-
Ogunlọ́gọ̀ ŃláÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
Orí 20
Ogunlọ́gọ̀ Ńlá
1. Lẹ́yìn ti Jòhánù ti ṣàpèjúwe fífi èdìdì di àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, àwùjọ mìíràn wo ló rí?
BÍ JÒHÁNÙ ṣe ṣàpèjúwe fífi èdìdì di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tán, ó ń bá a lọ láti ròyìn ọ̀kan nínú àwọn ìṣípayá tó wọni lọ́kàn jù lọ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́. Ayọ̀ ti ní láti gbà á lọ́kàn bó ti ń ròyìn rẹ̀ pé: “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo rí, sì wò ó! ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, wọ́n wọ aṣọ funfun; imọ̀ ọ̀pẹ sì ń bẹ ní ọwọ́ wọn.” (Ìṣípayá 7:9) Bẹ́ẹ̀ ni, dídá ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyẹn dúró mú kó ṣeé ṣe fún àwùjọ àwọn èèyàn mìíràn yàtọ̀ sí ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tó jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí láti lè rí ìgbàlà. Àwọn wọ̀nyí sì ni ogunlọ́gọ̀ ńlá èèyàn tí ń sọ èdè púpọ̀, tí wọ́n ti onírúurú orílẹ̀-èdè wá.a—Ìṣípayá 7:1.
2. Àlàyé wo làwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ayé ṣe nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá, ojú wo sì làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn lọ́hùn-ún pàápàá fi wo àwùjọ yìí?
2 Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ayé sọ pé ogunlọ́gọ̀ yìí túmọ̀ sí àwọn tí kì í ṣe Júù nípa tara tá a yí lọ́kàn padà sí ìsìn Kristẹni tàbí àwọn Kristẹni ajẹ́rìíkú tí wọ́n ń re ọ̀run. Kódà ìgbà kan tiẹ̀ wà táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kà wọ́n sí ẹgbẹ́ ti ọ̀run onípò kejì, gẹ́gẹ́ bá a ti sọ lọ́dún 1886 nínú Ìdìpọ̀ Kìíní ìwé Studies in the Scriptures, The Divine Plan of the Ages: “Wọ́n pàdánù ẹ̀bùn ìtẹ́ náà àti wíwà bí Ọlọ́run, àmọ́ níkẹyìn a óò bí wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni ẹ̀mí nínú ẹgbẹ́ kan tó rẹlẹ̀ sí wíwà bíi ti Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí la yà sí mímọ́ ní tòótọ́, ẹ̀mí ayé ti ṣẹ́pá wọn débi pé wọ́n kùnà láti fi ìwàláàyè wọn rúbọ.” Látọdún 1930 la sì tún ti sọ ọ̀rọ̀ tó jọ èyí nínú Light, Ìwé Kìíní: “Àwọn tó para pọ̀ di ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí kùnà láti di ẹlẹ́rìí onítara fún Olúwa.” A ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí àwùjọ olódodo lójú ara ẹni, tó ní ìmọ̀ òtítọ́ àmọ́ tí wọn ò wàásù rẹ̀ dà bí alárà. Àwọn náà máa dọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ onípò kejì tí kò ní bá Kristi ṣàkóso.
3. (a) Ìrètí wo ló wà fáwọn ọlọ́kàn títọ́ tí wọ́n wá di onítara lẹ́yìn náà nínú iṣẹ́ ìwàásù? (b) Báwo ni Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) tó jáde lọ́dún 1923 ṣe ṣàlàyé àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́?
3 Àmọ́ ṣá o, a rí àwọn míì lára àwọn alábàákẹ́gbẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọn ò fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú iṣẹ́ ìwàásù. Kò sí lọ́kàn wọn pé wọ́n á lọ sọ́run. Àní ṣe ní ìrètí wọn ṣe wẹ́kú pẹ̀lú àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn táwọn èèyàn Jèhófà sọ lọ́pọ̀ ibi látọdún 1918 sí ọdún 1922. Ohun tí àkòrí rẹ̀ pilẹ̀ jẹ́ ni “Ayé Ti Dópin—Ọ̀kẹ́ àìmọye Tí Wọ́n Wàláàyè Nísinsìnyí Kì Yóò Kú Láé.”b Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) ti October 15, 1923, fi ṣàlàyé àkàwé Jésù nípa àwọn àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́, (Mátíù 25:31-46) ó sọ pé: “Àgùntàn dúró fún gbogbo èèyàn orílẹ̀-èdè, kì í ṣe àwọn tá a fẹ̀mí bí bí kò ṣe àwọn tó fẹ́ láti máa hùwà òdodo, àwọn tó jẹ́ pé lérò ọkàn tiwọn, wọ́n gba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, wọ́n ń retí àkókò tó sàn jù lábẹ́ ìjọba rẹ̀, wọ́n sì ń wọ̀nà fún un.”
4. Báwo ni òye wa nípa ẹgbẹ́ orí ilẹ̀ ayé ṣe wá ń pọ̀ sí i bí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn yòò lọ́dún 1931? lọ́dún 1932? lọ́dún 1934?
4 Láwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 1931, Vindication, Ìwé Kìíní, jíròrò Ìsíkíẹ́lì orí 9, ó sì fi hàn pé àwọn èèyàn tá a sàmì sí níwájú orí pé wọ́n á la òpin ayé yìí já làwọn àgùntàn inú àkàwé òkè yí. Vindication, Ìwé Kẹta, tó jáde lọ́dún 1932, ṣàpèjúwe ẹ̀mí rere tó wà lọ́kàn Jèhónádábù, ọkùnrin kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, tó wọlé sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin Ọba Jéhù ẹni àmì òróró Ísírẹ́lì, tó sì bá a lọ láti rí bó ṣe ń fi ìtara pa àwọn onísìn èké. (2 Àwọn Ọba 10:15-17) Ìwé náà ṣàlàyé pé: “Jèhónádábù dúró fún ẹgbẹ́ àwọn èèyàn náà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé nísinsìnyí ní àkókò tí iṣẹ́ Jéhù [ti pípolongo àwọn ìdájọ́ Jèhófà] ń tẹ̀ síwájú tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́ inú rere, tí wọn kò sí ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ètò Sátánì, tí wọ́n fara mọ́ òdodo, àwọn sì ni Olúwa yóò pa mọ́ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, tí yóò mú wọn la ìjàngbọ̀n yẹn já, tí yóò sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn wọ̀nyí ló wá para pọ̀ di ẹgbẹ́ ‘àwọn àgùntàn.’” Lọ́dún 1934 Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) mú kó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé yìí gbọ́dọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi. Òye wa nípa ẹgbẹ́ orí ilẹ̀ ayé yìí ń pọ̀ síwájú àti síwájú bí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn yòò.—Òwe 4:18.
5. (a) Kí la sọ nípa àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá lọ́dún 1935? (b) Nígbà tí J. F. Rutherford ní káwọn tó wà ní àpéjọ ti ọdún 1935 tí wọ́n ní ìrètí wíwà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé dìde dúró, kí ló ṣẹlẹ̀?
5 Kí òye wa nípa Ìṣípayá 7:9-17 wá máa pọ̀ yanturu sí i ló kù báyìí! (Sáàmù 97:11) Léraléra ni ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) ti ń sọ pé àpéjọ àgbègbè kan tó máa wáyé ní May 30 sí June 3, ọdún 1935, nílùú Washington, D.C., lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, yóò jẹ́ “ìtùnú àti àǹfààní ní ti tòótọ́” fún àwọn tí Jèhónádábù ṣàpẹẹrẹ. Bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn! Nínú àsọyé kan tó wọni lára tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ògìdìgbó Ńlá Náà,” tí nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan èèyàn tó wà níbi àpéjọ náà tẹ́tí sí, J. F. Rutherford, tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé nígbà yẹn, fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé pé ọ̀kan náà làwọn àgùntàn mìíràn òde òní àtàwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá inú Ìṣípayá 7:9. Nígbà tí àsọyé yìí wọra tán, ó béèrè pé: “Ǹjẹ́ kí gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí wíwà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé jọ̀wọ́ dìde?” Bí ọ̀pọ̀ lára àwùjọ náà ti dìde dúró báyìí, ó polongo pé: “Wò ó! Ògìdìgbó ńlá náà!” Kẹ́kẹ́ kọ́kọ́ pa, lẹ́yìn náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pàtẹ́wọ́ kíkankíkan. Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún ẹgbẹ́ Jòhánù, àti àwùjọ Jèhónádábù! Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, òjìlélẹ́gbẹ̀rin [840] Ẹlẹ́rìí tuntun ló ṣèrìbọmi, èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn sì jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá.
Bí Ẹni Tí Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Náà Jẹ́ Ṣe Dá Wa Lójú
6. (a) Kí ló mú ká lóye ní kedere pé àwùjọ àwọn Kristẹni òde òní, tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n ní ìrètí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé ni ogunlọ́gọ̀ ńlá? (b) Kí ni aṣọ funfun ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ṣàpẹẹrẹ?
6 Báwo ló ṣe lè dá wa lójú tó bẹ́ẹ̀ pé àwùjọ àwọn Kristẹni òde òní yìí, tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì nírètí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run dá yìí ni ogunlọ́gọ̀ ńlá? Tẹ́lẹ̀, nínú ìran, Jòhánù ti rí àwùjọ ti ọ̀run tí a “rà . . . fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè.” (Ìṣípayá 5:9, 10) Látinú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àtàwọn èèyàn àti orílẹ̀-èdè náà ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ti wá, àmọ́ ìpín tiwọ́n yàtọ̀. Òté kankan ò sí lórí iye tí wọ́n máa jẹ́ bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Ísírẹ́lì Ọlọ́run. Kò sẹ́ni tó lè sọ tẹ́lẹ̀ pé iye pàtó tí wọ́n máa jẹ́ rèé. Wọ́n fọ aṣọ wọn di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn, èyí tó jẹ́ àpẹẹrẹ pé ojú olódodo ni Ọlọ́run fi ń wò wọ́n lọ́lá ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ Jésù. (Ìṣípayá 7:14) Wọ́n ń ju imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì ń yin Mèsáyà náà gẹ́gẹ́ bí Ọba wọn.
7, 8. (a) Jíju imọ̀ ọ̀pẹ láìsí iyè méjì rán àpọ́sítélì Jòhánù létí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo? (b) Kí ni jíjù tí ogunlọ́gọ̀ ńlá ń ju imọ̀ ọ̀pẹ fi hàn?
7 Bí Jòhánù ṣe ń wo ìran náà nìṣó, ó ti ní láti máa rántí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ léyìí tó ju ọgọ́ta [60] ọdún lọ, ní ọ̀sẹ̀ tí Jésù gbé kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Ní Nísàn 9, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí ogunlọ́gọ̀ rọ́ wá láti kí Jésù káàbọ̀ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n “mú àwọn imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé: ‘Gbà là, àwa bẹ̀ ọ́! Alábùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà, àní ọba Ísírẹ́lì!’” (Jòhánù 12:12, 13) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, jíjù tí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ń ju imọ̀ ọ̀pẹ tí wọ́n sì ń kígbe ń fi hàn pé wọn láyọ̀ gidigidi nítorí pé wọ́n tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Jèhófà yàn sípò.
8 Láìsí iyè méjì, imọ̀ ọ̀pẹ àti igbe ayọ̀ náà tún rán Jòhánù létí Àjọyọ̀ Àtíbàbà tí wọ́n máa ń ṣe ní Ísírẹ́lì láyé ọjọ́un. Jèhófà pàṣẹ nípa àjọyọ̀ yìí pé: “Ní ọjọ́ kìíní kí ẹ̀yin fúnra yín sì mú èso igi dáradára, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ àti àwọn ẹ̀tun ẹlẹ́ka púpọ̀ àti igi pọ́pílà àfonífojì olójú ọ̀gbàrá, kí ẹ sì yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.” Imọ̀ ọ̀pẹ tí wọ́n lò yìí ló dúró fún ayọ̀ yíyọ̀. Àwọn àgọ́ tó wà fún ìgbà díẹ̀ ránni létí pé Jèhófà ti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là kúrò ní Íjíbítì, kí wọ́n bàa lè máa gbé nínú àwọn àgọ́ nínú aginjù. “Àtìpó àti ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó” ń ṣe nínú àríyá yìí. Gbogbo Ísírẹ́lì sì ní láti “kún fún ìdùnnú.”—Léfítíkù 23:40; Diutarónómì 16:13-15.
9. Igbe ayọ̀ wo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jùmọ̀ ń kọ?
9 Bí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà kì í tilẹ̀ í ṣe apá kan Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ó bá a mú pé wọ́n ń ju imọ̀ ọ̀pẹ, níwọ̀n bí wọ́n ti ń fi ayọ̀ àti ìmoore gbé ògo ìjagunmólú àti ìgbàlà fún Ọlọ́run àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe ṣàlàyé níbí yìí pé: “Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní kíké pẹ̀lú ohùn rara, pé: ‘Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.’” (Ìṣípayá 7:10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé látinú gbogbo àwùjọ ẹ̀yà ìran ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ti jáde wá, kìkì “ohùn rara” kan ṣoṣo ni wọ́n ń ké jáde. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó jẹ́ pé ọ̀kankòjọ̀kan orílẹ̀-èdè ni wọ́n ti wá, tí èdè wọn sì yàtọ̀ síra?
10. Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ṣe lè máa fi “ohùn rara” kan ṣoṣo ké jáde ní ìṣọ̀kan bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kankòjọ̀kan orílẹ̀-èdè ni wọ́n ti wá, tí èdè wọn sí yàtọ̀ síra?
10 Ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí jẹ́ apá kan ètò kan ṣoṣo tó wà lórí ilẹ̀ ayé lónìí, táwọn èèyàn láti ọ̀kankòjọ̀kan orílẹ̀-èdè kóra jọ sí, tó sì wà ní ìṣọ̀kan ní tòótọ́. Wọn ò ní ìlànà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń tẹ̀ lé, àmọ́ níbi yòówù tí wọ́n bá ń gbé ìlànà títọ́ tó wà nínú Bíbélì ló ń darí gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ń ṣe. Wọn kì í dara pọ̀ mọ́ àwọn tó gbà pé orílẹ̀-èdè tàwọn lọ̀gá, tí wọ́n ń fọ̀tẹ̀ yí bí nǹkan ṣe ń lọ sí pa dà, nítorí pé lóòótọ́ ni wọ́n ti “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀.” (Aísáyà 2:4) Wọn ò pín sí ẹgbẹẹgbẹ́ tàbí ẹ̀kẹ̀ẹ̀ka ìsìn, débi tí ìdàrúdàpọ̀ á fi wà nínú ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni tí ohùn wọn ò sì ní ṣọ̀kan bíi tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì; wọn ò sì jókòó gẹlẹtẹ kí wọ́n wá ní kí ẹgbẹ́ àlùfáà aṣiṣẹ́-gbowó-oṣù wá máa bá àwọn yin Ọlọ́run lórúkọ ẹ̀sìn. Wọn kì í sọ pé ìgbàlà àwọn dọwọ́ ẹ̀mí mímọ́, nítorí pé wọn kì í ṣe ìránṣẹ́ ọlọ́run mẹ́talọ́kan. Délé dóko, ní nǹkan bí ọgbọ̀n-lénígba [230] ilẹ̀ lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, ni wọ́n ti ń fi èdè òtítọ́ mímọ́ gaara kan ṣoṣo tí wọ́n jùmọ̀ ń sọ ké pe orúkọ Jèhófà. (Sefanáyà 3:9) Bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, wọn kì í fi bò pé ìgbàlà àwọn dọwọ́ Jèhófà, Ọlọ́run ìgbàlà, nípasẹ̀ Jésù Kristi, Olórí Aṣojú Rẹ̀ fún ìgbàlà.—Sáàmù 3:8; Hébérù 2:10.
