NǸKAN Ń GBÓWÓ LÓRÍ! ỌGBỌ́N WO LO LÈ DÁ SÍ I?
Gbà Pé Nǹkan Ṣì Máa Dáa
Ṣé bí nǹkan ṣe ń gbówó lórí, tí owó tó ń wọlé fún ẹ ò sì pọ̀ sí i ń mú kí nǹkan nira fún ẹ? Ṣó o máa ń kọ́kàn sókè nípa bó o ṣe máa gbọ́ bùkátà ara ẹ àti ti ìdílé ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè máa wò ó pé tí nǹkan bá nira lásìkò tá a wà yìí, báwo ló ṣe máa wá rí lọ́dún bíi mélòó kan sí i? Tó o bá gbà pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa, ọkàn ẹ á balẹ̀ bí nǹkan ò tiẹ̀ rọrùn.
ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ
Ẹni tó bá gbà pé nǹkan ṣì máa dáa ò kàn ní káwọ́ gbera, kó wá máa retí pé nǹkan á ṣàdédé yí pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, á máa ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe kí nǹkan lè dáa. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí fi hàn pé tẹ́nì kan bá gbà pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa . . .
á rọrùn fún un láti fara da ìṣòro
á rọrùn fún un láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ tí ìṣòro bá dé
á máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí ìgbé ayé ẹ̀ àti ìlera ẹ̀ túbọ̀ dáa
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Àkọ́kọ́, ṣàyẹ̀wò bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn ló wà nínú Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fara dà á bí nǹkan ṣe ń gbówó lórí. Tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn yìí, kò ní máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sọ́nà àbáyọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkàn ẹ á balẹ̀ ní báyìí, wàá sì mọ ohun tó o máa ṣe tí ìṣòro bá tún dé lọ́jọ́ iwájú.
Ìkejì, ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Tó o bá rí báwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì ṣe wúlò tó, á wù ẹ́ láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la. Bí àpẹẹrẹ, wàá rí i pé Ọlọ́run fẹ́ kí ‘ọjọ́ ọ̀la ẹ dáa, ó sì ti fún ẹ ní ìrètí àgbàyanu!’ Wàá tún rí ẹ̀rí tó dájú pé Ọlọ́run máa mú ohun tó ní lọ́kàn yìí ṣẹ. (Jeremáyà 29:11) Ìjọba Ọlọ́run ni ẹ̀rí tó dájú yìí.
KÍ NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN, ÀWỌN NǸKAN WO LÓ SÌ MÁA ṢE?
Ìjọba Ọlọ́run ni ìjọba tó máa gba àkóso gbogbo ayé. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10) Ìjọba yìí máa ṣàkóso látọ̀run, á fòpin sí ìṣẹ́ àti òṣì, á mú kí àlàáfíà jọba kárí ayé, àwa èèyàn ò ní máa jìyà mọ́, àá sì ní ànító àti àníṣẹ́kù. Ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń retí ìgbà táwọn ìlérí yìí máa ṣẹ, torí ó dá wọn lójú pé Ọlọ́run ‘ò lè parọ́.’ (Títù 1:2) Oò ṣe gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó lè dá ìwọ náà lójú pé àwọn ìlérí yìí máa ṣẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè máa fara dà á bí nǹkan ò tiẹ̀ rọrùn, á sì dá ẹ lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.