ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ègbé Àkọ́kọ́—Àwọn Eéṣú
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • Orí 22

      Ègbé Àkọ́kọ́—Àwọn Eéṣú

      1. Nígbà táwọn áńgẹ́lì bá ti fun kàkàkí wọn, àwọn wo ló ń polongo ìró rẹ̀, kí sì ni ìró kàkàkí karùn-ún kéde?

      ÁŃGẸ́LÌ karùn-ún ń múra sílẹ̀ láti fun kàkàkí rẹ̀. Kàkàkí mẹ́rin ló ti dún látọ̀run, ìyọnu mẹ́rin sì ti dà sórí ìdá mẹ́ta tí Jèhófà kà séyìí tó jẹ̀bi jù lọ nínú ayé, ìyẹn àwùjọ oníṣọ́ọ̀ṣì. Àṣírí ti tú pé inú àìsàn tó máa pa á ló wà. Báwọn áńgẹ́lì ṣe ń fọn kàkàkí wọn yìí, àwọn èèyàn ń polongo rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Nísinsìnyí kàkàkí áńgẹ́lì karùn-ún máa tó kéde ègbé àkọ́kọ́, tó jẹ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ju àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ ṣáájú pàápàá. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ìyọnu eéṣú tó ń ṣẹ̀rù bani. Àmọ́ ṣá, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táá ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ìyọnu ọ̀hún.

      2. Ìwé Bíbélì wo ló ṣàpèjúwe ìyọnu àwọn eéṣú kan tó jọ èyí tí Jòhánù rí, ipa wo ló sì ní lórí Ísírẹ́lì ìgbàanì?

      2 Ìwé Jóẹ́lì nínú Bíbélì, tí wọ́n kọ ní ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Kristẹni, ṣàpèjúwe ìyọnu oríṣiríṣi kòkòrò, tó fi mọ́ eéṣú, tó jọ èyí tí Jòhánù rí. (Jóẹ́lì 2:1-11, 25)a Ó máa kó ìrora tó pọ̀ bá Ísírẹ́lì tó ti di apẹ̀yìndà ṣùgbọ́n á tún mú káwọn Júù ronú pìwà dà lọ́kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n sì padà rí ojú rere Jèhófà. (Jóẹ́lì 2:6, 12-14) Nígbà tí àkókò yẹn bá tó, Jèhófà á tú ẹ̀mí rẹ̀ jáde “sára gbogbo onírúurú ẹran ara,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àmì abanilẹ́rù àtàwọn àmì àgbàyanu akódàágìrì-báni ló máa ṣáájú “kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà tó dé.”—Jóẹ́lì 2:11, 28-32.

      Ìyọnu Ọ̀rúndún Kìíní

      3, 4. (a) Ìgbà wo ni Jóẹ́lì orí kejì ní ìmúṣẹ kan, báwo ló sì ṣe ní ìmúṣẹ? (b) Báwo ni ìyọnu tó ń ya luni bí eéṣú ṣe wà ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, báwo ló sì ṣe pẹ́ tó tí wọ́n fi ń mú ìyọnu náà wá sórí àwọn èèyàn?

      3 Jóẹ́lì orí kejì ní ìmúṣẹ lọ́nà kan ní ọ̀rúndún kìíní. Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tá a tú ẹ̀mí mímọ́ jáde, tí ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àkọ́kọ́ tó sì fún wọn lágbára láti sọ àwọn “ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè. Látàrí èyí, ogunlọ́gọ̀ ńlá pé jọ. Àpọ́sítélì Pétérù bá àwọn òǹwòran tẹ́nu ń yà sọ̀rọ̀, ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Jóẹ́lì 2:28, 29 ó sì ṣàlàyé pé ìmúṣẹ rẹ̀ ni wọ́n ń rí yẹn. (Ìṣe 2:1-21) Ṣùgbọ́n kò sí àkọsílẹ̀ pé ìyọnu kòkòrò gidi dé bá ẹnì kankan láti fa ìnira fún wọn kó sì mú kí wọ́n ronú pìwà dà.

      4 Ǹjẹ́ ìyọnu kankan ṣẹlẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ lákòókò yẹn bí? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ó ṣẹlẹ̀ látàrí ìwàásù táwọn Kristẹni tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ fi òróró yàn ń ṣe láìdáwọ́dúró.b Nípasẹ̀ wọn, Jèhófà ń pe àwọn Júù tó bá máa fetí sílẹ̀ láti ronú pìwà dà kí wọ́n sì gbádùn àwọn ìbùkún rẹ̀. (Ìṣe 2:38-40; 3:19) Àwọn tí wọ́n gbọ́ràn nínú wọn rí ojú rere rẹ̀ dé àyè kan. Ṣùgbọ́n fáwọn tó fi gbígbọ́ ṣaláìgbọ́, ṣe làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní dà bí àwọn eéṣú tó ń ya lù wọ́n tó sì ń jẹ wọ́n run. Láti Jerúsálẹ́mù, wọ́n tàn ká gbogbo Jùdíà àti Samáríà. Láìpẹ́ wọ́n tàn débi gbogbo, bí wọ́n sì ṣe ń pòkìkí àjíǹde Jésù ní gbangba, tí wọ́n tún ń sọ ohun tí àjíǹde náà túmọ̀ sí, ṣe ni wọ́n ń dá àwọn Júù aláìgbàgbọ́ lóró. (Ìṣe 1:8; 4:18-20; 5:17-21, 28, 29, 40-42; 17:5, 6; 21:27-30) Wọ́n ń bá a nìṣó láti máa mú ìyọnu náà wá sórí àwọn èèyàn títí di “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù,” ìyẹn lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jèhófà mú káwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù kọ lu Jerúsálẹ́mù láti pa á run. Kìkì àwọn Kristẹni tó fi ìgbàgbọ́ ké pe orúkọ Jèhófà ló rí ìgbàlà.—Jóẹ́lì 2:32; Ìṣe 2:20, 21; Òwe 18:10.

      Ìyọnu Eéṣú Lóde Òní

      5. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ti ṣe ń ní ìmúṣẹ látọdún 1919 wá?

      5 Ó bọ́gbọ́n mu láti fojú sọ́nà pé kí àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ní ìmúṣẹ ìkẹyìn rẹ̀ ní àkókò òpin. Òótọ́ pọ́ńbélé sì nìyẹn wá já sí! Ní àpéjọ àgbègbè àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílùú Cedar Point, ní ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ní September 1 sí 8, ọdún 1919, ẹ̀mí Jèhófà tó tú jáde lọ́nà tó kàmàmà mú káwọn èèyàn Jèhófà di alákitiyan lẹ́nu ṣíṣètò iṣẹ́ ìwàásù tó gba ayé kan. Nínú gbogbo àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni, àwọn èèyàn Jèhófà nìkan ṣoṣo ló ń ṣe gbogbo ohun tó wà lágbára wọn láti máa kéde ìhìn rere yẹn káàkiri torí wọ́n mọ̀ dájú ṣáká pé Jèhófà ti gbé Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọ̀run. Bí wọ́n ṣe ń wàásù láìdẹwọ́ yẹn, gẹ́gẹ́ bí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ṣe ló dà bí ìyọnu adánilóró fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì apẹ̀yìndà.—Mátíù 24:3-8, 14; Ìṣe 1:8.

      6. (a) Kí ni Jòhánù rí nígbà tí áńgẹ́lì karùn-ún fun kàkàkí rẹ̀? (b) Ta ni “ìràwọ̀” yìí ṣàpẹẹrẹ, kí sì nìdí ẹ̀?

      6 Ìwé Ìṣípayá, tí Jòhánù kọ ní nǹkan bí ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù, tún ṣàpèjúwe ìyọnu yẹn. Kí ló wá fi kún àpèjúwe Jóẹ́lì o? Ẹ jẹ́ ká gbé àkọsílẹ̀ náà yẹ̀ wò gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ti ròyìn rẹ̀, pé: “Áńgẹ́lì karùn-ún sì fun kàkàkí rẹ̀. Mo sì rí ìràwọ̀ kan tí ó ti jábọ́ láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé, a sì fún un ní kọ́kọ́rọ́ kòtò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” (Ìṣípayá 9:1) “Ìràwọ̀” yìí yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú Ìṣípayá 8:10 tí Jòhánù rí bó ṣe ń já bọ̀. “Ìràwọ̀ kan tí ó ti jábọ́ láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé” ló rí báyìí àti pé ó ní iṣẹ́ kan tí ìràwọ̀ náà ní í ṣe nínú ọ̀ràn ilẹ̀ ayé yìí. Ṣé ẹni ẹ̀mí ni ẹni yìí àbí èèyàn ẹlẹ́ran ara? Ẹni tó ní “kọ́kọ́rọ́ kòtò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” yìí lọ́wọ́ ni Ìṣípayá wá sọ nígbà tó yá pé ó fi Sátánì sọ̀kò sínú “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” (Ìṣípayá 20:1-3) Torí ìdí èyí, ó ní láti jẹ́ ẹni ẹ̀mí alágbára ńlá. Nínú Ìṣípayá 9:11, Jòhánù sọ fún wa pé àwọn eéṣú yẹn ní “ọba kan . . . , áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” Níwọ̀n bó sì ti bọ́gbọ́n mu pé áńgẹ́lì tó mú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà dání ní láti jẹ́ áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjèèjì yìí ní láti máa tọ́ka sí ẹnì kan náà. Bákan náà, ìràwọ̀ náà ní láti ṣàpẹẹrẹ Ọba tí Jèhófà yàn sípò, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé, Jésù Kristi ni Ọba kan ṣoṣo tó jẹ́ áńgẹ́lì táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mọ̀ lọ́ba.—Kólósè 1:13; 1 Kọ́ríńtì 15:25.

