NǸKAN Ń GBÓWÓ LÓRÍ! ỌGBỌ́N WO LO LÈ DÁ SÍ I?
Máa Ṣoore
Tí owó ọjà tó ń lọ sókè yìí bá ń mú kí àtijẹ àtimu nira fún ẹ, o lè máa wò ó pé ‘ṣé èmi tí mi ò tíì jẹun kánú ni màá wá máa fún àwọn èèyàn ní nǹkan?’ Àmọ́, tó o bá ń ṣoore fáwọn èèyàn, wàá máa láyọ̀ bí nǹkan ò tiẹ̀ rọrùn fún ẹ. Bó o tiẹ̀ ń ṣọ́wó ná, o ṣì lè jẹ́ ọ̀làwọ́.
ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ
Tá a bá ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan, tí nǹkan ọ̀hún ò bá tiẹ̀ pọ̀, inú wa máa dùn, àá sì níyì lójú ara wa. Kódà, àwọn onímọ̀ ìṣègùn sọ pé téèyàn bá jẹ́ ọ̀làwọ́, ó máa ń ní ipa tó dáa lórí ìlera ara àti ti ọpọlọ. Bí àpẹẹrẹ, ara onítọ̀hún á máa yá gágá, kò sì ní máa kọ́kàn sókè jù. Ó tún máa ń dín àwọn àìsàn kan kù, bí ẹ̀fọ́rí, ara ríro àti ẹ̀jẹ̀ ríru. Kódà, ó lè jẹ́ kéèyàn rí oorun sùn.
Tá a bá ń ṣoore fáwọn èèyàn, bóyá a fún wọn lówó tàbí à ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì, kò ní ṣòro fún wa láti ní kí wọ́n ran àwa náà lọ́wọ́ tá a bá níṣòro. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Howard lórílẹ̀-èdè England sọ pé: “Èmi àtìyàwó mi máa ń gbìyànjú láti fún àwọn èèyàn ní nǹkan, a sì máa ń wá bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Torí náà, tá a bá nílò ìrànlọ́wọ́, kì í ṣe wá bíi pé ńṣe là ń da àwọn èèyàn láàmú.” Àmọ́, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé tẹ́nì kan bá ń ṣoore fáwọn èèyàn torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, kò ní máa retí pé wọ́n gbọ́dọ̀ san oore náà pa dà fóun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kóun àtàwọn tó bá ṣoore fún di ọ̀rẹ́, kí wọ́n sì ṣe tán láti ràn án lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Máa fáwọn èèyàn ní nǹkan. Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan díẹ̀ lo ní, o ṣì lè máa fáwọn èèyàn ní nǹkan, bí ò tiẹ̀ ju ìpápánu lọ. Bí àpẹẹrẹ, tálákà ni Duncan àti ìdílé ẹ̀ tí wọ́n ń gbé lórílẹ̀-èdè Uganda, síbẹ̀ wọ́n máa ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan. Duncan sọ pé: “Ní gbogbo ọjọ́ Sunday, èmi àtìyàwó mi máa ń rí i pé a pe ẹnì kan wá sílé wa, àá sì jọ wá nǹkan fi panu. A máa ń gbádùn àkókò tá a fi ń wà pẹ̀lú àwọn èèyàn.”
Àmọ́ tó o bá ń ṣoore fáwọn èèyàn, á dáa kó o máa fọgbọ́n ṣe é. Kò ní dáa kí ìdílé ẹ máa jìyà torí pé ò ń ṣoore fáwọn ẹlòmíì.—Jóòbù 17:5.
Gbìyànjú èyí wò: O lè fún ẹnì kan ní ìpápánu tàbí ohun mímu. Tó o bá láwọn nǹkan tó ò lò mọ́, o lè fún àwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn aládùúgbò tó o mọ̀ pé wọ́n á nílò ẹ̀, tí wọ́n á sì mọyì ẹ̀.
Máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Àwọn nǹkan kan wà tó ṣeyebíye tó o lè fún àwọn èèyàn, àmọ́ tí kò ṣeé fowó rà. Bí àpẹẹrẹ, o lè lo àkókò ẹ láti tẹ́tí sí wọn tàbí kó o ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Kódà, tó o bá sọ̀rọ̀ tó tuni lára fẹ́nì kan, ẹ̀bùn lo fún un yẹn! Torí náà, jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, o sì mọyì wọn.
Gbìyànjú èyí wò: O lè bá àwọn èèyàn ṣiṣẹ́ nínú ilé wọn tàbí kó o bá wọn tún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe, o sì lè bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì. O lè ṣe káàdì kékeré kan kó o fi ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ ẹ tàbí kó o kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i pé o kàn ní kó o kí i ni, kó o sì béèrè àlàáfíà ẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àǹfààní lo máa rí tó o bá ń gbìyànjú láti máa ṣoore fáwọn èèyàn.