Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 6
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 6
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 12-15
No. 1: 2 Àwọn Ọba 13:1-11
No. 2: Bá A Ṣe Lè Rí Ẹ̀mí Mímọ́ Gbà
No. 3: Ojú Táwọn Kristẹni Fi Ń Wo Àwọn Ayẹyẹ Ọjọ́ Àjọ̀dún (td 38A)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Nígbà Àkọ́kọ́ Tó O Bá Wàásù fún Ẹnì Kan Lóṣù September. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni la máa lò lóṣù September, a ó sì gbìyànjú láti jíròrò ìpínrọ̀ kan tàbí méjì pẹ̀lú onílé nígbà àkọ́kọ́. Sọ àwọn ọ̀nà tá a lè gbà ṣe èyí. Ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì.
10 min: Ṣọ́ra fún Àwọn Wòlíì Èké! Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ February 1, 1992, ojú ìwé 3 sí 7.
10 min: Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Bí Ìhìn Rere Ṣe Wúlò. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 159. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ohun tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ní kí wọ́n dábàá bá a ṣe lè gbé ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wa ka àwọn ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn yẹn.