Ìyá Tó Mòye
Ìyá tó bá mòye tó sì bìkítà nípa ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń fẹ́ máa ń sapá gidigidi láti fún wọn lóúnjẹ tara tó máa fún wọn lókun. Irú ọ̀nà jíjáfáfá kan náà ni yóò sì máa gbà fún wọn ní oúnjẹ tẹ̀mí.
Láìpẹ́ yìí, obìnrin kan nílùú Brazil, kọ̀wé sí ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè náà láti fi ìmọrírì rẹ̀ hàn fún ìtẹ̀jáde Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Ó kọ̀wé pé: “Ìwé pẹlẹbẹ náà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni. Nígbà tí mo wo ẹ̀kọ́ kan gààràgà níbẹ̀ tó sọ nípa àwọn àṣà tí inú Ọlọ́run kò dùn sí, kíá ló sọ sí mi lọ́kàn pé mo gbọ́dọ̀ jíròrò ìsọfúnni pàtàkì náà pẹ̀lú àwọn ọmọ mi, ìyẹn ọmọ ọdún mẹ́wàá àti ọmọ ọdún mọ́kànlá, tí wọ́n jẹ́ obìnrin, àti ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún.” Ó sọ síwájú sí i pé: “Ó mà ṣe pàtàkì gan-an o pé mo nírú ìwé yìí fún kíkọ́ ìdílé mi ní àwọn ọ̀nà Ọlọ́run!”
Ó tún béèrè àwọn ìtẹ̀jáde púpọ̀ sí i tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Bó o bá ń fẹ́ oúnjẹ tẹ̀mí, fún ara rẹ àti fún àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ, o lè rí ẹ̀dà kan ìwé Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? gbà nípa kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, mo fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.