      7. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì náà ṣí “kòtò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà”? (b) Kí ni “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà,” ta sì ló lo àkókò kúkúrú nínú rẹ̀?

      7 Ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Ó sì ṣí kòtò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, èéfín sì gòkè wá láti inú kòtò náà bí èéfín ìléru ńlá, oòrùn sì ṣókùnkùn, àti afẹ́fẹ́ pẹ̀lú, nípasẹ̀ èéfín kòtò náà. Àwọn eéṣú sì jáde wá sórí ilẹ̀ ayé láti inú èéfín náà; a sì fún wọn ní ọlá àṣẹ, irú ọlá àṣẹ kan náà tí àwọn àkekèé ilẹ̀ ayé ní.” (Ìṣípayá 9:2, 3) Bí Ìwé Mímọ́ ṣe máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,” ó jẹ́ ibi tẹ́nì kan ò ti lè ṣiṣẹ́ mọ́, ipò ikú pàápàá. (Fi wé Róòmù 10:7; Ìṣípayá 17:8; 20:1, 3.) Ẹgbẹ́ àwọn arákùnrin Jésù tí wọ́n kéré lo àkókò kúkúrú nínú irú “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,” níbi tá a ti lè sọ pé wọn ò ṣiṣẹ́ mọ́, ní òpin Ogun Àgbáyé Kìíní (ìyẹn lọ́dún 1918 sí ọdún 1919). Ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhófà tú ẹ̀mí rẹ̀ dà sórí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ronú pìwà dà lọ́dún 1919, wọ́n tú jáde láti dàyà kọ iṣẹ́ tó wà níwájú wọn.

      8. Báwo ló ṣe jẹ́ pé “èéfín” púpọ̀ làwọn eéṣú náà bá jáde nígbà tí áńgẹ́lì náà tú wọn sílẹ̀?

      8 Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe kíyè sí i, bí áńgẹ́lì náà ṣe tú àwọn eéṣú yẹn sílẹ̀, ṣe ni èéfín púpọ̀ bá wọn jáde, irú èyí tó dà bí “èéfín ìléru ńlá” kan.c Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn lọ́dún 1919. Gbogbo nǹkan ṣókùnkùn fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti fáráyé lápapọ̀. (Fi wé Jóẹ́lì 2:30, 31.) Ìtìjú ńlá gbáà ló jẹ́ fún ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì bí áńgẹ́lì náà ṣe tú àwọn eéṣú, ìyẹn ẹgbẹ́ Jòhánù sílẹ̀ torí pé wọ́n ti di rìkíṣí, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti dojú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run bolẹ̀ títí láé, tí wọ́n sì ti pa Ìjọba Ọlọ́run tì báyìí. Àmì pé èéfín kan ṣú dẹ̀dẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tàn ká orí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì apẹ̀yìndà bí Ọlọ́run ṣe fún agbo eéṣú yẹn ní àṣẹ látọ̀run tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lo àṣẹ náà láti pòkìkí àwọn ìkéde ìdájọ́ tó lágbára. “Oòrùn” àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ìyẹn ohun tó dà bí ìlàlóye tí wọ́n ní, ti wọ òkùnkùn, àwọn ìpolongo ìdájọ́ Ọlọ́run sì ti gba inú “afẹ́fẹ́” kan bó ṣe di pé ó hàn gbangba pé “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́” ayé yìí ni ọlọ́run àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì.—Éfésù 2:2; Jòhánù 12:31; 1 Jòhánù 5:19.

      Àwọn Eéṣú Yẹn Mà Ń Dáni Lóró O!

      9. Àṣẹ wo làwọn eéṣú yẹn ní láti máa tẹ̀ lé lójú ogun?

      9 Àṣẹ wo làwọn eéṣú yẹn ní láti máa tẹ̀ lé lójú ogun? Jòhánù ròyìn pé: “A sì sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe pa ewéko ilẹ̀ ayé kankan lára tàbí ohun títutùyọ̀yọ̀ èyíkéyìí tàbí igi èyíkéyìí, bí kò ṣe kìkì àwọn ènìyàn tí kò ní èdìdì Ọlọ́run ní iwájú orí wọn. A sì yọ̀ǹda fún àwọn eéṣú náà, láti má ṣe pa wọ́n, ṣùgbọ́n pé kí a mú àwọn wọ̀nyí joró fún oṣù márùn-ún, oró náà lára wọn sì dà bí oró àkekèé nígbà tí ó bá ta ènìyàn. Ní ọjọ́ wọnnì, àwọn ènìyàn náà yóò wá ikú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i lọ́nàkọnà, wọn yóò sì fẹ́ láti kú, ṣùgbọ́n ikú yóò máa sá fún wọn.”—Ìṣípayá 9:4-6.

      10. (a) Àwọn wo ní pàtàkì ni ìyọnu náà dé bá, ipa wo ló sì ní lórí wọn? (b) Irú ìdálóró wo ló fà fún wọn? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      10 Kíyè sí i pé kì í ṣàwọn èèyàn tàbí àwọn sàràkí sàràkí láàárín wọn, ìyẹn ‘ewéko àti àwọn igi ilẹ̀ ayé’ ni ìyọnu yìí kọ́kọ́ dé bá. (Fi wé Ìṣípayá 8:7.) Kìkì àwọn táwọn eéṣú náà ní láti pa lára ni àwọn tí kò ní èdìdì Ọlọ́run ní iwájú orí wọn, ìyẹn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n sọ pé a ti fi èdìdì di àwọn ṣùgbọ́n tí ohun tó wà lákọọ́lẹ̀ pé wọ́n ṣe fi wọ́n hàn ní elékèé. (Éfésù 1:13, 14) Ìdí nìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì làwọn eéṣú òde òní yẹn dojú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń dáni lóró tó ń tẹnu wọn jáde kọ. Àbí ẹ ò rí i báwọn ọkùnrin ajọra-ẹni-lójú yẹn á ṣe máa joró tó nígbà tí wọ́n ń gbọ́ táwọn èèyàn Ọlọ́run kéde ní gbangba pé kì í ṣe pé wọ́n kùnà láti ṣamọ̀nà àwọn agbo wọn lọ sí ọ̀run nìkan ni ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn ò ní í débẹ̀!d Lóòótọ́, àfi bí ‘afọ́jú tó ń fọ̀nà han afọ́jú’!—Mátíù 15:14.

      11. (a) Báwo ni àkókò táwọn eéṣú náà láṣẹ láti dá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run lóró ti gùn tó, kí sì nìdí tá ò fi lè sọ pé àkókò yẹn kúrú? (b) Báwo ni oró náà á ṣe mú àwọn tí wọ́n ń dá lóró tó?

      11 “Oṣù márùn-ún” làwọn eéṣú náà fi dá wọn lóró. Àkókò yẹn ò wa dà bí ẹní kúrú bí? Bá a bá fojú eéṣú gidi wò ó, kò kúrú. Oṣù márùn-ún ṣàpèjúwe bí ẹ̀mí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kòkòrò yẹn ṣe máa ń gùn tó. Èyí fi hàn pé níwọ̀n ìgbà táwọn eéṣú òde òní yìí bá ṣì wà láàyè, wọ́n á máa ta àwọn ọ̀tá Ọlọ́run lọ ni ràì. Yàtọ̀ síyẹn, títa náà rorò tó bẹ́ẹ̀ débi táwọn èèyàn fi ń wá ikú. Lóòótọ́, a ò rí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn táwọn eéṣú náà ta gbìyànjú láti pa ara wọn ní ti gidi. Ṣùgbọ́n gbólóhùn yẹn jẹ́ ká lè fojú inú wo bí títa ríro náà á ṣe pọ̀ tó—àfi bí ẹni pé àwọn àkekèé ń ta èèyàn fàì fàì. Ó dà bí ìyà tí Jeremáyà rí tẹ́lẹ̀ pé ó ń bọ̀ lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòtítọ́ yẹn nígbà táwọn ará Bábílónì ajagunṣẹ́gun bá tú wọn ká, wọ́n á fẹ́ ikú ju ìyè lọ nígbà yẹn.—Jeremáyà 8:3; tún wo Oníwàásù 4:2, 3.

