyá ọmọ náà. 52 Àmọ́ gbogbo èèyàn ń sunkún, wọ́n sì ń lu ara wọn bí wọ́n ṣe ń dárò torí ọmọ náà. Torí náà, ó sọ pé: “Ẹ má sunkún mọ́,+ torí kò kú, ó ń sùn ni.”+ 53 Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń fi ṣẹlẹ́yà, torí wọ́n mọ̀ pé ọmọ náà ti kú. 54 Àmọ́ ó dì í lọ́wọ́ mú, ó sì pè é, ó ní: “Ọmọ, dìde!”+ 55 Ẹ̀mí rẹ̀*+ sì pa dà, ó dìde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,+ ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n fún un ní nǹkan tó máa jẹ. 56 Àwọn òbí rẹ̀ ò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, àmọ́ ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ẹnì kankan.+
9 Ó wá pe àwọn Méjìlá náà jọ, ó fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀mí èṣù,+ kí wọ́n sì máa ṣe ìwòsàn.+ 2 Ó rán wọn jáde láti wàásù Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa múni lára dá, 3 ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe gbé ohunkóhun dání fún ìrìn àjò náà, ì báà jẹ́ ọ̀pá, àpò oúnjẹ, oúnjẹ tàbí owó;* ẹ má sì mú aṣọ méjì.*+ 4 Àmọ́ ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ilé kan, ẹ dúró síbẹ̀, kí ẹ sì lọ láti ibẹ̀.+ 5 Ibikíbi tí àwọn èèyàn ò bá sì ti gbà yín, tí ẹ bá ń kúrò ní ìlú yẹn, ẹ gbọn iyẹ̀pẹ̀ ẹsẹ̀ yín dà nù, kó lè jẹ́ ẹ̀rí lòdì sí wọn.”+ 6 Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri agbègbè náà láti abúlé dé abúlé, wọ́n ń kéde ìhìn rere, wọ́n sì ń ṣe ìwòsàn níbi gbogbo.+
7 Hẹ́rọ́dù* alákòóso agbègbè náà* wá gbọ́ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀ rárá torí àwọn kan ń sọ pé a ti jí Jòhánù dìde,+ 8 àmọ́ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà ti fara hàn, àwọn míì sì ń sọ pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ti dìde.+ 9 Hẹ́rọ́dù sọ pé: “Mo ti bẹ́ Jòhánù lórí.+ Ta wá ni ẹni tí mò ń gbọ́ àwọn nǹkan yìí nípa rẹ̀?” Torí náà, ó ń wá bó ṣe máa rí i.+
10 Nígbà tí àwọn àpọ́sítélì dé, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n ṣe fún Jésù.+ Ó wá mú wọn lọ, wọ́n sì kúrò níbẹ̀ láwọn nìkan lọ sí ìlú kan tó ń jẹ́ Bẹtisáídà.+ 11 Àmọ́ nígbà tí àwọn èrò mọ̀ nípa rẹ̀, wọ́n tẹ̀ lé e. Ó gbà wọ́n tinútinú, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ṣe ìwòsàn fún àwọn tó nílò ìwòsàn.+ 12 Ọjọ́ ti ń lọ. Àwọn méjìlá náà wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ní kí àwọn èrò náà máa lọ, kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé àti ìgbèríko tó wà ní àyíká, kí wọ́n lè ríbi dé sí, kí wọ́n sì lè rí oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ, torí ibi tó dá la wà yìí.”+ 13 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.”+ Wọ́n sọ pé: “A ò ní ju búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì, àfi bóyá tí àwa fúnra wa bá lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn èèyàn yìí.” 14 Ní tòótọ́, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ni wọ́n. Àmọ́ ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ní kí wọ́n jókòó ní àwùjọ-àwùjọ, kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta (50) èèyàn.” 15 Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì ní kí gbogbo wọn jókòó. 16 Lẹ́yìn náà, ó mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre sórí wọn. Ó wá bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n gbé e síwájú àwọn èrò náà. 17 Torí náà, gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).+
18 Lẹ́yìn náà, bó ṣe ń dá gbàdúrà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bá a, ó sì bi wọ́n pé: “Ta ni àwọn èèyàn ń sọ pé mo jẹ́?”+ 19 Wọ́n fèsì pé: “Jòhánù Arinibọmi, àmọ́ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà, àwọn míì sì ń sọ pé ọ̀kan lára àwọn wòlíì àtijọ́ ti dìde.”+ 20 Ó wá bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin ńkọ́, ta lẹ sọ pé mo jẹ́?” Pétérù dáhùn pé: “Kristi ti Ọlọ́run.”+ 21 Àmọ́ ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má sọ èyí fún ẹnì kankan,+ 22 ó sì sọ pé: “Ọmọ èèyàn gbọ́dọ̀ jìyà púpọ̀, àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin máa kọ̀ ọ́, wọ́n máa pa á,+ a sì máa jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”+
23 Ó wá sọ fún gbogbo wọn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀,+ kó máa gbé òpó igi oró* rẹ̀ lójoojúmọ́, kó sì máa tẹ̀ lé mi.+ 24 Torí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gba ẹ̀mí* rẹ̀ là máa pàdánù rẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pàdánù ẹ̀mí* rẹ̀ nítorí mi ni ẹni tó máa gbà á là.+ 25 Lóòótọ́, àǹfààní wo ni èèyàn máa rí tó bá jèrè gbogbo ayé, àmọ́ tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ tàbí tó pa run?+ 26 Torí ẹnikẹ́ni tó bá tijú èmi àti àwọn ọ̀rọ̀ mi, Ọmọ èèyàn máa tijú ẹni yẹn nígbà tó bá dé nínú ògo rẹ̀ àti ti Baba àti ti àwọn áńgẹ́lì mímọ́.+ 27 Àmọ́ mò ń sọ fún yín ní tòótọ́ pé, àwọn kan wà lára àwọn tó dúró síbí yìí tí kò ní tọ́ ikú wò rárá títí wọ́n á fi kọ́kọ́ rí Ìjọba Ọlọ́run.”+
28 Lóòótọ́, ní nǹkan bí ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn tó sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó mú Pétérù, Jòhánù àti Jémíìsì dání, ó sì gun òkè lọ láti gbàdúrà.+ 29 Bó ṣe ń gbàdúrà, ìrísí ojú rẹ̀ yí pa dà, aṣọ rẹ̀ sì di funfun, ó ń tàn yinrin. 30 Wò ó! ọkùnrin méjì ń bá a sọ̀rọ̀; Mósè àti Èlíjà ni. 31 Àwọn yìí fara hàn nínú ògo, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa lílọ rẹ̀, èyí tó máa tó mú ṣẹ ní Jerúsálẹ́mù.+ 32 Oorun ń kun Pétérù àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gidigidi, àmọ́ nígbà tí oorun dá lójú wọn, wọ́n rí ògo rẹ̀+ àti ọkùnrin méjì tó dúró pẹ̀lú rẹ̀. 33 Bí àwọn yìí sì ṣe ń kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Pétérù sọ fún Jésù pé: “Olùkọ́, ó dáa bí a ṣe wà níbí. Torí náà, jẹ́ ká pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.” Kò mọ ohun tó ń sọ. 34 Àmọ́ bó ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí, ìkùukùu* kóra jọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣíji bò wọ́n. Bí wọ́n ṣe wọnú ìkùukùu náà, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n. 35 Ohùn kan+ wá dún látinú ìkùukùu náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi, ẹni tí mo ti yàn.+ Ẹ fetí sí i.”+ 36 Bí ohùn náà ṣe sọ̀rọ̀, Jésù nìkan ṣoṣo ni wọ́n rí. Àmọ́ wọ́n dákẹ́, wọn ò sì sọ ìkankan nínú àwọn ohun tí wọ́n rí fún ẹnì kankan ní àwọn ọjọ́ yẹn.+
37 Lọ́jọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà, èrò rẹpẹtẹ pàdé rẹ̀.+ 38 Wò ó! ọkùnrin kan ké jáde láti àárín èrò náà pé: “Olùkọ́, mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọkùnrin mi, torí òun nìkan ṣoṣo ni mo bí.+ 39 Wò ó! ẹ̀mí kan máa ń gbé e, á sì kígbe lójijì, á fi gìrì mú un, á sì máa yọ ìfófòó lẹ́nu, agbára káká ló fi máa ń fi í sílẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti ṣe é léṣe. 40 Mo bẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ pé kí wọ́n lé e jáde, àmọ́ wọn ò lè ṣe é.” 41 Jésù fèsì pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́ àti oníbékebèke,+ títí dìgbà wo ni màá fi wà pẹ̀lú yín, tí màá sì máa fara dà á fún yín? Mú ọmọkùnrin rẹ wá síbí.”+ 42 Àmọ́ bó ṣe ń sún mọ́ tòsí pàápàá, ẹ̀mí èṣù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì fi gìrì mú un lọ́nà tó le gan-an. Ṣùgbọ́n Jésù bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó wo ọmọ náà sàn, ó sì dá a pa dà fún bàbá rẹ̀. 43 Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí agbára ńlá Ọlọ́run.
Bí ẹnu ṣe ń ya gbogbo wọn sí gbogbo ohun tó ń ṣe, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: 44 “Ẹ fetí sílẹ̀ dáadáa, kí ẹ sì máa rántí àwọn ọ̀rọ̀ yìí, torí a máa fi Ọmọ èèyàn lé àwọn èèyàn lọ́wọ́.”+ 45 Àmọ́ ohun tó ń sọ kò yé wọn. Ní tòótọ́, a fi pa mọ́ fún wọn kó má bàa yé wọn, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí.
46 Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù nínú wọn.+ 47 Jésù mọ ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn, ó wá mú ọmọ kékeré kan, ó mú un dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, 48 ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá gba ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi gba èmi náà; ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí gba Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.+ Torí ẹni tó bá hùwà bí ẹni tó kéré láàárín gbogbo yín ni ẹni tó tóbi.”+
49 Jòhánù fèsì pé: “Olùkọ́, a rí ẹnì kan tó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a sì gbìyànjú láti dá a dúró, torí kì í tẹ̀ lé wa.”+ 50 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Ẹ má gbìyànjú láti dá a dúró, torí ẹnikẹ́ni tí kò bá ta kò yín, tiyín ló ń ṣe.”
51 Bí àwọn ọjọ́ tí a máa gbé e lọ sókè ṣe ń sún mọ́lé,*+ ó pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti lọ sí* Jerúsálẹ́mù. 52 Torí náà, ó ní kí àwọn ìránṣẹ́ lọ ṣáájú rẹ̀. Wọ́n sì lọ, wọ́n wọnú abúlé kan tó jẹ́ ti àwọn ará Samáríà kí wọ́n lè múra sílẹ̀ fún un. 53 Àmọ́ wọn ò tẹ́wọ́ gbà á,+ torí ó ti pinnu* láti lọ sí Jerúsálẹ́mù. 54 Nígbà tí Jémíìsì àti Jòhánù,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, rí èyí, wọ́n sọ pé: “Olúwa, ṣé o fẹ́ ká pe iná sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, kó sì pa wọ́n run?”+ 55 Àmọ́ ó yíjú pa dà, ó sì bá wọn wí. 56 Torí náà, wọ́n lọ sí abúlé míì.
57 Bí wọ́n ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, ẹnì kan sọ fún un pé: “Màá tẹ̀ lé ọ lọ ibikíbi tí o bá lọ.” 58 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, àmọ́ Ọmọ èèyàn kò ní ibì kankan tó máa gbé orí rẹ̀ lé.”+ 59 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún ẹlòmíì pé: “Máa tẹ̀ lé mi.” Ọkùnrin náà sọ pé: “Olúwa, gbà mí láyè kí n kọ́kọ́ lọ sìnkú bàbá mi.”+ 60 Àmọ́ ó sọ fún un pé: “Jẹ́ kí àwọn òkú+ máa sin òkú wọn, àmọ́ ìwọ lọ, kí o sì máa kéde Ìjọba Ọlọ́run káàkiri.”+ 61 Ẹlòmíì tún sọ pé: “Màá tẹ̀ lé ọ, Olúwa, àmọ́ kọ́kọ́ gbà mí láyè láti dágbére fún àwọn ará ilé mi pé ó dìgbòóṣe.” 62 Jésù sọ fún un pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun ìtúlẹ̀, tó wá wo àwọn ohun tó wà lẹ́yìn,+ kò yẹ fún Ìjọba Ọlọ́run.”+
10 Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, Olúwa yan àwọn àádọ́rin (70) míì, ó sì rán wọn jáde ṣáájú rẹ̀ ní méjì-méjì+ sínú gbogbo ìlú àti ibi tí òun fúnra rẹ̀ máa lọ. 2 Ó wá sọ fún wọn pé: “Òótọ́ ni, ìkórè pọ̀, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ò tó nǹkan. Torí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde láti bá a kórè.+ 3 Ẹ lọ! Ẹ wò ó! Mò ń rán yín jáde bí ọ̀dọ́ àgùntàn sí àárín ìkookò.+ 4 Ẹ má ṣe gbé àpò owó, àpò oúnjẹ tàbí bàtà,+ ẹ má sì kí ẹnikẹ́ni* lójú ọ̀nà. 5 Ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ilé kan, ẹ kọ́kọ́ sọ pé: ‘Àlàáfíà fún ilé yìí o.’+ 6 Tí ọ̀rẹ́ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín máa wá sórí rẹ̀. Àmọ́ tí kò bá sí, ó máa pa dà sọ́dọ̀ yín. 7 Torí náà, ẹ dúró sínú ilé yẹn,+ kí ẹ jẹ, kí ẹ sì mu ohun tí wọ́n bá pèsè,+ torí owó iṣẹ́ tọ́ sí òṣìṣẹ́.+ Ẹ má ṣe máa ti ilé kan bọ́ sí òmíràn.
8 “Bákan náà, ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ìlú kan, tí wọ́n sì gbà yín, ẹ jẹ ohun tí wọ́n bá gbé síwájú yín, 9 kí ẹ wo àwọn aláìsàn tó wà níbẹ̀ sàn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé: ‘Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́ ọ̀dọ̀ yín.’+ 10 Àmọ́ ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ìlú kan, tí wọn ò sì gbà yín, ẹ lọ sí àwọn ọ̀nà rẹ̀ tó bọ́ sí gbangba, kí ẹ sì sọ pé: 11 ‘A nu eruku tó lẹ̀ mọ́ wa lẹ́sẹ̀ pàápàá látinú ìlú yín kúrò lòdì sí yín.+ Síbẹ̀, ẹ fi èyí sọ́kàn pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.’ 12 Mò ń sọ fún yín pé Sódómù máa lè fara dà á ní ọjọ́ yẹn ju ìlú yẹn lọ.+
13 “O gbé, ìwọ Kórásínì! O gbé, ìwọ Bẹtisáídà! torí ká ní àwọn iṣẹ́ agbára tó ṣẹlẹ̀ nínú yín bá ṣẹlẹ̀ ní Tírè àti Sídónì ni, tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n á ti ronú pìwà dà, tí wọ́n á jókòó pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú.+ 14 Torí náà, Tírè àti Sídónì máa lè fara dà á lásìkò ìdájọ́ jù yín lọ. 15 Àti ìwọ, Kápánáúmù, ṣé a máa gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Inú Isà Òkú* nísàlẹ̀ lo máa lọ!
16 “Ẹnikẹ́ni tó bá fetí sí yín, fetí sí mi.+ Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì kà yín sí, kò ka èmi náà sí. Bákan náà, ẹnikẹ́ni tí kò bá kà mí sí, kò ka Ẹni tó rán mi náà sí.”+
17 Lẹ́yìn náà, àwọn àádọ́rin (70) náà pa dà dé tayọ̀tayọ̀, wọ́n ń sọ pé: “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá tẹrí ba fún wa torí pé a lo orúkọ rẹ.”+ 18 Ó wá sọ fún wọn pé: “Mo rí i tí Sátánì já bọ́+ bíi mànàmáná láti ọ̀run. 19 Ẹ wò ó! Mo ti fún yín ní àṣẹ láti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn ejò àti àkekèé mọ́lẹ̀ àti àṣẹ lórí gbogbo agbára ọ̀tá,+ kò sì ní sí ohunkóhun tó máa pa yín lára. 20 Ṣùgbọ́n, ẹ má yọ̀ torí pé a mú kí àwọn ẹ̀mí tẹrí ba fún yín, àmọ́ ẹ yọ̀ torí pé a ti kọ orúkọ yín sílẹ̀ ní ọ̀run.”+ 21 Ní wákàtí yẹn gan-an, ó yọ̀ gidigidi nínú ẹ̀mí mímọ́, ó sì sọ pé: “Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, mo yìn ọ́ ní gbangba, torí pé o rọra fi àwọn nǹkan yìí pa mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye,+ o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ọmọdé. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, torí pé ohun tí o fọwọ́ sí nìyí.+ 22 Baba mi ti fa ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́, kò sẹ́ni tó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba, kò sì sẹ́ni tó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ+ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ṣí i payá fún.”+
23 Ó wá yíjú sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì sọ fún wọn láwọn nìkan pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ojú tó rí àwọn ohun tí ẹ̀ ń rí.+ 24 Torí mò ń sọ fún yín pé, ó wu ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba pé kí wọ́n rí àwọn ohun tí ẹ̀ ń rí, àmọ́ wọn ò rí i,+ ó wù wọ́n kí wọ́n gbọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́, àmọ́ wọn ò gbọ́ ọ.”
