ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/10 ojú ìwé 7
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 8/10 ojú ìwé 7

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 30, 2010. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ July 5 sí August 30, 2010, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.

1. Báwo ni ṣíṣàṣàrò lórí àdúrà ìyàsímímọ́ tí Sólómọ́nì gbà ṣe lè jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì àwọn ànímọ́ títayọ tí Jèhófà ní? (1 Ọba 8:22-53) [w05 7/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3]

2. Kí nìdí tí a fi lè sọ pé Dáfídì rìn pẹ̀lú “ìwà títọ́ ọkàn àyà” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe ọ̀pọ̀ àṣìṣe? (1 Ọba 9:4) [w97 5/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1 sí 2]

3. Kí nìdí tí ọbabìnrin Ṣébà fi sọ nípa Sólómọ́nì pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ tìrẹ wọ̀nyí tí ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fetí sí ọgbọ́n rẹ!”? (1 Ọba 10:4-8) [w99 11/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 5 sí 7]

4. Kí la lè sọ nípa bí Jèhófà ṣe pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìsìnkú ẹ̀yẹ fún Ábíjà? (1 Ọba 14:13) [cl ojú ìwé 244 ìpínrọ̀ 11]

5. Kí nìdí tí àkókò tí Èlíjà kọ́kọ́ lọ bá Áhábù fi ṣe pàtàkì? (1 Ọba 17:1) [w08 4/1 ojú ìwé 19, àpótí]

6. Kí ni Èlíjà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń “tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra”? (1 Ọba 18:21) [w08 1/1 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 3 sí 4]

7. Bó ṣe hàn kedere nínú ọ̀ràn ti wòlíì Èlíjà, kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń lo agbára rẹ̀ nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀? (1 Ọba 19:1-12) [cl ojú ìwé 42 sí 43 ìpínrọ̀ 15 sí 16]

8. Kí nìdí tí Nábótì fi kọ̀ láti ta ọgbà àjàrà rẹ̀ fún Áhábù, ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? (1 Ọba 21:3) [w97 8/1 ojú ìwé  13 ìpínrọ̀ 18 sí 20]

9. Lọ́nà wo ni obìnrin ará Ṣúnémù gbà ‘ká ara rẹ̀ lọ́wọ́ kò’ tàbí ‘ṣe àníyàn’ nítorí Èlíṣà? (2 Ọba 4:13) [w97 10/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 6 sí 8]

10. Kí nìdí tí Èlíṣà kò fi gba ẹ̀bùn tí Náámánì fún un? (2 Ọba 5:15, 16) [w05 8/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 2]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́