      12. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé oró nìkan la yọ̀ǹda fáwọn eéṣú náà láti dá àwọn aṣáájú ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nípa tẹ̀mí, ṣùgbọ́n kí wọ́n má ṣe pa wọ́n?

      12 Kí nìdí tó fi jẹ́ pé oró nìkan la ní káwọn eéṣú yìí máa dá àwọn wọ̀nyí nípa tẹ̀mí kí wọ́n má ṣe pa wọ́n? Ègbé àkọ́kọ́ rèé nínú títú àwọn irọ́ àtàwọn ìkùnà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó. Ṣùgbọ́n nígbà tó bá yá, bí ọjọ́ Olúwa ti ń tẹ̀ síwájú, wọ́n ṣì ń bọ̀ wá kéde gbangba gbàǹgbà pé inú ipò òkú làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wà nípa tẹ̀mí. Ìgbà ègbé kejì ni ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn náà máa kú.—Ìṣípayá 1:10; 9:12, 18; 11:14.

      Àwọn Eéṣú Tá A Ti Dira Ogun Fún

      13. Báwo làwọn eéṣú yẹn ṣe rí?

      13 Ìrísí àwọn eéṣú yẹn mà pabanbarì o! Jòhánù ṣàpèjúwe ìrísí wọn pé: “Ìrí àwọn eéṣú náà sì jọ àwọn ẹṣin tí a múra sílẹ̀ fún ìjà ogun; àti ní orí wọn ni ohun tí ó rí bí adé tí ó dà bí wúrà wà, ojú wọn sì dà bí ojú ènìyàn, ṣùgbọ́n wọ́n ní irun bí irun obìnrin. Eyín wọn sì dà bí ti kìnnìún; wọ́n sì ní àwo ìgbàyà bí àwo ìgbàyà irin. Ìró ìyẹ́ apá wọn sì dà bí ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ti ọ̀pọ̀ ẹṣin tí ń sáré lọ sínú ìjà ogun.”—Ìṣípayá 9:7-9.

      14. Kí nìdí tí àpèjúwe Jòhánù nípa ìrísí àwọn eéṣú náà fi bá àwùjọ àwọn Kristẹni tá a mú sọ jí lọ́dún 1919 mu?

      14 Èyí ṣàpèjúwe bí àwùjọ àwọn Kristẹni adúróṣinṣin tá a mú sọ jí lọ́dún 1919 ṣe rí. Àfi bí ẹṣin, wọ́n ti ṣe tán ogun, wọ́n hára gàgà láti jà fún òtítọ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe ìjà náà. (Éfésù 6:11-13; 2 Kọ́ríńtì 10:4) Jòhánù ráwọn nǹkan tó rí bí adé wúrà lórí wọn. Kò ní í bójú mu fún wọn láti ní adé gidi nítorí wọn ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. (1 Kọ́ríńtì 4:8; Ìṣípayá 20:4) Ṣùgbọ́n lákòókò yẹn lọ́dún 1919, ọlá ọba ti hàn lára wọn. Arákùnrin Ọba náà ni wọ́n, adé wọn sì ń dúró dè wọ́n lọ́run bí wọ́n bá lè jẹ́ olóòótọ́ títí dópin.—2 Tímótì 4:8; 1 Pétérù 5:4.

      15. Ní tàwọn eéṣú náà, kí ni ìwọ̀nyí tọ́ka sí (a) àwo ìgbàyà irin? (b) ojú bíi ti èèyàn? (d) irun bíi tobìnrin? (e) eyín bíi ti kìnnìún? (ẹ) pípa ọ̀pọ̀ ariwo?

      15 Nínú ìran náà, àwọn eéṣú náà ní àwo ìgbàyà onírin, tó ń ṣàpẹẹrẹ ìwà òdodo tí kò lè fọ́. (Éfésù 6:14-18) Pẹ̀lúpẹ̀lù wọ́n ní ojú èèyàn, èyí ń tọ́ka sí ànímọ́ ìfẹ́, níwọ̀n bí Ọlọ́run, ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́, ti ṣe èèyàn ní àwòrán rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; 1 Jòhánù 4:16) Irun wọn gùn bíi tobìnrin, èyí tó jẹ́ àpẹẹrẹ pé wọ́n ń tẹrí ba fún Ọba wọn, tí í ṣe áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà. Eyín wọn sì jọ eyín kìnnìún. Kìnnìún máa ń fi eyín ẹ̀ fa ẹran ya. Látọdún 1919 wá, ẹgbẹ́ Jòhánù tún ti gba agbára láti jẹ oúnjẹ líle látinú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pàápàá àwọn òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run tí “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà,” Jésù Kristi, ń ṣàkóso. Bí kìnnìún ti ṣàpẹẹrẹ ìgboyà gẹ́lẹ́, ìgboyà ńlá ló gbà láti lóye ọ̀rọ̀ ìkéde yìí, ká sì tẹ́ ẹ̀ jáde ká tó wá pín in káàkiri ilẹ̀ ayé. Àwọn eéṣú ìṣàpẹẹrẹ yìí ti pa ariwo púpọ̀, bí “ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ti ọ̀pọ̀ ẹṣin tí ń sáré lọ sínú ìjà ogun.” Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tí wọ́n ń tẹ̀ lé, wọn ò ní in lọ́kàn láti dákẹ́ jẹ́ẹ́.—1 Kọ́ríńtì 11:7-15; Ìṣípayá 5:5.

      16. Kí ni ìtumọ̀ níní táwọn eéṣú náà ní ‘ìrù, tí wọ́n sì ń tani bí àkekèé’?

      16 Ìwàásù yìí kọjá ọ̀rọ̀ ẹnu lásán! “Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n ní ìrù, wọ́n sì ń tani bí àkekèé; àti ní ìrù wọn ni ọlá àṣẹ wọn wà láti ṣe àwọn ènìyàn náà lọ́ṣẹ́ fún oṣù márùn-ún.” (Ìṣípayá 9:10) Kí lèyí lè túmọ̀ sí o? Báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí wọn ń ṣe, wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu àtàwọn ìwé tí wọ́n tẹ̀ sọ àṣẹ ọ̀rọ̀ tó wá látinú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń kéde ní oró bíi ti àkekèé nítorí wọ́n ń kìlọ̀ nípa ọjọ́ ẹ̀san Jèhófà tó ń sún mọ́lé. (Aísáyà 61:2) Kí gbogbo àwọn eéṣú tẹ̀mí yìí tó parí ìgbésí ayé wọn, iṣẹ́ tí Ọlọ́run pàṣẹ fún wọn, pé kí wọ́n máa polongo àwọn ìdájọ́ òun, á parí—oró ńlá ló máa jẹ́ fún gbogbo àwọn asọ̀rọ̀-òdì tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn líle.

      17. (a) Kí ni nǹkan tí wọ́n kéde ní àpéjọ àgbègbè àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọdún 1919, èyí tí yóò máa mú kí oró ìjẹ́rìí wọn gbóná janjan sí i? (b) Báwo ni wọ́n ṣe dá àwùjọ àwọn àlùfáà lóró, báwo sì làwọn àlùfáà ṣe dáhùn padà?

      17 Ayọ̀ agbo eéṣú yẹn kún àkúnwọ́sílẹ̀ nígbà tí wọ́n kéde ní àpéjọ àgbègbè wọn lọ́dún 1919 pé ìwé ìròyìn tuntun kan, ìyẹn The Golden Age ti jáde. Ẹ̀ẹ̀mejì lóṣù ni ìwé ìròyìn yìí á máa jáde, ìdí tí wọ́n sì fi ń tẹ̀ ẹ́ jáde ni láti mú kí oró ìjẹ́rìí wọn múná janjan sí i.e Ìtẹ̀jáde rẹ̀ Nọnba 27, ti September 29, 1920, túdìí àṣírí bí ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ṣe ń fẹ̀jẹ̀ sínú tutọ́ funfun jáde lórí inúnibíni tí wọ́n ṣe sáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láàárín ọdún 1918 sí 1919. Jálẹ̀ ọdún 1920 wọ ọdún 1930, ìwé ìròyìn The Golden Age tún dá àwùjọ àwọn àlùfáà lóró sí i nípasẹ̀ àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn àwòrán ẹ̀fẹ̀ tó ń tani bí oró, èyí tó túdìí àṣírí báwọn àlùfáà ṣe fi àrékérekè yọjúràn sí ìṣèlú, àti àdéhùn táwọn Kátólíìkì ṣe pẹ̀lú àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ ti ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ àti Násì. Èyí mú kí àwùjọ àwọn àlùfáà “fi òfin dìmọ̀ ìwà ìkà” wọ́n sì kó àwọn èèyàn kéèyàn sòdí láti hùwà ipá sáwọn èèyàn Ọlọ́run.—Sáàmù 94:20.