25 Wò ó! ọkùnrin kan tó mọ Òfin dunjú dìde láti dán an wò, ó sì sọ pé: “Olùkọ́, kí ló yẹ kí n ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 26 Ó sọ fún un pé: “Kí la kọ sínú Òfin? Kí lo kà níbẹ̀?” 27 Ọkùnrin náà dáhùn pé: “‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo okun rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ,’+ kí o sì ‘nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’”+ 28 Ó sọ fún un pé: “Ìdáhùn rẹ tọ́; máa ṣe bẹ́ẹ̀, o sì máa rí ìyè.”+
29 Àmọ́ ọkùnrin náà fẹ́ fi hàn pé olódodo ni òun,+ ó wá sọ fún Jésù pé: “Ta ni ọmọnìkejì mi gan-an?” 30 Jésù dáhùn pé: “Ọkùnrin kan ń sọ̀ kalẹ̀ lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, wọ́n bọ́ ọ láṣọ, wọ́n lù ú, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ nígbà tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. 31 Ó ṣẹlẹ̀ pé àsìkò yẹn ni àlùfáà kan ń sọ̀ kalẹ̀ lọ lójú ọ̀nà yẹn, àmọ́ nígbà tó rí ọkùnrin náà, ó gba ọ̀nà tó wà ní òdìkejì kọjá lọ. 32 Bákan náà, nígbà tí ọmọ Léfì kan dé ibẹ̀, tó sì rí i, ó gba ọ̀nà tó wà ní òdìkejì kọjá lọ. 33 Àmọ́ ará Samáríà+ kan tó ń rìnrìn àjò gba ọ̀nà yẹn ṣàdédé bá a pàdé, nígbà tó rí i, àánú rẹ̀ ṣe é. 34 Torí náà, ó sún mọ́ ọn, ó di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì da òróró àti wáìnì sí i. Ó wá gbé e sórí ẹran rẹ̀, ó gbé e lọ sí ilé ìgbàlejò kan, ó sì tọ́jú rẹ̀. 35 Lọ́jọ́ kejì, ó mú owó dínárì* méjì jáde, ó fún olùtọ́jú ilé náà, ó sì sọ pé: ‘Tọ́jú rẹ̀, ohunkóhun tí o bá sì ná lẹ́yìn èyí, màá san án pa dà fún ọ tí mo bá dé.’ 36 Lójú tìẹ, èwo nínú àwọn mẹ́ta yìí ló fi hàn pé òun jẹ́ ọmọnìkejì+ ọkùnrin tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà náà?” 37 Ó sọ pé: “Ẹni tó ṣàánú rẹ̀ ni.”+ Jésù wá sọ fún un pé: “Ìwọ náà, lọ ṣe ohun kan náà.”+
38 Bí wọ́n ṣe ń lọ, ó wọ abúlé kan. Ibí ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Màtá+ ti gbà á lálejò sínú ilé rẹ̀. 39 Ó tún ní arábìnrin kan tó ń jẹ́ Màríà, ẹni tó jókòó síbi ẹsẹ̀ Olúwa, tó sì ń fetí sí ohun tó ń sọ.* 40 Àmọ́ ní ti Màtá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tó ń ṣe gbà á lọ́kàn. Torí náà, ó wá bá Jésù, ó sì sọ pé: “Olúwa, ṣé o ò rí i bí arábìnrin mi ṣe fi èmi nìkan sílẹ̀ láti bójú tó àwọn nǹkan ni? Sọ fún un pé kó wá ràn mí lọ́wọ́.” 41 Olúwa dá a lóhùn pé: “Màtá, Màtá, ò ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa nǹkan tó pọ̀. 42 Nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo la nílò. Màríà ní tiẹ̀, yan ìpín rere,*+ a ò sì ní gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.”
11 Ní báyìí, ó wà ní ibì kan tó ti ń gbàdúrà, nígbà tó sì ṣe tán, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé: “Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe máa gbàdúrà, bí Jòhánù náà ṣe kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.”
2 Torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Nígbàkigbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ sọ pé: ‘Baba, kí orúkọ rẹ di mímọ́.*+ Kí ìjọba rẹ dé.+ 3 Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa bí a ṣe nílò rẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.+ 4 Kí o sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,+ torí àwa náà máa ń dárí ji gbogbo ẹni tó jẹ wá ní gbèsè;+ má sì mú wa wá sínú ìdẹwò.’”+
5 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ká sọ pé ọ̀kan nínú yín ní ọ̀rẹ́ kan, o wá lọ bá a ní ọ̀gànjọ́ òru, o sì sọ fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́, yá mi ní búrẹ́dì mẹ́ta, 6 torí pé ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sọ́dọ̀ mi láti ìrìn àjò, mi ò sì ní nǹkan kan tí mo lè fún un.’ 7 Àmọ́ ẹni yẹn fèsì látinú ilé, ó ní: ‘Yéé dà mí láàmú. Mo ti ti ilẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi kéékèèké sì wà lọ́dọ̀ mi lórí ibùsùn. Mi ò lè dìde wá fún ọ ní ohunkóhun.’ 8 Mò ń sọ fún yín, bí kò bá tiẹ̀ ní dìde, kó sì fún un ní nǹkan kan torí pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó dájú pé torí pé ó ń fi ìgboyà béèrè léraléra,+ ó máa dìde, ó sì máa fún un ní ohunkóhun tó bá nílò. 9 Torí náà, mò ń sọ fún yín, ẹ máa béèrè,+ a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín.+ 10 Torí gbogbo ẹni tó bá ń béèrè máa rí gbà,+ gbogbo ẹni tó bá ń wá kiri máa rí, gbogbo ẹni tó bá sì ń kan ilẹ̀kùn la máa ṣí i fún. 11 Ká sòótọ́, bàbá wo ló wà láàárín yín tó jẹ́ pé, tí ọmọ rẹ̀ bá béèrè ẹja, ó máa fún un ní ejò dípò ẹja?+ 12 Tàbí tó bá tún béèrè ẹyin, tó máa fún un ní àkekèé? 13 Torí náà, tí ẹ̀yin bá mọ bí ẹ ṣe ń fún àwọn ọmọ yín ní ẹ̀bùn tó dáa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín, mélòómélòó wá ni Baba yín tó wà ní ọ̀run, ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”+
14 Lẹ́yìn náà, ó lé ẹ̀mí èṣù kan jáde, èyí tí kò jẹ́ kí ẹnì kan lè sọ̀rọ̀.+ Lẹ́yìn tí ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin tí kò lè sọ̀rọ̀ náà sọ̀rọ̀, ẹnu sì ya àwọn èrò tó wà níbẹ̀.+ 15 Àmọ́ àwọn kan nínú wọn sọ pé: “Agbára Béélísébúbù,* alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù, ló fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”+ 16 Kí àwọn míì sì lè dán an wò, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un pé kó fi àmì kan+ láti ọ̀run han àwọn. 17 Ó mọ ohun tí wọ́n ń rò,+ ó wá sọ fún wọn pé: “Gbogbo ìjọba tó bá pínyà sí ara rẹ̀ máa pa run, ilé tó bá sì pínyà sí ara rẹ̀ máa wó. 18 Lọ́nà kan náà, tí Sátánì náà bá pínyà sí ara rẹ̀, báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe máa dúró? Torí ẹ sọ pé Béélísébúbù ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. 19 Tó bá jẹ́ agbára Béélísébúbù ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Ìdí nìyí tí wọ́n fi máa jẹ́ adájọ́ yín. 20 Àmọ́ tó bá jẹ́ ìka Ọlọ́run + ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, Ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín lójijì lóòótọ́.+ 21 Tí ọkùnrin alágbára kan, tó dira ogun dáadáa, bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, kò sóhun tó máa ṣe àwọn ohun ìní rẹ̀. 22 Àmọ́ tí ẹnì kan tó lágbára jù ú lọ bá wá gbéjà kò ó, tó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ẹni yẹn máa kó gbogbo ohun ìjà rẹ̀ tó gbẹ́kẹ̀ lé lọ, á sì pín àwọn ohun tó kó lọ́dọ̀ rẹ̀. 23 Ẹnikẹ́ni tí kò bá sí lọ́dọ̀ mi ń ta kò mí, ẹnikẹ́ni tí kò bá sì dara pọ̀ mọ́ mi ń fọ́n ká.+
24 “Tí ẹ̀mí àìmọ́ kan bá jáde nínú ẹnì kan, á gba àwọn ibi tí kò lómi kọjá láti wá ibi ìsinmi, tí kò bá sì rí ìkankan, á sọ pé, ‘Màá pa dà sí ilé mi tí mo ti kúrò.’+ 25 Tó bá sì dé, á rí i pé wọ́n ti gbá ilé náà mọ́, wọ́n sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́. 26 Á wá lọ mú ẹ̀mí méje míì dání, tí wọ́n burú ju òun fúnra rẹ̀ lọ, lẹ́yìn tí wọ́n bá sì wọlé, wọ́n á máa gbé ibẹ̀. Ipò ẹni yẹn nígbẹ̀yìn á wá burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”
27 Bó ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí, obìnrin kan kígbe láàárín èrò, ó sọ fún un pé: “Aláyọ̀ ni ilé ọlẹ̀ tó gbé ọ àti ọmú tí o mu!”+ 28 Àmọ́ ó sọ pé: “Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”+
29 Nígbà tí àwọn èrò ń kóra jọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ìran burúkú ni ìran yìí; ó ń wá àmì, àmọ́ a ò ní fún un ní àmì kankan àfi àmì Jónà.+ 30 Torí bí Jónà+ ṣe di àmì fún àwọn ará Nínéfè, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ èèyàn ṣe máa jẹ́ fún ìran yìí. 31 A máa gbé ọbabìnrin gúúsù+ dìde láti ṣèdájọ́ àwọn èèyàn ìran yìí, ó sì máa dá wọn lẹ́bi, torí ó wá láti ìkángun ayé kó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n Sólómọ́nì. Àmọ́ ẹ wò ó! ohun kan tó ju Sólómọ́nì lọ wà níbí.+ 32 Àwọn ará Nínéfè máa dìde láti ṣèdájọ́ ìran yìí, wọ́n á sì dá a lẹ́bi, torí pé wọ́n ronú pìwà dà nígbà tí Jónà wàásù fún wọn.+ Àmọ́ ẹ wò ó! ohun kan tó ju Jónà lọ wà níbí. 33 Tí ẹnì kan bá tan fìtílà, kò ní gbé e síbi tó fara pa mọ́ tàbí sábẹ́ apẹ̀rẹ̀,* àmọ́ orí ọ̀pá fìtílà ló máa gbé e sí,+ kí àwọn tó bá wọlé lè rí ìmọ́lẹ̀. 34 Ojú rẹ ni fìtílà ara. Tí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan,* gbogbo ara rẹ náà máa mọ́lẹ̀ yòò;* àmọ́ tó bá ń ṣe ìlara,* ara rẹ náà máa ṣókùnkùn.+ 35 Torí náà, wà lójúfò, kí ìmọ́lẹ̀ tó wà nínú rẹ má bàa jẹ́ òkùnkùn. 36 Nítorí náà, tí gbogbo ara rẹ bá mọ́lẹ̀ yòò, tí kò sí apá kankan níbẹ̀ tó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ máa mọ́lẹ̀ yòò bí ìgbà tí fìtílà bá fi ìtànṣán rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ.”
37 Nígbà tó sọ èyí, Farisí kan ní kó wá bá òun jẹun. Ó wá wọlé lọ, ó sì jókòó* sídìí tábìlì. 38 Àmọ́ ó ya Farisí náà lẹ́nu nígbà tó rí i pé kò kọ́kọ́ wẹ ọwọ́* kó tó jẹun.+ 39 Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún un pé: “Ẹ̀yin Farisí, ẹ̀ ń fọ ẹ̀yìn ife àti abọ́ mọ́, àmọ́ wọ̀bìà àti ìwà burúkú kún inú yín.+ 40 Ẹ̀yin aláìlóye! Ṣebí ẹni tó ṣe ẹ̀yìn náà ló ṣe inú, àbí òun kọ́? 41 Àwọn ohun tó wá láti inú ni kí ẹ máa fi ṣe ìtọrẹ àánú,* ẹ wò ó! gbogbo nǹkan nípa yín máa mọ́. 42 Àmọ́ ẹ gbé ẹ̀yin Farisí, torí pé ẹ̀ ń san ìdá mẹ́wàá ewéko míńtì, ewéko rúè àti gbogbo ewébẹ̀* míì,+ àmọ́ ẹ ò ka ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ Ọlọ́run sí! Àwọn nǹkan yìí ló pọn dandan kí ẹ ṣe, àmọ́ kò yẹ kí ẹ ṣàìka àwọn nǹkan yòókù yẹn sí.+ 43 Ẹ gbé, ẹ̀yin Farisí, torí ẹ fẹ́ràn ìjókòó iwájú* nínú sínágọ́gù, ẹ sì fẹ́ràn kí wọ́n máa kí yín níbi ọjà!+ 44 Ẹ gbé, torí pé ẹ dà bí àwọn ibojì* tí kò ṣeé rí kedere,*+ tí àwọn èèyàn ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀!”
45 Ọ̀kan nínú àwọn tó mọ Òfin dunjú dá a lóhùn pé: “Olùkọ́, bí o ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí, ò ń sọ̀rọ̀ sí àwa náà.” 46 Ó wá sọ pé: “Kódà, ẹ̀yin tí ẹ mọ Òfin dunjú gbé, torí pé ẹ̀ ń di àwọn ẹrù tó ṣòroó gbé ru àwọn èèyàn, àmọ́ ẹ̀yin fúnra yín ò fi ọ̀kan nínú àwọn ìka yín kan àwọn ẹrù náà!+
47 “Ẹ gbé, torí pé ẹ̀ ń kọ́ ibojì* àwọn wòlíì, àmọ́ àwọn baba ńlá yín ló pa wọ́n!+ 48 Ó dájú pé ẹ jẹ́ ẹlẹ́rìí àwọn ohun táwọn baba ńlá yín ṣe, síbẹ̀, ẹ fọwọ́ sí i, torí pé wọ́n pa àwọn wòlíì,+ àmọ́ ẹ̀ ń kọ́ ibojì wọn. 49 Ìdí nìyẹn tí ọgbọ́n Ọlọ́run náà fi sọ pé: ‘Màá rán àwọn wòlíì àti àwọn àpọ́sítélì sí wọn, wọ́n máa pa àwọn kan, wọ́n sì máa ṣe inúnibíni sí àwọn kan lára wọn, 50 ká lè di ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn wòlíì tí wọ́n ta sílẹ̀ látìgbà ìpìlẹ̀ ayé ru* ìran yìí,+ 51 látorí ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì+ títí dórí ẹ̀jẹ̀ Sekaráyà, tí wọ́n pa láàárín pẹpẹ àti ilé.’*+ Àní, mò ń sọ fún yín, a máa di ẹ̀bi rẹ̀ ru* ìran yìí.
52 “Ẹ gbé, ẹ̀yin tí ẹ mọ Òfin dunjú, torí ẹ mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ lọ. Ẹ̀yin fúnra yín ò wọlé, ẹ sì ń dí àwọn tó ń wọlé lọ́wọ́!”+
53 Torí náà, nígbà tó kúrò níbẹ̀, àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí í yọ ọ́ lẹ́nu gidigidi, wọ́n sì ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè míì bò ó, 54 wọ́n ń ṣọ́ ọ, kí wọ́n lè fi ohun tó bá sọ mú un.+
12 Láàárín àkókò yìí, nígbà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn kóra jọ débi pé wọ́n ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó kọ́kọ́ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí, ìyẹn àgàbàgebè.+ 2 Àmọ́ kò sí ohun kan tí a rọra tọ́jú tí a ò ní ṣí payá, kò sì sí ohun tó jẹ́ àṣírí tí a ò ní mọ̀.+ 3 Torí náà, ohunkóhun tí ẹ bá sọ nínú òkùnkùn, a máa gbọ́ ọ nínú ìmọ́lẹ̀, ohun tí ẹ bá sì sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nínú yàrá àdáni, a máa wàásù rẹ̀ látorí ilé. 4 Bákan náà, mò ń sọ fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi,+ ẹ má bẹ̀rù àwọn tó ń pa ara, àmọ́ tí wọn ò lè ṣe ohunkóhun mọ́ lẹ́yìn èyí.+ 5 Ṣùgbọ́n màá fi ẹni tí ẹ máa bẹ̀rù hàn yín: Ẹ bẹ̀rù Ẹni tó jẹ́ pé lẹ́yìn tó bá pani, ó ní àṣẹ láti sọni sínú Gẹ̀hẹ́nà.*+ Àní, mò ń sọ fún yín, Ẹni yìí ni kí ẹ bẹ̀rù.+ 6 Ẹyọ owó méjì tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí* ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ márùn-ún, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀, Ọlọ́run ò gbàgbé* ìkankan nínú wọn.+ 7 Kódà, gbogbo irun orí yín la ti kà.+ Ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.+
8 “Mò ń sọ fún yín pé, gbogbo ẹni tó bá fi hàn pé òun mọ̀ mí níwájú àwọn èèyàn,+ Ọmọ èèyàn náà máa fi hàn pé òun mọ̀ ọ́n níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.+ 9 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sẹ́ mi níwájú àwọn èèyàn, a máa sẹ́ ẹ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.+ 10 Gbogbo ẹni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ọmọ èèyàn, a máa dárí rẹ̀ jì í, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́ kò ní rí ìdáríjì.+ 11 Tí wọ́n bá mú yín wọlé síwájú ibi táwọn èèyàn pé jọ sí,* síwájú àwọn aṣojú ìjọba àti àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣàníyàn nípa bí ẹ ṣe máa sọ̀rọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ tí ẹ máa fi gbèjà ara yín tàbí ohun tí ẹ máa sọ,+ 12 torí ní wákàtí yẹn gan-an, ẹ̀mí mímọ́ máa kọ́ yín ní àwọn ohun tó yẹ kí ẹ sọ.”+
13 Ẹnì kan láàárín èrò wá sọ fún un pé: “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kó pín ogún fún mi.” 14 Ó sọ fún un pé: “Ọkùnrin yìí, ta ló yàn mí ṣe adájọ́ tàbí alárinà láàárín ẹ̀yin méjèèjì?” 15 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún onírúurú ojúkòkòrò,*+ torí pé tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ní nǹkan rẹpẹtẹ, àwọn ohun tó ní kò lè fún un ní ìwàláàyè.”+ 16 Torí náà, ó sọ àpèjúwe kan fún wọn, ó ní: “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan méso jáde dáadáa. 17 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni kí n ṣe báyìí tí mi ò ní ibì kankan tí màá kó irè oko mi jọ sí?’ 18 Torí náà, ó sọ pé, ‘Ohun tí màá ṣe nìyí:+ Màá ya àwọn ilé ìkẹ́rùsí mi lulẹ̀, màá sì kọ́ àwọn tó tóbi, ibẹ̀ ni màá kó gbogbo ọkà mi àti gbogbo ẹrù mi jọ sí, 19 màá sì sọ fún ara* mi pé: “O ní* ọ̀pọ̀ nǹkan rere tí mo ti tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fọkàn balẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn ara ẹ.”’ 20 Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún un pé, ‘Aláìlóye, òru òní ni wọ́n máa béèrè ẹ̀mí* rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ló máa wá ni àwọn ohun tí o ti tò jọ?’+ 21 Bẹ́ẹ̀ ló máa rí fún ẹni tó bá ń to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀ àmọ́ tí kò ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”+
22 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ìdí nìyẹn tí mo fi ń sọ fún yín pé, ẹ yéé ṣàníyàn nípa ẹ̀mí* yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.+ 23 Torí ẹ̀mí* níye lórí ju oúnjẹ lọ, ara sì níye lórí ju aṣọ lọ. 24 Ẹ wo àwọn ẹyẹ ìwò: Wọn kì í fúnrúgbìn, wọn kì í sì í kárúgbìn; wọn ò ní abà tàbí ilé ìkẹ́rùsí; síbẹ̀ Ọlọ́run ń bọ́ wọn.+ Ṣé ẹ ò wá níye lórí gan-an ju àwọn ẹyẹ lọ ni?+ 25 Èwo nínú yín ló lè fi ìgbọ̀nwọ́* kan kún ìwàláàyè rẹ̀, tó bá ń ṣàníyàn? 26 Torí náà, tí ẹ ò bá lè ṣe ohun tó kéré bí èyí, kí ló wá dé tí ẹ̀ ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun tó ṣẹ́ kù?+ 27 Ẹ ronú nípa bí àwọn òdòdó lílì ṣe ń dàgbà: Wọn kì í ṣe làálàá, wọn kì í sì í rànwú;* àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, a ò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí.+ 28 Tó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe ń wọ ewéko inú pápá láṣọ, tó wà lónìí, tí a sì jù sínú ààrò lọ́la, ṣé kò wá ní wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? 29 Torí náà, ẹ yéé wá ohun tí ẹ máa jẹ àti ohun tí ẹ máa mu, ẹ má sì jẹ́ kí àníyàn kó yín lọ́kàn sókè mọ́;+ 30 torí gbogbo nǹkan yìí ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń wá lójú méjèèjì, àmọ́ Baba yín mọ̀ pé ẹ nílò àwọn nǹkan yìí.+ 31 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa wá Ìjọba rẹ̀, a sì máa fi àwọn nǹkan yìí kún un fún yín.+
32 “Má bẹ̀rù, agbo kékeré,+ torí Baba yín ti fọwọ́ sí i láti fún yín ní Ìjọba náà.+ 33 Ẹ ta àwọn ohun ìní yín, kí ẹ sì ṣe ìtọrẹ àánú.*+ Ẹ ṣe àwọn àpò owó tí kì í gbó, ìṣúra tí kò lè kùnà láé sí ọ̀run,+ níbi tí olè kankan kò lè sún mọ́, tí òólá* kankan ò sì lè jẹ ẹ́ run. 34 Torí ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà.