11. Báwo ni ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní ṣe ń ran àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá lọ́wọ́ láti mú kí ohùn rara wọn ròkè sí i?
11 Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní ti ṣèrànwọ́ láti mú kí ohùn rara ogunlọ́gọ̀ ńlá tó wà ní ìṣọ̀kan túbọ̀ máa ròkè. Kò sí àwùjọ ìsìn míì lórí ilẹ̀ ayé tó pọn dandan fún láti máa tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde lédè tó ju irínwó [400] lọ, níwọ̀n bí kò ti sí àwùjọ míì tó fẹ́ láti máa mú irú ìhìn rere kan náà tọ gbogbo olùgbé ilẹ̀ ayé lọ. Láti lè ràn wá lọ́wọ́ sí i lórí èyí, àwọn ẹni àmì òróró kan tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, fọwọ́ sí i pé ká ṣe ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà kan tó ṣe é tẹ èdè púpọ̀ tó ń jẹ́ Multilanguage Electronic Phototypesetting System, tàbí ní ìkékúrú MEPS. Ní àkókò tí wọ́n tẹ ìwé yìí, onírúurú ẹ̀rọ MEPS ni wọ́n lò jákèjádò ayé láwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Watch Tower Society tó ju márùnlélọ́gọ́fà [125] lọ, èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa tẹ ìwé ìròyìn ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù náà, ìyẹn Ilé Ìṣọ́, nígbà kan náà, lédè tó ju àádóje [130] lọ. Àwọn èèyàn Jèhófà tún máa ń tẹ àwọn ìwé ńlá, bí irú èyí tó ò ń kà yìí jáde nígbà kan náà, láwọn èdè mélòó kan. Èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ nínú wọn jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá náà láti máa pín ọ̀kẹ́ àìmọye lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìtẹ̀jáde kiri lọ́dọọdún ní gbogbo èdè táwọn èèyàn ń sọ jù lọ, tí ìyẹn sì ń mú káwọn èèyàn púpọ̀ sí i láti inú gbogbo ẹ̀yà àti èdè lè kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì pa ohùn wọn pọ̀ mọ́ ohùn rara ti ogunlọ́gọ̀ ńlá náà.—Aísáyà 42:10, 12.
Ní Ọ̀run Tàbí Lórí Ilẹ̀ Ayé?
12, 13. Lọ́nà wo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà gbà “dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn”?
12 Báwo la ṣe mọ̀ pé dídúró táwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà “dúró níwájú ìtẹ́” kò túmọ̀ sí pé wọ́n wà ní ọ̀run? Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó ṣe kedere wà tá a lè fi ti kókó yìí lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “níwájú” níbí yìí ni e·noʹpi·on. Ní tààràtà, ohun tó túmọ̀ sí ní “ní ọ̀kánkán iwájú,” a sì lò ó láwọn ìgbà mélòó kan fáwọn èèyàn lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n wà “níwájú” tàbí “ní ọ̀kánkán iwájú” Jèhófà. (1 Tímótì 5:21; 2 Tímótì 2:14; Róòmù 14:22; Gálátíà 1:20) Nígbà kan báyìí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní aginjù, Mósè sọ fún Áárónì pé: “Sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá pé, ‘Ẹ wá síwájú Jèhófà, nítorí pé ó ti gbọ́ ìkùnsínú yín.’” (Ẹ́kísódù 16:9) Kò di dandan kí Mósè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sọ́run kí wọ́n tó lè wà níwájú Jèhófà nígbà tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. (Fi wé Léfítíkù 24:8.) Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú aginjù níbẹ̀ gan-an ni wọ́n ti dúró ní ọ̀kánkán ojú Jèhófà, tí Jèhófà sì darí àfiyèsí rẹ̀ sára wọn.
13 Bíbélì tún kà síwájú sí i pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀ . . . Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀.”c Gbogbo ìran èèyàn ò ní sí lọ́run nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí bá ní ìmúṣẹ. Dájúdájú, àwọn tí yóò “lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun” ò ní sí lọ́run. (Mátíù 25:31-33, 41, 46) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni aráyé á dúró lórí ilẹ̀ ayé ní ọ̀kánkán ojú Jésù, tí Jésù á sì wá darí àfiyèsí rẹ̀ sí wọn láti ṣe ìdájọ́. Bó ṣe jẹ́ náà nìyẹn ní ti ogunlọ́gọ̀ náà, wọ́n wà “níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” ní ti pé wọ́n dúró ní ọ̀kánkán ojú Jèhófà àti Ọba rẹ̀, Kristi Jésù, tí wọ́n sì dá wọn láre.
14. (a) Àwọn wo ni Bíbélì sọ pé wọ́n wà “yí ká ìtẹ́” náà tí wọ́n sì tún wà “lórí Òkè Ńlá Síónì [ti ọ̀run]”? (b) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ń sin Ọlọ́run “nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀,” kí nìdí tíyẹn ò fi sọ wọ́n di ẹgbẹ́ agbo àlùfáà?
14 Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà àti àwùjọ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ẹni àmì òróró wà “yí ká ìtẹ́” Jèhófà, wọ́n sì wà “lórí Òkè Ńlá Síónì [ti ọ̀run].” (Ìṣípayá 4:4; 14:1) Ogunlọ́gọ̀ ńlá náà kì í ṣe ẹgbẹ́ àlùfáà wọn ò sì dé ipò gíga yẹn. Òótọ́ ni pé Ìṣípayá 7:15 wá sọ lẹ́yìn náà pé ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ń sin Ọlọ́run “nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀,” àmọ́, kì í ṣe ibi ìjọsìn inú lọ́hùn-ún, tó jẹ́ ibi Mímọ́ Jù Lọ ni tẹ́ńpìlì yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àgbàlá orí ilẹ̀ ayé ti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà na·osʹ, tó túmọ̀ sí “tẹ́ńpìlì” níbí sábà máa ń túmọ̀ ní gbogbo gbòò sí odidi ilé tá a kọ́ kalẹ̀ nítorí àtimáa lò ó fún ìjọsìn Jèhófà. Lónìí, èyí jẹ́ ìgbékalẹ̀ tẹ̀mí tí ọ̀run àti ilẹ̀ ayé jẹ́ ara rẹ̀.—Fi wé Mátíù 26:61; 27:5, 39, 40; Máàkù 15:29, 30; Jòhánù 2:19-21, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
Igbe Ìyìn Láyé àti Lọ́run
15, 16. (a) Kí làwọn ẹ̀dá olùṣòtítọ́ tó wà lókè ọ̀run ṣe nígbà tí ogunlọ́gọ̀ ńlá jáde wá? (b) Bí Jèhófà ṣe ń ṣí àwọn ohun kọ̀ọ̀kan tó ní lọ́kàn láti ṣe payá, kí làwọn ẹ̀dá ẹ̀mí rẹ̀ ń ṣe? (d) Báwo làwa tá a wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe lè bá wọn kọ nínú orin ìyìn náà?
15 Ogunlọ́gọ̀ ńlá ń yin Jèhófà, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn pẹ̀lú ń kọrin ìyìn rẹ̀. Jòhánù ròyìn pé: “Gbogbo àwọn áńgẹ́lì sì dúró yí ká ìtẹ́ náà àti àwọn alàgbà àti ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, wọ́n sì dojú bolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run, wí pé: ‘Àmín! Ìbùkún àti ògo àti ọgbọ́n àti ìdúpẹ́ àti ọlá àti agbára àti okun ni fún Ọlọ́run wa títí láé àti láéláé. Àmín.’”—Ìṣípayá 7:11, 12.
16 Nígbà tí Jèhófà dá ilẹ̀ ayé, gbogbo àwọn áńgẹ́lì mímọ́ rẹ̀ “jùmọ̀ ń fi ìdùnnú ké jáde, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.” (Jóòbù 38:7) Bí Jèhófà ṣe ń ṣí àwọn ohun tuntun kọ̀ọ̀kan tó ní lọ́kàn láti ṣe payá, ó dájú pé ṣe làwọn áńgẹ́lì á máa hó ìhó ayọ̀. Nígbà tí àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà, ìyẹn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] nínú ògo wọn ti ọ̀run, ké jáde láti fi ìmọrírì hàn fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, gbogbo ẹ̀dá Ọlọ́run yòókù tó kù lọ́run fi ohùn kan ṣoṣo dara pọ̀ mọ́ wọn láti fìyìn fún Jésù àti Jèhófà Ọlọ́run. (Ìṣípayá 5:9-14) Ayọ̀ àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí ti kọ́kọ́ kún àkúnwọ́sílẹ̀ nígbà tí wọ́n rí i pé Jèhófà ti ṣe ohun tó ní lọ́kàn nípa jíjí àwọn olùṣòtítọ́ ẹni àmì òróró dìde síbi ògo níbi táwọn áńgẹ́lì ń gbé. Àmọ́ ní báyìí táwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ti jáde wá, ńṣe làwọn ẹ̀dá olùṣòtítọ́ ti Jèhófà lọ́run yìí ń hó ìhó ayọ̀ tí wọ́n sì ń yin Ọlọ́run. Ní tòótọ́, àkókò tó wúni lórí láti máa gbé ni ọjọ́ Olúwa jẹ́ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. (Ìṣípayá 1:10) Àǹfààní ńláǹlà ló sì jẹ́ fún wa lórí ilẹ̀ ayé ńbí láti máa bá wọn kọrin ìyìn yìí bá a ṣe ń jẹ́rìí nípa Ìjọba Jèhófà!
Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Náà Jáde Wá
17. (a) Kí ni ìbéèrè tí ọ̀kan nínú àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà béèrè, kí nìyẹn sì fi hàn pé ó ṣeé ṣe? (b) Ìgbà wo la dáhùn ìbéèrè alàgbà náà?
17 Láti àkókò àpọ́sítélì Jòhánù títí lọ dé ọjọ́ Olúwa, ẹni tí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jẹ́ rú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lójú. Ó bá a mu rẹ́gí, nígbà náà, pé ọ̀kan nínú àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24], tó ń ṣojú fún àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n wà lọ́run báyìí, béèrè ìbéèrè kan tó ṣí Jòhánù níyè. “Ní ìdáhùnpadà, ọ̀kan nínú àwọn alàgbà náà wí fún mi pé: ‘Àwọn wọ̀nyí tí wọ́n wọ aṣọ funfun, ta ni wọ́n, ibo ni wọ́n sì ti wá?’ Nítorí náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ mo wí fún un pé: ‘Olúwa mi, ìwọ ni ẹni tí ó mọ̀.’” (Ìṣípayá 7:13, 14a) Bẹ́ẹ̀ ni, alàgbà yẹn lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà kó sì fi fún Jòhánù. Èyí fi hàn pé ó ṣeé ṣe káwọn tá a ti jí dìde lára àwùjọ àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà máa lọ́wọ́ nínú fífi àwọn òtítọ́ àtọ̀runwá ránṣẹ́ lónìí. Àmọ́ bí ẹgbẹ́ Jòhánù lórí ilẹ̀ ayé ṣe ń fara balẹ̀ kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe láàárín wọn ló mú kí wọ́n mọ ẹni tí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jẹ́. Ó tètè yé wọn yékéyéké pé àkókò ló tó lọ́dún 1935 tí Jèhófà fi fi ẹ̀kún rẹ́rẹ́ òye nípa àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣàkóso Ìjọba Rẹ̀ dá àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́lá.
18, 19. (a) Ìrètí wo ni ẹgbẹ́ Jòhánù tẹnu mọ́ lọ́dún 1920 sí ọdún 1929 àti ní ọdún 1930 sí ọdún 1934, ṣùgbọ́n àwọn tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i wo ni wọ́n tẹ́tí sí iṣẹ́ ìwàásù? (b) Kí ni dídá tá a dá ogunlọ́gọ̀ ńlá mọ̀ lọ́dún 1935 jẹ́ ká mọ̀ nípa ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]? (d) Kí ni àkọsílẹ̀ ìṣirò nípa Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ ká mọ̀?
18 Láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1929 àti lọ́dún 1930 sí 1934, gbọnmọgbọnmọ ni ẹgbẹ́ Jòhánù ń tẹnu mọ́ ìrètí ti ọ̀run, nínú àwọn ìwé àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ìyẹn sì lè jẹ́ nítorí pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ò tíì pé nígbà náà. Ṣùgbọ́n, ńṣe ni iye èèyàn tó ń pọ̀ sí i tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwàásù náà tí wọ́n sì ń fi ìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí ń fojú sọ́nà fún gbígbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Wọn ò ní ìrètí àtilọ sókè ọ̀run. Ìyẹn kọ́ ni ìpè tiwọn. Wọn kì í ṣe ara agbo kékeré, ara àwọn àgùntàn mìíràn ni wọ́n wà. (Lúùkù 12:32; Jòhánù 10:16) Dídá tá a dá wọn mọ̀ lọ́dún 1935 gẹ́gẹ́ bí ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn ni ẹ̀rí tó fi hàn pé yíyàn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí nígbà yẹn.
19 Ṣé àkọsílẹ̀ ìṣirò tó wà lọ́wọ́ ti èrò yìí lẹ́yìn? Bẹ́ẹ̀ ni. Lọ́dún 1938, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà kárí ayé jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárùn-ún àti mẹ́tàdínláàádọ́ta [59,047]. Nínú iye yìí, ẹgbàá méjìdínlógún, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti méjìlélọ́gbọ̀n [36,732] ló jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ níbi Ìrántí Ikú Jésù tó máa ń wáyé lọ́dọọdún, èyí tó fi hàn pé wọ́n nírètí àtilọ sọ́run. Látìgbà yẹn wá, iye àwọn tó ń jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa yìí ti ń dín kù síwájú àti síwájú sí i, ìdí pàtàkì tó sì fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn olùṣòtítọ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà wọ̀nyí ń parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé. Lọ́dún 2005, ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ, ọgọ́rùn márùn-ún ó lé mẹ́rìnlélógún [8,524] èèyàn péré ló jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìrántí Ikú Kristi, èyí sì kéré jọjọ sí àròpọ̀ iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi kárí ayé, èyí tó jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún àti ẹgbàá márùndínnígba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́fà [16,390,116].