      Wọ́n Kìlọ̀ Fáwọn Olùṣàkóso Ayé

      18. Iṣẹ́ wo ni àwọn eéṣú náà ní láti ṣe, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìró kàkàkí karùn-ún dún?

      18 Àwọn eéṣú òde òní ní iṣẹ́ pàtàkì láti ṣe. Wọ́n ní láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Wọ́n ní láti túdìí àwọn ìṣìnà. Wọ́n ní láti wá àwọn àgùntàn tó sọ nù rí. Báwọn eéṣú náà ti ń bá iṣẹ́ wọ̀nyí lọ, ó di dandan fún ayé láti kíyè sí i. Ní ìgbọràn sí ìró kàkàkí àwọn áńgẹ́lì, ẹgbẹ́ Jòhánù ti ń bá a lọ láti tú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó pé wọ́n yẹ fún ìdájọ́ Jèhófà. Nígbà tí kàkàkí karùn-ún dún, wọ́n tẹnu mọ́ apá kan pàtó lára ìdájọ́ wọ̀nyí ní àpéjọ àgbègbè kan táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nílùú London, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní May 25 sí 31, ọdún 1926. Wọ́n tẹ́wọ́ gba ìpinnu kan níbẹ̀, èyí tí wọ́n pè ní “Ẹ̀rí fún Àwọn Olùṣàkóso Ayé,” wọ́n sì gbọ́ àsọyé kan fún gbogbo èèyàn ní gbọ̀ngàn Royal Albert Hall lórí “Ìdí Táwọn Agbára Ayé Fi Ń Ta Gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n—Ojútùú Rẹ̀.” Ọ̀kan nínú ìwé ìròyìn tó gbajúmọ̀ jù lọ nílùú London gbé ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìpinnu àti àsọyé yẹn jáde lọ́jọ́ kejì lẹ́yìn tí àpéjọ náà parí. Lẹ́yìn náà, agbo eéṣú náà pín àádọ́ta mílíọ̀nù [50,000,000] ẹ̀dà ìwé àṣàrò kúkúrú tó gbé ìpinnu yẹn jáde káàkiri ayé. Àbí ẹ ò rí i pé oró ńlá ló dá àwùjọ àwọn àlùfáà! Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà làwọn èèyàn ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi ń sọ̀rọ̀ nípa ìtúfó tó ń tani yìí.

      19. Ohun ìjà mìíràn wo làwọn eéṣú ìṣàpẹẹrẹ náà tún rí gbà, kí sì ló ní í sọ nípa ìpolongo ìlú London náà?

      19 Ní àpéjọ àgbègbè yìí, àwọn eéṣú ìṣàpẹẹrẹ náà tún gba ohun ìjà mìíràn, ìyẹn ìwé tuntun kan tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ Idande. Ìjíròrò kan wà nínú rẹ̀ tó dá lórí Ìwé Mímọ́ nípa àmì tó fi hàn pé a ti bí ‘ọmọ ọkùnrin’ náà tó jẹ́ ìjọba, ìyẹn Ìjọba ọ̀run ti Kristi, látọdún 1914. (Mátíù 24:3-14; Ìṣípayá 12:1-10) Lẹ́yìn náà, ó gbé ìpolongo kan jáde èyí táwọn àlùfáà mẹ́jọ tí wọ́n sọ pé wọ́n jẹ́ “ara àwọn oníwàásù tó lókìkí jù lọ lágbàáyé,” fọwọ́ sí, tí wọ́n sì tẹ̀ nílùú London lọ́dún 1917. Àwọn àlùfáà náà wá látinú àwọn ìsìn tó lókìkí jù lọ nínú àwọn ẹ̀ka ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì, ìyẹn látinú ijọ Onítẹ̀bọmi, ìjọ Congregational, ìjọ Presbyterian, ìjọ Episcopalian, àti ìjọ Mẹ́tọ́díìsì. Nínú ìpolongo tí wọ́n fọwọ́ sí yìí, wọ́n pòkìkí pé “yánpọnyánrin tó ń lọ lọ́wọ́ yìí fi hàn pé òpin àkókò àwọn Kèfèrí ti dé” àti pé “ìṣípayá Olúwa la lè retí nígbàkigbà.” Dájúdájú, èyí fi hàn pé àwọn àlùfáà yìí ti rí àmì wíwàníhìn-ín Jésù kedere! Ṣùgbọ́n ṣé wọ́n fẹ́ láti ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀ bí? Ìwé náà, Idande, sọ fún wa pé: “Eyiti o yani lẹnu julọ nínú ọran na ni eyi pe àwọn ẹni gãn ti o fi ọwọ si ọrọ na tun yipada lẹhinna nwọn si kọ̀ àwọn ẹri ti o tọka si pe a wà li opin aiye àti ni ọjọ dide Olúwa lẹ̃keji.”

      20. (a) Kí ni àwùjọ àwọn àlùfáà ti yàn láti ṣe lórí ọ̀ràn agbo eéṣú náà àti Ọba wọn? (b) Ta ni Jòhánù sọ pé ó wà lórí agbo eéṣú náà, kí sì ni orúkọ rẹ̀?

      20 Kàkà kí wọ́n kéde Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀, àwùjọ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti yàn láti fara mọ́ ayé Sátánì. Wọn ò fẹ́ láti ní ìpín kankan pẹ̀lú agbo eéṣú náà àti Ọba wọn, àwọn tí Jòhánù sọ nípa wọn báyìí pé: “Wọ́n ní ọba kan lórí wọn, áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà. Lédè Hébérù, orúkọ rẹ̀ ni Ábádónì [tó túmọ̀ sí “Ìparun”], ṣùgbọ́n lédè Gíríìkì, ó ní orúkọ náà Ápólíónì [tí ó túmọ̀ sí “Apanirun”].” (Ìṣípayá 9:11) Gẹ́gẹ́ bí “áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” àti “Apanirun,” Jésù ti tú ègbé tó ń kó ìyọnu báni sórí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lóòótọ́. Àmọ́, ó kù ni ìbọn ń ró!

      [Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Fi Jóẹ́lì 2:4, 5, 7 (tó sọ pé àwọn kòkòrò náà dà bí ẹṣin, èèyàn, àtàwọn ọkùnrin, tó sì ní wọ́n ń dún bíi kẹ̀kẹ́ ẹṣin) wé Ìṣípayá 9:7-9; bákan náà, fi Jóẹ́lì 2:6, 10 (tó ń ṣàpèjúwe ìrora ìyọnu kòkòrò náà) wé Ìṣípayá 9:2, 5.

      b Wo àpilẹ̀kọ náà “Wiwa ni Irẹpọ Lodisi Àwọn Orilẹ-ede ni Afonifoji Idajọ” nínú Ile-Iṣọ Na ti November 1, 1962.

      c Kíyè sí i pé a ò lè lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí láti fi hàn pé iná ń bẹ nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, bí ẹni pé ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà jẹ́ hẹ́ẹ̀lì oníná. Jòhánù sọ pé òun rí èéfín tó nípọn “bí,” tàbí tó dà bí, èéfín ìléru ńlá. (Ìṣípayá 9:2) Kò sọ pé òun ráwọn ọwọ́ iná gidi nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà.

      d Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a lò níhìn-ín wá láti inú ọ̀rọ̀ náà ba·sa·niʹzo, èyí tá a máa ń lò nígbà mìíràn fún ìdálóró gidi. Ṣùgbọ́n, a tún lè lò ó fún ohun tó ń da èèyàn lọ́kàn rú bíi pé ó ń dá a lóró. Bí àpẹẹrẹ, ní 2 Pétérù 2:8, a kà pé Lọ́ọ̀tì “ń mú ọkàn òdodo rẹ̀ joró” nítorí ìwà ibi tó rí ní Sódómù. Àwọn aṣáájú ìsìn ayé ìgbà àwọn àpọ́sítélì fara gbá irú ìdálóró ọkàn bẹ́ẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó dájú pé, nǹkan míì tó yàtọ̀ pátápátá ló fà á.

      e Lọ́dún 1937, a yí orúkọ ìwé ìròyìn yìí padà sí Consolation, a sì yí i padà sí Awake! (Jí!) lọ́dún 1946.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 143]

      Nígbà tí wọ́n fun kàkàkí karùn-ún, ó mú èkíní nínú ègbé mẹ́ta náà wá

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 146]

      Àwọn ọfà rẹ mú ní ọkàn-àyà àwọn ọ̀tá Ọba. (Sáàmù 45:5) Àwòrán ẹ̀fẹ̀ yìí, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí, jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ẹ̀ tá a tẹ̀ jáde láàárín ọdún 1930 sí 1940 èyí tó ta “àwọn èèyàn tí kò ní èdìdì Ọlọ́run”

      [Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 147]

      Gbọ̀ngàn Royal Albert Hall, níbi tí wọ́n ti mú ìwé náà Idande jáde tí wọ́n sì ti tẹ́wọ́ gba ìpinnu náà “Ẹ̀rí fún Àwọn Olùṣàkóso Ayé”

  • Ègbé Kejì—Agbo Àwọn Agẹṣinjagun
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • Orí 23

      Ègbé Kejì—Agbo Àwọn Agẹṣinjagun

      1. Pẹ̀lú ìsapá àwùjọ àwọn àlùfáà láti pa àwọn eéṣú náà run, kí ló ti ṣẹlẹ̀, kí sì ni bíbọ̀ táwọn ègbé méjì sí i ṣì ń bọ̀ fi hàn?