35 “Ẹ múra, kí ẹ sì wà ní sẹpẹ́,*+ kí ẹ jẹ́ kí àwọn fìtílà yín máa jó,+ 36 kí ẹ sì dà bí àwọn ọkùnrin tó ń dúró de ọ̀gá wọn pé kó pa dà dé+ láti ibi ìgbéyàwó,+ kó lè jẹ́ pé tó bá dé, tó sì kan ilẹ̀kùn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n á ṣílẹ̀kùn fún un. 37 Aláyọ̀ ni àwọn ẹrú tí ọ̀gá náà rí i pé wọ́n ń ṣọ́nà nígbà tó dé! Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó máa múra* láti ṣiṣẹ́, á sì ní kí wọ́n jókòó* sídìí tábìlì, ó máa wá sí tòsí, á sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. 38 Tó bá sì dé ní ìṣọ́ kejì,* kódà kó jẹ́ ìkẹta,* tó sì rí i pé wọ́n wà ní sẹpẹ́, aláyọ̀ ni wọ́n! 39 Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí, ká ní baálé ilé mọ wákàtí tí olè máa wá ni, kò ní jẹ́ kí wọ́n ráyè wọ ilé òun.+ 40 Ẹ̀yin náà, ẹ múra sílẹ̀, torí pé wákàtí tí ẹ ò rò pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ èèyàn ń bọ̀.”+
41 Pétérù wá sọ pé: “Olúwa, ṣé àwa nìkan lò ń sọ àpèjúwe yìí fún àbí gbogbo èèyàn?” 42 Olúwa sọ pé: “Ní tòótọ́, ta ni ìríjú olóòótọ́* náà, tó jẹ́ olóye,* tí ọ̀gá rẹ̀ máa yàn pé kó bójú tó àwọn ìránṣẹ́* rẹ̀, kó máa fún wọn ní ìwọ̀n oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ?+ 43 Aláyọ̀ ni ẹrú yẹn tí ọ̀gá rẹ̀ bá dé, tó sì rí i tó ń ṣe bẹ́ẹ̀! 44 Mò ń sọ fún yín ní tòótọ́, ó máa yàn án pé kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní rẹ̀. 45 Àmọ́ tí ẹrú yẹn bá lọ sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọ̀gá mi ò tètè dé,’ tó wá bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, tó ń jẹ, tó ń mu, tó sì mutí yó,+ 46 ọ̀gá ẹrú yẹn máa dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀ àti wákàtí tí kò mọ̀, ó máa fi ìyà tó le jù lọ jẹ ẹ́, ó sì máa kà á mọ́ àwọn aláìṣòótọ́. 47 Nígbà náà, ẹrú yẹn tó lóye ohun tí ọ̀gá rẹ̀ fẹ́ àmọ́ tí kò múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe ohun tó ní kó ṣe* la máa nà ní ẹgba tó pọ̀.+ 48 Àmọ́ èyí tí kò lóye, síbẹ̀ tó ṣe àwọn ohun tó fi yẹ kó jẹgba la máa nà ní ẹgba díẹ̀. Ní tòótọ́, gbogbo ẹni tí a bá fún ní púpọ̀, a máa béèrè púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹni tí a bá sì yàn pé kó máa bójú tó ohun púpọ̀, ohun tó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ la máa béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.+
49 “Mo wá láti dá iná kan ní ayé, kí ni mo tún fẹ́ tó bá jẹ́ pé a ti dá iná náà báyìí? 50 Ní tòótọ́, mo ní ìbatisí kan tí a fi máa batisí mi, ẹ sì wo bí ìdààmú tó bá mi ṣe pọ̀ tó títí ó fi máa parí!+ 51 Ṣé ẹ rò pé mo wá láti mú kí àlàáfíà wà ní ayé ni? Rárá o, mò ń sọ fún yín pé, dípò ìyẹn, ìpínyà ni.+ 52 Torí láti ìsinsìnyí lọ, ẹni márùn-ún máa pínyà nínú ilé kan, ẹni mẹ́ta sí méjì àti ẹni méjì sí mẹ́ta. 53 Wọ́n máa pínyà, bàbá sí ọmọkùnrin àti ọmọkùnrin sí bàbá, ìyá sí ọmọbìnrin àti ọmọbìnrin sí ìyá, ìyá ọkọ sí ìyàwó ọmọ rẹ̀ àti ìyàwó sí ìyá ọkọ rẹ̀.”+
54 Lẹ́yìn náà, ó tún sọ fún àwọn èrò náà pé: “Tí ẹ bá rí i tí ojú ọ̀run ṣú ní ìwọ̀ oòrùn, kíá lẹ máa sọ pé, ‘Ìjì ń bọ̀,’ ó sì máa ń rí bẹ́ẹ̀. 55 Tí ẹ bá sì rí i pé atẹ́gùn ń fẹ́ láti gúúsù, ẹ máa sọ pé, ‘Ooru máa mú,’ ó sì máa ń ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀. 56 Ẹ̀yin alágàbàgebè, ẹ mọ bí wọ́n ṣe ń ṣàyẹ̀wò bí ayé àti òfúrufú ṣe rí, àmọ́ kí nìdí tí ẹ ò fi mọ bí ẹ ṣe máa ṣàyẹ̀wò àkókò yìí gan-an?+ 57 Kí ló dé tí ẹ̀yin fúnra yín náà ò pinnu ohun tó jẹ́ òdodo? 58 Bí àpẹẹrẹ, tí ìwọ àti ẹni tó fẹ̀sùn kàn ọ́ lábẹ́ òfin bá ń lọ sọ́dọ̀ alákòóso kan, sapá láti yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ̀ lójú ọ̀nà, kó má bàa mú ọ wá síwájú adájọ́, kí adájọ́ wá fi ọ́ lé òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ lọ́wọ́, kí òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ sì jù ọ́ sẹ́wọ̀n.+ 59 Mò ń sọ fún ọ pé, ó dájú pé o ò ní kúrò níbẹ̀ títí wàá fi san ẹyọ owó kékeré tó kù* tí o jẹ́.”
13 Ní àkókò yẹn, àwọn kan tó wà níbẹ̀ ròyìn fún un nípa àwọn ará Gálílì tí Pílátù po ẹ̀jẹ̀ wọn mọ́ àwọn ẹbọ wọn. 2 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ṣé ẹ rò pé torí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Gálílì yẹn pọ̀ ju ti gbogbo àwọn ará Gálílì yòókù lọ ni àwọn nǹkan yìí ṣe ṣẹlẹ̀ sí wọn ni? 3 Rárá ni mo sọ fún yín; àfi tí ẹ bá ronú pìwà dà, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo yín ṣe máa pa run.+ 4 Àbí àwọn méjìdínlógún (18) tí ilé gogoro tó wà ní Sílóámù wó lù, tó sì pa wọ́n, ṣé ẹ rò pé ẹ̀bi wọn pọ̀ ju ti gbogbo èèyàn yòókù tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ni? 5 Rárá ni mo sọ fún yín; àfi tí ẹ bá ronú pìwà dà, gbogbo yín máa pa run, bí wọ́n ṣe pa run.”
6 Ó wá sọ àpèjúwe yìí, ó ní: “Ọkùnrin kan gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀, ó sì wá síbẹ̀, ó ń wá èso lórí rẹ̀, àmọ́ kò rí ìkankan.+ 7 Ó wá sọ fún ẹni tó ń rẹ́wọ́ àjàrà pé, ‘Ó ti pé ọdún mẹ́ta báyìí tí mo ti ń wá síbí, tí mò ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, àmọ́ mi ò rí ìkankan. Gé e lulẹ̀! Ṣe ló kàn ń fi ilẹ̀ ṣòfò lásán.’ 8 Ó dá a lóhùn pé, ‘Ọ̀gá, jẹ́ kó lo ọdún kan sí i, títí màá fi gbẹ́lẹ̀ yí i ká, tí màá sì fi ajílẹ̀ sí i. 9 Tó bá so èso lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn dáa; àmọ́ tí kò bá so, o lè wá gé e lulẹ̀.’”+
10 Ní Sábáàtì, ó ń kọ́ni nínú ọ̀kan lára àwọn sínágọ́gù. 11 Wò ó! obìnrin kan wà níbẹ̀ tó ti ní ẹ̀mí àìlera* fún ọdún méjìdínlógún (18); ẹ̀yìn rẹ̀ ti tẹ̀ gan-an, kò sì lè nàró rárá. 12 Nígbà tí Jésù rí i, ó bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Obìnrin, a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú àìlera rẹ.”+ 13 Ó wá gbé ọwọ́ rẹ̀ lé obìnrin náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó nàró ṣánṣán, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo. 14 Àmọ́ inú bí alága sínágọ́gù torí pé Sábáàtì ni Jésù wo obìnrin náà sàn, ó wá sọ fún àwọn èrò pé: “Ọjọ́ mẹ́fà ló yẹ ká fi máa ṣiṣẹ́;+ torí náà, àwọn ọjọ́ yẹn ni kí ẹ wá gba ìwòsàn, kì í ṣe lọ́jọ́ Sábáàtì.”+ 15 Àmọ́ Olúwa dá a lóhùn pé: “Ẹ̀yin alágàbàgebè,+ ṣebí ní Sábáàtì, ọ̀kọ̀ọ̀kan yín máa ń tú akọ màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò níbi tó so ó mọ́, tí á sì mú un lọ kó lè fún un ní ohun tó máa mu?+ 16 Ṣé kò yẹ kí obìnrin yìí, ẹni tó jẹ́ ọmọ Ábúráhámù, tí Sátánì sì ti dè fún ọdún méjìdínlógún (18), rí ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ìdè yìí ní ọjọ́ Sábáàtì?” 17 Nígbà tó sọ àwọn nǹkan yìí, ojú bẹ̀rẹ̀ sí í ti gbogbo àwọn tó ń ta kò ó, àmọ́ inú gbogbo àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí í dùn torí gbogbo nǹkan ológo tó ṣe.+
18 Ó wá sọ pé: “Kí ni Ìjọba Ọlọ́run jọ, kí sì ni mo lè fi wé? 19 Ó dà bíi hóró músítádì tí ọkùnrin kan mú, tó sì gbìn sínú ọgbà rẹ̀, tó wá dàgbà, tó sì di igi, tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì fi àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣe ibùgbé.”+
20 Ó tún sọ pé: “Kí ni mo lè fi Ìjọba Ọlọ́run wé? 21 Ó dà bí ìwúkàrà tí obìnrin kan mú, tó sì pò mọ́ ìyẹ̀fun tó kún òṣùwọ̀n* ńlá mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ fi wú.”+
22 Ó rìnrìn àjò láti ìlú dé ìlú, láti abúlé dé abúlé, ó ń kọ́ni, ó sì ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù. 23 Ọkùnrin kan wá sọ fún un pé: “Olúwa, ṣé díẹ̀ ni àwọn tí a máa gbà là?” Ó sọ fún wọn pé: 24 “Ẹ sa gbogbo ipá yín láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé,+ torí mò ń sọ fún yín pé, ọ̀pọ̀ èèyàn máa fẹ́ wọlé àmọ́ wọn ò ní lè wọlé. 25 Tí baálé ilé bá dìde, tó sì ti ilẹ̀kùn pa, ìta lẹ máa dúró sí, ẹ máa kan ilẹ̀kùn, ẹ sì máa sọ pé, ‘Olúwa, ṣílẹ̀kùn fún wa.’+ Àmọ́ ó máa dá yín lóhùn pé: ‘Mi ò mọ ibi tí ẹ ti wá.’ 26 Ẹ máa wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé, ‘Ìṣojú rẹ la ti jẹ, tí a sì mu, o sì kọ́ni ní àwọn ọ̀nà wa tó bọ́ sí gbangba.’+ 27 Àmọ́ ó máa sọ fún yín pé, ‘Mi ò mọ ibi tí ẹ ti wá. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin aláìṣòdodo!’ 28 Ibẹ̀ ni ẹ ti máa sunkún, tí ẹ sì ti máa payín keke, nígbà tí ẹ bá rí Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù àti gbogbo wòlíì nínú Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́ tí wọ́n ju ẹ̀yin fúnra yín síta.+ 29 Bákan náà, àwọn èèyàn máa wá láti ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, láti àríwá àti gúúsù, wọ́n sì máa jókòó* sídìí tábìlì nínú Ìjọba Ọlọ́run. 30 Ẹ wò ó! àwọn tó jẹ́ ẹni ìkẹyìn máa di ẹni àkọ́kọ́, àwọn tó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ sì máa di ẹni ìkẹyìn.”+
31 Ní wákàtí yẹn gan-an, àwọn Farisí kan wá, wọ́n sì sọ fún un pé: “Jáde kúrò níbí, torí Hẹ́rọ́dù fẹ́ pa ọ́.” 32 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yẹn pé, ‘Wò ó! Mò ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, mo sì ń wo àwọn èèyàn sàn lónìí àti lọ́la, màá ṣe tán ní ọjọ́ kẹta.’ 33 Síbẹ̀, mo gbọ́dọ̀ máa lọ lónìí, lọ́la àti ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, torí kò lè ṣẹlẹ̀* pé kí wọ́n pa wòlíì lẹ́yìn òde Jerúsálẹ́mù.+ 34 Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, ìlú tó ń pa àwọn wòlíì, tó sì ń sọ àwọn tí a rán sí i lókùúta,+ wo bí mo ṣe máa ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ tó lọ́pọ̀ ìgbà, bí ìgbà tí adìyẹ ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ jọ sábẹ́ ìyẹ́ rẹ̀! Àmọ́ ẹ ò fẹ́ bẹ́ẹ̀.+ 35 Ẹ wò ó! A ti pa ilé yín tì fún yín.+ Mò ń sọ fún yín, ó dájú pé ẹ ò ní rí mi títí ẹ fi máa sọ pé: ‘Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!’”*+
14 Ní àkókò míì, ó lọ jẹun ní ilé ọ̀kan nínú àwọn aṣáájú àwọn Farisí ní Sábáàtì, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ lójú méjèèjì. 2 Wò ó! ọkùnrin kan wà níwájú rẹ̀ tí ara rẹ̀ wú.* 3 Jésù wá bi àwọn tó mọ Òfin dunjú àti àwọn Farisí pé: “Ṣé ó bófin mu láti ṣe ìwòsàn ní Sábáàtì àbí kò bófin mu?”+ 4 Àmọ́ wọn ò fèsì. Ló bá di ọkùnrin náà mú, ó wò ó sàn, ó sì ní kó máa lọ. 5 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ta ni ọmọ rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ máa já sí kànga nínú yín,+ tí kò ní fà á jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní ọjọ́ Sábáàtì?”+ 6 Wọn ò sì lè fèsì ọ̀rọ̀ yìí.
7 Ó wá sọ àpèjúwe kan fún àwọn èèyàn tí wọ́n pè síbẹ̀, nígbà tó kíyè sí bí wọ́n ṣe ń yan àwọn ibi tó lọ́lá jù lọ fún ara wọn.+ Ó sọ fún wọn pé: 8 “Tí ẹnì kan bá pè ọ́ síbi àsè ìgbéyàwó, má ṣe jókòó* síbi tó lọ́lá jù.+ Ó ṣeé ṣe kó ti pe ẹnì kan tí wọ́n kà sí pàtàkì jù ọ́ lọ. 9 Ẹni tó pe ẹ̀yin méjèèjì á wá sọ fún ọ pé, ‘Dìde fún ọkùnrin yìí.’ O máa wá fi ìtìjú dìde lọ jókòó síbi tó rẹlẹ̀ jù lọ. 10 Àmọ́ tí wọ́n bá pè ọ́, lọ jókòó síbi tó rẹlẹ̀ jù, kó lè jẹ́ pé tí ẹni tó pè ọ́ wá bá dé, ó máa sọ fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, lọ síbi tó ga.’ Ìgbà yẹn lo máa wá gbayì níṣojú gbogbo àwọn tí ẹ jọ jẹ́ àlejò.+ 11 Torí gbogbo ẹni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.”+
12 Lẹ́yìn náà, ó tún sọ fún ọkùnrin tó pè é wá, ó ní: “Tí o bá se àsè oúnjẹ ọ̀sán tàbí oúnjẹ alẹ́, má pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tàbí àwọn aládùúgbò rẹ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀. Torí tó bá yá, àwọn náà lè pè ọ́ wá, wọ́n á sì fìyẹn san án fún ọ. 13 Àmọ́ tí o bá se àsè, àwọn aláìní, arọ, àwọn tí kò lè rìn dáadáa àti afọ́jú ni kí o pè;+ 14 o sì máa láyọ̀, torí wọn ò ní ohunkóhun láti fi san án pa dà fún ọ. A máa san án pa dà fún ọ nígbà àjíǹde+ àwọn olódodo.”
15 Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ àlejò gbọ́ àwọn nǹkan yìí, ó sọ fún un pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tó ń jẹun* ní Ìjọba Ọlọ́run.”