20. (a) Láwọn ọdún làásìgbò ti ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì, kí la gbọ́ ti J. F. Rutherford sọ nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá? (b) Kí wá la fi mọ̀ báyìí pé ògìdìgbó èèyàn ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jẹ́?
20 Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, Sátánì sapá kíkankíkan láti dá iṣẹ́ kíkó ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jọ dúró. Àwọn aláṣẹ ká iṣẹ́ ìwàásù lọ́wọ́ kò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè. Láwọn ọdún làásìgbò wọ̀nyẹn, àti ní kété ṣáájú kí J. F. Rutherford tó kú lọ́dún 1942, a gbọ́ tó sọ pé: “Tóò . . . ó jọ bíi pé ògìdìgbó ńlá náà kì yóò fi bẹ́ẹ̀ tó bá a ṣe rò pó máa tó tẹ́lẹ̀ mọ́ o.” Ṣùgbọ́n ìbùkún Ọlọ́run ti mú ká ronú gba ibi tó yàtọ̀! Nígbà tó fi máa di ọdún 1946 iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìwàásù náà kárí ayé ti ròkè, ó ti di ẹgbàá méjìdínláàádọ́rùn-ún, ọ̀tàlénírínwó ó dín mẹ́rin [176,456], èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ló sì jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá. Lọ́dún 2005, ọ̀ọ́dúnrún ọ̀kẹ́, ẹgbàá márùndínnígba àti méjìlélógún [6,390,022] làwọn Ẹlẹ́rìí tó ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà ní òjìlénígba ó dín márùn-ún [235] ilẹ̀, OGUNLỌ́GỌ̀ ŃLÁ gbáà mà nìyẹn o! Ńṣe ni iye náà sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i.
21. (a) Báwo ni kíkó àwọn èèyàn Ọlọ́run jọ ní ọjọ́ Olúwa ṣe bá ìran Jòhánù mu wẹ́kú? (b) Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ?
21 Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí ti wá mú kí kíkó àwọn èèyàn Ọlọ́run jọ ní ọjọ́ Olúwa bá ìran tí Jòhánù rí mu wẹ́kú: lákọ̀ọ́kọ́ kíkó àwọn tó ṣẹ́ kù lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] jọ; lẹ́yìn náà, kíkó ogunlọ́gọ̀ ńlá jọ. Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀, nísinsìnyí “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè ń wọ́ tìrítìrí lọ kí wọ́n bàa lè lọ́wọ́ sí ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jèhófà. Ayọ̀ wa sì kún nítorí a mọ̀ pé Jèhófà ń dá “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.” (Aísáyà 2:2-4; 65:17, 18) Ọlọ́run ń kó “ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Éfésù 1:10) Àwọn ẹni àmì òróró ajogún Ìjọba ọ̀run, tá a ti ń fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún kó jọ látìgbà tí Jésù ti wà láyé, ni “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run.” Ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn sì tún ti wá jáde wá báyìí gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni àkọ́kọ́ lára “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” Bó o bá ń bá a nìṣó láti máa sin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ètò tó ṣe yìí, ó lè já sí ayọ̀ ayérayé fún ọ.
Ìbùkún Tí Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Máa Gbádùn
22. Ìsọfúnni síwájú sí i wo ni Jòhánù rí gbà nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá?
22 Ọlọ́run lo ọ̀nà tó ń gbà fi ìran han Jòhánù láti fún un ní ìsọfúnni síwájú sí i nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí: “Ó [ìyẹn alàgbà náà] sì wí fún mi pé: ‘Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà, wọ́n sì ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi wà níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run; wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀; Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ yóò sì na àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n.’”—Ìṣípayá 7:14b, 15.
23. Kí ni ìpọ́njú ńlá láti inú èyí tí ogunlọ́gọ̀ ńlá ti “jáde wá”?
23 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ́ rí, Jésù ti sọ pé ní ìparí wíwàníhìn-ín òun nínú ògo Ìjọba ni “ìpọ́njú ńlá” máa bẹ̀rẹ̀, “irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mátíù 24:21, 22) Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bá máa nímùúṣẹ, àwọn áńgẹ́lì á tú ẹ̀fúùfù mẹ́rin ilẹ̀ ayé náà dà sílẹ̀ láti pa ayé Sátánì run. Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé láá kọ́kọ́ pa run. Lẹ́yìn náà, nígbà tí ìpọ́njú náà bá ti rinlẹ̀ dáadáa, Jésù á dá àwọn tí wọ́n ṣẹ́ kù lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] lórí ilẹ̀ ayé nídè, pa pọ̀ pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ńlá.—Ìṣípayá 7:1; 18:2.
24. Báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan lára ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe ń dẹni tó yẹ fún lílà á já?
24 Kí ló máa mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan lára ogunlọ́gọ̀ ńlá yẹ lẹ́ni tí yóò là á já? Alàgbà náà sọ fún Jòhánù pé wọ́n ti “fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Lédè mìíràn, wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù gẹ́gẹ́ bí Olùràpadà wọn, wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n ti ṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wọn nípasẹ̀ ìrìbọmi, wọ́n sì ní “ẹ̀rí-ọkàn rere” nítorí pé wọ́n ń hùwà àìlábòsí. (1 Pétérù 3:16, 21; Mátíù 20:28) Nítorí náà, wọ́n mọ́ tónítóní wọ́n sì jẹ́ olódodo lójú Jèhófà. Wọ́n sì ń pa ara wọn mọ́ “láìní èérí kúrò nínú ayé.”—Jákọ́bù 1:27.
25. (a) Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ṣe ń ṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀” fún Jèhófà “tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀”? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe “na àgọ́ rẹ̀” bo ogunlọ́gọ̀ ńlá náà?
25 Síwájú sí i, wọ́n ti di ẹlẹ́rìí onítara fún Jèhófà, “wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.” Ṣé ọ̀kan lára àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tó ti ya ara wọn sí mímọ́ yìí ni ìwọ náà? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún ọ láti máa sin Jèhófà nìṣó nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì ńlá rẹ̀ tẹ̀mí lórí ilẹ̀ ayé. Lónìí, ogunlọ́gọ̀ ńlá ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà lábẹ́ ìdarí àwọn ẹni àmì òróró. Láìka wíwá àtijẹ àtimu sí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún lára wọn ń ya àkókò sọ́tọ̀ láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nípa sísìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́, yálà o wà lára wọn tàbí o kò sí níbẹ̀, yíyà tó o ti ya ara ẹ sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ara ogunlọ́gọ̀ ńlá, tó ohun tó lè mú kó o máa yọ̀ pé nítorí ìgbàgbọ́ àti àwọn iṣẹ́ rẹ, a polongo rẹ ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run a sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlejò nínú àgọ́ rẹ̀. (Sáàmù 15:1-5; Jákọ́bù 2:21-26) Ìdí ẹ̀ nìyẹn tí Jèhófà fi “na àgọ́ rẹ̀” bo àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé, gẹ́gẹ́ bí olùgbàlejò rere, ó ń dáàbò bò wọ́n.—Òwe 18:10.
26. Àwọn ìbùkún mìíràn wo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà máa gbádùn?
26 Alàgbà náà ń bá a lọ pé: “Ebi kì yóò pa wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọ́n tàbí ooru èyíkéyìí tí ń jóni gbẹ, nítorí Ọ̀dọ́ Àgùntàn, tí ó wà ní àárín ìtẹ́ náà, yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, yóò sì máa ṣamọ̀nà wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè. Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” (Ìṣípayá 7:16, 17) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àlejò ní tòótọ́! Ṣùgbọ́n ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ wo ní ń bẹ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ yìí?
27. (a) Báwo ni Aísáyà ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun kan tó jọ àwọn ọ̀rọ̀ alàgbà náà? (b) Kí ló fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ sórí ìjọ Kristẹni ní ọjọ́ Pọ́ọ̀lù?
27 Ẹ jẹ́ ká gbé àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fara jọ èyí yẹ̀ wò: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo ti dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ti ràn ọ́ lọ́wọ́ . . . Ebi kì yóò pa wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru amóhungbẹ hán-ún hán-ún mú wọn tàbí kí oòrùn pa wọ́n. Nítorí pé Ẹni tí ń ṣe ojú àánú sí wọn yóò ṣamọ̀nà wọn, ẹ̀bá àwọn ìsun omi sì ni yóò darí wọn lọ.” (Aísáyà 49:8, 10; tún wo Sáàmù 121:5, 6.) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàyọlò apá kan àsọtẹ́lẹ̀ yìí ó sì so ó pọ̀ mọ́ “ọjọ́ ìgbàlà” tó bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ó kọ̀wé pé: “Nítorí ó [ìyẹn Jèhófà] wí pé: ‘Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.’ Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.”—2 Kọ́ríńtì 6:2.
28, 29. (a) Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣe ní ìmúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ Ìṣípayá 7:16 ṣe ṣẹ mọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá lára? (d) Kí ló máa tìdí títọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá sọ́nà sí “àwọn ìsun omi ìyè” wá? (e) Kí ló máa mú kí ti ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣàrà ọ̀tọ̀ láàárín aráyé?
28 Kí ni ìlérí pé ebi ò ní pani mọ́, òùngbẹ ò ní gbẹni mọ́ tàbí pé ooru tó ń mú nǹkan gbẹ́ hán-ún hán-ún ò ní múni mọ́ túmọ̀ sí nígbà náà lọ́hùn-ún? Ó dájú pé àwọn ìgbà míì wà táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní jìyà ebi tí òùngbẹ gidi sì gbẹ wọ́n. (2 Kọ́ríńtì 11:23-27) Àmọ́, wọ́n ní ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Ọlọ́run rí sí i pé wọ́n ní ànító àti àníṣẹ́kù, nítorí náà ebi kì í pa wọ́n, òùngbẹ kì í sì í gbẹ́ wọn bó bá dọ̀ràn àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ náà sì ní Jèhófà ò jẹ́ kí ooru ìbínú rẹ̀ bì lù wọ́n nígbà tó pa ètò àwọn nǹkan Júù run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. Bákan náà làwọn ọ̀rọ̀ inú Ìṣípayá 7:16 ní ìmúṣẹ tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run fáwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá lónìí. Àwọn àtàwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jùmọ̀ ń gbádùn ọ̀pọ̀ yanturu ìpèsè tó jẹ mọ́ ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run.—Aísáyà 65:13; Náhúmù 1:6, 7.
29 Bó o bá jẹ́ ọ̀kan lára ogunlọ́gọ̀ ńlá, ipò rere tí ọkàn rẹ wà á mú kó o “fi ìdùnnú ké jáde,” láìfi ohun tí o ní láti fara dà lábẹ́ ètò Sátánì tó ń kógbá sílé yìí pè, ì báà jẹ́ ìfi-nǹkan-duni tàbí àwọn pákáǹleke mìíràn. (Aísáyà 65:14) Bó o bá sì wá bára ẹ nípò tí wàá fi nílò ìfaradà, Jèhófà lè ‘nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú rẹ.’ Ìdájọ́ mímúná tó dà bí “oòrùn” tí ń jóni lára ò tún ní jẹ́ ewu fún ọ mọ́, àti pé nígbà táwọn áńgẹ́lì náà bá tú ẹ̀fúùfù ìparun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dà sílẹ̀, Jèhófà lè dá ọ sí kúrò lọ́wọ́ ìbínú Rẹ̀ tó dà bí “ooru . . . tí ń jóni gbẹ.” Lẹ́yìn tí ìparun náà bá ti ṣọṣẹ́ rẹ̀ tán, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò tọ́ ọ sọ́nà kó o bàa lè jàǹfààní kíkún látinú “àwọn ìsun omi ìyè” tí ń sọ agbára dọ̀tun, àwọn wọ̀nyí dúró fún gbogbo ìpèsè Jèhófà fún ọ láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Ìgbàgbọ́ rẹ nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà la óò dá láre ní ti pé kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni wàá di ẹni pípé. Tẹ̀yin tẹ́ ẹ bá jẹ́ ará ogunlọ́gọ̀ ńlá náà á tún ṣàrà ọ̀tọ̀ láàárín aráyé gẹ́gẹ́ bí “ọ̀kẹ́ àìmọye” tí kò pọn dandan fún pé kí wọ́n kú! Ìgbà yẹn gan-an lọ̀rọ̀ náà á wá ní ìmúṣẹ ní kíkún pé Ọlọ́run á nu gbogbo omijé nù kúrò lójú yín.—Ìṣípayá 21:4.
Bí Pípè Náà Ṣe Lè Dájú
30. Báwo ni ìran tí Jòhánù rí ṣe mú ká wo sàkun àwọn ohun títóbilọ́lá tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, ta ni yóò sì lè “dúró”?
30 Ẹ wo báwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe jẹ́ ká wo sàkun àwọn ohun títóbilọ́lá tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀! Jèhófà fúnra rẹ̀ wà lórí ìtẹ́ rẹ̀, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, ń fi ìyìn fún un ní ìṣọ̀kan. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé mọrírì bó ṣe jẹ́ àgbàyanu àǹfààní tó fáwọn láti kópa nínú ègbè orin ìyìn tí ń kọ lálá. Láìpẹ́ láìjìnnà, Jèhófà àti Kristi Jésù á mú ìdájọ́ ṣẹ a óò sì gbọ́ igbe pé: “Ọjọ́ ńlá ìrunú wọn ti dé, ta ni ó sì lè dúró?” (Ìṣípayá 6:17) Ta ló lè dúró ná? Ìwọ̀nba kéréje lára àwọn olùgbé ayé, títí kan àwọn tó wà lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tá a fi èdìdì dì tó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣì wà nínú ẹran ara àti ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àgùntàn mìíràn ni yóò “dúró,” ìyẹn ni pé àwọn ni yóò, là á já pẹ̀lú wọn.—Jeremáyà 35:19; 1 Kọ́ríńtì 16:13.
31. Báwo ni ìmúṣẹ ìran Jòhánù ṣe yẹ kó nípa lórí àwọn Kristẹni, yálà wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí ara ogunlọ́gọ̀ ńlá?
31 Bọ́rọ̀ ṣe wá rí yìí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ẹgbẹ́ Jòhánù ń lo ara wọn tokuntokun láti máa “lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 3:14) Wọ́n mọ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àkókò yìí á gba pé káwọn ní ìfaradà tó pọ̀. (Ìṣípayá 13:10) Lẹ́yìn tí wọ́n ti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n di ìgbàgbọ́ mú ṣinṣin, wọ́n sì ń yọ̀ pé orúkọ àwọn ti wà ‘lákọọ́lẹ̀ ní ọ̀run.’ (Lúùkù 10:20; Ìṣípayá 3:5) Àwọn tí wọ́n jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá, pẹ̀lú, mọ̀ pé kìkì “ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 24:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti sàmì sí ogunlọ́gọ̀ ńlá gẹ́gẹ́ bí àwùjọ tó jáde wá látinú ìpọ́njú ńlá, ẹnì kọ̀ọ̀kan lara wọn gbọ́dọ̀ fi tokuntokun lo ara wọn kí wọ́n bàa lè wà ní mímọ́ kí ọwọ́ wọn sì dí fún iṣẹ́.