      LÁTI ọdún 1919 wá, ogun táwọn eéṣú ìṣàpẹẹrẹ ń gbé ti ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti fa ìnira tó pọ̀ fún àwùjọ àwọn àlùfáà. Wọ́n ti gbìyànjú láti pa àwọn eéṣú náà run pátápátá, ṣùgbọ́n ṣe làwọn eéṣú yìí túbọ̀ wá ń di alágbára sí i ju ti tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ rí lọ. (Ìṣípayá 9:7) Kò wá tán síbẹ̀ o! Jòhánù kọ̀wé pé: “Ègbé kan ti kọjá. Wò ó! Ègbé méjì sí i ń bọ̀ lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí.” (Ìṣípayá 9:12) Àwọn ìyọnu adánilóró púpọ̀ sí i wà níwájú fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì.

      2. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì kẹfà fun kàkàkí rẹ̀? (b) Kí ni “ohùn kan látinú àwọn ìwo orí pẹpẹ wúrà” náà dúró fún? (d) Kí ló dé tá a fi mẹ́nu kan áńgẹ́lì mẹ́rin?

      2 Ibo ni ègbé kejì ti wá? Jòhánù kọ̀wé pé: “Áńgẹ́lì kẹfà sì fun kàkàkí rẹ̀. Mo sì gbọ́ tí ohùn kan láti inú àwọn ìwo orí pẹpẹ wúrà tí ó wà níwájú Ọlọ́run wí fún áńgẹ́lì kẹfà, tí ó ní kàkàkí lọ́wọ́ pé: ‘Tú àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí a dè síbi odò ńlá Yúfírétì sílẹ̀.’” (Ìṣípayá 9:13, 14) Ohùn tó wá láti ibi àwọn ìwo pẹpẹ wúrà náà ló pàṣẹ pé kí wọ́n tú àwọn áńgẹ́lì náà sílẹ̀. Èyí ni pẹpẹ tùràrí wúrà, ó di ẹ̀ẹ̀mejì sẹ́yìn tí tùràrí àwọn àwokòtò wúrà láti orí pẹpẹ yìí ti ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àdúrà àwọn ẹni mímọ́. (Ìṣípayá 5:8; 8:3, 4) Torí náà, ohùn kan ṣoṣo yìí dúró fún àdúrà táwọn ẹni mímọ́ lórí ilẹ̀ ayé ń gbà níṣọ̀kan. Wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ pé ká dá àwọn nídè káwọn lè máa fi aápọn ṣe iṣẹ́ ìsìn àwọn lọ bí “àwọn òjíṣẹ́” Jèhófà, níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, “àwọn áńgẹ́lì” ní ìpìlẹ̀ ti túmọ̀ sí “àwọn òjíṣẹ́.” Kí ló dé táwọn áńgẹ́lì náà fi jẹ́ mẹ́rin? Nọ́ńbà ìṣàpẹẹrẹ yìí jọ bí ẹni ń fi hàn pé wọn yóò wà létòlétò tó bẹ́ẹ̀ tí wọn yóò fi kárí ilẹ̀ ayé pátápátá, ìyẹn igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.—Ìṣípayá 7:1; 20:8.

      3. Ọ̀nà wo la gbà “de” áńgẹ́lì mẹ́rin náà “síbi odò ńlá Yúfírétì”?

      3 Ọ̀nà wo la gbà “de” àwọn áńgẹ́lì yẹn “síbi odò ńlá Yúfírétì”? Odò Yúfírétì ìgbàanì ni ààlà tó wà ní ìhà àríwá ìlà oòrùn ilẹ̀ tí Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 15:18; Diutarónómì 11:24) Ó hàn gbangba pé àwọn áńgẹ́lì náà la ti ṣèdíwọ́ fún ní ààlà ilẹ̀ tí Ọlọ́run fi fún wọn, tó túmọ̀ sí àgbègbè ìgbòkègbodò orí ilẹ̀ ayé. A dá wọn dúró láti má ṣe bọ́ sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tí Jèhófà ti gbé lé wọn lọ́wọ́ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Yúfírétì sábà máa ń ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Bábílónì gan-an, pẹ̀lúpẹ̀lù, lẹ́yìn ìṣubú Jerúsálẹ́mù ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lo 70 ọdún níbẹ̀ nínú oko òǹdè, àwọn ni wọ́n “dè síbi odò ńlá Yúfírétì.” (Sáàmù 137:1) Lọ́dún 1919, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí wà nínú ìkálọ́wọ́kò tó jọ ìyẹn, wọ́n ń banú jẹ́, wọ́n sì ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà tọ́ àwọn sọ́nà.

      4. Iṣẹ́ wo làwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà ní í ṣe, báwo ló sì ṣe di ṣíṣe?

      4 Ó múni láyọ̀, láti gbọ́ tí Jòhánù ròyìn pé: “A sì tú àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀, àwọn tí a ti múra sílẹ̀ fún wákàtí àti ọjọ́ àti oṣù àti ọdún náà, láti pa ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn náà.” (Ìṣípayá 9:15) Jèhófà máa ń ṣe nǹkan lákòókò tó yẹ gẹ́ẹ́. Ó ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkókò, ó sì ń pa á mọ́. Fún ìdí yìí, ìgbà tó tó àkókò tó ti ṣètò tẹ́lẹ̀, tó bá a mu wẹ́kú láti parí ohun tàwọn òjíṣẹ́ yìí ní í ṣe, ló tú wọn sílẹ̀. Fojú inú wo bí inú wọn ṣe máa dùn tó bí wọ́n ti ń kúrò nínú ìdè lọ́dún 1919, tí wọ́n sì ti ṣe tán láti ṣiṣẹ́! Iṣẹ́ wọn ò mọ sórí dídáni lóró nìkan, àmọ́ ó kan kí wọ́n “pa ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn.” Èyí tan mọ́ àwọn ìyọnu tí ìró kàkàkí mẹ́rin àkọ́kọ́ kéde, tó pọ́n ìdá mẹ́ta ilẹ̀ ayé, òkun, àti ẹ̀dá inú òkun, àwọn ìsun omi àti àwọn odò, àtàwọn orísun ìmọ́lẹ̀ ọ̀run lójú. (Ìṣípayá 8:7-12) Áńgẹ́lì mẹ́rin náà ṣe jù báyẹn lọ. Wọ́n “pa” ní ìtumọ̀ ti pé wọ́n tú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó pé òkú ni wọ́n nípa tẹ̀mí. Àwọn ìkéde tó dún jáde bíi kàkàkí, ìyẹn àwọn ìkéde tá a ti ń ṣe látọdún 1922 wá títí di ìsinsìnyí, ló ṣe èyí.

      5. Lórí ọ̀ràn ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, báwo ni ìró kàkàkí kẹfà ṣe dún lẹ́ẹ̀kan sí i lọ́dún 1927?

      5 Rántí pé áńgẹ́lì ọ̀run náà ṣẹ̀ṣẹ̀ fun kàkàkí kẹfà ni. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ìkẹfà nínú ọ̀wọ́ àwọn àpéjọ tí wọ́n ń ṣe lọ́dọọdún nílùú Tòróńtò, Ontario, lórílẹ̀-èdè Kánádà, lọ́dún 1927. A gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Sunday July 24, ọdún 1927 sáfẹ́fẹ́ nípasẹ̀ ilé iṣẹ́ rédíò mẹ́tàléláàádọ́ta tí wọ́n so kọ́ra, èyí ni ètò ìròyìn alápapọ̀ tó tíì gbòòrò jù lọ títí di àkókò yẹn. Ọ̀kẹ́ àìmọye làwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn lórí ètò yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, ìpinnu alágbára kan tú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó pé wọ́n ti kú nípa tẹ̀mí, ìpinnu náà sì ké sáwọn èèyàn pé: “Ní wákàtí tí nǹkan dojú rú yìí, Jèhófà Ọlọ́run ń ké sáwọn èèyàn láti pa ‘ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì’ tàbí ‘ìsìn Kristẹni àtọwọ́dá’ tì kí wọ́n sì kọ̀ ọ́ lákọ̀tán kí wọ́n sì kẹ̀yìn sí i pátápátá . . . ; [jẹ́ kí] àwọn èèyàn fún Jèhófà Ọlọ́run àti Ọba tó yàn àti ìjọba rẹ̀ ní ìfọkànsìn wọn pátápátá kí wọ́n sì fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run, Ọba àti ìjọba rẹ̀ nìkan làwọn tẹrí ba fún.” “Òmìnira fún Àwọn Èèyàn” ni àkòrí àsọyé fún gbogbo èèyàn tó tẹ̀ lé e. J. F. Rutherford sọ èyí tagbáratagbára gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, èyí sì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú “iná àti èéfín àti imí ọjọ́” tí Jòhánù rí tẹ̀ lé e nínú ìran.