16 Jésù sọ fún un pé: “Ọkùnrin kan ń se àsè oúnjẹ alẹ́ rẹpẹtẹ,+ ó sì pe ọ̀pọ̀ èèyàn. 17 Ó rán ẹrú rẹ̀ jáde ní wákàtí tí wọ́n fẹ́ jẹ oúnjẹ alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tó pè wá pé, ‘Ẹ máa bọ̀, torí gbogbo nǹkan ti wà ní sẹpẹ́ báyìí.’ 18 Àmọ́ ohun kan náà ni gbogbo wọn ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwáwí.+ Ẹni àkọ́kọ́ sọ fún un pé, ‘Mo ra pápá kan, ó sì yẹ kí n jáde lọ wò ó; jọ̀ọ́, yọ̀ǹda mi.’ 19 Ẹlòmíì sọ pé, ‘Mo ra màlúù mẹ́wàá,* mo sì fẹ́ lọ yẹ̀ wọ́n wò; jọ̀ọ́, yọ̀ǹda mi.’+ 20 Ẹlòmíì tún sọ pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó ni, torí náà, mi ò ní lè wá.’ 21 Ẹrú náà wá, ó sì jábọ̀ àwọn nǹkan yìí fún ọ̀gá rẹ̀. Inú wá bí baálé ilé náà, ó sì sọ fún ẹrú rẹ̀ pé, ‘Tètè jáde lọ sí àwọn ọ̀nà tó bọ́ sí gbangba àti àwọn ọ̀nà tóóró nínú ìlú, kí o sì mú àwọn òtòṣì, arọ, afọ́jú àti àwọn tí kò lè rìn dáadáa wọlé wá síbí.’ 22 Nígbà tó yá, ẹrú náà sọ pé, ‘Ọ̀gá, mo ti ṣe ohun tí o pa láṣẹ, àmọ́ àyè ṣì kù.’ 23 Ọ̀gá náà wá sọ fún ẹrú náà pé, ‘Jáde lọ sí àwọn ojú ọ̀nà àti àwọn ọ̀nà tí kò fẹ̀, kí o sì fi dandan mú wọn wọlé wá, kí ilé mi lè kún.+ 24 Torí mò ń sọ fún yín pé, ìkankan nínú àwọn èèyàn tí mo pè yẹn ò ní tọ́ oúnjẹ alẹ́ mi wò.’”+
25 Nígbà tí èrò rẹpẹtẹ ń bá a rìnrìn àjò, ó yíjú pa dà, ó sì sọ fún wọn pé: 26 “Tí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ mi, tí kò sì kórìíra* bàbá, ìyá, ìyàwó, àwọn ọmọ, àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin rẹ̀, àní ẹ̀mí*+ òun fúnra rẹ̀ pàápàá, kò lè di ọmọ ẹ̀yìn mi.+ 27 Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé òpó igi oró* rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi, kò lè di ọmọ ẹ̀yìn mi.+ 28 Bí àpẹẹrẹ, èwo nínú yín ló máa fẹ́ kọ́ ilé gogoro, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kó ṣírò ohun tó máa ná an, kó lè mọ̀ bóyá àwọn ohun tó ní máa tó parí ilé náà? 29 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè fi ìpìlẹ̀ ilé náà lélẹ̀, àmọ́ kó má lè parí rẹ̀, gbogbo àwọn tó ń wò ó sì máa bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe ẹlẹ́yà, 30 wọ́n á ní: ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́lé àmọ́ kò lè parí rẹ̀.’ 31 Àbí ọba wo, tó fẹ́ lọ bá ọba míì jagun, ni kò ní kọ́kọ́ jókòó, kó sì gba ìmọ̀ràn láti mọ̀ bóyá òun máa lè fi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọmọ ogun gbéjà ko ẹni tó ń kó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) bọ̀ wá bá a jà? 32 Ní tòótọ́, tí kò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé nígbà tí ọ̀nà ẹni yẹn ṣì jìn, ó máa rán àwọn ikọ̀ lọ, á sì bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà. 33 Lọ́nà kan náà, ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé, ìkankan nínú yín tí kò bá sọ pé ó dìgbòóṣe sí* gbogbo ohun ìní rẹ̀, kò lè di ọmọ ẹ̀yìn mi.+
34 “Ó dájú pé iyọ̀ dáa. Àmọ́ tí iyọ̀ ò bá lágbára mọ́, kí la máa fi mú kó ní adùn?+ 35 Kò ṣeé lò fún iyẹ̀pẹ̀ tàbí ajílẹ̀. Ṣe ni àwọn èèyàn máa ń dà á nù. Kí ẹni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”+
15 Gbogbo àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ 2 Àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin sì ń ráhùn ṣáá, pé: “Ọkùnrin yìí ń tẹ́wọ́ gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.” 3 Ó wá sọ àpèjúwe yìí fún wọn, ó ní: 4 “Ọkùnrin wo nínú yín, tó ní ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, ló jẹ́ pé tí ọ̀kan nínú wọn bá sọ nù, kò ní fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ nínú aginjù, kó sì wá èyí tó sọ nù lọ títí ó fi máa rí i?+ 5 Tó bá sì rí i, ó máa gbé e lé èjìká rẹ̀, inú rẹ̀ sì máa dùn. 6 Tó bá wá dé ilé, á pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, á sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, torí mo ti rí àgùntàn mi tó sọ nù.’+ 7 Mò ń sọ fún yín pé, lọ́nà kan náà, inú àwọn tó wà ní ọ̀run máa dùn gan-an torí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà+ ju olódodo mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) tí kò nílò ìrònúpìwàdà.
8 “Àbí obìnrin wo, tó ní ẹyọ owó dírákímà* mẹ́wàá, ló jẹ́ pé tí dírákímà* kan bá sọ nù, kò ní tan fìtílà, kó gbá ilé rẹ̀, kó sì fara balẹ̀ wá a títí ó fi máa rí i? 9 Tó bá sì rí i, á pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀* àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, á sọ pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, torí mo ti rí ẹyọ owó dírákímà* tí mo sọ nù.’ 10 Mò ń sọ fún yín pé, lọ́nà kan náà, àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run máa ń yọ̀ torí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà.”+
11 Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Ọkùnrin kan ní ọmọkùnrin méjì. 12 Èyí àbúrò sọ fún bàbá rẹ̀ pé, ‘Bàbá, fún mi ní ìpín tó yẹ kó jẹ́ tèmi nínú ohun ìní rẹ.’ Ó wá pín àwọn ohun ìní rẹ̀ fún wọn. 13 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, èyí àbúrò kó gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀ jọ, ó sì rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ tó jìnnà gan-an, ibẹ̀ ló ti ń gbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla,* tó sì lo àwọn ohun ìní rẹ̀ nílòkulò. 14 Nígbà tó ti ná gbogbo rẹ̀ tán, ìyàn mú gan-an ní gbogbo ilẹ̀ yẹn, ó sì di aláìní. 15 Ó tiẹ̀ lọ fi ara rẹ̀ sọ́dọ̀ ọ̀kan nínú àwọn aráàlú yẹn, ẹni yẹn sì rán an lọ sínú àwọn pápá rẹ̀ pé kó máa tọ́jú àwọn ẹlẹ́dẹ̀.+ 16 Ó sì máa ń wù ú kó jẹ èèpo èso kárọ́ọ̀bù tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ, àmọ́ ẹnì kankan kì í fún un ní ohunkóhun.
17 “Nígbà tí orí rẹ̀ wálé, ó sọ pé, ‘Àìmọye àwọn alágbàṣe bàbá mi ló ní oúnjẹ ní àníṣẹ́kù, ebi wá ń pa èmi kú lọ níbí! 18 Jẹ́ kí n kúkú dìde, kí n rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ bàbá mi, kí n sì sọ fún un pé: “Bàbá, mo ti ṣẹ̀ sí ọ̀run, mo sì ti ṣẹ̀ ọ́. 19 Mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè pè ní ọmọ rẹ mọ́. Jẹ́ kí n dà bí ọ̀kan lára àwọn alágbàṣe rẹ.”’ 20 Ló bá dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀. Bó ṣe ń bọ̀ ní òkèèrè ni bàbá rẹ̀ tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó wá sáré lọ dì mọ́ ọn,* ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 21 Ọmọkùnrin náà wá sọ fún un pé, ‘Bàbá, mo ti ṣẹ̀ sí ọ̀run, mo sì ti ṣẹ̀ ọ́.+ Mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè pè ní ọmọ rẹ mọ́.’ 22 Àmọ́ bàbá náà sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘Ó yá! ẹ mú aṣọ wá, aṣọ tó dáa jù, kí ẹ wọ̀ ọ́ fún un, kí ẹ fi òrùka sí i lọ́wọ́, kí ẹ sì wọ bàtà sí i lẹ́sẹ̀. 23 Kí ẹ tún mú ọmọ màlúù tó sanra wá, kí ẹ dúńbú rẹ̀, ká jọ jẹun, ká sì yọ̀, 24 torí pé ọmọ mi yìí kú, àmọ́ ó ti pa dà wà láàyè;+ ó sọ nù, a sì rí i.’ Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ara wọn.
25 “Ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà wà nínú pápá, bó sì ṣe dé, tó sún mọ́ ilé, ó gbọ́ orin àti ijó. 26 Torí náà, ó pe ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ sọ́dọ̀, ó sì béèrè ohun tó ń ṣẹlẹ̀. 27 Ìránṣẹ́ náà sọ fún un pé, ‘Àbúrò rẹ ti dé, bàbá rẹ sì dúńbú ọmọ màlúù tó sanra torí ó pa dà rí i ní àlàáfíà.’* 28 Àmọ́ inú bí i, kò sì wọlé. Bàbá rẹ̀ wá jáde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́. 29 Ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Ọ̀pọ̀ ọdún yìí ni mo ti ń sìn ọ́, mi ò tàpá sí àṣẹ rẹ rí, síbẹ̀, o ò fún mi ní ọmọ ewúrẹ́ kan rí kí èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi lè fi gbádùn ara wa. 30 Àmọ́ gbàrà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tó lo àwọn ohun ìní rẹ nílòkulò* pẹ̀lú àwọn aṣẹ́wó, o dúńbú ọmọ màlúù tó sanra fún un.’ 31 Bàbá rẹ̀ wá sọ fún un pé, ‘Ọmọ mi, ìgbà gbogbo lo wà lọ́dọ̀ mi, ìwọ lo sì ni gbogbo ohun tó jẹ́ tèmi. 32 Àmọ́ ó yẹ ká yọ̀, kí inú wa sì dùn, torí pé arákùnrin rẹ kú, àmọ́ ó ti wà láàyè; ó sọ nù, a sì rí i.’”
16 Ó tún wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan ní ìríjú* kan, tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó ń fi àwọn ẹrù ọ̀gá rẹ̀ ṣòfò. 2 Torí náà, ó pè é, ó sì sọ fún un pé, ‘Kí ni mo gbọ́ pé o ṣe yìí? Gbé àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìríjú rẹ wá, torí o ò lè bójú tó ilé yìí mọ́.’ 3 Ìríjú náà wá sọ fún ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni kí n ṣe, ní báyìí tí ọ̀gá mi fẹ́ gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi? Mi ò lágbára tó láti gbẹ́lẹ̀, ojú sì ń tì mí láti ṣagbe. 4 Áà! Mo mọ ohun tí màá ṣe, kó lè jẹ́ pé tí wọ́n bá gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi, àwọn èèyàn máa gbà mí sínú ilé wọn.’ 5 Ó wá pe ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó jẹ ọ̀gá rẹ̀ ní gbèsè, ó sì sọ fún ẹni àkọ́kọ́ pé, ‘Èló lo jẹ ọ̀gá mi?’ 6 Ó fèsì pé, ‘Ọgọ́rùn-ún (100) òṣùwọ̀n* òróró ólífì.’ Ó sọ fún un pé, ‘Gba ìwé àdéhùn tí o kọ pa dà, jókòó, kí o sì kọ àádọ́ta (50) kíákíá.’ 7 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún ẹlòmíì pé, ‘Ìwọ, èló ni gbèsè tí o jẹ?’ Ó ní, ‘Ọgọ́rùn-ún (100) òṣùwọ̀n ńlá* àlìkámà.’* Ó sọ fún un pé, ‘Gba ìwé àdéhùn tí o kọ pa dà, kí o sì kọ ọgọ́rin (80).’ 8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìṣòdodo ni ìríjú náà, ọ̀gá rẹ̀ yìn ín, torí pé ó lo ọgbọ́n tó gbéṣẹ́;* torí àwọn ọmọ ètò àwọn nǹkan yìí* gbọ́n féfé sí ìran tiwọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ + lọ.
9 “Bákan náà, mò ń sọ fún yín pé: Ẹ fi ọrọ̀ àìṣòdodo wá ọ̀rẹ́ fún ara yín,+ kó lè jẹ́ pé, tó bá kùnà, wọ́n máa lè gbà yín sínú àwọn ibùgbé ayérayé.+ 10 Ẹni tó bá jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tó kéré jù jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tó pọ̀ pẹ̀lú, ẹni tó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tó kéré jù jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tó pọ̀ pẹ̀lú. 11 Torí náà, tí ẹ kò bá tíì fi hàn pé olóòótọ́ ni yín tó bá kan ọrọ̀ àìṣòdodo, ta ló máa fi ohun tó jẹ́ òtítọ́ sí ìkáwọ́ yín? 12 Tí ẹ kò bá sì tíì fi hàn pé olóòótọ́ ni yín tó bá kan ohun tó jẹ́ ti ẹlòmíì, ta ló máa fún yín ní nǹkan pé kó jẹ́ tiyín?+ 13 Kò sí ìránṣẹ́ tó lè jẹ́ ẹrú ọ̀gá méjì, àfi kó kórìíra ọ̀kan, kó sì nífẹ̀ẹ́ ìkejì tàbí kó fara mọ́ ọ̀kan, kó má sì ka ìkejì sí. Ẹ ò lè jẹ́ ẹrú Ọlọ́run àti Ọrọ̀.”+
14 Àwọn Farisí, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó, ń fetí sí gbogbo nǹkan yìí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í yínmú sí i.+ 15 Torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin lẹ̀ ń kéde pé olódodo ni yín níwájú àwọn èèyàn,+ àmọ́ Ọlọ́run mọ ohun tó wà lọ́kàn yín.+ Torí ohun tí àwọn èèyàn kà sí ohun tí a gbé ga jẹ́ ohun ìríra lójú Ọlọ́run.+
16 “Òfin àti àwọn Wòlíì wà títí dìgbà Jòhánù. Látìgbà yẹn lọ, à ń kéde Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere, onírúurú èèyàn sì ń fi agbára lépa rẹ̀.+ 17 Ní tòótọ́, ó rọrùn kí ọ̀run àti ayé kọjá lọ ju kí ìlà kan lára lẹ́tà inú Òfin lọ láìṣẹ.+
18 “Gbogbo ẹni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀ ti ṣe àgbèrè.+
19 “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà tó máa ń wọ aṣọ aláwọ̀ pọ́pù àti aṣọ ọ̀gbọ̀,* ojoojúmọ́ ló ń gbádùn ara rẹ̀ dọ́ba. 20 Àmọ́ wọ́n máa ń gbé alágbe kan tó ń jẹ́ Lásárù sí ẹnubodè rẹ̀, egbò wà ní gbogbo ara rẹ̀, 21 ó sì máa ń wù ú pé kó jẹ lára àwọn nǹkan tó ń já bọ́ látorí tábìlì ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà. Àní àwọn ajá pàápàá máa ń wá pọ́n àwọn egbò rẹ̀ lá. 22 Nígbà tó yá, alágbe náà kú, àwọn áńgẹ́lì sì gbé e lọ sí ẹ̀gbẹ́* Ábúráhámù.
“Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn náà kú, wọ́n sì sin ín. 23 Ó gbé ojú rẹ̀ sókè nínú Isà Òkú,* ó ń joró, ó wá rí Ábúráhámù ní ọ̀ọ́kán, ó sì rí Lásárù ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.* 24 Torí náà, ó pè é, ó sì sọ pé, ‘Ábúráhámù baba, ṣàánú mi, kí o sì rán Lásárù pé kó ki orí ìka rẹ̀ bọ omi, kó sì mú kí ahọ́n mi tutù, torí mò ń jẹ̀rora nínú iná tó ń jó yìí.’ 25 Àmọ́ Ábúráhámù sọ pé, ‘Ọmọ, rántí pé ìwọ gbádùn ohun rere dáadáa nígbà ayé rẹ, àmọ́ ohun burúkú ni Lásárù gbà ní tiẹ̀. Ní báyìí, ó ń gba ìtura níbí, àmọ́ ìwọ ń jẹ̀rora. 26 Yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan yìí, a ti mú kí ọ̀gbun ńlá kan wà láàárín àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tó fẹ́ lọ sọ́dọ̀ yín láti ibí má bàa kọjá, kí àwọn èèyàn má sì kọjá láti ibẹ̀ yẹn sọ́dọ̀ wa.’ 27 Ó wá sọ pé, ‘Tó bá rí bẹ́ẹ̀, mo bẹ̀ ọ́, baba, pé kí o rán an sí ilé bàbá mi, 28 torí mo ní arákùnrin márùn-ún, kó lè jẹ́rìí kúnnákúnná fún wọn, kí àwọn náà má bàa wá sínú ibi oró yìí.’ 29 Àmọ́ Ábúráhámù sọ pé, ‘Wọ́n ní Mósè àti àwọn Wòlíì; kí wọ́n fetí sí àwọn yìí.’+ 30 Ó wá sọ pé, ‘Rárá o, Ábúráhámù baba, àmọ́ tí ẹnì kan tó ti kú bá lọ sọ́dọ̀ wọn ní tòótọ́, wọ́n máa ronú pìwà dà.’ 31 Àmọ́ ó sọ fún un pé, ‘Tí wọn ò bá fetí sí Mósè+ àti àwọn Wòlíì, wọn ò lè yí èrò wọn pa dà tí ẹnì kan tó ti kú bá tiẹ̀ dìde.’”