32. Kí la rí pé ó jẹ́ kánjúkánjú nínú ọ̀ràn náà pé kìkì àwùjọ méjì ni yóò “dúró” ní ọjọ́ ìkannú Jèhófà?
32 Kò sí ẹ̀rí kankan pé ẹnikẹ́ni yàtọ̀ sí àwùjọ méjì yìí máa “dúró” ní ọjọ́ ìkannú Jèhófà. Kí lèyí túmọ̀ sí fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ń fọ̀wọ̀ hàn lọ́nà kan fún ẹbọ Jésù lọ́dọọdún nípa wíwá tí wọ́n ń wá síbi Ìrántí Ikú rẹ̀, àmọ́ tí wọn ò tíì máa lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù débi tí wọ́n á fi di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ya ara wọn sí mímọ́, tó ṣe ìrìbọmi, tó sì ń fi taratara ṣiṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run? Láfikún sí ìyẹn, àwọn tí ọwọ́ wọn ti fìgbà kan dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run àmọ́ tí wọ́n yọ̀ǹda kí ọkàn wọn di èyí tí a “dẹrù pa pẹ̀lú . . . àwọn àníyàn ìgbésí ayé” ńkọ́? Ǹjẹ́ kí gbogbo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ta jí, kí wọ́n wà lójúfò, kí wọ́n bàa lè “kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn” ìyẹn, Jésù Kristi. Ọjọ́ ti lọ o!—Lúùkù 21:34-36.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
b Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì), April 1, 1918, ojú ìwé 98.
c Ní tààràtà, ó túmọ̀ sí “níwájú rẹ̀,” ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ The Kingdom Interlinear Translation of the Greek Scriptures.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 119]
Ti Ọlọ́run Ni Ìtumọ̀
Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ni ẹgbẹ́ Jòhánù fi ṣèwádìí ẹni tí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jẹ́ tí wọn kò sì rí àlàyé tó tẹ́ wọn lọ́rùn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? A rí ìdáhùn nínú àwọn ọ̀rọ̀ Jósẹ́fù olùṣòtítọ́, nígbà tó wí pé: “Ìtúmọ̀ kò ha jẹ́ ti Ọlọ́run?” (Jẹ́nẹ́sísì 40:8) Ìgbà wo ni Ọlọ́run ń túmọ̀ ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ báwo ló sì ṣe ń túmọ̀ wọn? Ó sábà máa ń jẹ́ nígbà tó bá tó àkókò kí wọ́n nímùúṣẹ tàbí lọ́wọ́lọ́wọ́ tí wọ́n bá ń nímùúṣẹ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣèwádìí lè fòye mọ ohun tí wọ́n túmọ̀ sí ní kedere. Òye tí wọ́n bá ní yìí má ń wà “fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.”—Róòmù 15:4.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 124]
Àwọn tó para pọ̀ di ogunlọ́gọ̀ ńlá
▪ jáde wá láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti àwọn ènìyàn àti èdè
▪ dúró níwájú ìtẹ́ Jèhófà
▪ ti fọ aṣọ wọn di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà
▪ gbé ògo ìgbàlà wọn fún Jèhófà àti Jésù
▪ jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá
▪ ń sin Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ tọ̀sán tòru
▪ ń rí ààbò onífẹ̀ẹ́ àti ìtọ́jú Jèhófà gbà
▪ ni Jésù ṣolùṣọ́ àgùntàn wọn lọ síbi ìsun omi ìyè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 121]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 127]
Ọlọ́run àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn nìkan ló lè gba ogunlọ́gọ̀ ńlá là
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 128]
Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ló máa darí ogunlọ́gọ̀ ńlá lọ síbi ìsun omi ìyè
-
-
Àwọn Ìyọnu Tó Wá Sórí Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Látọ̀dọ̀ JèhófàÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
Orí 21
Àwọn Ìyọnu Tó Wá Sórí Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Látọ̀dọ̀ Jèhófà
Ìran 5—Ìṣípayá 8:1–9:21
Ohun tó dá lé: Fífun mẹ́fà nínú àwọn kàkàkí méje náà
Ìgbà tó nímùúṣẹ: Látìgbà tí Jèhófà ti gbé Kristi Jésù gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914 títí dìgbà ìpọ́njú ńlá
1. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọ̀dọ́ Àgùntàn ṣí èdìdì keje?
ÀWỌN áńgẹ́lì ti dá “ẹ̀fúùfù mẹ́rin” náà dúró títí tí a ó fi fi èdìdì di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ọlọ́run tí a ó sì fún ogunlọ́gọ̀ ńlá náà láǹfààní láti là á já. (Ìṣípayá 7:1-4, 9) Ṣùgbọ́n, kí ìjì ẹlẹ́fùúùfù líle yẹn tó rọ́ lu ayé, a gbọ́dọ̀ kéde àwọn ìdájọ́ Jèhófà tó ń bọ̀ lórí ayé Sátánì pẹ̀lú! Bí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣe ń ṣí èdìdì keje tó kẹ́yìn, Jòhánù ti ní láti máa fi gbogbo ọkàn bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ bọ̀ kó lè rí ohun tí a ó fi hàn kedere. Ẹ wo ohun tó lóhun rí wàyí: “Nígbà tí ó [ìyẹn Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà] sì ṣí èdìdì keje, kẹ́kẹ́ pa ní ọ̀run fún nǹkan bí ààbọ̀ wákàtí. Mo sì rí àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n dúró níwájú Ọlọ́run, a sì fún wọn ní kàkàkí méje.”—Ìṣípayá 8:1, 2.
Àkókò Àdúrà Àtọkànwá
2. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí kẹ́kẹ́ pa fún ààbọ̀ wákàtí ìṣàpẹẹrẹ ní ọ̀run?
2 Àkókò pàtàkì làkókò tí kẹ́kẹ́ pa yìí o! Ààbọ̀ wákàtí lè ti gùn jù nígbà tó o bá ń dúró pé kí ohun kan ṣẹlẹ̀. Kódà, Jòhánù ò tiẹ̀ gbúròó orin ìyìn tí wọ́n ń kọ lọ́run mọ́ báyìí. (Ìṣípayá 4:8) Kí ló fà á? Jòhánù rí ohun tó fà á nínú ìran: “Áńgẹ́lì mìíràn sì dé, ó sì dúró nídìí pẹpẹ, ó ní ajere tùràrí oníwúrà lọ́wọ́; a sì fún un ní ìwọ̀n tùràrí púpọ̀ gan-an láti sun ún pẹ̀lú àdúrà gbogbo ẹni mímọ́ lórí pẹpẹ wúrà tí ó wà níwájú ìtẹ́ náà. Èéfín tùràrí náà sì gòkè láti ọwọ́ áńgẹ́lì náà pẹ̀lú àdúrà àwọn ẹni mímọ́ síwájú Ọlọ́run.”—Ìṣípayá 8:3, 4.
3. (a) Kí ni tùràrí tí wọ́n ń sun rán wa létí rẹ̀? (b) Kí nìdí tí kẹ́kẹ́ fi pa fún ààbọ̀ wákàtí lọ́run?
3 Èyí á rán wa létí pé nínú ètò ìjọsìn àwọn Júù, ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń sun tùràrí nínú àgọ́ ìjọsìn, wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù tí wọ́n kọ́ lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà. (Ẹ́kísódù 30:1-8) Lákòókò tí wọ́n bá ń sun tùràrí báyìí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kì í ṣe àlùfáà máa dúró lẹ́yìn òde ibi mímọ́, wọ́n á máa gbàdúrà. Ó dájú pé àdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ látinú ọkàn wọn ni wọ́n ń gbà, ẹni tí èéfín tùràrí náà ń gòkè tọ̀ lọ ni wọ́n sì ń gbàdúrà sí. (Lúùkù 1:10) Jòhánù wá rí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ báyìí, tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run. Tùràrí áńgẹ́lì náà ní í ṣe pẹ̀lú “àdúrà àwọn ẹni mímọ́.” Kódà, nínú ìran kan tó ṣáájú èyí, a rí i pé tùràrí náà dúró fún irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀. (Ìṣípayá 5:8; Sáàmù 141:1, 2) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a wá rí i kedere pé kẹ́kẹ́ tó pa ní ọ̀run yẹn pa láti jẹ́ kí wọ́n máa gbọ́ àdúrà àwọn ẹni mímọ́ orí ilẹ̀ ayé.
4, 5. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo tá a rí nínú ìtàn ló jẹ́ ká lè mọ àkókò tó bá àkókò tí kẹ́kẹ́ pa fún ààbọ̀ wákàtí ìṣàpẹẹrẹ mu?
4 Ǹjẹ́ a lè mọ ìgbà tí èyí ṣẹlẹ̀? A kúkú lè mọ̀ ọ́n tá a bá yẹ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ní àyíká ọ̀rọ̀ náà wò, tá a wá fi wé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ìtàn fi hàn pé ó wáyé lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa. (Ìṣípayá 1:10) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé láàárín ọdún 1918 sí ọdún 1919, bá ìran tí Ìṣípayá 8:1-4 ṣàpèjúwe mu rẹ́gí. Láti ogójì [40] ọdún ṣáájú 1914 làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, ti ń kéde láìṣojo pé àwọn àkókò Kèfèrí yóò dópin lọdún yẹn. Àwọn àjálù tó wáyé lọ́dún 1914 fi hàn pé òótọ́ ni wọ́n sọ. (Lúùkù 21:24, Bibeli Mimọ; Mátíù 24:3, 7, 8) Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn tún gbà gbọ́ pé ọdún 1914 ni a óò mú wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé yìí lọ síbi ogún wọn lọ́run. Ìyẹn ò ṣẹlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, wọ́n fara da àkókò inúnibíni tó gbóná girigiri. Ní October 31, ọdún 1916, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Society, Charles T. Russell, kú. Lẹ́yìn náà, ní July 4, ọdún 1918, wọ́n kó ààrẹ tuntun tó tẹ̀ lé e, Joseph F. Rutherford, àtàwọn aṣojú Society méje mìíràn lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà nílùú Atlanta, ní ìpínlẹ̀ Georgia, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn lẹ́jọ́ tí ò tọ́ sí wọn pé kí wọ́n lọ fi ẹ̀wọ̀n ọlọ́dún gbọọrọ jura.
5 Jẹbẹtẹ gbọ́mọ lé àwọn Kristẹni olóòótọ́ ẹgbẹ́ Jòhánù lọ́wọ́. Kí wá ni Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe lẹ́yìn ìyẹn o? Ìgbà wo la máa gbà wọ́n sókè ọ̀run? Àpilẹ̀kọ kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ìkórè Dópin—Kí Ni Yóò Tẹ̀ Lé E?” jáde nínú Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) ìtẹ̀jáde May 1, 1919. Ó fi hàn pé àwọn nǹkan ò dá wọn lójú ó sì rọ àwọn olóòótọ́ láti máa fara dà á nìṣó, ó wá fi kún un pé: “A gbà nísinsìnyí pé tòótọ́ ni pé ìkórè ẹgbẹ́ ìjọba náà jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tá a ti ṣe láṣeparí àti pé gbogbo àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ti fi èdìdì dì lọ́nà tó tọ́ àti pé ilẹ̀kùn ni a ti tì.” Ní àkókò ìṣòro yìí, àwọn àdúrà àtọkànwá táwọn ẹgbẹ́ Jòhánù ń gbà ń gòkè lọ, bí ẹni pé èéfín tùràrí tó pọ̀ púpọ̀ ló ń gbé e. Ọlọ́run sì ń gbọ́ àdúrà wọn!
Fífi Iná Sọ̀kò sí Ilẹ̀ Ayé
6. Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn kẹ́kẹ́ tó pa lọ́run, ìdáhùn kí lèyí sì jẹ́?
6 Jòhánù sọ fún wa pé: “Ṣùgbọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ áńgẹ́lì náà mú ajere tùràrí náà, ó sì fi díẹ̀ nínú iná pẹpẹ kún inú rẹ̀, ó sì fi í sọ̀kò sí ilẹ̀ ayé. Ààrá àti ohùn àti mànàmáná àti ìsẹ̀lẹ̀ sì sẹ̀.” (Ìṣípayá 8:5) Lẹ́yìn tí kẹ́kẹ́ ti pa, àwọn nǹkan àràmàǹdà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ lójijì! Ó hàn gbangba pé ìdáhùn àdúrà àwọn ẹni mímọ́ nìyẹn, torí pé iná tí áńgẹ́lì náà mú látorí pẹpẹ tùràrí ló fà á. Nígbà náà lọ́hùn-ún lọ́dún 1513 ṣááju Sànmánì Kristẹni, lórí Òkè Ńlá Sínáì, ààrá pẹ̀lú mànàmáná, ariwo tó pọ̀, iná, àti ìmìtìtì òkè ńlá náà jẹ́ àmì pé Jèhófà ti yí àfiyèsí rẹ̀ sáwọn èèyàn rẹ̀. (Ẹ́kísódù 19:16-20) Irú àwọn ìran bẹ́ẹ̀, èyí tí Jòhánù ròyìn ẹ̀ yìí, fi hàn pé Jèhófà ti yí àfiyèsí rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n àmì ni àwọn ohun tí Jòhánù rí. (Ìṣípayá 1:1) Nítorí náà báwo la ṣe lè lóye àwọn nǹkan tí iná, ààrá, ohùn, mànàmáná, àti ìsẹ̀lẹ̀ túmọ̀ sí lónìí?
7. (a) Iná ìṣàpẹẹrẹ wo ni Jésù dá lórí ilẹ̀ ayé lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? (b) Báwo làwọn Kristẹni arákùnrin Jésù ṣe mú kí iná kan ràn níbi tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀?
7 Lákòókò kan, Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èmi wá láti dá iná kan sórí ilẹ̀ ayé.” (Lúùkù 12:49) Lóòótọ́ sì ni, ó dá iná kan. Nípasẹ̀ ìwàásù tí Jésù fi ìtara ṣe, ó sọ Ìjọba Ọlọ́run di ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ táwọn Júù ní láti gbé yẹ̀ wò, èyí sì tanná ran àríyànjiyàn gbígbóná jákèjádò orílẹ̀-èdè yẹn. (Mátíù 4:17, 25; 10:5-7, 17, 18) Lọ́dún 1919 àwọn Kristẹni arákùnrin Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn agbo kékeré tàwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ti la àwọn ọjọ́ aládàn-án-wò Ogun Àgbáyé Kìíní já, dá irú iná tó jọ ìyẹn náà níbi tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀. Lóṣù September ọdún yẹn, ó hàn gbangba pé ẹ̀mí Jèhófà ń ṣiṣẹ́, báwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ adúróṣinṣin ṣe pé jọ láti itòsí àti ọ̀nà jíjìn, sí Cedar Point, Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Joseph F. Rutherford, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tú sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, tí wọn ò sì ní í pẹ́ sọ pé kò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, fi àìṣojo bá àwọn tó pé jọ náà sọ̀rọ̀ pé: “Gẹ́gẹ́ bí àmì ìgbọràn sí àṣẹ Ọ̀gá wa, tá a sì tún mọ àǹfààní tá a ní àti iṣẹ́ wa, pé a ní láti túdìí àṣírí àwọn ohun tó ti ń kó àwọn èèyàn ṣìnà tipẹ́tipẹ́, iṣẹ́ wa ni láti kéde ìjọba Mèsáyà ológo tó ń bọ̀ wá, bẹ́ẹ̀ ẹnu iṣẹ́ náà la ṣì wà.” Ọ̀ràn pàtàkì tó wà nílẹ̀ nìyẹn, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run!