      6. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe agbo àwọn agẹṣinjagun tó rí tẹ̀ lé e?

      6 “Iye àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti agbo agẹṣinjagun náà sì jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún: mo gbọ́ iye wọn. Báyìí sì ni mo ṣe rí àwọn ẹṣin náà nínú ìran náà, àti àwọn tí wọ́n jókòó lórí wọn: wọ́n ní àwo ìgbàyà pupa bí iná àti búlúù bí háyásíǹtì àti yẹ́lò bí imí ọjọ́; orí àwọn ẹṣin náà sì dà bí orí kìnnìún, iná àti èéfín àti imí ọjọ́ sì jáde wá láti ẹnu wọn. Ìyọnu àjàkálẹ̀ mẹ́ta wọ̀nyí ni a fi pa ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn náà, láti inú iná àti èéfín àti imí ọjọ́ tí ó jáde wá láti ẹnu wọn.”—Ìṣípayá 9:16-18.

      7, 8. (a) Abẹ́ ìdarí atọ́nisọ́nà ta ni agbo agẹṣinjagun yìí tí ń sán jáde wá bí ààrá? (b) Láwọn ọ̀nà wo ni agbo agẹṣinjagun yìí gbà jọ àwọn eéṣú tó ṣáájú rẹ̀?

      7 Ó ṣe kedere pé lábẹ́ ìdarí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà ni agbo agẹṣinjagun yìí fi sán jáde bí ààrá. Ìran ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ mà lèyí o! Fojú inú wo ohun tí wàá ṣe ká ní ìwọ ni irú agbo agẹṣinjagun kan báyẹn fẹ́ wá dojú kọ! Ìrísí wọn lásán gan-an ti tó mú kí ọkàn ẹ là gààrà. Àmọ́, ǹjẹ́ o kíyè sí bí agbo agẹṣinjagun yìí ṣe jọ àwọn eéṣú tó ṣáájú wọn? Àwọn eéṣú náà dà bí ẹṣin; àwọn ẹṣin wà nínú agbo agẹṣinjagun yìí. Èyí fi hàn nígbà náà pé àwọn méjèèjì ń lọ́wọ́ nínú ogun tí Ọlọ́run ń darí. (Òwe 21:31) Àwọn eéṣú náà ní eyín tó dà bíi ti kìnnìún; àwọn ẹṣin agbo agẹṣinjagun yìí náà ní orí tó dà bíi ti kìnnìún. Nítorí náà ọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì ní í ṣe pẹ̀lú Kìnnìún onígboyà ti ẹ̀yà Júdà náà, Jésù Kristi, ẹni tó jẹ́ Aṣáájú, Balógun, àti Àwòfiṣàpẹẹrẹ wọn.—Ìṣípayá 5:5; Òwe 28:1.

      8 Àtàwọn eéṣú àti agbo agẹṣinjagun náà ni wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ ìdájọ́ Jèhófà. Àwọn eéṣú náà ṣẹ́ yọ láti inú èéfín tó ṣàpẹẹrẹ ègbé àti iná apanirun fún àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì; iná, èéfín, àti imí ọjọ́ sì ń jáde látẹnu àwọn ẹṣin náà. Àwọn eéṣú náà ní àwo ìgbàyà irin, tó túmọ̀ sí pé ìfọkànsìn tí ò ṣeé tẹ̀ fún òdodo ló dáàbò bo ọkàn wọn; agbo agẹṣinjagun yìí wọ àwo ìgbàyà aláwọ̀ pupa, búlúù, àti yẹ́lò, èyí tó ń ṣàfihàn iná, èéfín, àti imí ọjọ́ tó ń wá látàrí àwọn ọ̀rọ̀ ìdájọ́ panipani tó ń tẹnu àwọn ẹṣin náà tú jáde. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 19:24, 28; Lúùkù 17:29, 30.) Àwọn eéṣú náà ní ìrù tó dà bíi ti àkekèé láti fi dáni lóró; àwọn ẹṣin yìí ní ìrù tí ó dà bíi ti ejò láti fi pani! Ó dà bí ẹni pé ohun táwọn eéṣú náà bẹ̀rẹ̀ ni agbo agẹṣinjagun yìí fẹ́ máa fi ìtara bá lọ títí tó fi máa parí.

      9. Kí ni agbo agẹṣinjagun náà ṣàpẹẹrẹ?

      9 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni agbo agẹṣinjagun yìí ṣàpẹẹrẹ? A ti rí bí ẹgbẹ́ Jòhánù tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró ṣe ti bẹ̀rẹ̀ ìpolongo ẹ̀san tí Jèhófà máa san àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Pẹ̀lú ìpolongo tó ń dún bíi kàkàkí yìí, wọ́n ní ọlá àṣẹ láti ‘tani àti láti ṣọṣẹ́.’ A retí bákan náà pé Jèhófà yóò lo ẹgbẹ́ Jòhánù kan náà yìí tó wà láàyè láti “pa” ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti àwùjọ àwọn àlùfáà rẹ̀, ní ìtumọ̀ pé wọ́n sọ ọ́ di mímọ̀ pé ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti kú fin-ín-fin-ín lójú Ọlọ́run, Jèhófà ti gbá a jù nù, ó sì ti wà ní sẹpẹ́ láti dèrò inú “ìléru oníná” ti ìparun àìnípẹ̀kun. Àní sẹ́, gbogbo Bábílónì Ńlá gbọ́dọ̀ pa run. (Ìṣípayá 9:5, 10; 18:2, 8; Mátíù 13:41-43) Àmọ́ ṣá o, ṣáájú ìparun rẹ̀, ẹgbẹ́ Jòhánù ń lo “idà ẹ̀mí, ìyẹn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” láti fi tú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó pé wọ́n ti dòkú. Áńgẹ́lì mẹ́rin àtàwọn agẹṣin náà ló ń darí bí wọ́n ṣe ń pa “ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn náà” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. (Éfésù 6:17; Ìṣípayá 9:15, 18) Èyí fi hàn pé bí agbo ọmọ ogun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yìí ṣe yan wàìwàì lọ sójú ogun, wọ́n wà létòlétò lábẹ́ àbójútó Jésù Kristi Olúwa.

      Ẹgbẹẹgbàárùn-ún Méjì Lọ́nà Ẹgbẹẹgbàárùn-ún

      10. Lọ́nà wo ni agbo agẹṣinjagun fi jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún?

      10 Báwo ni agbo agẹṣinjagun yìí ṣe jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún? Ẹgbàárùn-ún kan jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá. Á wá jẹ́ pé ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún yóò jẹ́ igba mílíọ̀nù.a Inú wa dùn pé ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù làwọn olùpòkìkí Ìjọba ló wà báyìí, ṣùgbọ́n iye wọ́n kéré lọ́pọ̀lọpọ̀ sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù! Síbẹ̀, rántí ọ̀rọ̀ Mósè nínú Númérì 10:36: “Jèhófà, padà sọ́dọ̀ ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ísírẹ́lì.” (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 24:60.) Lóréfèé, ìyẹn á túmọ̀ sí, ‘Padà sọ́dọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà mẹ́wàá mẹ́wàá Ísírẹ́lì.’ Àmọ́, bíi mílíọ̀nù méjì sí mẹ́ta péré niye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Mósè. Nítorí náà, kí ni Mósè ń sọ? Ó dájú pé ohun tó ní lọ́kàn ni pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á jẹ́ àìmọye bí “àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun,” dípò kí wọ́n ṣeé kà. (Jẹ́nẹ́sísì 22:17; 1 Kíróníkà 27:23) Nítorí náà, ó lo ọ̀rọ̀ náà, “ẹgbẹẹgbàárùn-ún,” láti sọ iye tó pọ̀ ṣùgbọ́n tí kò lè sọ bó ṣe pọ̀ tó. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì The New English Bible fi túmọ̀ ẹsẹ̀ yìí báyìí: “Sinmi, OLÚWA ẹgbẹẹgbẹ̀rún àìlóǹkà Ísírẹ́lì.” Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ kejì fún ọ̀rọ̀ náà “ẹgbẹẹgbàárùn-ún” tá a rí nínú àwọn ìwé atúmọ̀ èdè ti Gíríìkì àti Hébérù: “ògìdìgbó aláìníye,” “ògìdìgbó.”—The New Thayer’s Greek-English Lexicon of the New Testament; A Hebrew and English Lexicon of the Old Testament ti Gesenius, tí Edward Robinson túmọ̀.