17 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò sí bí àwọn ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀ ò ṣe ní wá. Àmọ́, ẹni tí wọ́n tipasẹ̀ rẹ̀ wá gbé! 2 Ó máa sàn fún un gan-an tí wọ́n bá so ọlọ mọ́ ọn lọ́rùn, tí wọ́n sì jù ú sínú òkun ju pé kó mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí kọsẹ̀.+ 3 Ẹ kíyè sí ara yín. Tí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, bá a wí,+ tó bá sì ronú pìwà dà, dárí jì í.+ 4 Kódà, tó bá ṣẹ̀ ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́, tó sì pa dà wá bá ọ ní ìgbà méje, tó ń sọ pé, ‘Mo ti ronú pìwà dà,’ o gbọ́dọ̀ dárí jì í.”+
5 Àwọn àpọ́sítélì wá sọ fún Olúwa pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.”+ 6 Olúwa wá sọ pé: “Tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ tó rí bíi hóró músítádì, ẹ máa sọ fún igi mọ́líbẹ́rì dúdú yìí pé, ‘Fà tu, kí o sì lọ fìdí sọlẹ̀ sínú òkun!’ ó sì máa gbọ́ tiyín.+
7 “Èwo nínú yín, tó ní ẹrú kan tó ń túlẹ̀ tàbí tó ń tọ́jú agbo ẹran, ló máa sọ fún un tó bá dé láti oko pé, ‘Máa bọ̀ níbí kíá, kí o sì wá jẹun lórí tábìlì’? 8 Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣebí ó máa sọ fún un pé, ‘Ṣètò nǹkan fún mi kí n lè jẹ oúnjẹ alẹ́, gbé épírọ́ọ̀nù kan wọ̀, kí o sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi títí màá fi parí jíjẹ àti mímu, lẹ́yìn náà o wá lè jẹ, kí o sì mu’? 9 Kò ní dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹrú náà, torí pé iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un ló ṣe, àbí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀? 10 Bákan náà, tí ẹ bá ti ṣe gbogbo ohun tí a yàn fún yín, kí ẹ sọ pé: ‘Ẹrú tí kò dáa fún ohunkóhun ni wá. Ohun tó yẹ ká ṣe ni a ṣe.’”+
11 Nígbà tó ń lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó gba àárín Samáríà àti Gálílì kọjá. 12 Bó sì ṣe ń wọ abúlé kan, ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n ní àrùn ẹ̀tẹ̀ wá pàdé rẹ̀, àmọ́ wọ́n dúró lókèèrè.+ 13 Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọ pé: “Jésù, Olùkọ́, ṣàánú wa!” 14 Nígbà tó rí wọn, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ fi ara yín han àwọn àlùfáà.”+ Bí wọ́n ṣe ń lọ, ara wọn mọ́.+ 15 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé ara òun ti yá, ó pa dà, ó sì gbóhùn sókè, ó yin Ọlọ́run lógo. 16 Ó sì wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ Jésù, ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ará Samáríà ni.+ 17 Jésù fún un lésì pé: “Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá la wẹ̀ mọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ibo làwọn mẹ́sàn-án yòókù wà? 18 Ṣé kò sí ẹlòmíì tó pa dà wá yin Ọlọ́run lógo yàtọ̀ sí ọkùnrin yìí tó wá láti orílẹ̀-èdè míì ni?” 19 Ó wá sọ fún un pé: “Dìde, kí o sì máa lọ; ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+
20 Nígbà tí àwọn Farisí bi í nípa ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run ń bọ̀,+ ó dá wọn lóhùn pé: “Dídé Ìjọba Ọlọ́run kò ní pàfiyèsí tó ṣàrà ọ̀tọ̀; 21 àwọn èèyàn ò sì ní máa sọ pé, ‘Wò ó níbí!’ tàbí, ‘Lọ́hùn-ún!’ Torí pé, wò ó! Ìjọba Ọlọ́run wà ní àárín yín.”+
22 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ọjọ́ ń bọ̀ tó máa wù yín pé kí ẹ rí ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ Ọmọ èèyàn, àmọ́ ẹ ò ní rí i. 23 Àwọn èèyàn á máa sọ fún yín pé, ‘Wò ó lọ́hùn-ún!’ tàbí, ‘Wò ó níbí!’ Ẹ má ṣe jáde lọ, ẹ má sì sáré tẹ̀ lé wọn.+ 24 Torí bí mànàmáná ṣe ń kọ láti apá kan ọ̀run dé apá ibòmíì ní ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ èèyàn+ máa rí ní ọjọ́ rẹ̀.+ 25 Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́, ó gbọ́dọ̀ jìyà púpọ̀, ìran yìí sì máa kọ̀ ọ́.+ 26 Bákan náà, bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ní àwọn ọjọ́ Nóà,+ bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rí ní àwọn ọjọ́ Ọmọ èèyàn:+ 27 wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, à ń fa àwọn obìnrin fún ọkọ, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì,+ Ìkún Omi sì dé, ó pa gbogbo wọn run.+ 28 Bákan náà, bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ní àwọn ọjọ́ Lọ́ọ̀tì:+ wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé. 29 Àmọ́ lọ́jọ́ tí Lọ́ọ̀tì kúrò ní Sódómù, òjò iná àti imí ọjọ́ rọ̀ láti ọ̀run, ó sì pa gbogbo wọn run.+ 30 Bẹ́ẹ̀ náà ló máa rí ní ọjọ́ tí a bá ṣí Ọmọ èèyàn payá.+
31 “Ní ọjọ́ yẹn, kí ẹni tó wà lórí ilé, àmọ́ tí àwọn ohun ìní rẹ̀ wà nínú ilé má sọ̀ kalẹ̀ wá kó o, bákan náà, ẹni tó bá wà nínú pápá ò gbọ́dọ̀ pa dà sí àwọn ohun tó wà lẹ́yìn. 32 Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.+ 33 Ẹnikẹ́ni tó bá ń wá bó ṣe máa dáàbò bo ẹ̀mí* rẹ̀ máa pàdánù rẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pàdánù rẹ̀ máa pa á mọ́ láàyè.+ 34 Mò ń sọ fún yín, ní òru yẹn, ẹni méjì máa wà lórí ibùsùn kan náà; a máa mú ọ̀kan lọ, àmọ́ a máa pa ìkejì tì.+ 35 Obìnrin méjì á máa lọ nǹkan lórí ọlọ kan náà; a máa mú ọ̀kan lọ, àmọ́ a máa pa ìkejì tì.” 36* —— 37 Torí náà, wọ́n dá a lóhùn pé: “Ibo ni, Olúwa?” Ó sọ fún wọn pé: “Ibi tí òkú bá wà, ibẹ̀ náà ni àwọn ẹyẹ idì máa kóra jọ sí.”+
18 Ó wá sọ àpèjúwe kan fún wọn nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí wọ́n má sì jẹ́ kó sú wọn,+ 2 ó ní: “Ní ìlú kan, adájọ́ kan wà tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ka àwọn èèyàn sí. 3 Opó kan wà ní ìlú yẹn tó máa ń lọ sọ́dọ̀ adájọ́ náà ṣáá, ó máa ń sọ pé, ‘Rí i dájú pé o dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́ láàárín èmi àti ẹni tó ń bá mi ṣẹjọ́.’ 4 Adájọ́ náà ò kọ́kọ́ fẹ́ gbà, àmọ́ nígbà tó yá, ó sọ fún ara rẹ̀ pé, ‘Bí mi ò tiẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí mi ò sì ka èèyàn kankan sí, 5 torí pé opó yìí ò yéé yọ mí lẹ́nu, màá rí i dájú pé a dá ẹjọ́ rẹ̀ bó ṣe tọ́, kó má bàa máa pa dà wá ṣáá, kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ má bàa sú mi torí ohun tó ń béèrè.’”*+ 6 Olúwa wá sọ pé: “Ẹ gbọ́ ohun tí adájọ́ náà sọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìṣòdodo ni! 7 Ṣé kò wá dájú pé Ọlọ́run máa mú kí a dájọ́ bó ṣe tọ́ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń ké pè é tọ̀sántòru,+ bó ṣe ń ní sùúrù fún wọn?+ 8 Mò ń sọ fún yín, ó máa mú kí a dá ẹjọ́ wọn bó ṣe tọ́ kíákíá. Àmọ́ tí Ọmọ èèyàn bá dé, ṣé ó máa bá ìgbàgbọ́ yìí* ní ayé lóòótọ́?”
9 Ó tún sọ àpèjúwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé òdodo ara wọn, tí wọ́n sì ka àwọn míì sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan: 10 “Ọkùnrin méjì gòkè lọ sínú tẹ́ńpìlì láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisí, ìkejì sì jẹ́ agbowó orí. 11 Farisí náà dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà, ó ń dá sọ àwọn nǹkan yìí pé, ‘Ọlọ́run, mo dúpẹ́ pé mi ò dà bíi gbogbo àwọn èèyàn yòókù, àwọn tó ń fipá gba tọwọ́ àwọn èèyàn, àwọn aláìṣòdodo, àwọn alágbèrè, kódà mi ò dà bí agbowó orí yìí. 12 Ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ni mò ń gbààwẹ̀; mò ń san ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí mo ní.’+ 13 Àmọ́ agbowó orí náà dúró ní ọ̀ọ́kán, kò fẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè láti wo ọ̀run pàápàá, ṣùgbọ́n ó ń lu àyà rẹ̀ ṣáá, ó ń sọ pé, ‘Ọlọ́run, ṣàánú mi,* ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.’+ 14 Mo sọ fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀ kalẹ̀ lọ sílé rẹ̀, a sì kà á sí olódodo ju Farisí yẹn lọ.+ Torí pé gbogbo ẹni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.”+
15 Àwọn èèyàn tún ń mú àwọn ọmọ wọn kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kó lè fọwọ́ kàn wọ́n, àmọ́ nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn wí.+ 16 Ṣùgbọ́n, Jésù pe àwọn ọmọ kéékèèké náà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì dá wọn dúró, torí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irú wọn.+ 17 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé ẹnikẹ́ni tí kò bá gba Ìjọba Ọlọ́run bí ọmọdé kò ní wọnú rẹ̀.”+
18 Ọ̀kan lára àwọn alákòóso wá béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Olùkọ́ Rere, kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 19 Jésù sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kankan, àfi Ọlọ́run nìkan.+ 20 O mọ àwọn àṣẹ náà pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,+ o ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ o ò gbọ́dọ̀ jalè,+ o ò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké,+ bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ.’”+ 21 Ọkùnrin náà wá sọ pé: “Gbogbo nǹkan yìí ni mo ti ń ṣe láti ìgbà ọ̀dọ́ mi.” 22 Lẹ́yìn tó gbọ́ ìyẹn, Jésù sọ fún un pé, “Ohun kan ṣì wà tó ò tíì ṣe: Ta gbogbo ohun tí o ní, kí o pín owó tí o bá rí níbẹ̀ fún àwọn aláìní, wàá sì ní ìṣúra ní ọ̀run; kí o wá máa tẹ̀ lé mi.”+ 23 Nígbà tó gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bà jẹ́ gan-an, torí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.+
24 Jésù wò ó, ó sì sọ pé: “Ẹ wo bó ṣe máa ṣòro tó fún àwọn olówó láti rí ọ̀nà wọ Ìjọba Ọlọ́run!+ 25 Ní tòótọ́, ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ ìránṣọ kọjá ju fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run.”+ 26 Àwọn tó gbọ́ èyí sọ pé: “Ta ló máa wá lè rígbàlà?”+ 27 Ó sọ pé: “Àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún èèyàn ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”+ 28 Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Wò ó! A ti fi àwọn nǹkan tí a ní sílẹ̀, a sì ti tẹ̀ lé ọ.”+ 29 Ó sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, kò sí ẹni tó fi ilé sílẹ̀ tàbí ìyàwó, àwọn arákùnrin, àwọn òbí tàbí àwọn ọmọ nítorí Ìjọba Ọlọ́run,+ 30 tí kò ní gba ìlọ́po-ìlọ́po sí i lásìkò yìí àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀.”*+
31 Ó wá pe àwọn Méjìlá náà sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, gbogbo nǹkan tí a tipasẹ̀ àwọn wòlíì kọ sílẹ̀ nípa Ọmọ èèyàn ló sì máa ṣẹ délẹ̀délẹ̀.*+ 32 Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,+ wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n á hùwà àfojúdi sí i, wọ́n á sì tutọ́ sí i lára.+ 33 Lẹ́yìn tí wọ́n bá sì nà án, wọ́n máa pa á,+ àmọ́ ó máa dìde ní ọjọ́ kẹta.”+ 34 Ṣùgbọ́n, ìkankan nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí ò yé wọn, torí wọn ò mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, wọn ò sì lóye ohun tó sọ.
35 Bí Jésù ṣe ń sún mọ́ Jẹ́ríkò, ọkùnrin afọ́jú kan jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ó ń ṣagbe.+ 36 Torí ó gbọ́ ariwo èrò tó ń kọjá lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wádìí ohun tó ń ṣẹlẹ̀. 37 Wọ́n sọ fún un pé: “Jésù ará Násárẹ́tì ló ń kọjá lọ!” 38 Ló bá kígbe pé: “Jésù, Ọmọ Dáfídì, ṣàánú mi!” 39 Àwọn tó wà níwájú sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí, wọ́n ní kó dákẹ́, àmọ́ ṣe ló túbọ̀ ń kígbe pé: “Ọmọ Dáfídì, ṣàánú mi!” 40 Jésù wá dúró, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ òun. Lẹ́yìn tó sún mọ́ tòsí, Jésù bi í pé: 41 “Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” Ó sọ pé: “Olúwa, jẹ́ kí n pa dà ríran.” 42 Jésù wá sọ fún un pé: “Kí ojú rẹ pa dà ríran; ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ 43 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó pa dà ríran, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e,+ ó ń yin Ọlọ́run lógo. Bákan náà, gbogbo èèyàn yin Ọlọ́run nígbà tí wọ́n rí èyí.+
19 Lẹ́yìn náà, ó wọ Jẹ́ríkò, ó sì ń kọjá lọ. 2 Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sákéù wà níbẹ̀; olórí àwọn agbowó orí ni, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀. 3 Ó gbìyànjú láti rí ẹni tó ń jẹ́ Jésù yìí, àmọ́ èrò tó wà níbẹ̀ ò jẹ́ kó lè rí i, torí èèyàn kúkúrú ni. 4 Ló bá sáré lọ síwájú, ó sì gun igi síkámórè* kó lè rí i, torí ọ̀nà yẹn ló fẹ́ gbà kọjá. 5 Nígbà tí Jésù dé ibẹ̀, ó wòkè, ó sì sọ fún un pé: “Sákéù, tètè sọ̀ kalẹ̀, torí mo gbọ́dọ̀ dé sí ilé rẹ lónìí.” 6 Ló bá yára sọ̀ kalẹ̀, ó sì gbà á lálejò tayọ̀tayọ̀. 7 Nígbà tí wọ́n rí èyí, gbogbo wọn ń kùn pé: “Ọ̀dọ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ló lọ dé sí.”+ 8 Àmọ́ Sákéù dìde dúró, ó sì sọ fún Olúwa pé: “Wò ó! Olúwa, ìdajì àwọn ohun ìní mi ni màá fún àwọn aláìní, ohunkóhun tí mo bá sì fipá gbà* lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni ni màá dá pa dà ní ìlọ́po mẹ́rin.”+ 9 Jésù wá sọ fún un pé: “Lónìí, ìgbàlà ti wọnú ilé yìí, torí pé ọmọ Ábúráhámù ni òun náà. 10 Torí Ọmọ èèyàn wá, kó lè wá ohun tó sọ nù, kó sì gbà á là.”+
11 Bí wọ́n ṣe ń fetí sí àwọn nǹkan yìí, ó sọ àpèjúwe míì torí ó ti sún mọ́ Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì rò pé Ìjọba Ọlọ́run máa fara hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+ 12 Torí náà, ó sọ pé: “Ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní ilé ọlá rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ kan tó jìnnà+ kó lè lọ gba agbára láti jọba, kó sì pa dà. 13 Ó pe mẹ́wàá lára àwọn ẹrú rẹ̀, ó fún wọn ní mínà* mẹ́wàá, ó sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ máa fi ṣòwò títí màá fi dé.’+ 14 Àmọ́ àwọn aráàlú rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán àwọn ikọ̀ tẹ̀ lé e, kí wọ́n sọ pé, ‘A ò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jọba lé wa lórí.’
15 “Nígbà tó pa dà dé lẹ́yìn tó gba agbára láti jọba,* ó pe àwọn ẹrú tó fún ní owó* náà, kó lè mọ èrè tí wọ́n jẹ nínú òwò tí wọ́n ṣe.+ 16 Èyí àkọ́kọ́ wá bá a, ó sọ pé, ‘Olúwa, mo fi mínà rẹ jèrè mínà mẹ́wàá.’+ 17 Ó sọ fún un pé, ‘O káre láé, ẹrú rere! Torí o ti fi hàn pé o jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tó kéré gan-an, jẹ́ aláṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’+ 18 Ìkejì wá dé, ó sọ pé, ‘Olúwa, mo fi mínà rẹ jèrè mínà márùn-ún.’+ 19 Ó sọ fún ẹni yìí náà pé, ‘Ìwọ náà, máa bójú tó ìlú márùn-ún.’ 20 Àmọ́ ẹrú míì dé, ó sì sọ pé, ‘Olúwa, mínà rẹ rèé tí mo fi pa mọ́ sínú aṣọ. 21 Ṣó o rí i, ẹ̀rù rẹ ló bà mí, torí pé èèyàn tó le ni ọ́; ohun tó ò fi sílẹ̀ lo máa ń gbà, ohun tó ò sì gbìn lo máa ń ká.’+ 22 Ó sọ fún un pé, ‘Ẹrú burúkú, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ni mo fi dá ọ lẹ́jọ́. O mọ̀, àbí, pé èèyàn tó le ni mí, ohun tí mi ò fi sílẹ̀ ni mò ń gbà, ohun tí mi ò sì gbìn ni mò ń ká?+ 23 Kí ló dé tó ò fi owó* mi sí báǹkì? Tí n bá sì dé, ǹ bá gbà á pẹ̀lú èlé.’
24 “Ló bá sọ fún àwọn tó dúró nítòsí pé, ‘Ẹ gba mínà náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fún ẹni tó ní mínà mẹ́wàá.’+ 25 Àmọ́ wọ́n sọ fún un pé, ‘Olúwa, mínà mẹ́wàá ló ní!’— 26 ‘Mò ń sọ fún yín, gbogbo ẹni tó bá ní, a máa fi kún èyí tó ní, àmọ́ ẹni tí kò bá ní, a máa gba èyí tó ní pàápàá lọ́wọ́ rẹ̀.+ 27 Bákan náà, ẹ mú àwọn ọ̀tá mi yìí wá síbí, àwọn tí ò fẹ́ kí n jọba lórí wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi.’”
28 Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, ó ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. 29 Nígbà tó sún mọ́ Bẹtifágè àti Bẹ́tánì, ní òkè tí wọ́n ń pè ní Òkè Ólífì,+ ó rán méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn jáde,+ 30 ó sọ pé: “Ẹ lọ sínú abúlé ọ̀ọ́kán yìí, tí ẹ bá sì ti wọ ibẹ̀, ẹ máa rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* kan tí wọ́n so, èyí tí èèyàn kankan ò jókòó lé rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú un wá síbí. 31 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tú u?’ kí ẹ sọ pé, ‘Olúwa fẹ́ lò ó.’” 32 Torí náà, àwọn tó rán níṣẹ́ lọ, wọ́n sì rí i bó ṣe sọ fún wọn gẹ́lẹ́.+ 33 Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn tó ni ín sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yẹn?” 34 Wọ́n sọ pé: “Olúwa fẹ́ lò ó.” 35 Wọ́n wá mú un lọ sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n ju aṣọ àwọ̀lékè wọn sórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n sì mú kí Jésù jókòó sórí rẹ̀.+
36 Bó ṣe ń lọ, wọ́n ń tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sí ojú ọ̀nà.+ 37 Gbàrà tó dé tòsí ojú ọ̀nà tó lọ sísàlẹ̀ láti Òkè Ólífì, inú gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ bẹ̀rẹ̀ sí í dùn, wọ́n sì gbóhùn sókè, wọ́n ń yin Ọlọ́run torí gbogbo iṣẹ́ agbára tí wọ́n ti rí, 38 wọ́n ń sọ pé: “Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ bí Ọba ní orúkọ Jèhófà!* Àlàáfíà ní ọ̀run àti ògo ní ibi gíga lókè!”+ 39 Àmọ́ àwọn kan nínú àwọn Farisí tó wà láàárín èrò sọ fún un pé: “Olùkọ́, bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ wí.”+ 40 Àmọ́ ó fún wọn lésì pé: “Mò ń sọ fún yín, tí àwọn yìí bá dákẹ́, àwọn òkúta máa ké jáde.”
41 Nígbà tó dé tòsí, ó wo ìlú náà, ó sì sunkún lé e lórí,+ 42 ó ní: “Ká sọ pé ìwọ, àní ìwọ, ti fòye mọ àwọn ohun tó jẹ mọ́ àlàáfíà ní ọjọ́ yìí ni, àmọ́ a ti fi wọ́n pa mọ́ kúrò ní ojú rẹ báyìí.+ 43 Torí pé àwọn ọjọ́ máa dé bá ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ máa fi àwọn igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ po, wọ́n máa yí ọ ká, wọ́n á sì dó tì ọ́* yí ká.+ 44 Wọ́n máa fọ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ tó wà nínú rẹ mọ́lẹ̀,+ wọn ò sì ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan nínú rẹ,+ torí pé o ò fi òye mọ àkókò tí a máa bẹ̀ ọ́ wò.”