8, 9. (a) Báwo ni J. F. Rutherford ṣe ṣàlàyé báwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ń ṣe àti ìfẹ́ ọkàn wọn ní gbogbo ọdún tí ìṣòro fi dojú kọ wọ́n? (b) Báwo ló ṣe jẹ́ pé a ju iná sí ilẹ̀ ayé? (d) Báwo ni ààrá, ohùn, mànàmáná, àti ìsẹ̀lẹ̀ ṣe wáyé?
8 Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ yìí bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ débi àwọn ìnira tó ń kojú èèyàn Ọlọ́run lákòókò yẹn, ó wí pé: “Àwọn ọ̀tá yìí fojú agbo tó jẹ́ ààyò Olúwa rí màbo, débi tó fi ya àwọn tó wà nínú agbo náà lẹ́nu. Wọn ò lè ṣe nǹkan kan, ṣe ló ń ṣe wọ́n ní kàyéfì bí wọ́n ṣe ń gbàdúrà tí wọ́n sì ń fojú sọ́nà sí mímọ ìfẹ́ Olúwa. . . . Àmọ́, láìka ìrẹ̀wẹ̀sì tó bá wọn fúngbà díẹ̀ sí, bí iná ni ìfẹ́ láti wàásù ọ̀rọ̀ Ìjọba náà ṣe ń jó lọ́kàn wọn.”—Wo ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) ti September 15, 1919, ojú ìwé 280.
9 Lọ́dún 1919, ó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn. Iná tẹ̀mí ran agbo àwọn Kristẹni tí wọ́n kéré ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ akíkanjú yìí, èyí sì mú kí wọ́n máa fi ìtara wàásù káàkiri ayé. (Fi wé 1 Tẹsalóníkà 5:19.) A fi iná sọ̀kò sí ilẹ̀ ayé ní ti pé Ìjọba Ọlọ́run di ọ̀rọ̀ tó ń ràn bí iná, bó sì ṣe ń bá a lọ nìyẹn! Dípò kẹ́kẹ́ tó pa, ohùn alágbára ń dún, ó sì ń gbé ọ̀rọ̀ Ìjọba náà jáde ketekete. Àwọn ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ ń dún gbọnmọgbọnmọ bí ààrá látinú Bíbélì bẹ́ẹ̀ ló ń rọ́ yìì bí ìjì. Àfi bíi mànàmáná tó ń kọ mọ̀nà, Ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Jèhófà ń mú kí òtítọ́ tàn yanran, ṣe làwọn ìsìn lápapọ̀ mì jìgìjìgì dórí ìpìlẹ̀ wọn bíi pé ìsẹ̀lẹ̀ alágbára ńlá ló dé. Ẹgbẹ́ Jòhánù rí i pé iṣẹ́ wà láti ṣe. Títí dòní olónìí, iṣẹ́ náà ń bá a lọ láti gbilẹ̀ tògotògo jákèjádò ilẹ̀ ayé tí a ń gbé!—Róòmù 10:18.
Mímúrasílẹ̀ Láti Fun Kàkàkí
10. Kí làwọn áńgẹ́lì méje náà ṣe tán láti ṣe nísinsìnyí, kí ló sì fà á?
10 Jòhánù tẹ̀ síwájú pé: “Àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní kàkàkí méje lọ́wọ́ sì múra sílẹ̀ láti fun wọ́n.” (Ìṣípayá 8:6) Kí ni fífun àwọn kàkàkí yẹn túmọ̀ sí? Nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìró kàkàkí ni wọ́n fi ń sàmì sáwọn ọjọ́ pàtàkì tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì. (Léfítíkù 23:24; 2 Àwọn Ọba 11:14) Bákan náà, àwọn ìró kàkàkí tí Jòhánù máa tó gbọ́ yóò mú káwọn èèyàn kíyè sí àwọn ọ̀ràn pàtàkì tó lè mú ẹ̀mí lọ́wọ́.
11. Láàárín ọdún 1919 sí 1922 iṣẹ́ ìmúrasílẹ̀ wo ni ẹgbẹ́ Jòhánù dáwọ́ lé lórí ilẹ̀ ayé?
11 Báwọn áńgẹ́lì náà ti ṣe tán láti fun àwọn kàkàkí yẹn, kò sí iyè méjì pé wọ́n tún darí iṣẹ́ ìmúrasílẹ̀ kan lórí ilẹ̀ ayé. Láti ọdún 1919 sí ọdún 1922, ẹgbẹ́ Jòhánù tí wọ́n ti gba agbára kún agbára dáwọ́ lé ṣíṣe àtúntò iṣẹ́ ìwàásù ìta gbangba, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ilé tí wọ́n á ti máa tẹ ìwé jáde. Lọ́dún 1919, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn náà, The Golden Age, tá a mọ̀ sí Ji! báyìí gẹ́gẹ́ bí “Ìwé Ìròyìn Tó Ń Gbé Ìròyìn Òtítọ́, Ìrètí, àti Ìgbàgbọ́ Tó Dáni Lójú Jáde.” Òun ni irin iṣẹ́ kan tó dà bíi kàkàkí tó máa ṣe bẹbẹ nínú títú àṣírí bí ìsìn èké ṣe ń lọ́wọ́ sí ìṣèlú.
12. Kí ni ìró kàkàkí kọ̀ọ̀kan ń polongo, ó sì rán wa létí ìṣẹ̀lẹ̀ wo nígbà ayé Mósè?
12 Bá a ó ṣe rí i nísinsìnyí, bí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìró kàkàkí náà ṣe ń dún, ṣe ló ń polongo àgbàyanu ìran nípa báwọn ìyọnu bíbanilẹ́rù ṣe ń dé bá apá kan ilẹ̀ ayé. Díẹ̀ lára ìyọnu wọ̀nyí rán wa létí àwọn ìyọnu tí Jèhófà lò láti fìyà jẹ àwọn ará Íjíbítì nígbà ayé Mósè. (Ẹ́kísódù 7:19–12:32) Wọ́n jẹ́ ìdájọ́ Jèhófà lórí orílẹ̀-èdè yẹn, wọ́n sì jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run ráàyè bọ́ lóko ẹrú. Ohun tó jọ èyí làwọn ìyọnu tí Jòhánù rí mú kó ṣeé ṣe. Àmọ́, àwọn ìyọnu yẹn kì í ṣe ìyọnu gidi tó ṣẹlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àmì tó ń ṣàpẹẹrẹ àwọn ìdájọ́ òdodo Jèhófà ni wọ́n.—Ìṣípayá 1:1.
Ohun Tí “Ìdá Mẹ́ta” Náà Jẹ́
13. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn áńgẹ́lì náà fun kàkàkí mẹ́rin àkọ́kọ́, ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ látàrí èyí?
13 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i, nígbà táwọn áńgẹ́lì náà bá fun kàkàkí mẹ́rin àkọ́kọ́, wọ́n á mú ìyọnu wá sórí “ìdá mẹ́ta” ilẹ̀ ayé, òkun, àwọn odò àti àwọn ìsun omi, àti àwọn orísun ìmọ́lẹ̀ ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 8:7-12) Ìdá mẹ́ta nínú nǹkan kan pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo nǹkan ọ̀hún. (Fi wé Aísáyà 19:24; Ìsíkíẹ́lì 5:2; Sekaráyà 13:8, 9.) “Ìdá mẹ́ta” wo nínú ayé ni ìyọnu yìí tọ́ sí jù lọ? Sátánì àti irú ọmọ rẹ̀ ti fọ́ àwọn tó pọ̀ jù lọ láàárín aráyé lójú ó sì ti sọ wọ́n dìbàjẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 2 Kọ́ríńtì 4:4) Ọ̀ràn náà rí bí Dáfídì ti ṣàpèjúwe rẹ̀, pé: “Gbogbo wọn ti yapa, gbogbo wọn pátá jẹ́ ẹni ìbàjẹ́; kò sí ẹni tí ń ṣe rere, kò tilẹ̀ sí ẹyọ kan.” (Sáàmù 14:3) Bẹ́ẹ̀ ni, ewu ìdájọ́ mímúná rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí gbogbo aráyé. Ṣùgbọ́n apá kan nínú ayé jẹ̀bi ní pàtàkì. Ì bá mà dáa o ká ní apá kan, ìyẹn “ìdá mẹ́ta” náà mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe máa rí nìyẹn! Kí ni “ìdá mẹ́ta” yẹn?
14. Kí ni ìdá mẹ́ta táwọn ọ̀rọ̀ alágbára, tí ń kó ìyọnu báni látọ̀dọ̀ Jèhófà ń já bọ́ lé lórí dúró fún?
14 Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni! Láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1929, nǹkan bí ìdá mẹ́ta aráyé ló wà nínú ìsìn èké. Àwọn apẹ̀yìndà láti inú ìsìn Kristẹni tòótọ́ ló dá a sílẹ̀, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìpẹ̀yìndà ńlá yẹn. (Mátíù 13:24-30; Ìṣe 20:29, 30; 2 Tẹsalóníkà 2:3; 2 Pétérù 2:1-3) Ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sọ pé àwọn wà nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run, wọ́n sì ti sọ pé olùkọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni làwọn. Ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ wọn jìnnà pátápátá sí òtítọ́ Bíbélì, nígbà gbogbo ni wọ́n sì ń tàbùkù sí orúkọ Ọlọ́run. Àwọn ọ̀rọ̀ alágbára, tí ń kó ìyọnu báni á máa ti ọ̀dọ̀ Jèhófà bọ́ sórí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó dúró fún ìdá mẹ́ta náà. Ìdá mẹ́ta yẹn láàárín aráyé kò yẹ fún ojú rere Ọlọ́run páàpáà!
15. (a) Ǹjẹ́ fífun ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kàkàkí náà mọ sí àárín ọdún kan pàtó? Ṣàlàyé. (b) Ohùn àwọn wo ló ti dà pọ̀ mọ́ ti ẹgbẹ́ Jòhánù ní pípòkìkí àwọn ìdájọ́ Jèhófà?
15 Báwọn ìró kàkàkí yìí ṣe ń dún tẹ̀ léra, àwọn ìpinnu pàtàkì pàtàkì làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń gbé jáde láwọn àpéjọ àgbègbè tó wáyé láàárín ọdún 1922 sí ọdún 1928. Ṣùgbọ́n fífun àwọn kàkàkí náà ò mọ sórí àwọn ọdún yẹn. Wọ́n ṣì ń bá a lọ láìsọsẹ̀ láti máa túdìí àṣírí iṣẹ́ láabi àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, kódà wọ́n ṣì wà lẹ́nu títú àṣírí ọ̀hún bí ọjọ́ Olúwa ti ń tẹ̀ síwájú. A gbọ́dọ̀ kéde ìdájọ́ Jèhófà káàkiri ayé, fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láìka ìkórìíra àti inúnibíni tó wà jákèjádò ayé sí. Ó dìgbà tá a bá tó ṣèyẹn kí òpin ètò Sátánì tó dé. (Máàkù 13:10, 13) Inú wa ń dùn pé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà nísinsìnyí ti fi ohùn tiwọn kún ti ẹgbẹ́ Jòhánù láti máa jẹ́ kí ìkéde tó ṣe pàtàkì fún gbogbo àgbáyé náà máa dún bí ààrá.
Ìdá Mẹ́ta Ilẹ̀ Ayé Jóná
16. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì kìíní fun kàkàkí ẹ̀?
16 Nígbà tí Jòhánù tún dẹ́nu lé ìròyìn nípa àwọn áńgẹ́lì náà, ó kọ̀wé pé: “Èyí èkíní sì fun kàkàkí rẹ̀. Yìnyín àti iná tí ó dà pọ̀ mọ́ ẹ̀jẹ̀ sì ṣẹlẹ̀, a sì fi í sọ̀kò sí ilẹ̀ ayé; ìdá mẹ́ta ilẹ̀ ayé sì jóná, ìdá mẹ́ta àwọn igi sì jóná, gbogbo ewéko tútù sì jóná.” (Ìṣípayá 8:7) Eléyìí jọ ìyọnu keje tó wá sórí Íjíbítì, ṣùgbọ́n kí ló túmọ̀ sí lákòókò tiwa yìí?—Ẹ́kísódù 9:24.
17. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ilẹ̀ ayé” tó wà nínú Ìṣípayá 8:7 dúró fún? (b) Báwo ni ìdá mẹ́ta ilẹ̀ ayé tí ó jẹ́ ti ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe jóná?
17 Lọ́pọ̀ ìgbà nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ilẹ̀ ayé” máa ń tọ́ka sí aráyé. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1; Sáàmù 96:1) Níwọ̀n bí ìyọnu kejì ti wá sórí òkun, tí òkun náà sì ní í ṣe pẹ̀lú aráyé, “ilẹ̀ ayé” ní láti tọ́ka sí àgbájọ àwọn èèyàn tí Sátánì gbé kalẹ̀ tó dà bí èyí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, tó sì yẹ fún ìparun. (2 Pétérù 3:7; Ìṣípayá 21:1) Ìran ìyọnu náà fi hàn pé ìdá mẹ́ta ilẹ̀ ayé tó jẹ́ ti ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ooru ìbínú Jèhófà tó ń bù yìì jó gbẹ. Àwọn jàǹkàn jàǹkàn tó wà nínú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, tí wọ́n dúró bí igi láàárín rẹ̀, ni ìpolongo ìdájọ́ mímúná Jèhófà dáná sun. Bí ẹgbàágbèje àwọn ọmọ ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyí bá ń bá a lọ láti máa dúró sínú àwọn ìsìn wọn, lójú Ọlọ́run, wọ́n ti rọ dà nù bí ewé koríko tí ooru jó gbẹ.—Fi wé Sáàmù 37:1, 2.a
18. Báwo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe pòkìkí ìhìn ìdájọ́ Jèhófà ní ìpàdé tó wáyé ní Cedar Point lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1922?