      11. Kí ni ẹgbẹ́ Jòhánù nílò láti di ẹgbẹẹgbàárùn-ún, kódà kó jẹ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ?

      11 Síbẹ̀síbẹ̀, iye àwọn tí wọ́n jẹ́ ara ẹgbẹ́ Jòhánù tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé ò tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá—ó dín ní ẹgbàáàrún kan ní ti gidi. Báwo la ṣe wá lè fi wọ́n wé agbo agẹṣinjagun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àìlóǹkà? Tí wọ́n bá ní láti di ẹgbẹẹgbàárùn-ún, kódà kó jẹ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ṣé wọn ò ní nílò àwọn tó máa tì wọ́n lẹ́yìn? Èyí lohun tí wọ́n ti nílò, wọ́n sì ti rí i gbà lọ́lá inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà! Ibo ni àwọn wọ̀nyí ti wá?

      12, 13. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé wo tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún 1918 sí 1935 ló jẹ́ ká rí ibi tí àwọn tó ṣe ìtìlẹ́yìn náà ti wá?

      12 Láti ọdún 1918 sí ọdún 1922, ẹgbẹ́ Jòhánù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ìrètí aláyọ̀ fáráyé tó wà nínú ìdààmú pé “ọ̀kẹ́ àìmọye tí wọ́n wà láàyè nísinsìnyí kì yóò kú láé.” Ní 1923 wọ́n tún sọ ọ́ di mímọ̀ pé àwọn àgùntàn inú Mátíù 25:31-34 yóò jogún ìyè lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n tún kéde irú ìrètí yìí nínú ìwé kékeré náà Freedom for the Peoples, tí wọ́n mú jáde ní àpéjọ àgbáyé ti ọdún 1927. Kété lẹ́yìn ọdún 1930, wọ́n fi hàn pé ẹgbẹ́ Jèhónádábù adúróṣinṣin, àti ‘àwọn tí ń mí ìmí ẹ̀dùn tí wọ́n sì ń kérora’ nítorí ipò tẹ̀mí tó ń ṣeni láàánú táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wà, bá àwọn àgùntàn ìṣàpẹẹrẹ tí wọ́n ní ìrètí ìyè lórí ilẹ̀ ayé mu. (Ìsíkíẹ́lì 9:4; 2 Àwọn Ọba 10:15, 16) Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) ti August 15, 1934 ń darí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sí ‘àwọn ìlú ńlá ìsádi’ tòde òní, ó sọ pé: “Àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ẹgbẹ́ Jónádábù ti gbọ́ ìró kàkàkí Ọlọ́run wọ́n sì ti ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ náà nípa sísá tọ ètò Ọlọ́run lọ àti nípa kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run, ibẹ̀ ni wọ́n sì gbọ́dọ̀ wà títí lọ.”—Númérì 35:6.

      13 Lọ́dún 1935, a ké sí àwọn tí wọ́n jẹ́ ti agbo Jónádábù yìí ní pàtàkì láti wá sí àpéjọ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Washington, D.C., lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Níbẹ̀, lọ́jọ́ Friday, May 31, J. F. Rutherford sọ àsọyé rẹ̀ olókìkí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ògìdìgbó Ńlá Náà,” nínú èyí tó ti fi hàn kedere pé àwọn èèyàn kan náà ni àwùjọ ti Ìṣípayá 7:9 àti àwọn àgùntàn ti Mátíù 25:33, wọ́n jẹ́ àwùjọ olùṣèyàsímímọ́ tó ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé. Gẹ́gẹ́ bí òjìji àwọn ohun tó ń bọ̀ lọ́nà, ní àpéjọ yẹn òjìlélẹ́gbẹ̀rin [840] àwọn Ẹlẹ́rìí tuntun ló ṣèrìbọmi, púpọ̀ jù lọ wọn ló sì jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá.b

      14. Ṣé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà máa kópa nínú fifi ẹṣin jagun lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ìpinnu wo la sì ṣe lọ́dún 1963?

      14 Ǹjẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ti kópa nínú fifi ẹṣin jagun yìí, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1922, tí wọ́n sì tẹnu mọ́ gan-an ní àpéjọ àgbègbè ti ìlú Tòróńtò lọ́dún 1927? Dájúdájú, lábẹ́ ìdarí áńgẹ́lì mẹ́rin náà, tó túmọ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró ẹgbẹ́ Jòhánù, wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀! Ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun,” tá a ṣe yí ká ayé lọ́dún 1963, wọ́n dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Jòhánù nínú ìpinnu kan tí ń runi sókè. Ìpinnu náà polongo pé ayé “dojú kọ ìjàngbọ̀n tó máa mi gbogbo àgbáyé jìgìjìgì, irú èyí táyé ò tíì rí rí, àti pé gbogbo àwọn ètò ìṣèlú rẹ̀ àti ìsìn Bábílónì rẹ̀ òde òní ni a ó mì títí yóò fi fọ́ sí wẹ́wẹ́.” Wọ́n sọ nínú ìpinnu náà pé “àwa yóò máa bá a nìṣó láti máa polongo ‘ìhìn rere àìnípẹ̀kun’ nípa ìjọba Mèsáyà ti Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn láìṣègbè, a ó sì máa polongo àwọn ìdájọ́ rẹ̀, èyí tó dà bí ìyọnu fáwọn ọ̀tá rẹ̀, àmọ́ tí yóò fi mú òmìnira wá fún gbogbo àwọn tó fẹ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá náà lọ́nà tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́.” Tìtaratìtara ni àpapọ̀ iye tó jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìlélógún lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ dín mẹ́tàlélógún [454,977] tó pé jọ fi tẹ́wọ́ gba ìpinnu yìí, tá a bá sì kó ọgọ́rùn èèyàn jọ nínú wọn, iye tó ju márùndínlọ́gọ́rùn-ún lọ ló jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá ní àpéjọ mẹ́rìnlélógún [24] káàkiri àgbáyé.

      15. (a) Ní ọdún 2005, báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe pọ̀ tó nínú àwọn òṣìṣẹ́ tí Jèhófà ń lò nínú pápá? (b) Báwo ni àdúrà Jésù nínú Jòhánù 17:20, 21 ṣe fi ìṣọ̀kan tó wà láàárín ogunlọ́gọ̀ ńlá náà àti ẹgbẹ́ Jòhánù hàn?

      15 Ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ti ń bá a lọ láti fi hàn pé àwọn wà ní ìṣọ̀kan látòkèdélẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ Jòhánù nínú títú àwọn ìyọnu dà sórí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Ní ọdún 2005, ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ló pọ̀ jù nínú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tí Jèhófà ń lò nínú pápá. Àwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá fi tọkàntọkàn fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ẹgbẹ́ Jòhánù, àwọn tí Jésù gbàdúrà nípa wọn nínú Jòhánù 17:20, 21 pé: “Èmi kò ṣe ìbéèrè nípa àwọn wọ̀nyí nìkan, ṣùgbọ́n nípa àwọn tí yóò ní ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn; kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí àwọn náà lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa, kí ayé lè gbà gbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi jáde.” Bí ẹgbẹ́ Jòhánù tí í ṣe àwọn ẹni àmì òróró ṣe ń mú ipò iwájú lábẹ́ ìdarí Jésù, ogunlọ́gọ̀ ńlá onítara ń dara pọ̀ mọ́ wọn láti rọ́ lu àwọn ọ̀tá gẹ́gẹ́ bí ara agbo agẹṣinjagun yìí, èyí tó jẹ́ aṣèparun jù lọ látọjọ́ táláyé di dáyé!c

      16. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ẹnu àti ìrù àwọn ẹṣin ìṣàpẹẹrẹ náà? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe múra ẹnu àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn? (d) Kí ló bá “ìrù wọ́n [tó] dà bí ejò” mu?