45 Ó wá wọnú tẹ́ńpìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn tó ń tajà síta,+ 46 ó ń sọ fún wọn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘A ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà,’+ àmọ́ ẹ ti sọ ọ́ di ihò àwọn olè.”+
47 Ó ń kọ́ni lójoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì. Síbẹ̀, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn ẹni pàtàkì láàárín àwọn èèyàn ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á;+ 48 àmọ́ wọn ò rí ọ̀nà kankan tí wọ́n lè gbà ṣe é, torí ṣe ni gbogbo èèyàn ń rọ̀ mọ́ ọn ṣáá kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.+
20 Lọ́jọ́ kan, bó ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nínú tẹ́ńpìlì, tó sì ń kéde ìhìn rere, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà wá, 2 wọ́n sì bi í pé: “Sọ fún wa, àṣẹ wo lo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Àbí ta ló fún ọ ní àṣẹ yìí?”+ 3 Ó dá wọn lóhùn pé: “Èmi náà á bi yín ní ìbéèrè kan, kí ẹ sì dá mi lóhùn: 4 Ṣé láti ọ̀run ni ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fún àwọn èèyàn ti wá àbí látọ̀dọ̀ èèyàn?” 5 Wọ́n jọ rò ó láàárín ara wọn, wọ́n ní: “Tí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ ó máa sọ pé, ‘Kí ló dé tí ẹ ò gbà á gbọ́?’ 6 Àmọ́ tí a bá sọ pé, ‘Látọ̀dọ̀ èèyàn,’ gbogbo èèyàn ló máa sọ wá lókùúta, torí ó dá wọn lójú pé wòlíì ni Jòhánù.”+ 7 Nítorí náà, wọ́n fèsì pé àwọn ò mọ orísun rẹ̀. 8 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Èmi náà ò ní sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín.”
9 Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àpèjúwe yìí fún àwọn èèyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin àjàrà,+ ó gbé e fún àwọn tó ń dáko, ó sì rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fúngbà díẹ̀.+ 10 Nígbà tí àsìkò tó, ó rán ẹrú kan lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń dáko náà, kí wọ́n lè fún un lára èso ọgbà àjàrà náà. Àmọ́ àwọn tó ń dáko náà lù ú, wọ́n sì ní kó máa lọ lọ́wọ́ òfo.+ 11 Àmọ́ ó tún rán ẹrú míì. Wọ́n lu ìyẹn náà, wọ́n dójú tì í,* wọ́n sì ní kó máa lọ lọ́wọ́ òfo. 12 Ó tún rán ẹnì kẹta; wọ́n ṣe ẹni yìí náà léṣe, wọ́n sì jù ú síta. 13 Ni ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà bá sọ pé, ‘Kí ni kí n ṣe? Màá rán ọmọ mi ọ̀wọ́n.+ Ó ṣeé ṣe kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún un.’ 14 Nígbà tí àwọn tó ń dáko náà tajú kán rí i, wọ́n rò ó láàárín ara wọn pé, ‘Ẹni tó máa jogún rẹ̀ nìyí. Ẹ jẹ́ ká pa á, kí ogún náà lè di tiwa.’ 15 Torí náà, wọ́n jù ú sí ìta ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á.+ Kí ni ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà máa wá ṣe sí wọn? 16 Ó máa wá, ó máa pa àwọn tó ń dáko yìí, á sì gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn míì.”
Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n sọ pé: “Kí ìyẹn má ṣẹlẹ̀ láé!” 17 Àmọ́ ó wò wọ́n tààràtà, ó sì sọ pé: “Kí wá ni èyí túmọ̀ sí, ohun tí a kọ pé, ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé’?*+ 18 Gbogbo ẹni tó bá kọ lu òkúta yẹn máa fọ́ túútúú.+ Tó bá sì bọ́ lu ẹnikẹ́ni, ó máa rún ẹni náà wómúwómú.”
19 Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn olórí àlùfáà wá ń wá bí ọwọ́ wọn ṣe máa tẹ̀ ẹ́ ní wákàtí yẹn gangan, àmọ́ wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èèyàn, torí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń fi àpèjúwe yìí bá wí.+ 20 Lẹ́yìn tí wọ́n ṣọ́ ọ dáadáa, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tí wọ́n háyà ní bòókẹ́lẹ́ jáde pé kí wọ́n díbọ́n pé àwọn jẹ́ olódodo, kí wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un,+ kí wọ́n lè fà á lé ìjọba lọ́wọ́, kí wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ gómìnà. 21 Wọ́n bi í pé: “Olùkọ́, a mọ̀ pé o máa ń sọ̀rọ̀, o sì máa ń kọ́ni lọ́nà tó tọ́, o kì í ṣe ojúsàájú rárá, àmọ́ ò ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́: 22 Ṣé ó bófin mu* fún wa láti san owó orí fún Késárì àbí kò bófin mu?” 23 Àmọ́ ó rí i pé alárèékérekè ni wọ́n, ó wá sọ fún wọn pé: 24 “Ẹ fi owó dínárì* kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ta ló wà níbẹ̀?” Wọ́n sọ pé: “Ti Késárì.” 25 Ó sọ fún wọn pé: “Torí náà, ẹ rí i dájú pé ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì,+ àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+ 26 Wọn ò wá lè fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un níwájú àwọn èèyàn, kàkà bẹ́ẹ̀, ìdáhùn rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì dákẹ́.
27 Àmọ́ àwọn kan lára àwọn Sadusí, àwọn tó sọ pé kò sí àjíǹde,+ wá bi í pé:+ 28 “Olùkọ́, Mósè kọ̀wé fún wa pé, ‘Tí arákùnrin ọkùnrin kan bá kú, tó fi ìyàwó sílẹ̀, àmọ́ tí kò bímọ, kí arákùnrin rẹ̀ fẹ́ ìyàwó rẹ̀, kó sì bímọ fún arákùnrin rẹ̀.’+ 29 Ó ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin méje wà. Ẹni àkọ́kọ́ fẹ́ ìyàwó, àmọ́ ó kú láìbímọ. 30 Bákan náà ni ẹnì kejì 31 àti ẹnì kẹta náà fẹ́ ẹ. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn méjèèje; wọ́n kú láìfi ọmọ kankan sílẹ̀. 32 Níkẹyìn, obìnrin náà kú. 33 Tó bá wá dìgbà àjíǹde, èwo nínú wọn ló máa fẹ́? Torí àwọn méjèèje ló ti fi ṣe aya.”
34 Jésù sọ fún wọn pé: “Àwọn ọmọ ètò àwọn nǹkan yìí* máa ń gbéyàwó, a sì máa ń fà wọ́n fún ọkọ, 35 àmọ́ àwọn tí a ti kà yẹ pé kí wọ́n jèrè ètò àwọn nǹkan yẹn àti àjíǹde òkú kì í gbéyàwó, a kì í sì í fà wọ́n fún ọkọ.+ 36 Kódà, wọn ò lè kú mọ́, torí wọ́n dà bí àwọn áńgẹ́lì, ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n ní ti pé wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ àjíǹde. 37 Àmọ́ tó bá kan àjíǹde àwọn òkú, Mósè pàápàá jẹ́ ká mọ̀ nínú ìtàn igi ẹlẹ́gùn-ún, nígbà tó pe Jèhófà* ní ‘Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù.’+ 38 Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, àmọ́ ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn alààyè, torí lójú rẹ̀,* gbogbo wọn wà láàyè.”+ 39 Àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin wá dá a lóhùn pé: “Olùkọ́, ohun tí o sọ dáa.” 40 Torí wọn ò ní ìgboyà láti bi í ní ìbéèrè kankan mọ́.
41 Ó wá bi wọ́n pé: “Kí nìdí tí wọ́n fi sọ pé ọmọ Dáfídì ni Kristi?+ 42 Torí Dáfídì fúnra rẹ̀ sọ nínú ìwé Sáàmù pé, ‘Jèhófà* sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi 43 títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”’+ 44 Torí náà, Dáfídì pè é ní Olúwa; báwo ló ṣe wá jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
45 Bí gbogbo èèyàn ṣe ń fetí sílẹ̀, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: 46 “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa rìn kiri nínú aṣọ ńlá, tí wọ́n sì fẹ́ràn kí wọ́n máa kí wọn níbi ọjà, wọ́n fẹ́ ìjókòó iwájú* nínú àwọn sínágọ́gù àti ibi tó lọ́lá jù níbi oúnjẹ alẹ́,+ 47 wọ́n ń jẹ ilé* àwọn opó run, wọ́n sì ń gba àdúrà tó gùn láti ṣe ojú ayé.* Ìdájọ́ tó le* gan-an ni àwọn yìí máa gbà.”
21 Bó ṣe gbójú sókè, ó rí i tí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àwọn àpótí ìṣúra.+ 2 Ó wá rí opó aláìní kan tó fi ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré gan-an* síbẹ̀,+ 3 ó sì sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé ohun tí opó aláìní yìí fi sílẹ̀ ju ti gbogbo wọn lọ.+ 4 Torí gbogbo àwọn yìí fi ẹ̀bùn sílẹ̀ látinú àjẹṣẹ́kù wọn, àmọ́ òun, láìka pé kò ní lọ́wọ́,* ó fi gbogbo ohun tó ní láti gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró síbẹ̀.”+
5 Lẹ́yìn náà, nígbà tí àwọn kan ń sọ̀rọ̀ nípa tẹ́ńpìlì, bí wọ́n ṣe fi òkúta tó rẹwà àti àwọn ohun tí a yà sí mímọ́ ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,+ 6 ó sọ pé: “Ní ti àwọn nǹkan yìí tí ẹ̀ ń rí báyìí, ọjọ́ ń bọ̀ tí wọn ò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta míì láìwó o palẹ̀.”+ 7 Wọ́n wá bi í pé: “Olùkọ́, ìgbà wo gan-an ni àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, kí ló sì máa jẹ́ àmì ìgbà tí àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀?”+ 8 Ó sọ pé: “Ẹ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa ṣì yín lọ́nà;+ torí ọ̀pọ̀ èèyàn máa wá ní orúkọ mi, wọ́n á sọ pé, ‘Èmi ni ẹni náà’ àti pé, ‘Àkókò náà ti sún mọ́lé.’ Ẹ má tẹ̀ lé wọn.+ 9 Bákan náà, tí ẹ bá gbọ́ nípa ogun àti rògbòdìyàn,* ẹ má bẹ̀rù. Torí àwọn nǹkan yìí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, àmọ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀ kọ́ ni òpin máa dé.”+
10 Ó wá sọ fún wọn pé: “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè+ àti ìjọba sí ìjọba.+ 11 Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára máa wáyé, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì;+ ẹ máa rí àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù, àwọn àmì tó lágbára sì máa wà láti ọ̀run.
12 “Àmọ́ kí gbogbo àwọn nǹkan yìí tó ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn máa gbé ọwọ́ wọn lé yín, wọ́n á sì ṣe inúnibíni sí yín,+ wọ́n á fà yín lé àwọn sínágọ́gù lọ́wọ́, wọ́n á sì fi yín sẹ́wọ̀n. Wọ́n máa mú yín lọ síwájú àwọn ọba àti àwọn gómìnà nítorí orúkọ mi.+ 13 Èyí máa jẹ́ kí ẹ lè jẹ́rìí. 14 Torí náà, ẹ pinnu lọ́kàn yín pé ẹ ò ní fi bí ẹ ṣe máa gbèjà ara yín dánra wò ṣáájú,+ 15 torí màá fún yín ní àwọn ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n tí gbogbo àwọn alátakò yín lápapọ̀ ò ní lè ta kò tàbí kí wọ́n jiyàn rẹ̀.+ 16 Bákan náà, àwọn òbí, àwọn arákùnrin, àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn ọ̀rẹ́ pàápàá máa fà yín léni lọ́wọ́,* wọ́n máa pa àwọn kan nínú yín,+ 17 gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.+ 18 Àmọ́ ìkankan nínú irun orí yín pàápàá kò ní ṣègbé.+ 19 Tí ẹ bá ní ìfaradà, ẹ máa lè pa ẹ̀mí yín mọ́.*+
20 “Àmọ́, tí ẹ bá rí i tí àwọn ọmọ ogun pàgọ́ yí Jerúsálẹ́mù ká,+ nígbà náà, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tó máa dahoro ti sún mọ́lé.+ 21 Kí àwọn tó wà ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè,+ kí àwọn tó wà nínú ìlú náà kúrò níbẹ̀, kí àwọn tó sì wà ní ìgbèríko má wọ ibẹ̀, 22 torí pé àwọn ọjọ́ yìí la máa ṣe ìdájọ́,* kí gbogbo ohun tí a kọ lè ṣẹ. 23 Ó mà ṣe o, fún àwọn aláboyún àti àwọn tó ń tọ́ ọmọ jòjòló ní àwọn ọjọ́ yẹn o!+ Torí wàhálà ńlá máa bá ilẹ̀ náà, ìbínú sì máa wá sórí àwọn èèyàn yìí. 24 Wọ́n máa fi ojú idà ṣá wọn balẹ̀, wọ́n á sì kó wọn lẹ́rú lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè;+ àwọn orílẹ̀-èdè* sì máa tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀, títí àkókò tí a yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè* fi máa pé.+
25 “Bákan náà, àwọn àmì máa wà nínú oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀,+ ìdààmú sì máa bá àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé, wọn ò ní mọ ọ̀nà àbáyọ torí ariwo omi òkun àti bó ṣe ń ru gùdù. 26 Àwọn èèyàn máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti àwọn ohun tí wọ́n ń retí pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, torí a máa mi àwọn agbára ọ̀run. 27 Nígbà náà, wọ́n á rí Ọmọ èèyàn+ tó ń bọ̀ nínú àwọsánmà* pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.+ 28 Àmọ́ tí àwọn nǹkan yìí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, ẹ nàró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, torí ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.”
29 Ó wá sọ àpèjúwe kan fún wọn pé: “Ẹ kíyè sí igi ọ̀pọ̀tọ́ àti gbogbo igi yòókù.+ 30 Tí wọ́n bá ti ń rúwé, ẹ máa rí i fúnra yín, ẹ sì máa mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti sún mọ́lé nìyẹn. 31 Bákan náà, tí ẹ bá rí i tí àwọn nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé. 32 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó dájú pé ìran yìí ò ní kọjá lọ títí gbogbo nǹkan fi máa ṣẹlẹ̀.+ 33 Ọ̀run àti ayé máa kọjá lọ, àmọ́ ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ mi ò ní kọjá lọ.+
34 “Àmọ́ ẹ kíyè sí ara yín, kí àjẹjù, ọtí àmujù + àti àníyàn ìgbésí ayé má bàa di ẹrù pa ọkàn yín,+ láìròtẹ́lẹ̀ kí ọjọ́ yẹn sì dé bá yín lójijì 35 bí ìdẹkùn.+ Torí ó máa dé bá gbogbo àwọn tó ń gbé ní gbogbo ayé. 36 Torí náà, ẹ máa wà lójúfò,+ kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nígbà gbogbo,+ kí ẹ lè bọ́ nínú gbogbo nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ yìí, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ èèyàn.”+
37 Torí náà, ní ọ̀sán, ó máa ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì, àmọ́ ní alẹ́, ó máa ń lọ dé sí òkè tí wọ́n ń pè ní Òkè Ólífì. 38 Gbogbo èèyàn sì máa ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àárọ̀ kùtù kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì.
22 Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú, tí wọ́n ń pè ní Ìrékọjá,+ ti ń sún mọ́lé.+ 2 Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin sì ń wá ọ̀nà tó máa dáa gan-an láti rẹ́yìn rẹ̀,+ torí wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èèyàn.+ 3 Sátánì wá wọnú Júdásì, tí wọ́n ń pè ní Ìsìkáríọ́tù, tó wà lára àwọn Méjìlá náà,+ 4 ó sì lọ bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa fà á lé wọn lọ́wọ́.+ 5 Èyí múnú wọn dùn gan-an, wọ́n sì gbà láti fún un ní owó fàdákà.+ 6 Torí náà, ó gbà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá ìgbà tó máa dáa jù láti fà á lé wọn lọ́wọ́ níbi tí kò sí èrò.
7 Nígbà tó di ọjọ́ àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú, tí wọ́n gbọ́dọ̀ fi ẹran Ìrékọjá rúbọ,+ 8 Jésù rán Pétérù àti Jòhánù lọ, ó ní: “Ẹ lọ pèsè Ìrékọjá sílẹ̀ fún wa ká lè jẹ ẹ́.”+ 9 Wọ́n sọ fún un pé: “Ibo lo fẹ́ ká pèsè rẹ̀ sí?” 10 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Tí ẹ bá ti wọnú ìlú náà, ọkùnrin kan tó ru ìṣà omi máa pàdé yín. Ẹ tẹ̀ lé e lọ sínú ilé tó bá wọ̀.+ 11 Kí ẹ sì sọ fún ẹni tó ni ilé náà pé, ‘Olùkọ́ ní ká bi ọ́ pé: “Ibo ni yàrá àlejò wà, tí èmi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi ti lè jẹ Ìrékọjá?”’ 12 Ọkùnrin yẹn sì máa fi yàrá ńlá kan hàn yín lókè, tó ti ní àwọn ohun tí a nílò. Ẹ ṣètò rẹ̀ síbẹ̀.” 13 Torí náà, wọ́n lọ, wọ́n rí i bó ṣe sọ fún wọn gẹ́lẹ́, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá.
14 Nígbà tí wákàtí náà wá tó, ó jókòó* sídìí tábìlì pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì.+ 15 Ó sọ fún wọn pé: “Ó wù mí gan-an pé kí n jẹ Ìrékọjá yìí pẹ̀lú yín kí n tó jìyà; 16 torí mò ń sọ fún yín pé, mi ò ní jẹ ẹ́ mọ́ títí a fi máa mú un ṣẹ nínú Ìjọba Ọlọ́run.” 17 Ó wá gba ife kan, ó dúpẹ́, ó sì sọ pé: “Ẹ gbà, kí ẹ gbé e yí ká láàárín ara yín, 18 torí mò ń sọ fún yín, láti ìsinsìnyí lọ, mi ò tún ní mu àwọn ohun tí wọ́n fi àjàrà ṣe mọ́ títí Ìjọba Ọlọ́run fi máa dé.”
