Bó Ṣe Ń Kọ́ Wọn Ni Òun Náà Ń Kẹ́kọ̀ọ́
● Obìnrin kan tó ti lé ní ọgbọ̀n [30] ọdún tó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ àti ọmọ mẹ́ta ní ìlú Kentucky lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ̀wé pé: “Èmi àti ìdílé mi gbádùn gbogbo ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde tó wà lọ́wọ́ wa.” Ó ṣàlàyé pé: “Èyí tó wù mí jù lọ kí n máa fi kọ́ àwọn ọmọ mi ni Ìwé Ìtàn Bíbélì,” torí pé “bí mo ṣe ń kọ́ wọn ni èmi náà ń kẹ́kọ̀ọ́.”
Ìwé náà ní àwọn àwòrán tó fani mọ́ra, ó sì sọ àwọn ìtàn inú Bíbélì bí wọ́n ṣe tò tẹ̀ léra. Bí àpẹẹrẹ: Lára ìtàn tó wà ní Apá 2 ni “Ọba Búburú Kan Jẹ ní Íjíbítì,” “Bá A Ṣe Gba Mósè Ọmọ Ọwọ́ Là,” “Ìdí Tí Mósè Fi Sá Lọ,” “Mósè àti Áárónì Lọ Rí Fáráò,” “Àwọn Ìyọnu Mẹ́wàá” àti “Líla Òkun Pupa Kọjá.”
Apá 6 nínú ìwé náà tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Ìgbà Ìbí Jésù sí Àkókò Ikú Rẹ̀,” ṣe àwọn àlàyé kan nípa ìgbésí ayé Jésù láti ìgbà tí wọ́n ti bí i títí dìgbà tó kú. Lára wọn ni, “Wọ́n Bí Jésù sí Ibùso Ẹran” àti “Àwọn Ọkùnrin Tí Ìràwọ̀ Kan Darí.” Ohun tó wà nínú àkòrí tá a sọ gbẹ̀yìn yìí jẹ́ ká mọ̀ pé awòràwọ̀ gan-an làwọn “amoye” tó lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Jésù àti pé “inú ilé” ni wọ́n ti lọ kí Jésù, kì í ṣe ibùso ẹran tí wọ́n bí i sí. Nínú ilé náà, wọ́n “ri ọmọ-ọwọ na pẹlu Maria iya rẹ̀.” Ọlọ́run kìlọ̀ fáwọn ọkùnrin yìí pé kí wọ́n má ṣe pa dà sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù tó ń wá bó ṣe máa pa Jésù. Pẹ̀lú ohun tá a kà nínú ìtàn yìí, ta ló yẹ ká gbà pé ó fi ìràwọ̀ darí àwọn ọkùnrin yẹn?—Mátíù 2:1, 11, 12, Bíbélì Mímọ́.
Bí ìwọ náà bá ń fi Ìwé Ìtàn Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́, bó o ṣe ń kà á fún wọn ni ìwọ náà á máa kẹ́kọ̀ọ́. Àkòrí mẹ́rìndínlọ́gọ́fà [116] ni ìwé náà ní, wọ́n sì sọ ìtàn àwọn èèyàn àti ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú Bíbélì. Tó o bá fẹ́ ìwé yìí, kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sí ojú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Mo fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé yìí.
Kọ èdè tó o fẹ́.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.