      16 Agbo agẹṣinjagun yẹn nílò ohun ìjà fún ogun náà. Ẹ sì wo bí Jèhófà ṣe pèsè rẹ̀ lọ́nà ìyanu! Jòhánù ṣàpèjúwe rẹ̀ pé: “Nítorí ọlá àṣẹ àwọn ẹṣin náà wà ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn; nítorí ìrù wọ́n dà bí ejò, wọ́n sì ní orí, ìwọ̀nyí ni wọ́n sì fi ń ṣe ìpalára.” (Ìṣípayá 9:19) Jèhófà ti yan àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ tó ti ṣèyàsímímọ́ àti ìrìbọmi fún iṣẹ́ ìsìn yìí. Ó ti kọ́ wọn bí wọn yóò ṣe wàásù ọ̀rọ̀ náà nípasẹ̀ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ìpàdé ìjọ tó fi mọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ mìíràn, èyí sì mú kí wọ́n kúnjú ìwọ̀n láti fàṣẹ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú “ahọ́n àwọn tí a kọ́.” Ó ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí wọn lẹ́nu ó sì ti rán wọn láti lọ sọ àwọn ìdájọ́ rẹ̀ di mímọ̀ “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” (2 Tímótì 4:2; Aísáyà 50:4; 61:2; Jeremáyà 1:9, 10; Ìṣe 20:20) Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni ẹgbẹ́ Jòhánù àti ogunlọ́gọ̀ ńlá ti ń fi ọ̀kẹ́ àìmọye Bíbélì, ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ àti ìwé ìròyìn sílẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn, èyí sì bá àpèjúwe “ìrù” náà mu. Lójú àwọn alátakò wọn tí wọ́n ń sọ fún nípa “ìpalára” tó ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, bí ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún ni agbo àwọn agẹṣinjagun wọ̀nyí rí lóòótọ́.—Fi wé Jóẹ́lì 2:4-6.

      17. Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kópa nínú fífi ẹṣin jagun láwọn ilẹ̀ tá ò ti lè pín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ torí pé wọ́n fi òfin de iṣẹ́ wa bí? Ṣàlàyé.

      17 Àwọn tó ní ìtara jù lọ nínú agbo agẹṣinjagun yìí làwọn arákùnrin tó wà láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí àwọn àgùntàn láàárín àwọn ìkookò, ó di dandan fáwọn wọ̀nyí láti jẹ́ ‘oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ kí wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.’ Bẹ́ẹ̀ sì rèé, gẹ́gẹ́ bí onígbọràn sí Jèhófà, wọn ò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí wọ́n ti rí tí wọ́n sì ti gbọ́. (Mátíù 10:16; Ìṣe 4:19, 20; 5:28, 29, 32) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni wọ́n ní lára àwọn ìwé tá a tẹ̀ tàbí bóyá wọn ò tiẹ̀ ní in rárá láti pín kiri ní gbangba, ṣé a lè sọ pé wọn ò dá sí iṣẹ́ fífi ẹṣin jagun náà bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá! Wọ́n ní ẹnu wọn àti àṣẹ látọ̀dọ̀ Jèhófà láti fi sọ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Wọ́n ń ṣe èyí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà àti pẹ̀lú ìyíniléròpadà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń mú ‘ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo.’ (Dáníẹ́lì 12:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè má fi ìrù wọn tani ní ti pé wọn ò fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ gbàkan-o-ṣubú sílẹ̀, iná, èéfín, àti imí-ọjọ́ ìṣàpẹẹrẹ ń jáde látẹnu wọn bí wọ́n ti ń fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ àti òye wàásù nípa ọjọ́ ìdáláre Jèhófà tó ń sún mọ́lé.

      18. Èdè mélòó ni agbo agẹṣinjagun yìí ti fi ṣe ìpínkiri ìwé ọ̀rọ̀ tó ń kó ìyọnu báni, ẹ̀dà mélòó sì ni wọ́n ti pín?

      18 Láwọn ibòmíràn, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ṣì ń bá a lọ láti máa tú àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ àtàwọn ọ̀nà Bábílónì tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ìpalára tó tọ́ sí wọn wá bá wọn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ní ọdún méjìdínláàádọ́rin [68] ṣáájú 2005, ó ti ṣeé ṣe fún àìmọye àwọn agẹṣinjagun yìí láti fáwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù Bíbélì, ìwé ìròyìn, ìwé ńlá, àti ìwé pẹlẹbẹ ní èdè tó tó 450, èyí tó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ju ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún gidi lọ, èyí sì ṣeé ṣe nípa lílo àwọn ọ̀nà ìtẹ̀wé ìgbàlódé. Ẹ wo bí oró ìtani tí ìrù wọ̀nyẹn ti dá sílẹ̀ ti pọ̀ tó!

      19, 20. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ní pàtó la darí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń kó ìyọnu báni náà sí ní tààràtà, kí làwọn tó wà láwọn ilẹ̀ kan tó jìnnà sáwọn ibi tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀ ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà? (b) Ṣùgbọ́n báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ohun táwọn èèyàn ní gbogbo gbòò ṣe lórí ẹ̀?

      19 Jèhófà ní in lọ́kàn pé kí ìhìn tí ń kó ìyọnu báni yìí “pa ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn.” Fún ìdí yìí, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì la darí ẹ̀ sí ní tààràtà. Ṣùgbọ́n ó ti dé àwọn ilẹ̀ mìíràn yàtọ̀ sáwọn ilẹ̀ tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀, tó fi mọ́ ọ̀pọ̀ ibi táwọn èèyàn ti mọ àgàbàgebè àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ní àmọ̀dunjú. Ṣé àwọn èèyàn tó wà láwọn ilẹ̀ yìí ti sún mọ́ Jèhófà nítorí rírí tí wọ́n ń rí i pé à ń mú ìyọnu bá ètò ìsìn oníwà ìbàjẹ́ yìí? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ti ṣe bẹ́ẹ̀! Àwọn onínú tútù àtàwọn èèyàn tó yááyì tó ń gbé láwọn àgbègbè tó jìnnà sí àgbègbè tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti jẹ gàba ń ṣègbọràn láìlọ́tìkọ̀. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò, Jòhánù ṣàpèjúwe ohun tí wọ́n ṣe, ó ní: “Ṣùgbọ́n ìyókù àwọn ènìyàn tí ìyọnu àjàkálẹ̀ wọ̀nyí kò pa kò ronú pìwà dà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọ́n má ṣe jọ́sìn àwọn ẹ̀mí èṣù àti àwọn òrìṣà wúrà àti fàdákà àti bàbà àti òkúta àti igi, tí kò lè ríran tàbí gbọ́ràn tàbí rìn; wọn kò sì ronú pìwà dà àwọn ìṣìkàpànìyàn wọn tàbí iṣẹ́ ìbẹ́mìílò wọn tàbí àgbèrè wọn tàbí olè jíjà wọn.” (Ìṣípayá 9:20, 21) Kò ní í ṣẹlẹ̀ pé kí gbogbo aráyé tí kò ronú pìwà dà yí padà lọ́nà yẹn. Gbogbo àwọn tó bá ń bá a lọ láwọn ọ̀nà burúkú wọn ló máa dojú kọ ìdájọ́ mímúná lẹ́sẹ̀-ò-gbèjì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní ọjọ́ ńlá ìdáláre rẹ̀. Ṣùgbọ́n “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.”—Jóẹ́lì 2:32; Sáàmù 145:20; Ìṣe 2:20, 21.

      20 Ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò tán yìí jẹ́ ara ègbé kejì. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i láwọn orí tó wà níwájú, púpọ̀ sí i ń bọ̀ lọ́nà kí ègbé náà tó tán.

      [Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Ìwé náà, Commentary on Revelation, látọwọ́ Henry Barclay Swete, sọ nípa iye náà, “ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún,” pé: “Pẹ̀lú bí iye yìí ṣe pọ̀ tó, kò yẹ ká retí pé báwọn agẹsinjagun náà á ṣe pọ̀ tó nìyẹn nígbà tí ìran náà bá nímùúṣẹ.”

      b Wo ojú ìwé 119 sí 126 nínú ìwé yìí; tún wo ojú ìwé 83 àti 84 nínú Vindication, Ìwé Kẹta. Ọdún 1932 ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ ìwé náà jáde.

      c Láìdà bí àwọn eéṣú náà, agbo àwọn agẹṣinjagun tí Jòhánù rí yìí ò dé “ohun tí ó rí bí adé tí ó dà bí wúrà.” (Ìṣípayá 9:7) Èyí bá òtítọ́ náà mu pé ogunlọ́gọ̀ ńlá, tó pọ̀ jù nínú agbo agẹṣinjagun náà lónìí, kò nírètí láti jọba nínú Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 149]

      Bí áńgẹ́lì náà ṣe fun kàkàkí kẹfà, ègbé kejì wọlé dé

      [Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 150, 151]

      Àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin ń darí agbo agẹṣinjagun tó tíì lágbára jù lọ látọjọ́ táláyé ti dáyé

      [Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 153]

      Agbo agẹṣinjagun tí ò lóǹkà ti pín ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì kiri

      [Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 154]

      Ìyókù àwọn èèyàn náà kò ronú pìwà dà

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́