19 Bákan náà, ó mú búrẹ́dì,+ ó dúpẹ́, ó bù ú, ó sì fún wọn, ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ara mi,+ tí a máa fúnni nítorí yín.+ Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+ 20 Ó ṣe bákan náà ní ti ife náà, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ oúnjẹ alẹ́, ó ní: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun+ tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá,*+ tí a máa dà jáde nítorí yín.+
21 “Àmọ́ ẹ wò ó! ọwọ́ èmi àti ẹni tó máa dà mí jọ wà lórí tábìlì.+ 22 Torí, ní tòótọ́, Ọmọ èèyàn ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ bí a ṣe pinnu rẹ̀; + síbẹ̀, ọkùnrin tí a tipasẹ̀ rẹ̀ fi í léni lọ́wọ́ gbé!”+ 23 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ láàárín ara wọn nípa ẹni tó máa ṣe èyí nínú wọn lóòótọ́.+
24 Àmọ́, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn gidigidi nípa ẹni tí wọ́n kà sí ẹni tó tóbi jù nínú wọn.+ 25 Ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé: “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè máa ń jẹ ọ̀gá lé àwọn èèyàn lórí, wọ́n sì máa ń pe àwọn tó ní àṣẹ lórí wọn ní Olóore.+ 26 Àmọ́ kò yẹ kí ẹ̀yin ṣe bẹ́ẹ̀.+ Kí ẹni tó tóbi jù láàárín yín dà bí ẹni tó kéré jù,+ kí ẹni tó jẹ́ aṣáájú sì dà bí ẹni tó ń ṣe ìránṣẹ́. 27 Torí ta ló tóbi jù, ṣé ẹni tó ń jẹun* ni àbí ẹni tó ń gbé oúnjẹ wá?* Ṣebí ẹni tó ń jẹun* ni? Àmọ́ mo wà láàárín yín bí ẹni tó ń gbé oúnjẹ wá.*+
28 “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin lẹ ti dúró tì mí+ nígbà àdánwò;+ 29 mo sì bá yín dá májẹ̀mú fún ìjọba kan, bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú,+ 30 kí ẹ lè máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ní tábìlì mi nínú Ìjọba mi,+ kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́+ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì.+
31 “Símónì, Símónì, wò ó! Sátánì ti béèrè pé òun fẹ́ gba gbogbo yín, kó lè kù yín bí àlìkámà.*+ 32 Àmọ́ mo ti bá yín bẹ̀bẹ̀, kí ìgbàgbọ́ yín má bàa yẹ̀; + ní ti ìwọ, gbàrà tí o bá pa dà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.”+ 33 Ó wá sọ fún un pé: “Olúwa, mo ṣe tán láti bá ọ lọ sẹ́wọ̀n, kí n sì bá ọ kú.”+ 34 Àmọ́ ó sọ pé: “Mò ń sọ fún ọ, Pétérù, àkùkọ ò ní kọ lónìí tí wàá fi sẹ́ lẹ́ẹ̀mẹta pé o ò mọ̀ mí.”+
35 Ó tún sọ fún wọn pé: “Nígbà tí mo ní kí ẹ lọ láìgbé àpò owó, àpò oúnjẹ àti bàtà,+ ẹ ò ṣaláìní nǹkan kan, àbí ẹ ṣaláìní?” Wọ́n dáhùn pé: “Rárá!” 36 Ó wá sọ fún wọn pé: “Àmọ́ ní báyìí, kí ẹni tó ní àpò owó gbé e, bẹ́ẹ̀ náà ni àpò oúnjẹ, kí ẹni tí kò bá ní idà ta aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, kó sì ra ọ̀kan. 37 Torí mò ń sọ fún yín pé ohun tó wà ní àkọsílẹ̀ ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe sí mi délẹ̀délẹ̀, pé, ‘A kà á mọ́ àwọn arúfin.’+ Torí èyí ń ṣẹ sí mi lára.”+ 38 Wọ́n wá sọ pé: “Olúwa, wò ó! idà méjì nìyí.” Ó sọ fún wọn pé: “Ó ti tó.”
39 Nígbà tó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí Òkè Ólífì bó ṣe máa ń ṣe, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà sì tẹ̀ lé e.+ 40 Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.”+ 41 Ó wá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ sí ìwọ̀n ibi tí òkúta lè dé tí wọ́n bá jù ú látọ̀dọ̀ wọn, ó kúnlẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà, 42 ó ní: “Baba, tí o bá fẹ́, mú ife yìí kúrò lórí mi. Àmọ́, ìfẹ́ rẹ ni kó ṣẹ, kì í ṣe tèmi.”+ 43 Áńgẹ́lì kan wá fara hàn án láti ọ̀run, ó sì fún un lókun.+ 44 Àmọ́ ìdààmú bá a gan-an débi pé ṣe ló túbọ̀ ń gbàdúrà taratara;+ òógùn rẹ̀ sì dà bí ẹ̀jẹ̀ tó ń kán sílẹ̀. 45 Nígbà tó dìde níbi tó ti ń gbàdúrà, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì bá wọn tí wọ́n ń tòògbé, ẹ̀dùn ọkàn ti mú kó rẹ̀ wọ́n gan-an.+ 46 Ó sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sùn? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.”+
47 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! àwọn èrò dé, ọkùnrin tí wọ́n ń pè ní Júdásì, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà, ló ṣáájú wọn, ó sì sún mọ́ Jésù kó lè fẹnu kò ó lẹ́nu.+ 48 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Júdásì, ṣé o fẹ́ fi ẹnu ko Ọmọ èèyàn lẹ́nu kí o lè dalẹ̀ rẹ̀ ni?” 49 Nígbà tí àwọn tó yí i ká rí ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀, wọ́n sọ pé: “Olúwa, ṣé ká fi idà bá wọn jà?” 50 Ọ̀kan nínú wọn tiẹ̀ ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó gé etí rẹ̀ ọ̀tún dà nù.+ 51 Àmọ́ Jésù fèsì pé: “Ó tó.” Ló bá fọwọ́ kan etí ọkùnrin náà, ó sì wò ó sàn. 52 Jésù wá sọ fún àwọn olórí àlùfáà, àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì àti àwọn àgbààgbà tí wọ́n wá a wá síbẹ̀ pé: “Ṣé olè lẹ fẹ́ wá mú ni, tí ẹ fi kó idà àti kùmọ̀ dání?+ 53 Nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nínú tẹ́ńpìlì lójoojúmọ́,+ ẹ ò fọwọ́ kàn mí.+ Àmọ́ wákàtí yín àti ti àṣẹ òkùnkùn nìyí.”+
54 Wọ́n wá fàṣẹ ọba mú un, wọ́n sì mú un lọ,+ wọ́n mú un wá sínú ilé àlùfáà àgbà; àmọ́ Pétérù ń tẹ̀ lé wọn ní òkèèrè.+ 55 Nígbà tí wọ́n dáná láàárín àgbàlá, tí wọ́n sì jọ jókòó, Pétérù jókòó láàárín wọn.+ 56 Àmọ́ ìránṣẹ́bìnrin kan rí i tó jókòó síbi iná náà, ó wò ó dáadáa, ó sì sọ pé: “Ọkùnrin yìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.” 57 Àmọ́ ó sẹ́, ó ní: “Ìwọ obìnrin yìí, mi ò mọ̀ ọ́n.” 58 Nígbà tó ṣe díẹ̀, ẹlòmíì rí i, ó sì sọ pé: “Ìwọ náà wà lára wọn.” Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Wò ó ọkùnrin yìí, mi ò sí lára wọn.”+ 59 Lẹ́yìn nǹkan bíi wákàtí kan, ọkùnrin míì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹnu mọ́ ọn pé: “Ó dájú pé ọkùnrin yìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀, torí ká sòótọ́, ará Gálílì ni!” 60 Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Ìwọ ọkùnrin yìí, mi ò mọ ohun tó ò ń sọ.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àkùkọ kọ. 61 Ni Olúwa bá yíjú pa dà, ó sì wo Pétérù tààràtà, Pétérù wá rántí ohun tí Olúwa sọ fún un pé: “Kí àkùkọ tó kọ lónìí, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ 62 Ló bá bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.
63 Àwọn ọkùnrin tó mú Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n ń lù ú;+ 64 lẹ́yìn tí wọ́n sì fi nǹkan bò ó lójú, wọ́n ń bi í pé: “Sọ tẹ́lẹ̀! Ta lẹni tó gbá ọ?” 65 Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ òdì míì sí i.
66 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kóra jọ,+ wọ́n sì mú un lọ sínú gbọ̀ngàn Sàhẹ́ndìrìn wọn, wọ́n sọ pé: 67 “Sọ fún wa, tó bá jẹ́ ìwọ ni Kristi náà.”+ Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Tí mo bá tiẹ̀ sọ fún yín, ẹ ò ní gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ rárá. 68 Bákan náà, tí mo bá bi yín ní ìbéèrè, ẹ ò ní dáhùn. 69 Àmọ́ láti ìsinsìnyí lọ, Ọmọ èèyàn+ máa jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”+ 70 Ni gbogbo wọn bá sọ pé: “Ṣé ìwọ wá ni Ọmọ Ọlọ́run?” Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ń sọ pé èmi ni.” 71 Wọ́n sọ pé: “Kí la tún nílò ẹ̀rí fún? Torí a ti fetí ara wa gbọ́ ọ lẹ́nu òun fúnra rẹ̀.”+
23 Torí náà, èrò rẹpẹtẹ náà gbéra, gbogbo wọn pátá, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ Pílátù.+ 2 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀sùn kàn án+ pé: “A rí i pé ọkùnrin yìí fẹ́ dojú ìjọba ilẹ̀ wa dé, ó ní ká má ṣe san owó orí fún Késárì,+ ó sì ń pe ara rẹ̀ ní Kristi ọba.”+ 3 Pílátù wá bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ọba Àwọn Júù?” Ó fèsì pé: “Òun ni ìwọ fúnra rẹ ń sọ yẹn.”+ 4 Pílátù wá sọ fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn èrò náà pé: “Mi ò rí ìwà ọ̀daràn kankan tí ọkùnrin yìí hù.”+ 5 Àmọ́ wọn ò gbà, wọ́n ń sọ pé: “Ó ń ru àwọn èèyàn sókè ní ti pé ó ń kọ́ wọn káàkiri gbogbo Jùdíà, bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì títí dé ibí yìí pàápàá.” 6 Nígbà tí Pílátù gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn, ó béèrè bóyá ará Gálílì ni ọkùnrin náà. 7 Lẹ́yìn tó rí i dájú pé abẹ́ àṣẹ Hẹ́rọ́dù ló wà, ó ní kí wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù,+ tí òun náà wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn.
8 Nígbà tí Hẹ́rọ́dù rí Jésù, inú rẹ̀ dùn gan-an. Ó ti pẹ́ tó ti fẹ́ rí Jésù torí ó ti gbọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa rẹ̀,+ ó sì ń retí pé kí òun rí i kó ṣiṣẹ́ àmì díẹ̀. 9 Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bò ó, àmọ́ kò dá a lóhùn rárá.+ 10 Síbẹ̀, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin ń dìde ṣáá, wọ́n sì ń fẹ̀sùn kàn án kíkankíkan. 11 Hẹ́rọ́dù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wá kàn án lábùkù,+ ó wọ aṣọ tó rẹwà fún un láti fi ṣe ẹlẹ́yà,+ ó sì ní kí wọ́n mú un pa dà sọ́dọ̀ Pílátù. 12 Ọjọ́ yẹn gan-an ni Hẹ́rọ́dù àti Pílátù di ọ̀rẹ́, torí ṣáájú ìgbà yẹn, ọ̀tá ni àwọn méjèèjì jẹ́ síra wọn.
13 Pílátù wá pe àwọn olórí àlùfáà, àwọn alákòóso àti àwọn èèyàn jọ, 14 ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ mú ọkùnrin yìí wá sọ́dọ̀ mi pé ó ń mú kí àwọn èèyàn dìtẹ̀. Ẹ wò ó! Mo yẹ̀ ẹ́ wò níwájú yín, àmọ́ mi ò rí ẹ̀rí pé ọkùnrin yìí jẹ̀bi ìkankan nínú ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn án.+ 15 Kódà, Hẹ́rọ́dù náà ò rí ẹ̀rí, torí ó dá a pa dà sọ́dọ̀ wa, ẹ wò ó! kò ṣe ohunkóhun tí ikú fi tọ́ sí i. 16 Torí náà, ṣe ni màá fìyà jẹ ẹ́,+ màá sì tú u sílẹ̀.” 17 * —— 18 Àmọ́ gbogbo èrò kígbe pé: “Pa ọkùnrin yìí dà nù,* kí o sì tú Bárábà sílẹ̀ fún wa!”+ 19 (Wọ́n ti fi ọkùnrin yìí sẹ́wọ̀n torí ìdìtẹ̀ sí ìjọba tó wáyé nínú ìlú náà àti nítorí ìpànìyàn.) 20 Pílátù tún gbóhùn sókè bá wọn sọ̀rọ̀, torí ó fẹ́ tú Jésù sílẹ̀.+ 21 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!”*+ 22 Ó sọ fún wọn lẹ́ẹ̀kẹta pé: “Kí ló dé? Nǹkan burúkú wo ni ọkùnrin yìí ṣe? Mi ò rí ohunkóhun tó ṣe tí ikú fi tọ́ sí i; torí náà, ṣe ni màá fìyà jẹ ẹ́, màá sì tú u sílẹ̀.” 23 Ni wọ́n bá kọ̀ jálẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé àfi kó pa á,* ọ̀rọ̀ wọn ló sì borí.+ 24 Torí náà, Pílátù pinnu pé òun máa ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. 25 Ó tú ọkùnrin tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀, ẹni tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ìdìtẹ̀ sí ìjọba àti ìpànìyàn, àmọ́ ó fa Jésù lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ sí i.
26 Bí wọ́n ṣe ń mú un lọ, wọ́n mú ẹnì kan, ìyẹn Símónì ará Kírénè, ó ń bọ̀ láti ìgbèríko, wọ́n sì gbé òpó igi oró* náà lé e pé kó gbé e tẹ̀ lé Jésù.+ 27 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ń tẹ̀ lé e, títí kan àwọn obìnrin tó ń lu ara wọn ṣáá torí ẹ̀dùn ọkàn, tí wọ́n sì ń pohùn réré ẹkún nítorí rẹ̀. 28 Jésù yíjú sí àwọn obìnrin náà, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, ẹ má sunkún torí mi mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ sunkún torí ara yín àti àwọn ọmọ yín;+ 29 torí ẹ wò ó! ọjọ́ ń bọ̀ tí àwọn èèyàn máa sọ pé, ‘Aláyọ̀ ni àwọn àgàn, àwọn ilé ọlẹ̀ tí kò bímọ àti àwọn ọmú tí ọmọ kò mu!’+ 30 Wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn òkè ńláńlá pé, ‘Ẹ wó lù wá!’ àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀!’+ 31 Tí wọ́n bá ṣe àwọn nǹkan yìí nígbà tí igi ṣì tutù, kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá gbẹ?”
32 Wọ́n tún ń mú àwọn ọkùnrin méjì míì tí wọ́n jẹ́ ọ̀daràn lọ, kí wọ́n lè pa wọ́n pẹ̀lú rẹ̀.+ 33 Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọ́n ń pè ní Agbárí,+ wọ́n kàn án mọ́gi níbẹ̀, àwọn ọ̀daràn náà sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ọ̀kan ní ọ̀tún rẹ̀ àti ọ̀kan ní òsì rẹ̀.+ 34 Àmọ́ Jésù ń sọ pé: “Baba, dárí jì wọ́n, torí wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Bákan náà, wọ́n ṣẹ́ kèké láti fi pín aṣọ rẹ̀.+ 35 Àwọn èèyàn sì dúró, wọ́n ń wòran. Àmọ́ àwọn alákòóso ń yínmú, wọ́n ń sọ pé: “Ó gba àwọn ẹlòmíì là; kó gba ara rẹ̀ là tó bá jẹ́ òun ni Kristi ti Ọlọ́run, Àyànfẹ́.”+ 36 Àwọn ọmọ ogun pàápàá fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n wá, wọ́n sì fún un ní wáìnì kíkan,+ 37 wọ́n ń sọ pé: “Tó bá jẹ́ ìwọ ni Ọba Àwọn Júù, gba ara rẹ là.” 38 Àkọlé kan tún wà lórí rẹ̀ pé: “Ọba Àwọn Júù nìyí.”+
39 Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn tí wọ́n gbé kọ́ síbẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í bú u+ pé: “Ṣebí ìwọ ni Kristi, àbí ìwọ kọ́? Gba ara rẹ là, kí o sì gba àwa náà là!” 40 Ẹnì kejì bá a wí, ó sọ fún un pé: “Ṣé o ò bẹ̀rù Ọlọ́run rárá ni, ní báyìí tó jẹ́ pé ìdájọ́ kan náà nìwọ náà gbà? 41 Ó tọ́ sí àwa, torí pé ohun tó yẹ wá là ń gbà yìí torí àwọn ohun tí a ṣe; àmọ́ ọkùnrin yìí ò ṣe nǹkan kan tó burú.” 42 Ó wá sọ pé: “Jésù, rántí mi tí o bá dé inú Ìjọba rẹ.”+ 43 Ó sì sọ fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, o máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”+
44 Ó ti tó nǹkan bíi wákàtí kẹfà* báyìí, síbẹ̀ òkùnkùn ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà títí di wákàtí kẹsàn-án,*+ 45 torí pé oòrùn ò ràn; aṣọ ìdábùú ibi mímọ́+ wá ya délẹ̀ ní àárín.+ 46 Jésù sì ké jáde, ó sọ pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.”+ Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó gbẹ́mìí mì.*+ 47 Nígbà tí ọ̀gágun náà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo, ó ní: “Ní tòótọ́, olódodo ni ọkùnrin yìí.”+ 48 Nígbà tí gbogbo èrò tó kóra jọ síbẹ̀ láti wòran rí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀, wọ́n pa dà sílé, wọ́n ń lu àyà wọn. 49 Gbogbo àwọn tó mọ̀ ọ́n sì dúró ní ọ̀ọ́kán. Bákan náà, àwọn obìnrin tó tẹ̀ lé e láti Gálílì wà níbẹ̀, wọ́n rí àwọn nǹkan yìí.+
50 Wò ó! ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Jósẹ́fù, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ ni, èèyàn dáadáa ni, ó sì jẹ́ olódodo.+ 51 (Ọkùnrin yìí ò tì wọ́n lẹ́yìn nígbà tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀, tí wọ́n sì ṣe ohun tí wọ́n ṣe.) Arimatíà, ìlú àwọn ará Jùdíà, ló ti wá, ó sì ń retí Ìjọba Ọlọ́run. 52 Ọkùnrin yìí wọlé lọ síwájú Pílátù, ó sì ní kí wọ́n gbé òkú Jésù fún òun. 53 Ó wá gbé e sọ̀ kalẹ̀,+ ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa* dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì* tí wọ́n gbẹ́ sínú àpáta,+ tí wọn ò tẹ́ ẹnì kankan sí rí. 54 Ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́+ ni, Sábáàtì+ ò sì ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀. 55 Àmọ́ àwọn obìnrin tó bá a wá láti Gálílì tẹ̀ lé e lọ, wọ́n yọjú wo ibojì* náà, wọ́n sì rí i bí wọ́n ṣe tẹ́ òkú rẹ̀,+ 56 wọ́n wá pa dà lọ pèsè èròjà tó ń ta sánsán àti àwọn òróró onílọ́fínńdà. Àmọ́ wọ́n sinmi ní Sábáàtì+ bí a ṣe pa á láṣẹ.