18 Báwo ni wọ́n ṣe ń kéde ìdájọ́ yìí? Wọn kì í sábàá lo àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ayé, tí wọ́n jẹ́ apá kan ayé, tí wọ́n sì sábà máa ń kẹ́gàn “ẹrú” Ọlọ́run. (Mátíù 24:45) Wọ́n pòkìkí rẹ̀ lọ́nà tó gba àfiyèsí ní ìpàdé mánigbàgbé ẹlẹ́ẹ̀kejì táwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ní Cedar Point, Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní September 10, ọdún 1922. Pẹ̀lú ìfohùnṣọ̀kan àti ìtara, wọ́n tẹ́wọ́ gba ìpinnu kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́: “Ìpèníjà Fáwọn Aṣáájú Ayé.” Láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, ó fún ilẹ̀ ayé ìṣàpẹẹrẹ ti òde òní ní ìkìlọ̀ àwítẹ́lẹ̀ yìí pé: “Nítorí náà a ké sí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyé, àwọn alákòóso wọn pẹ̀lú àwọn aṣáájú wọn, a sì ké sí gbogbo ẹgbẹ́ àlùfáà gbogbo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ ayé ní ẹlẹ́kajẹ̀ka, àwọn ọmọlẹ́yìn wọn àtàwọn alájọṣepọ̀ wọn, tó fi mọ́ àwọn oníṣòwò aládàá ńlá àtàwọn èèkàn nínú òṣèlú, pé kí wọ́n mú ẹ̀rí wá láti sọ ìdí tí wọ́n fi sọ pé àwọn lè mú kí àlàáfíà àti aásìkí rídìí jókòó àti pé àwọn lè mú ayọ̀ wá fáwọn èèyàn; tí wọn ò bá sì lè mú ẹ̀rí wá, a ké sí wọn láti dẹtí wọn sílẹ̀ sí ẹ̀rí tí àwa ń jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí fún Olúwa, kí wọ́n sì wá sọ bóyá ẹ̀rí wa jẹ́ òótọ́ tàbí èké.”
19. Ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run gbé jáde fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nípa Ìjọba Ọlọ́run?
19 Ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wo ni àwọn Kristẹni wọ̀nyí gbé jáde? Òun rèé: “Àwa gbà gbọ́ a sì polongo pé ìjọba Mèsáyà ni yóò fòpin sí gbogbo ìpọ́njú ìran èèyàn, tí yóò mú àlàáfíà wá sórí ilẹ̀ ayé tí yóò sì fi inú rere bá àwọn èèyàn lò, ohun tí gbogbo orílẹ̀-èdè ń fẹ́ nìyí; a polongo pé àwọn tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn tinútinú fún ìjọba òdodo rẹ̀ tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso nísinsìnyí yóò rí àlàáfíà, ìyè, ìtúsílẹ̀ tí yóò wà títí láé àti ayọ̀ aláìlópin gbà gẹ́gẹ́ bí ìbùkún.” Láwọn àkókò ìdíbàjẹ́ wọ̀nyí, nígbà tíjọba táwọn èèyàn gbé kalẹ̀, pàápàá jù lọ àwọn tó wà ní àwọn ibi tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀, ń kùnà láti yanjú àwọn ìṣòro ayé tí ẹ̀tẹ́ sì ń bá wọn, ṣe ni ìpèníjà náà ń dún bíi kàkàkí, tí ohùn rẹ̀ sì ròkè ju ti ọdún 1922. Ẹ wo bó ti jẹ́ òótọ́ tó pé Ìjọba Ọlọ́run níkàáwọ́ Kristi aṣẹ́gun rẹ̀ ni ìrètí kan ṣoṣo tó wà fún aráyé!
20. (a) Kí làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lò láti mú àwọn ìhìn ìdájọ́ dún jáde bíi kàkàkí lọ́dún 1922 àti lẹ́yìn náà? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nígbà tí ìró kàkàkí kìíní dún?
20 Nípasẹ̀ àwọn ìpinnu, àwọn àṣàrò kúkúrú, àwọn ìwé pẹlẹbẹ, àwọn ìwé ńlá, àwọn ìwé ìròyìn, àtàwọn àwíyé, ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gbé ìkéde yìí àtàwọn mìíràn lẹ́yìn náà jáde bíi pé nípasẹ̀ kàkàkí ni. Nígbà tí kàkàkí kìíní dún, ṣe ló dà bíi pé ohun tó jọ yìnyín tí ń ya luni ya lu àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Àṣírí bí wọ́n ṣe jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tú borokoto. Nítorí bí wọ́n sì ṣe nípìn-ín nínú àwọn ogun tó jà ní ọ̀rúndún ogún, ó ti wá hàn pé wọ́n yẹ fún ìbínú amú-bí-iná ti Jèhófà. Ẹgbẹ́ Jòhánù, tí ogunlọ́gọ̀ ńlá wá ń ṣètìlẹ́yìn fún lẹ́yìn náà, ti ń bá a lọ láti mú kí ìró kàkàkí kìíní yìí máa dún gbọnmọ gbọnmọ, èyí sì ń jẹ́ ká rí ojú tí Jèhófà fi ń wo ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ó kà á sí ohun tó yẹ fún ìparun.—Ìṣípayá 7:9, 15.
Bí Òkè Ńlá Kan Tí Ń Jó
21. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì kejì fun kàkàkí rẹ̀?
21 “Áńgẹ́lì kejì sì fun kàkàkí rẹ̀. Ohun kan bí òkè ńlá títóbi tí iná ń jó ni a sì fi sọ̀kò sínú òkun. Ìdá mẹ́ta òkun sì di ẹ̀jẹ̀; ìdá mẹ́ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú òkun tí wọ́n ní ọkàn sì kú, ìdá mẹ́ta àwọn ọkọ̀ ojú omi sì fọ́ bàjẹ́.” (Ìṣípayá 8:8, 9) Kí ni ìran ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yìí ṣàpẹẹrẹ?
22, 23. (a) Ìpinnu wo ló dájú pé ó jáde nígbà tí kàkàkí kejì dún? (b) Kí ni “ìdá mẹ́ta òkun” dúró fún?
22 A lè lóye ìṣẹ̀lẹ̀ yìí dáadáa bá a bá fi wé ohun tó wáyé ní àpéjọ àgbègbè àwọn èèyàn Jèhófà tí wọ́n ṣe ní nílùú Los Angeles, ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ní August 18 sí 26, ọdún 1923. Àkòrí àkànṣe àsọyé ọ̀sán Saturday, látẹnu J. F. Rutherford, ni “Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́.” Àsọyé náà fi hàn kedere pé “àwọn àgùntàn” ni àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òdodo tí wọn yóò jogún ilẹ̀ ayé nínú Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà làwọn tó wà ní àpéjọ náà wá tẹ́wọ́ gba ìpinnu kan tó jẹ́ ká rí àgàbàgebè “ẹgbẹ́ àlùfáà apẹ̀yìndà àti ‘mọ́gàjí nínú agbo wọn,’ ìyẹn àwọn ẹni ayé tí wọ́n lówó lọ́wọ́ tí wọ́n sì tún lẹ́nu nínú ọ̀rọ̀ ìṣèlú.” Ó ké sí “ògìdìgbó àwọn èèyàn olùfẹ́ àlàáfíà àti ètò, tí wọ́n wà nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ní ẹlẹ́kajẹ̀ka . . . pé kí wọ́n dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ètò aláìṣòdodo ti ẹgbẹ́ àlùfáà tí Olúwa pè ní ‘Bábílónì’” kí wọ́n sì múra sílẹ̀ “láti gba àwọn ìbùkún ìjọba Ọlọ́run.”
23 Láìsí àní-àní, kàkàkí kejì tó dún ló mú ìpinnu yìí wá. Àwọn tó máa ṣègbọràn sí ìkéde náà tó bá yá máa ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn tí Aísáyà sọ ọ̀rọ̀ wọn báyìí pé: “Ṣùgbọ́n àwọn ẹni burúkú dà bí òkun tí a ń bì síwá bì sẹ́yìn, nígbà tí kò lè rọ̀ wọ̀ọ̀, èyí tí omi rẹ̀ ń sọ èpò òkun àti ẹrẹ̀ sókè.” (Aísáyà 57:20; 17:12, 13) A ti rí i báyìí pé “òkun” ṣàpẹẹrẹ ìran èèyàn oníwọ́nranwọ̀nran, aláraàbalẹ̀, ọlọ̀tẹ̀, tí wọ́n ń rúná sí rògbòdìyàn àti ìyípadà oníjàgídíjàgan. (Fi wé Ìṣípayá 13:1.) Àkókò náà ń bọ̀ tí “òkun” yẹn kì yóò sí mọ́. (Ìṣípayá 21:1) Ṣùgbọ́n ní báyìí ná, Jèhófà fi ìró kàkàkí yẹn kéde ìdájọ́ lòdì sí ìdá mẹ́ta rẹ̀, èyí tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ ara rẹ̀.
24. Kí ni nǹkan ràbàtà bí òkè ńlá tó ń jó tá a fi sọ̀kò sínú òkun ṣàpẹẹrẹ?
24 A ju ohun ràbàtà títóbi bí òkè ńlá kan tí iná ń jó sínú “òkun.” Nínú Bíbélì, àwọn òkè ńlá sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ àwọn ìjọba. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì fi Ìjọba Ọlọ́run wé òkè ńlá kan. (Dáníẹ́lì 2:35, 44) Bábílónì apanirun di “òkè ńlá jíjóná ráúráú.” (Jeremáyà 51:25) Ṣùgbọ́n ohun ràbàtà bí òkè ńlá tí Jòhánù rí yìí ṣì ń jó síbẹ̀. Jíjù tí wọ́n jù ú sínú òkun ṣàpẹẹrẹ bí ìṣòro àtiyan irú ìjọba tó tọ́ ṣe di àríyànjiyàn tó ń jà ràn-ìn láàárín aráyé ní ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní àti lẹ́yìn náà, pàápàá jù lọ láwọn ilẹ̀ tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Ítálì, Mussolini dá ètò ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ sílẹ̀. Àwọn ará ilẹ̀ Jámánì fọwọ́ sí ètò ìjọba Násì ti Hitler, àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn sì ń gbìyànjú oríṣiríṣi ètò ìjọba àjùmọ̀ní. Ìyípadà tegbò-tigaga wáyé lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, níbi tí àtúntò táwọn Bolshevik ṣe ti mú kí wọ́n gbé ìjọba Kọ́múníìsì àkọ́kọ́ kalẹ̀, èyí sì wá mú kó di pé agbára bọ́ lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ìsìn tí wọn ò sì lẹ́nu mọ́ láwọn ibi tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ ibi odi agbára wọn.
25. Báwo ni àríyànjiyàn lórí irú ètò ìjọba tó tọ́ ṣe ń bá a lọ láti dá wàhálà sílẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì?
25 Ogun Àgbáyé Kejì fòpin sí ètò ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ àti ìjọba Násì, síbẹ̀ àwọn èèyàn ṣì ń ba ara wọn jiyàn lórí irú ìjọba tó tọ́. Látàrí èyí, ìdàrúdàpọ̀ ṣì ń bá a lọ láàárín aráyé, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n gbé oríṣiríṣi ìjọba tó máa ṣàtúntò tipátipá kalẹ̀. Fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ọdún 1945, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ti ṣètò ìjọba oníjàgídíjàgan, lára wọn ni Ṣáínà, Vietnam, Cuba, àti Nicaragua. Wọ́n dán ìjọba ológun abàṣẹwàá wò lórílẹ̀-èdè Gíríìsì, ṣùgbọ́n ó kùnà. Nígbà tí wọ́n gbìyànjú irú ètò ìjọba Kọ́múníìsì kan lórílẹ̀-èdè Kampuchea (ìyẹn Cambodia), ó ju ọgọ́rùn-ún ọ̀kẹ́ èèyàn lọ tó kú látàrí wàhálà tó tẹ̀yìn ẹ̀ wá.
26. Báwo ni “òkè ńlá títóbi tí iná ń jó” ṣe ń bá a lọ láti máa mú kí ìgbì ru nínú òkun aráyé?
26 “Òkè ńlá títóbi tí iná ń jó” yẹn ń bá a lọ láti mú kí ìgbì máa rú nínú òkun aráyé. Ìròyìn fi hàn pé rògbòdìyàn wà lórí irú ìjọba tí wọ́n fẹ́ ní ilẹ̀ Áfíríkà, ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ilẹ̀ Éṣíà, àti láwọn erékùṣù òkun Pàsífíìkì. Àwọn ilẹ̀ tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀ tàbí níbi táwọn míṣọ́nárì wọn ti di ajàfẹ́tọ̀ọ́ lọ̀pọ̀ rògbòdìyàn yìí ti ṣẹlẹ̀. Kódà, àwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ajàjàgbara ti Kọ́múníìsì tí wọ́n sì jọ ń ja ìjà ọ̀hún. Lákòókò tá à ń sọ yìí, àwọn ajíhìnrere àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó yàtọ̀ sí Kátólíìkì ti ṣakitiyan ní Amẹ́ríkà Àárín láti kojú àwọn Kọ́múníìsì tí wọ́n “forí ṣe fọrùn ṣe láti wá agbára rí ní gbogbo ọ̀nà.” Ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kan nínú àwọn ohun tó ń mi òkun aráyé jìgìjìgì yìí tó tíì mú kí ayé wà lálàáfíà àti àìséwu.—Fi wé Aísáyà 25:10-12; 1 Tẹsalóníkà 5:3.
27. (a) Báwo ni “ìdá mẹ́ta òkun” ṣe dà bí ẹ̀jẹ̀? (b) Báwo ni ‘ìdá mẹ́ta àwọn ẹ̀dá nínú òkun’ ṣe kú, báwo ni ó sì ṣe rí fún “ìdá mẹ́ta àwọn ọkọ̀”?
27 Ìrò kàkàkí kejì tó dún fi hàn pé ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wà lọ́rùn àwọn ọmọ aráyé, tí wọ́n lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn àti ìdàrúdàpọ̀ torí àtigbé ìjọba tó máa tẹ́ aráyé lọ́rùn kalẹ̀, dípò kí wọ́n juwọ́ sílẹ̀ fún Ìjọba Ọlọ́run. “Ìdá mẹ́ta òkun,” ní pàtàkì jù lọ, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti dà bí ẹ̀jẹ̀. Gbogbo àwọn ohun alààyè inú ẹ̀ ti kú lójú Ọlọ́run. Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn àjọ tó wà nídìí àwọn àtúntò yẹn, tí wọ́n lé téńté bí ọkọ̀ sójú ìdá mẹ́ta agbami òkun yẹn, tí ò ní rì nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Inú wa mà dùn o, pé ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn ẹni bí àgùntàn ń ṣègbọràn báyìí sí ìkìlọ̀ náà tó ń dún bí ìró kàkàkí. Ìró kàkàkí náà ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n jáde kúrò láàárín àwọn tí wọ́n ṣì ń ri ara wọn bọ inú ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tí wọ́n sì lẹ́jẹ̀ lọ́rùn nínú òkun yẹn!
Ìràwọ̀ Kan Jábọ́ Láti Ọ̀run
28. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì kẹta fun kàkàkí tirẹ̀?
