Ẹ̀KỌ́ 103
“Kí Ìjọba Rẹ Dé”
Jèhófà ṣèlérí pé: ‘Kò ní sí ẹkún, ìrora àìsàn àti ikú mọ́. Màá nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn. Wọn ò sì ní rántí gbogbo àwọn nǹkan burúkú tó ti ṣẹlẹ̀ mọ́.’
Jèhófà fi Ádámù àti Éfà sínú ọgbà Édẹ́nì, ó sì fẹ́ kí wọ́n ní ayọ̀ àti àlàáfíà. Ó yẹ kí wọ́n máa jọ́sìn Ọlọ́run, kí wọ́n sì bímọ káwọn èèyàn lè pọ̀ láyé. Kí ni Ádámù àti Éfà wá ṣe? Wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà, àmọ́ Jèhófà ṣì máa mú káyé rí bó ṣe fẹ́. Nínú ìwé yìí, a ti rí i pé gbogbo ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí ló ṣẹ. Ìjọba rẹ̀ sì máa mú ọ̀pọ̀ nǹkan tó dáa wá bó ṣe ṣèlérí fún Ábúráhámù.
Láìpẹ́, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ẹ̀ àti gbogbo àwọn èèyàn burúkú ò ní sí mọ́. Tó bá dìgbà yẹn, Jèhófà ni gbogbo èèyàn á máa sìn. A ò ní máa ṣàìsàn mọ́, a ò sì ní máa kú mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ara gbogbo èèyàn máa le, inú wa á sì máa dùn lójoojúmọ́. Ayé máa di Párádísè, gbogbo èèyàn sì máa ní oúnjẹ tó dáa àti ilé tó rẹwà. A tún máa nífẹ̀ẹ́ ara wa, a ò ní máa jà. Kódà a ò ní máa bẹ̀rù àwọn ẹranko bíi kìnìún, ejò àtàwọn míì, àwọn ẹranko náà ò sì ní máa sá fún wa mọ́.
Inú wa tún máa dùn gan-an nígbà tí Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ sí í jí àwọn tó ti kú dìde. A máa rí àwọn olóòótọ́ bí Ébẹ́lì, Nóà, Ábúráhámù, Sérà, Mósè, Rúùtù, Ẹ́sítà àti Dáfídì. Gbogbo wa pátá jọ máa ṣiṣẹ́ pọ̀ láti sọ ayé di Párádísè. Gbogbo iṣẹ́ tá a bá ń ṣe làá máa gbádùn nígbà yẹn.
Jèhófà fẹ́ kíwọ náà wà níbẹ̀. Àwọn ohun tí wàá máa mọ̀ sí i nípa Jèhófà máa yà ẹ́ lẹ́nu gan-an! Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà lójoojúmọ́, lónìí àti títí láé!
“Jèhófà, Ọlọ́run wa, ìwọ ló tọ́ sí láti gba ògo àti ọlá àti agbára, torí ìwọ lo dá ohun gbogbo.”—Ìfihàn 4:11