ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • scl ojú ìwé 71-73
  • Ìrònúpìwàdà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrònúpìwàdà
  • Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
scl ojú ìwé 71-73

Ìrònúpìwàdà

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà, kí wọ́n sì bẹ Jèhófà pé kó dárí ji àwọn?

Ro 3:23; 5:12; 1Jo 1:8

Tún wo Iṣe 26:20

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Lk 18:9-14—Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ká sì gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́

    • Ro 7:15-25—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àpọ́sítélì ni Pọ́ọ̀lù, tó sì tún ní ìgbàgbọ́ tó lágbára gan-an, inú ẹ̀ bà jẹ́ torí pé ó máa ń ro èròkerò nígbà míì

Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tẹ́nì kan bá ronú pìwà dà?

Isk 33:11; Ro 2:4; 2Pe 3:9

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Lk 15:1-10—Jésù sọ àwọn àpèjúwe tó jẹ́ ká rí i pé inú Jèhófà àtàwọn áńgẹ́lì máa ń dùn tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà

    • Lk 19:1-10—Olórí àwọn agbowó orí ni Sákéù, ó sì máa ń fipá gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn, àmọ́ nígbà tó ronú pìwà dà tó sì yíwà pa dà, Jésù dárí jì í

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn?

Isk 18:21-23; Iṣe 3:19; Ef 4:17, 22-24; Kol 3:5-10

Tún wo 1Pe 4:1-3

Tẹ́nì kan bá ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn, kí nìdí tó fi yẹ kẹ́ni náà ní ìmọ̀ tó péye?

Ro 12:2; Kol 3:9, 10; 2Ti 2:25

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 17:29-31—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Áténì pé àìmọ̀kan ló ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa bọ̀rìṣà, ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ronú pìwà dà

    • 1Ti 1:12-15—Kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó ní ìmọ̀ tó péye nípa Jésù Kristi, ó ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn ronú pìwà dà?

Mk 1:14, 15; Lk 24:45-47; Iṣe 2:38; 17:30; 20:21

Tá a bá tiẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, kí ló mú kó dá wa lójú pé tá a bá ronú pìwà dà, Jèhófà máa dárí jì wá?

Ais 1:18; Ga 6:1; 1Jo 2:1

Kí ni Jèhófà máa ṣe fáwọn tó bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tí wọ́n sì yí pa dà?

Sm 32:5; Owe 28:13; 1Jo 1:9

Tún wo “Àánú”

Báwo la ṣe mọ̀ pé ìrònúpìwàdà kọjá kéèyàn kàn banú jẹ́ tàbí kó kábàámọ̀ ohun tó ṣe?

2Kr 7:14; Owe 28:13; Isk 18:30, 31; 33:14-16; Mt 3:8; Iṣe 3:19; 26:20

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Kr 33:1-6, 10-16—Ọba Mánásè dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, àmọ́ kó lè fi hàn pé òun ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ó rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, ó gbàdúrà léraléra, ó sì yíwà pa dà

    • Sm 32:1-6; 51:1-4, 17—Ọba Dáfídì fi hàn pé òun ronú pìwà dà bó ṣe kábàámọ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, tó jẹ́wọ́, tó sì gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí ji òun

Tẹ́ni tó ṣẹ̀ wá bá ti ronú pìwà dà, kí nìdí tó fi yẹ ká dárí jì í?

Mt 6:14, 15; 18:21, 22; Lk 17:3, 4

Tún wo “Ìdáríjì”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́