28 “Áńgẹ́lì kẹta sì fun kàkàkí rẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá tí ń jó bí fìtílà sì jábọ́ láti ọ̀run, ó sì jábọ́ sórí ìdá mẹ́ta àwọn odò àti sórí àwọn ìsun omi. A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ní Iwọ. Ìdá mẹ́ta àwọn omi sì di iwọ, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ènìyàn sì kú láti ọwọ́ àwọn omi náà, nítorí a ti sọ ìwọ̀nyí di kíkorò.” (Ìṣípayá 8:10, 11) Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn apá mìíràn nínú Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti rí bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe kan ọjọ́ Olúwa.
29. Kí ni àpẹẹrẹ “ìràwọ̀ ńlá tí ń jó bí fìtílà” dúró fún, kí sì nìdí?
29 Ṣáájú, nínú àwọn iṣẹ́ tí Jésù rán sáwọn ìjọ méje, a kà nípa bí ìràwọ̀ ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ, a rí i pé àwọn ìràwọ̀ méje náà ṣàpẹẹrẹ àwọn alàgbà nínú àwọn ìjọ.b (Ìṣípayá 1:20) Tá a bá fojú tẹ̀mí wò ó lọ́nà àpẹẹrẹ, “àwọn ìràwọ̀” tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹni àmì òróró yòókù, ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé lọ́run látìgbà tá a ti fi èdìdì dì wọ́n pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì ogún wọn tọ̀run. (Éfésù 2:6, 7) Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé àwọn kan látinú irú àwọn ẹni bí ìràwọ̀ bẹ́ẹ̀ máa di apẹ̀yìndà, olùdá-ìyapa-sílẹ̀, wọn sì máa ṣi agbo lọ́nà. (Ìṣe 20:29, 30) Irú àìṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ yóò yọrí sí ìpẹ̀yìndà ńlá, àwọn alàgbà tí wọ́n ṣubú wọ̀nyẹn á sì wá para pọ̀ di ọkùnrin àìlófin kan tó máa gbé ara rẹ̀ ga débi táá fi sọ ara ẹ̀ di ọlọ́run láàárín aráyé. (2 Tẹsalóníkà 2:3, 4) Àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa rẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ nígbà táwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sọ́ràn aráyé. Àbí ẹ ò rí i pé ó bá a mu gẹ́ẹ́, pé àwọn wọ̀nyí ni àpẹẹrẹ “ìràwọ̀ ńlá tí ń jó bí fìtílà” dúró fún.
30. (a) Nígbà tí Aísáyà sọ pé ọba Bábílónì á ṣubú látọ̀run, kí ló ní lọ́kàn? (b) Kí ni ìṣubú láti ọ̀run lè tọ́ka sí?
30 Ìràwọ̀ yìí gan-an ni Jòhánù rí tó já bọ́ látọ̀run. Lọ́nà wo? Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọba ìgbà àtijọ́ kan á ràn wá lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀. Nígbà tí wòlíì Aísáyà ń bá ọba Bábílónì sọ̀rọ̀, ó wí pé: “Wo bí o ti já bọ́ láti ọ̀run, ìwọ ẹni tí ń tàn, ọmọ ọ̀yẹ̀! Wo bí a ti ké ọ lulẹ̀, ìwọ tí ń sọ àwọn orílẹ̀-èdè di aláìlágbára!” (Aísáyà 14:12) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí nímùúṣẹ nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kírúsì bi Bábílónì ṣubú, tí ọba rẹ̀ sì ré bọ́ lójijì pẹ̀lú ìtìjú látorí ipò tó wà gẹ́gẹ́ bí alákòóso ayé. A lè rí i báyìí pé ìṣubú látọ̀run lè tọ́ka sí ìgbà tí ipò gíga kan bá bọ́ lọ́wọ́ èèyàn tónítọ̀hún sì dẹni ìtìjú tó tẹ́ pátápátá.
31. (a) Nígbà wo ni àwùjọ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣubú láti ipò ti “ọ̀run?” (b) Báwo ni omi táwọn àlùfáà gbé kalẹ̀ ṣe yí padà di “iwọ,” kí nìyẹn sì fà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀?
31 Nígbà tí ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pẹ̀yìn dà kúrò nínú ìsìn Kristẹni tòótọ́, wọ́n ṣubú láti ipò gíga fíofío ti “ọ̀run” tí Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe nínú Éfésù 2:6, 7. Kàkà kí wọ́n fáwọn èèyàn ní omi òtítọ́ títunilára mu, wọ́n gbé “iwọ” kalẹ̀, ìyẹn àwọn irọ́ kíkorò bí ẹ̀kọ́ ọ̀run àpáàdì, pọ́gátórì, Mẹ́talọ́kan, àti àyànmọ́; bákan náà, wọ́n ti kó àwọn orílẹ̀-èdè lọ sógun, nípa kíkùnà láti mú kí wọ́n di ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó níwà ọmọlúwàbí. Kí ló tẹ̀yìn ẹ̀ wá? Wọ́n ń fún àwọn tó gba ẹ̀kọ́ èké wọn gbọ́ ní májèlé tẹ̀mí jẹ. Ọ̀ràn wọn jọ tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ nígbà ayé Jeremáyà, àwọn ẹni tí Jèhófà wí fún pé: “Kíyè sí i, èmi yóò mú, èyíinì ni, àwọn èèyàn yìí, jẹ iwọ, dájúdájú, èmi yóò sì mú wọn mu omi onímájèlé. Nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerúsálẹ́mù ni ìpẹ̀yìndà ti jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀.”—Jeremáyà 9:15; 23:15.
32. Nígbà wo ni ìṣubú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kúrò ní ọ̀run tẹ̀mí hàn kedere, kí ló sì fi í hàn?
32 Ọdún 1919 ló hàn gbangba pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti ṣubú látọ̀run tẹ̀mí nígbà tí Jésù yan ìwọ̀nba kéréje ìyókù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sórí gbogbo ohun tó jẹ́ mọ́ ọ̀ràn Ìjọba náà, dípò ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. (Mátíù 24:45-47) Àwọn Kristẹni yìí sì fi ìṣubú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì hàn kedere láti 1922 nígbà tí wọ́n ń polongo lákọ̀tun nípa títú àṣírí ibi táwọn àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti kùnà láìfi ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ.
33. Báwo làwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe tú àwùjọ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó ní àpéjọ àgbègbè ọdún 1924 tí wọ́n ṣe nílùú Columbus, ní ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà?
33 Èyí tó ta yọ nínú pípòkìkí ìṣubú yìí ni ìpolongo táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ní àpéjọ kan tí ìwé ìròyìn The Golden Age pè ní “àpéjọ àgbègbè gíga jù lọ táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tíì ṣe rí.” Ìlú Columbus ní ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ti ṣe àpéjọ yìí ní July 20 sí 27, ọdún 1924. Kò síyè méjì pé áńgẹ́lì tó fun kàkàkí kẹta ń darí wọn, torí wọ́n fọwọ́ sí ìpinnu lílágbára kan níbẹ̀ wọ́n sì pín àádọ́ta mílíọ̀nù ẹ̀dà ìpinnu náà kiri nígbà tí wọ́n sọ ọ́ di ìwé àṣàrò kúkúrú. Wọ́n tẹ̀ ẹ́ jáde wọ́n sì pe àkọlé rẹ̀ ní Ecclesiastics Indicted (Ẹ̀sùn Tó Wà Lọ́rùn Ẹgbẹ́ Àwọn Àlùfáà). Ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ kan gbé àríyànjiyàn náà kalẹ̀, ó sọ pé: “Irú-Ọmọ Ìlérí Ní Ìdojúùjà Kọ Irú-Ọmọ Ejò.” Ẹ̀sùn náà tú ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó ní gbogbo ọ̀nà, irú bí wọ́n ṣe ń fi ara wọn jẹ oyè ìsìn kàǹkà-kàǹkà, bí wọ́n ṣe ń fàwọn oníṣòwò tó rọ́wọ́ mú àtàwọn ògbóǹtarìgì olóṣèlú ṣe àwọn ògúnná gbòǹgbò nínú agbo wọn, bí wọ́n ṣe ń fẹ́ láti máa fẹlá níwájú àwọn èèyàn, àti kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Mèsáyà fáwọn èèyàn. Ó tẹnu mọ́ ọn pé olúkúlùkù Kristẹni olùṣèyàsímímọ́ ni Ọlọ́run fún níṣẹ́ láti máa pòkìkí “ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa; láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.”—Aísáyà 61:2.
34, 35. (a) Látìgbà tí áńgẹ́lì kẹta ti bẹ̀rẹ̀ sí í fun kàkàkí rẹ̀, kí ló ṣẹlẹ̀ sí àṣẹ àti agbára àwùjọ àwọn àlùfáà? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwùjọ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lọ́jọ́ iwájú?
34 Láti ìgbà tí áńgẹ́lì kẹta ti bẹ̀rẹ̀ sí í fun kàkàkí rẹ̀ lagbára ti ń bọ́ lọ́wọ́ àwọn àlùfáà, wọn ò sì lè fi bẹ́ẹ̀ jẹ gàba láàárín aráyé mọ́. Ó burú fún wọn débi pé, lóde òní yìí, ìwọ̀nba kéréje nínú wọn ló ṣì ń rí agbára tí wọ́n fi sọ ara wọn di ọlọ́run lò, bẹ́ẹ̀ sì rèé wọ́n nírú agbára bẹ́ẹ̀ láwọn ọ̀rúndún tó kọjá. Nítorí ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá mọ̀ pé májèlé tẹ̀mí, tàbí “iwọ” ni ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ táwọn ẹgbẹ́ àlùfáà fi ń kọ́ni. Síwájú sí i, láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní àríwá ilẹ̀ Yúróòpù, agbára ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán lọ́wọ́ àwọn àlùfáà, nígbà tó jẹ́ pé ní àwọn ilẹ̀ kan ìjọba ká wọn lọ́wọ́ kò gan-an. Láwọn apá ibi tí ẹ̀sìn Kátólíìkì pọ̀ sí nílẹ̀ Yúróòpù àti nílẹ̀ Amẹ́ríkà, orúkọ ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ti bà jẹ́ nítorí mọ́namọ̀na tí wọ́n ń ṣe nínú ọ̀ràn owó, ìṣèlú, àti nítorí ìwà pálapàla wọn. Láti ìsinsìnyí lọ, ṣe ni wọ́n á kàn máa tẹ́ sí i torí pé àgbákò tó máa bá gbogbo àwọn onísìn èké yòókù láìpẹ́ máa kan àwọn náà.—Ìṣípayá 18:21; 19:2.
35 Ìyọnu tí Jèhófà ń mú wá sórí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kò tíì tán o. Ìwọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí kàkàkí kẹrin dún.
Òkùnkùn!
36. Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí áńgẹ́lì kẹrin fun kàkàkí rẹ̀?
36 “Áńgẹ́lì kẹrin sì fun kàkàkí rẹ̀. A sì fi agbára lu ìdá mẹ́ta oòrùn àti ìdá mẹ́ta òṣùpá àti ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀, kí ìdá mẹ́ta wọn bàa lè ṣókùnkùn, kí ọ̀sán má sì ní ìmọ́lẹ̀ títàn fún ìdá mẹ́ta rẹ̀, àti òru bákan náà.” (Ìṣípayá 8:12) Òkùnkùn gidi ni ìyọnu kẹsàn-án tó wá sórí ilẹ̀ Íjíbítì. (Ẹ́kísódù 10:21-29) Ṣùgbọ́n, kí ni òkùnkùn ìṣàpẹẹrẹ yìí tó mú ìyọnu wá sórí àwọn èèyàn?
37. Báwo ni àpọ́sítélì Pétérù àti Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe ipò tẹ̀mí àwọn tí ń bẹ lẹ́yìn òde ìjọ Kristẹni?
37 Àpọ́sítélì Pétérù sọ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé inú òkùnkùn tẹ̀mí ni wọ́n wà, kí wọ́n tó di Kristẹni. (1 Pétérù 2:9) Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú lo ọ̀rọ̀ náà “òkùnkùn” láti ṣàpèjúwe ipò táwọn tó wà lẹ́yìn òde ìjọ Kristẹni wà. (Éfésù 5:8; 6:12; Kólósè 1:13; 1 Tẹsalóníkà 5:4, 5) Ṣùgbọ́n àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ńkọ́, ìyẹn àwọn tí wọ́n sọ pé àwọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tí wọ́n sì sọ pé àwọ́n gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà àwọn?
38. Òtítọ́ wo ni áńgẹ́lì kẹrin fi kàkàkí ẹ̀ fun jáde nípa “ìmọ́lẹ̀” àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?
38 Jésù sọ pé èso àwọn Kristẹni tòótọ́ la ó fi mọ̀ wọ́n àti pé ọ̀pọ̀ àwọn tó sọ pé ọmọlẹ́yìn òun làwọn ló máa jẹ́ àwọn “oníṣẹ́ ìwà àìlófin.” (Mátíù 7:15-23) Kò sẹ́nì kankan tó lè máa wo àwọn èso ìdá mẹ́ta ayé tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì gba inú ẹ̀ kan yìí tí ò ní í gbà pé inú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí ló ti ń tá ràrà. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Ẹ̀bi tiẹ̀ ló pọ̀ jù lọ, torí ó sọ pé Kristẹni lòun. Torí náà, kò sí ṣíṣe kò sí àìṣe, áńgẹ́lì kẹrin ní láti fun kàkàkí ẹ̀ kó lè fi gbé òtítọ́ náà jáde pé òkùnkùn biribiri ni “ìmọ́lẹ̀” àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ìmọ́lẹ̀ Bábílónì làwọn orísun “ìmọ́lẹ̀” wọn, kì í ṣe ti Kristẹni.—Máàkù 13:22, 23; 2 Tímótì 4:3, 4.
39. (a) Báwo ni ìpinnu táwọn èèyàn Jèhófà tẹ́wọ́ gbà ní àpéjọ àgbègbè ní 1925 ṣe ṣàpèjúwe ìmọ́lẹ̀ èké àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì? (b) Ìtúfó síwájú sí i wo ni a ṣe ní 1955?