24 Àmọ́ ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, wọ́n wá síbi ibojì* náà ní àárọ̀ kùtù, wọ́n gbé èròjà tó ń ta sánsán tí wọ́n ṣe dání.+ 2 Ṣùgbọ́n wọ́n rí i pé òkúta náà ti yí kúrò níbi ibojì* náà,+ 3 nígbà tí wọ́n sì wọlé, wọn ò rí òkú Jésù Olúwa.+ 4 Bí wọ́n ṣe ń ro ọ̀rọ̀ náà torí ó rú wọn lójú, wò ó! ọkùnrin méjì tí aṣọ wọn ń kọ mànà dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. 5 Ẹ̀rù ba àwọn obìnrin náà, wọ́n sì sorí kodò, àwọn ọkùnrin náà wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń wá alààyè láàárín àwọn òkú?+ 6 Kò sí níbí, a ti gbé e dìde. Ẹ rántí bó ṣe bá yín sọ̀rọ̀ nígbà tó wà ní Gálílì, 7 tó sọ pé a gbọ́dọ̀ fi Ọmọ èèyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n kàn án mọ́gi, kó sì dìde ní ọjọ́ kẹta.”+ 8 Wọ́n wá rántí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀,+ 9 wọ́n dé látibi ibojì* náà, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan yìí fún àwọn Mọ́kànlá náà àti gbogbo àwọn yòókù.+ 10 Àwọn obìnrin náà ni Màríà Magidalénì, Jòánà àti Màríà ìyá Jémíìsì. Bákan náà, àwọn obìnrin yòókù tó wà pẹ̀lú wọn ń sọ àwọn nǹkan yìí fún àwọn àpọ́sítélì. 11 Àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí dà bí ìsọkúsọ létí wọn, wọn ò sì gba àwọn obìnrin náà gbọ́.
12 Àmọ́ Pétérù dìde, ó sì sáré lọ sí ibojì* náà, nígbà tó bẹ̀rẹ̀ wo iwájú, aṣọ ọ̀gbọ̀* nìkan ló rí níbẹ̀. Torí náà, ó lọ, ó ń ronú ohun tó lè ti ṣẹlẹ̀.
13 Àmọ́ wò ó! lọ́jọ́ yẹn gangan, méjì nínú wọn ń rìnrìn àjò lọ sí abúlé kan tí wọ́n ń pè ní Ẹ́máọ́sì, ó tó nǹkan bíi máìlì méje* láti Jerúsálẹ́mù, 14 wọ́n sì jọ ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ yìí.
15 Bí wọ́n ṣe jọ ń sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń jíròrò àwọn nǹkan yìí, Jésù fúnra rẹ̀ sún mọ́ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn rìn, 16 àmọ́ a ò jẹ́ kí wọ́n dá a mọ̀.+ 17 Ó sọ fún wọn pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ wo lẹ̀ ń bá ara yín fà bí ẹ ṣe ń rìn lọ?” Wọ́n wá dúró sójú kan, inú wọn ò sì dùn. 18 Èyí tó ń jẹ́ Kíléópà dá a lóhùn pé: “Ṣé àjèjì tó ń dá gbé ní Jerúsálẹ́mù ni ọ́ ni, tó ò fi mọ* àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu ọjọ́ mélòó kan yìí?” 19 Ó bi wọ́n pé: “Àwọn nǹkan wo?” Wọ́n sọ fún un pé: “Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù ará Násárẹ́tì,+ ẹni tó fi hàn pé wòlíì tó lágbára ni òun nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe níwájú Ọlọ́run àti gbogbo èèyàn;+ 20 àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alákòóso wa ṣe fà á kalẹ̀ pé kí wọ́n dájọ́ ikú fún un,+ tí wọ́n sì kàn án mọ́gi. 21 Àmọ́ àwa ń retí pé ọkùnrin yìí ni ẹni tó máa gba Ísírẹ́lì sílẹ̀.+ Àní, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan yìí, ọjọ́ kẹta nìyí tí àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀. 22 Bákan náà, àwọn obìnrin kan láàárín wa tún mú kí ẹnu yà wá, torí wọ́n lọ síbi ibojì* náà ní àárọ̀ kùtù,+ 23 nígbà tí wọn ò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá sọ fún wa pé àwọn tún rí ohun kan tó ju agbára ẹ̀dá lọ, àwọn áńgẹ́lì, tí wọ́n sọ pé ó wà láàyè. 24 Lẹ́yìn náà, àwọn kan lára àwọn tó wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì* náà,+ wọ́n sì bá ibẹ̀ bí àwọn obìnrin náà ṣe sọ gẹ́lẹ́, àmọ́ wọn ò rí i.”
25 Torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin aláìlóye, tí ọkàn yín ò tètè gba gbogbo ohun tí àwọn wòlíì sọ gbọ́! 26 Ṣé kò pọn dandan kí Kristi jìyà àwọn nǹkan yìí,+ kó sì wọnú ògo rẹ̀ ni?”+ 27 Ó wá bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Mósè àti gbogbo àwọn Wòlíì,+ ó sì túmọ̀ àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ òun fúnra rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn.
28 Níkẹyìn, wọ́n sún mọ́ abúlé tí wọ́n ń rìnrìn àjò lọ, ó sì ṣe bí ẹni ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ. 29 Àmọ́ wọ́n rọ̀ ọ́ pé kó dúró, wọ́n ní: “Dúró sọ́dọ̀ wa, torí ó ti ń di ọwọ́ alẹ́, ọjọ́ sì ti lọ.” Ló bá wọlé, ó sì dúró sọ́dọ̀ wọn. 30 Bó ṣe ń bá wọn jẹun,* ó mú búrẹ́dì, ó súre sí i, ó bù ú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún wọn.+ 31 Ìgbà yẹn ni ojú wọn là rekete, wọ́n sì dá a mọ̀; àmọ́ ó pòórá láàárín wọn.+ 32 Wọ́n wá ń sọ fúnra wọn pé: “Àbí ẹ ò rí i bí ọkàn wa ṣe ń jó fòfò nínú wa bó ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ lójú ọ̀nà, tó ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́* fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́!” 33 Wọ́n gbéra ní wákàtí yẹn gangan, wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì rí àwọn Mọ́kànlá náà àti àwọn tó kóra jọ pẹ̀lú wọn, 34 tí wọ́n sọ pé: “Ní tòótọ́, a ti gbé Olúwa dìde, ó sì fara han Símónì!”+ 35 Wọ́n wá ròyìn àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà àti bí wọ́n ṣe dá a mọ̀ nígbà tó ń bu búrẹ́dì.+
36 Bí wọ́n ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí, ó fara hàn ní àárín wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.”+ 37 Àmọ́ torí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí àyà wọn sì ń já, wọ́n rò pé ẹ̀mí ni àwọn ń rí. 38 Ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ọkàn yín ò balẹ̀, kí sì nìdí tí ẹ fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì lọ́kàn yín? 39 Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi náà ni; ẹ fọwọ́ kàn mí kí ẹ lè rí i, torí pé ẹ̀mí ò ní ẹran ara àti egungun bí ẹ ṣe rí i pé èmi ní.” 40 Bó ṣe ń sọ èyí, ó fi ọwọ́ rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n. 41 Síbẹ̀, wọn ò gbà gbọ́ torí pé inú wọn ń dùn gan-an, ẹnu sì yà wọ́n, ó wá bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ ní nǹkan jíjẹ níbẹ̀?” 42 Wọ́n wá fún un ní ẹja yíyan kan, 43 ó gbà á, ó sì jẹ ẹ́ níṣojú wọn.
44 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún wọn pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ tí mo bá yín sọ nìyí, nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ yín,+ pé gbogbo ohun tí a kọ nípa mi nínú Òfin Mósè àti nínú ìwé àwọn Wòlíì àti Sáàmù gbọ́dọ̀ ṣẹ.”+ 45 Ó wá là wọ́n lóye ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ kí ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́ lè yé wọn,+ 46 ó sì sọ fún wọn pé: “Ohun tí a kọ nìyí: pé Kristi máa jìyà, ó sì máa dìde láàárín àwọn òkú ní ọjọ́ kẹta,+ 47 àti pé ní gbogbo orílẹ̀-èdè,+ bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù,+ a máa wàásù ní orúkọ rẹ̀ pé kí àwọn èèyàn ronú pìwà dà kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.+ 48 Ẹ máa jẹ́ ẹlẹ́rìí àwọn nǹkan yìí.+ 49 Ẹ wò ó! màá rán ohun tí Baba mi ti ṣèlérí sórí yín. Àmọ́ kí ẹ dúró sínú ìlú náà títí a fi máa fi agbára wọ̀ yín láti òkè.”+
50 Ó wá mú wọn jáde títí dé Bẹ́tánì, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì súre fún wọn. 51 Bó ṣe ń súre fún wọn, a mú un kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run.+ 52 Wọ́n tẹrí ba* fún un, inú wọn sì dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń pa dà sí Jerúsálẹ́mù.+ 53 Ìgbà gbogbo ni wọ́n sì ń wà nínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n ń yin Ọlọ́run.+
Tàbí “gbà pé ó jẹ́ òótọ́.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ohun tó ti fìdí múlẹ̀ táwọn àlùfáà máa ń ṣe.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “látinú ilé ọlẹ̀ ìyá rẹ̀.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ìran.”
Tàbí “iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo èèyàn.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “wúńdíá kan tí a ṣèlérí pé ó máa fẹ́.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ọlẹ̀ máa sọ nínú rẹ.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ohun tí kò ṣeé ṣe.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “Gbogbo ara mi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àfikún A5.
Ní Grk., “èso.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “kọlà fún.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “olùgbàlà tó lágbára.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìwo.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “àwọn èèyàn tó tẹ́wọ́ gbà.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “kọ ọ́ nílà.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Ní Grk., “Gbogbo àkọ́bí ọkùnrin tó ṣí ilé ọmọ kọ̀ọ̀kan.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “gún ọkàn rẹ.”
Ní Grk., “láti ìgbà wúńdíá rẹ̀.”
Wo Àfikún A5.
Ní Grk., “fi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn.”
Ìyẹn, Hẹ́rọ́dù Áńtípà. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “alákòóso ìdá mẹ́rin.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “gbogbo èèyàn.”
Tàbí “ohun tí Ọlọ́run fi máa gbani là.”
Tàbí “aṣọ míì.”
Tàbí “fipá béèrè.”
Tàbí “rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ.”
Tàbí “owó iṣẹ́ yín.”
Tàbí “wíìtì.”
Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ìgbátí; ibi tó ga jù ní.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “wo ìkankan nínú wọn sàn.”
Tàbí “wá a kiri.”
Ìyẹn, Òkun Gálílì.
Tàbí “mú.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “jókòó sídìí tábìlì pẹ̀lú wọn.”
Ìyẹn, orí ọkà.
Tàbí “búrẹ́dì àfihàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Grk., “orúkọ yín.”
Tàbí “tí wọ́n ta orúkọ yín nù pé.”
Ní Grk., “ẹ̀rẹ̀kẹ́.”
Ìyẹn, láìgba èlé.
Tàbí “túni sílẹ̀.”
Tàbí “tú yín sílẹ̀.”
Tàbí “Ọmọ ẹ̀yìn.”
Ní Grk., “òun ni ọmọ bíbí kan ṣoṣo ìyá rẹ̀.”
Tàbí “ibùsùn ìgbókùú.”
Ìyẹn, koríko etí omi.
Ní Grk., “aṣọ múlọ́múlọ́.”
Ní Grk., “síwájú ojú rẹ.”
Tàbí “ìtọ́sọ́nà.”
Tàbí “a dá ọgbọ́n láre.”
Tàbí “àwọn èso rẹ̀.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Tàbí “jókòó nídìí tábìlì.”
Tàbí “ìgò.”
Wo Àfikún B14.
Tàbí “burú jáì.”
Tàbí “àwọn ibojì ìrántí.”
Tàbí kó jẹ́, “Ó ti pẹ́ gan-an tó ti wà lára rẹ̀, tí kò lọ.”
Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.”
Ní Grk., “ọmọbìnrin bíbí kan ṣoṣo rẹ̀.”
Tàbí “Agbára ìwàláàyè rẹ̀.”
Ní Grk., “fàdákà.”
Tàbí “aṣọ míì.”
Ìyẹn, Hẹ́rọ́dù Áńtípà. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “alákòóso ìdá mẹ́rin.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Grk., “ṣe ń pé bọ̀.”
Ní Grk., “ó gbé ojú rẹ̀ sọ́nà.”
Ní Grk., “ojú rẹ̀ ti wà lọ́nà.”
Tàbí “gbá ẹnikẹ́ni mọ́ra láti kí i.”
Ní Grk., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún B14.
Ní Grk., “ọ̀rọ̀ rẹ̀.”
Tàbí “ìpín tó dáa jù.”
Tàbí “kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ; kí a ka orúkọ rẹ sí mímọ́.”
Orúkọ tí wọ́n ń pe Sátánì.
Tàbí “apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n.”
Tàbí “ríran kedere.”
Tàbí “kún fún ìmọ́lẹ̀.”
Ní Grk., “burú.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Ìyẹn, láti wẹ ara rẹ̀ mọ́, bí àṣà ìwẹ̀mọ́.
Tàbí “ìtọrẹ fún àwọn aláìní.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ewéko.”
Tàbí “tó dáa jù.”
Tàbí “àwọn ibojì ìrántí.”
Tàbí “àwọn ibojì tí wọn ò sàmì sí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ká lè béèrè ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn wòlíì tí wọ́n ta sílẹ̀ látìgbà ìpìlẹ̀ ayé lọ́wọ́.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “a máa béèrè rẹ̀ lọ́wọ́.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “Ásáríò méjì.” Wo Àfikún B14.
Tàbí “gbójú fo.”
Tàbí “síwájú àwọn sínágọ́gù.”
Tàbí “wọ̀bìà.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “Ọkàn, o ní.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Wo Àfikún B14.
Tàbí “ṣe òwú.”
Tàbí “ìtọrẹ fún àwọn aláìní.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “kòkòrò.”
Ní Grk., “Ẹ di abẹ́nú yín lámùrè.”
Tàbí “dira rẹ̀ lámùrè.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Láti nǹkan bí aago mẹ́sàn-án alẹ́ sí ọ̀gànjọ́ òru.
Láti ọ̀gànjọ́ òru sí nǹkan bí aago mẹ́ta àárọ̀.
Tàbí “alábòójútó ilé.”
Tàbí “ọlọ́gbọ́n.”
Tàbí “àwọn ìránṣẹ́ ilé.”
Tàbí “ṣe ìfẹ́ rẹ̀.”
Ní Grk., “lẹ́pítónì tó kù.” Wo Àfikún B14.
Tàbí “ẹ̀mí tí kò jẹ́ kó lè ṣe nǹkan kan.”
Ní Grk., “òṣùwọ̀n síà.” Síà kan jẹ́ Lítà 7.33. Wo Àfikún B14.
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Tàbí “kò ṣeé gbà gbọ́.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “tó ní àrùn ògùdùgbẹ̀,” àpọ̀jù omi ara mú kí ara rẹ̀ wú.
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Ní Grk., “jẹ búrẹ́dì.”
Ní Grk., “màlúù méjì-méjì lọ́nà márùn-ún tí wọ́n de àjàgà mọ́.”
Tàbí “tí kò sì nífẹ̀ẹ́ tó dín kù sí.”
Tàbí “ọkàn.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “tí kò bá yááfì.”
Wo Àfikún B14.
Wo Àfikún B14.
Tàbí “àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ obìnrin.”
Wo Àfikún B14.
Tàbí “onínàákúnàá; aláìníjàánu.”
Ní Grk., “rọ̀ mọ́ ọrùn rẹ̀.”
Tàbí “rí i láyọ̀.”
Ní Grk., “run àwọn ohun ìní rẹ.”
Tàbí “alábòójútó ilé.”
Tàbí “báàtì.” Báàtì kan jẹ́ Lítà 22 (gálọ́ọ̀nù 5.81). Wo Àfikún B14.
Tàbí “Ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n kọ́ọ̀.” Kọ́ọ̀ kan jẹ́ Lítà 220. Wo Àfikún B14.
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “fi ọgbọ́n hùwà; fi òye hùwà.”
Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Ní Grk., “oókan àyà.”
Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “ní oókan àyà rẹ̀.”
Tàbí “ọkàn.”
Wo Àfikún A3.
Tàbí “kó sì máa lù mí láti tán mi lókun.”
Tàbí “irú ìgbàgbọ́ yìí.” Ní Grk., “ìgbàgbọ́ náà.”
Tàbí “ṣojúure sí mi.”
Tàbí “ní àsìkò tó ń bọ̀.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ló máa ṣẹlẹ̀ pátápátá.”
Tàbí “igi ọ̀pọ̀tọ́ mọ́líbẹ́rì.”
Tàbí “fipá gbà lórí ẹ̀sùn èké.”
Mínà kan nílẹ̀ Gíríìsì jẹ́ 340 gíráàmù, wọ́n sì gbà pé ó tó 100 dírákímà. Wo Àfikún B14.
Tàbí “agbára ìjọba.”
Ní Grk., “owó fàdákà.”
Ní Grk., “fàdákà.”
Tàbí “agódóńgbó.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “kó wàhálà bá ọ.”
Tàbí “rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀.”
Ní Grk., “olórí igun.”
Tàbí “tọ́.”
Wo Àfikún B14.
Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “lójú ìwòye rẹ̀.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “tó dáa jù.”
Tàbí “ohun ìní.”
Tàbí “láti ṣe bojúbojú.”
Tàbí “wúwo.”
Ní Grk., “lẹ́pítónì méjì.” Wo Àfikún B14.
Tàbí “pé ó jẹ́ òtòṣì.”
Tàbí “rúkèrúdò; ìdàrúdàpọ̀.”
Tàbí “máa dà yín.”
Tàbí “jèrè ọkàn yín.”
Tàbí “máa jẹ́ ọjọ́ ẹ̀san.”
Tàbí “àwọn Kèfèrí.”
Tàbí “àwọn Kèfèrí.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Tàbí “tí a dá lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀jẹ̀ mi.”
Tàbí “tó jókòó nídìí tábìlì.”
Tàbí “ṣe ìránṣẹ́.”
Tàbí “tó jókòó nídìí tábìlì.”
Tàbí “ṣe ìránṣẹ́.”
Tàbí “wíìtì.”
Wo Àfikún A3.
Ní Grk., “Mú ẹni yìí lọ.”
Tàbí “mọ́ òpó igi!” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “kàn án mọ́gi.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.
Tàbí “ó mí èémí àmíkẹ́yìn.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Nǹkan bíi kìlómítà 11. Ní Grk., “60 sítédíọ̀mù.” Sítédíọ̀mù kan jẹ́ mítà 185 (606.95 ẹsẹ̀ bàtà). Wo Àfikún B14.
Tàbí kó jẹ́, “Ṣé ìwọ nìkan ni àlejò ní Jerúsálẹ́mù tí kò mọ.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “jókòó sídìí tábìlì pẹ̀lú wọn.”
Ní Grk., “ṣí Ìwé Mímọ́.”
Tàbí “forí balẹ̀.”