39 Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí áńgẹ́lì yẹn pòkìkí láti ọ̀run, ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run pé jọ sí àpéjọ àgbègbè kan nílùú Indianapolis, ní ìpínlẹ̀ Indiana, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ní August 29, ọdún 1925, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìpinnu kan tó sojú abẹ níkòó, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ìhìn Ìrètí,” èyí tí wọ́n tẹ̀ jáde lẹ́yìn náà. Wọ́n pín nǹkan bí àádọ́ta [50] mílíọ̀nù ẹ̀dà rẹ̀ kiri láwọn èdè mélòó kan. Ó sọ̀rọ̀ nípa ìmọ́lẹ̀ èké tí àpapọ̀ àwọn oníṣòwò elérè àjẹpajúdé, àwọn aṣíwájú òṣèlú, àti àwùjọ àwọn àlùfáà ìsìn ń tàn, èyí tó fi jẹ́ pé “àwọn ènìyàn ti ṣubú sínú òkùnkùn.” Ó sì fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ni ìrètí tòótọ́ fún rírí “ìbùkún àlàáfíà, aásìkí, ìlera, ìyè, òmìnira àti ayọ̀ ayérayé” gbà. Ó gba ìgboyà kí agbo kékeré àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró náà tó lè polongo irú àwọn ìkéde bẹ́ẹ̀ lòdì sí ètò ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó tóbi gbàràmù gbaramu. Ṣùgbọ́n láti bí ọdún mélòó kan lẹ́yìn ọdún 1920, wọ́n ti ń bá ìkéde náà bọ̀ láìdáwọ́ dúró títí di ìsinsìnyí. Kódà lákòókò tí kò tíì pẹ́ tóyẹn, ìyẹn lọ́dún 1955, ìwé pẹlẹbẹ kan táwọn èèyàn Ọlọ́run pín káàkiri àgbáyé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè tú ẹgbẹ́ àlùfáà fó síwájú sí i. Àkòrí ìwé náà ni Kristẹndọm Tabi Jijẹ-Kristian—Ewo Ni “Imọlẹ Aiye”? Lónìí, àgàbàgebè àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti wá hàn gbangba débi pé ọ̀pọ̀ nínú ayé ti ń rí i fúnra wọn. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn Jèhófà ò tíì dẹ́kun títú u fó nípa jíjẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó jẹ́ gan-an: ìyẹn ìjọba òkùnkùn.
Idì Tí Ń Fò
40. Kí ni àwọn ìró kàkàkí mẹ́rin náà fi hàn pé ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì jẹ́?
40 Lóòótọ́, àwọn ìró kàkàkí mẹ́rin àkọ́kọ́ wọ̀nyí jẹ́ ká mọ ipò ahoro tó sì ń ṣekú pani tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wà. Ó hàn gbangba pé apá tó jẹ́ ti ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lórí “ilẹ̀ ayé” yẹ fún ìdájọ́ Jèhófà. A ti rí i kedere pé àwọn ìjọba oníyìípadà jàgídíjàgan tó ń rú yọ láwọn ilẹ̀ rẹ̀ àti ní ibòmíràn léwu nípa tẹ̀mí. Àṣírí bí ẹgbẹ́ àlùfáà rẹ̀ ṣe ṣubú ti tú pátápátá, ó sì ti ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn láti rí i kedere pé inú òkùnkùn tẹ̀mí ló wà. Ní tòótọ́, ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló jẹ̀bi jù lọ nínú ètò àwọn nǹkan Sátánì.
41. Nígbà táwọn ìró kàkàkí náà dáwọ́ dúró díẹ̀, kí ni Jòhánù rí tó sì gbọ́?
41 Kí ló tún kù ńbẹ̀ láti ṣí payá? Ká tó rí ìdáhùn sí ìbéèrè yí, àwọn ìró kàkàkí dáwọ́ dúró díẹ̀ ná. Ohun tí Jòhánù lóun rí nísinsìnyí rèé: “Mo sì rí, mo sì gbọ́ tí idì kan tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run wí pẹ̀lú ohùn rara pé: ‘Ègbé, ègbé, ègbé ni fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé nítorí ìyókù ìró ìpè kàkàkí àwọn áńgẹ́lì mẹ́ta tí wọ́n máa tó fun kàkàkí wọn!’”—Ìṣípayá 8:13.
42. Kí ni idì tí ń fò náà dúró fún, kí ló sì ń polongo?
42 Idì a máa fò lókèlókè lójú sánmà, tó fi jẹ́ pé àwọn èèyàn púpọ̀ lórí ilẹ̀ lè rí i. Ojú ẹ̀ ríran ketekete ó sì lè rí nǹkan tó bá wà lọ́nà jíjìn. (Jóòbù 39:29) A fi ẹyẹ idì tí ń fò ṣàpẹẹrẹ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ kérúbù, tí wọ́n yí ìtẹ́ Ọlọ́run ká. (Ìṣípayá 4:6, 7) Bóyá kérúbù yẹn ni o, tàbí ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì tójú ẹ̀ lè rína jìnnà mìíràn ni o, ó ń fi ohùn rara polongo ìkéde alágbára kan pé: “Ègbé, ègbé, ègbé”! Káwọn tó ń gbé ilẹ̀ ayé kíyè sí i, bí wọ́n bá ti ń gbọ́ àwọn ìró kàkàkí mẹ́ta tó kù wọ̀nyẹn, ègbé kọ̀ọ̀kan ń bá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn rìn ni.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìṣípayá 7:16 fi ìyàtọ̀ hàn pé ti ogunlọ́gọ̀ ńlá náà máa yàtọ̀, wọn ò ní rí ooru tó ń jó nǹkan gbẹ, èyí tí í ṣe ìbínú Jèhófà.
b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìràwọ̀ méje náà tó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Jésù dúró fún àwọn alábòójútó ẹni àmì òróró nínú ìjọ Kristẹni, àwọn alàgbà inú èyí tó pọ̀ jù lọ lára iye tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] ìjọ tó wà láyé báyìí jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá náà. (Ìṣípayá 1:16; 7:9) Ipò wo ni wọ́n wà? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀mí mímọ́ la fi yàn wọ́n sípò nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró, a lè sọ pé àwọn wọ̀nyí wà ní ọwọ́ ọ̀tun Jésù níbi tó ti ń ṣàkóso wọn, nítorí olùṣọ́ àgùntàn tó ń sìn lábẹ́ rẹ̀ làwọn náà. (Aísáyà 61:5, 6; Ìṣe 20:28) Wọ́n ń ṣètìlẹ́yìn fún “àwọn ìràwọ̀ méje” ní ti pé wọ́n ń sìn níbi táwọn arákùnrin ẹni àmì òróró tó kúnjú ìwọ̀n ò bá ti sí.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 139]
Iwọ Ni Omi Ìsìn Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì
Ìgbàgbọ́ àti Àṣà Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Ohun Tí Bíbélì Wí Gan-an
Orúkọ Ọlọ́run kò ṣe pàtàkì: “Lílo Jésù gbàdúrà pé kí a sọ orúkọ
orúkọ èyíkéyìí kan pàtó fún Ọlọ́run di mímọ́. Pétérù wí pé:
Ọlọ́run tó wà . . . kò bójú mu “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì ń ké
rárá àti rárá fáwọn Ṣọ́ọ̀ṣì pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà
Kristẹni ní gbogbo àgbáyé.” là.” (Ìṣe 2:21; Jóẹ́lì 2:32;
(Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú nínú ìtumọ̀ Bíbélì Ìṣípayá 4:11; 15:3; 19:6)
Revised Standard Version)
Mẹ́talọ́kan ni Ọlọ́run: “Baba jẹ́ Bíbélì sọ pé Jèhófà tóbi ju
Ọlọ́run, Ọmọ jẹ́ Ọlọ́run, Ẹ̀mí Jésù lọ àti pé òun ni Ọlọ́run
Mímọ́ sì jẹ́ Ọlọ́run, síbẹ̀ Ọlọ́run àti orí fún Kristi.
mẹ́ta kọ́ ló wà bí kò ṣe (Jòhánù 14:28; 20:17;
Ọlọ́run kan.” (Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ 1 Kọ́ríńtì 11:3) Ipá ìṣiṣẹ́
The Catholic Encyclopedia, Ọlọ́run ni ẹ̀mí mímọ́ jẹ́.
ìtẹ̀jáde ti 1912) (Mátíù 3:11; Lúùkù 1:41;
Ọkàn ẹ̀dá èèyàn jẹ́ aláìleèkú: Èèyàn jẹ́ ọkàn. Nígbà ikú, ọkàn
“Nígbà tí èèyàn bá kú ọkàn àti ò lè ronú mọ́ bẹ́ẹ̀ ni kò lè mòye
ara rẹ̀ ni a pín níyà. Ara ohunkóhun mọ́, yóò padà sí
rẹ̀ . . . máa jẹrà . . . Ṣùgbọ́n, erùpẹ̀ láti inú èyí tí a ti
ọkàn ẹ̀dá èèyàn kì í kú.” dá a. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; 3:19;
(Ìtẹ̀jáde Roman Kátólíìkì kan Sáàmù 146:3, 4;
tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní What Oníwàásù 3:19, 20; 9:5, 10;
Happens After Death) Ìsíkíẹ́lì 18:4, 20)
Àwọn èèyàn burúkú máa ń jìyà Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, kì í ṣe
lẹ́yìn ikú ní hẹ́ẹ̀lì: “Gẹ́gẹ́ bó ìdálóró ayérayé. (Róòmù 6:23)
ṣe wà nínú ìgbàgbọ́ Kristẹni Àwọn òkú ń sinmi láìmọ
látọjọ́ pípẹ́, hẹ́ẹ̀lì jẹ́ ibi ohunkóhun nínú hẹ́ẹ̀lì
làásìgbò àti ìrora tí kì í (Hédíìsì, Ṣìọ́ọ̀lù), wọ́n
dópin.” (Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ ń dúró de àjíǹde.
The World Book Encyclopedia, (Sáàmù 89:48; Jòhánù 5:28, 29;
ìtẹ̀jáde ti 1987) 11:24, 25; Ìṣípayá 20:13, 14)
“Orúkọ oyè náà Midiatrix Alárinà kan ṣoṣo láàárín
[alárinà obìnrin] la fi ń pe Ọlọ́run àti èèyàn ni Jésù.
Ìyálóde Wa.” (Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ (Jòhánù 14:6; 1 Tímótì 2:5;
New Catholic Encyclopedia, Hébérù 9:15; 12:24)
ìtẹ̀jáde 1967)
Àwọn ọmọ ọwọ́ la ní láti batisí: Ìrìbọmi wà fún àwọn tá a ti sọ
“Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀ṣì ti ń pín di ọmọ ẹ̀yìn tá a sì ti kọ́ láti
Sákírámẹ́ǹtì Ìbatisí fáwọn ọmọ ọwọ́. máa ṣègbọràn sáwọn àṣẹ Jésù.
Kì í ṣe kìkì pé a ka àṣà yìí sí Láti kúnjú ìwọ̀n láti ṣe
èyí tó bófin mu nìkan ni, ṣùgbọ́n a ìrìbọmi, èèyàn gbọ́dọ̀ lóye Ọ̀rọ̀
tún fi kọ́ni pé ó pọn dandan fún Ọlọ́run kó sì lo ìgbàgbọ́.
ìgbàlà.” (Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ (Mátíù 28:19, 20;
New Catholic Encyclopedia, Lúùkù 3:21-23; Ìṣe 8:35, 36)
ìtẹ̀jáde 1967)
Ṣọ́ọ̀ṣì tó pọ̀ jù ni wọ́n pín sí ẹgbẹ́ Gbogbo àwọn Kristẹni ọ̀rúndún
ọmọ ìjọ àti ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà, tí kìíní ló jẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n sì ń
wọ́n ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ fáwọn ọmọ ìjọ. kópa nínú wíwàásù ìhìn rere.
Wọ́n sábà máa ń fún ẹgbẹ́ àlùfáà (Ìṣe 2:17, 18; Róòmù 10:10-13;
lówó oṣù fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, wọ́n sì 16:1) Kristẹni kan ní láti
máa ń fi oyè bí “Ẹni Ọ̀wọ̀,” “Fadá,” ‘fúnni lọ́fẹ̀ẹ́,’ kò gbọ́dọ̀ máa
“Ẹni Ọ̀wọ̀ Jù Lọ” dá wọn lọ́lá. retí owó oṣù kankan.
(Mátíù 10:7, 8) Jésù ka lílo
àwọn orúkọ oyè ìsìn léèwọ̀.
Àwọn ère, àwòrán ìjọsìn, àtàwọn Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ sá fún
àgbélébùú ni wọ́n máa ń lò nínú oríṣiríṣi ìbọ̀rìṣà gbogbo,
ìjọsìn: “Àwọn ère . . . Kristi, títí kan àwọn ìjọsìn míì bẹ́ẹ̀.
ti Wúńdíá Ìyá Ọlọ́run, àti tàwọn (Ẹ́kísódù 20:4, 5;
ẹni mímọ́ mìíràn, la ní láti . . . 1 Kọ́ríńtì 10:14;
fi sínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ká sì máa fún 1 Jòhánù 5:21) Kì í ṣe ohun tí
wọn ní ọ̀wọ̀ àti ọlá tó yẹ wọ́n.” wọ́n ń fojú rí ni wọ́n fi ń jọ́sìn
(Ìpolongo Ìgbìmọ̀ Trent Ọlọ́run bí kò ṣe ní ẹ̀mí àti ní
[1545 sí 1563]) òtítọ́. (Jòhánù 4:23, 24;
Àwọn olùre ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n kọ́ pé Jésù wàásù Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́
ìṣèlú ayé ni Ọlọ́run á lò láti mú bí ìrètí tí aráyé ní, kò sọ pé
àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Olóògbé ètò ìṣèlú ni ìrètí ayé.
Kádínà Spellman sọ pé: “Kìkì ọ̀nà (Mátíù 4:23; 6:9, 10)
kan ṣoṣo ló wà sí àlàáfíà . . . , Jésù kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìṣèlú.
ọ̀nà márosẹ̀ ti ìjọba tiwa-n-tiwa.” (Jòhánù 6:14, 15) Ìjọba ẹ̀ kì
Àwọn kókó inú ìròyìn ń fi bí ìsìn í ṣe apá kan ayé yìí; fún ìdí
ti ń lọ́wọ́ sí ìṣèlú ayé hàn (kódà yìí, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ò ní
nínú àwọn ìdìtẹ̀ sí ìjọba) àti láti jẹ́ apá kan ayé.
ìtìlẹyìn rẹ̀ fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn (Jòhánù 18:36; 17:16) Jákọ́bù
Orílẹ̀-Èdè gẹ́gẹ́ bí “ìrètí ìkẹyìn kìlọ̀ lòdì sí bíbá ayé dọ́rẹ̀ẹ́.
fún ìrẹ́pọ̀ àti àlàáfíà.” (Jákọ́bù 4:4)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 132]
Ṣíṣí èdìdì méje náà ló ṣáájú fífun àwọn kàkàkí méje
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 140]
“Ìpèníjà Fáwọn Aṣáájú Ayé” (1922)
Ìpinnu yìí ṣèrànwọ́ láti polongo ìyọnu látọ̀dọ̀ Jèhófà lòdì sí “ilẹ̀ ayé”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 140]
“Ìkìlọ̀ fún Gbogbo Kristẹni” (1923)
Ìpinnu yìí la fi pòkìkí ìdájọ́ mímúná Jèhófà lórí “ìdá mẹ́ta òkun”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 141]
“Ẹ̀sùn Tó Wà Lọ́rùn Ẹgbẹ́ Àwọn Àlùfáà” (1924)
Pínpín tá a pín ìwé àṣàrò kúkúrú yìí délé dóko jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé “ìràwọ̀” tó jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti já bọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 141]
“Ìhìn Ìrètí” (1925)
Ìpinnu tó ṣe tààràtà yìí la fi tú àṣírí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pé ohun tí wọ́n pè ní orísun ìmọ́lẹ̀ wọn jẹ́ orísun òkùnkùn
-