ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 January ojú ìwé 2-7
  • Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Jèhófà Tọ́ Ẹ Sọ́nà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Jèhófà Tọ́ Ẹ Sọ́nà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó YẸ KÁ NÍRẸ̀LẸ̀, KÁ MÁ JẸ́ KÍ NǸKAN SÚ WA, KÁ SÌ NÍGBÀGBỌ́
  • BÍI PÉTÉRÙ, MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
  • BÍI PỌ́Ọ̀LÙ, MÁA HÙWÀ TÓ Ń MÚNÚ ỌLỌ́RUN DÙN
  • BÍI DÁFÍDÌ, JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ DÁÀBÒ BÒ Ẹ́
  • MÁA ṢE OHUN TÁÁ JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ TỌ́ Ẹ SỌ́NÀ
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Máa Ronú Bí Jèhófà àti Jésù Ṣe Ń Ronú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Wá Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Yìí
    Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká 2025-2026—Tí Alábòójútó Àyíká Máa Bá Wa Ṣe
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 January ojú ìwé 2-7

MARCH 2-8, 2026

ORIN 97 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ló Ń Mú Ká Wà Láàyè

Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Jèhófà Tọ́ Ẹ Sọ́nà

ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ ỌDÚN 2026: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.”—MÁT. 5:3.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Bá a ṣe lè máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ká máa hùwà táá múnú ẹ̀ dùn, ká sì jẹ́ kó máa dáàbò bò wá.

1. Nígbà tí Jèhófà dá wa, àwọn nǹkan pàtàkì wo ló mọ̀ pé ó yẹ ká ní? (Mátíù 5:3)

NÍGBÀ tí Jèhófà dá wa, ó mọ̀ pé àwọn nǹkan pàtàkì kan wà tó yẹ ká ní. Bí àpẹẹrẹ, ká lè gbádùn ayé wa, ó yẹ ká ní oúnjẹ, aṣọ àti ilé. Tá ò bá ní ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì yìí, ì báà jẹ́ fúngbà díẹ̀, ìgbésí ayé máa nira gan-an. Yàtọ̀ sáwọn nǹkan tí Jèhófà fún wa ká lè gbádùn ayé wa, ó tún fẹ́ ká máa wá ìtọ́sọ́nà òun. (Ka Mátíù 5:3.) Torí náà, tá a bá fẹ́ láyọ̀, ó yẹ ká máa wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, ká sì jẹ́ kó máa darí wa.

2. Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó ní ká máa “wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run”? Sọ àpèjúwe kan.

2 Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó ní ká máa “wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run”? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò nínú ẹsẹ yìí ń tọ́ka sí ẹni tó ń ṣagbe nípa tẹ̀mí. Ọ̀rọ̀ yìí lè jẹ́ ká fojú inú wo ẹnì kan tó ń tọrọ owó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà. Aṣọ ẹ̀ dọ̀tí, kò sì ní nǹkan tó máa jẹ. Ó jókòó sínú oòrùn tó mú ganrín-ganrín lọ́sàn-án, kò sì níbi tó máa sùn lálẹ́. Àwọn èèyàn ò fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ torí bó ṣe rí, èyí ò sì múnú ẹ̀ dùn rárá. Ọkùnrin yìí mọ̀ pé kóun tó lè bọ́ nínú ipò tóun wà yìí, àfi kẹ́nì kan ran òun lọ́wọ́. Lọ́nà kan náà, ẹni tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, ìyẹn ẹni tó ń ṣagbe nípa tẹ̀mí, gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́. Torí náà, ó máa ń wù ú láti jàǹfààní ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jèhófà ń pèsè fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kọ́kọ́ jíròrò ohun tá a lè kọ́ lára obìnrin ará Foníṣíà tó sọ pé kí Jésù ran òun lọ́wọ́. Ìtàn obìnrin yìí máa jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan pàtàkì mẹ́ta tó yẹ ká máa ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ wa sọ́nà. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò bá a ṣe lè fìwà jọ àpọ́sítélì Pétérù, Pọ́ọ̀lù àti Ọba Dáfídì tí wọ́n jẹ́ kí Jèhófà tọ́ àwọn sọ́nà.

Ó YẸ KÁ NÍRẸ̀LẸ̀, KÁ MÁ JẸ́ KÍ NǸKAN SÚ WA, KÁ SÌ NÍGBÀGBỌ́

4. Kí ni obìnrin ará Foníṣíà kan fẹ́ kí Jésù ṣe fún òun?

4 Lọ́jọ́ kan, obìnrin ará Foníṣíà kan wá sọ́dọ̀ Jésù. Obìnrin náà sọ fún un pé ‘ẹ̀mí èṣù ń yọ ọmọbìnrin òun lẹ́nu gidigidi.’ (Mát. 15:21-28) Obìnrin náà kúnlẹ̀, ó sì ń bẹ Jésù pé kó ran òun lọ́wọ́. Ohun tí obìnrin yìí ṣe nígbà tó wá sọ́dọ̀ Jésù fi hàn pé ó láwọn ànímọ́ tó dáa. Ẹ jẹ́ ká sọ díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ yìí.

5. Àwọn ànímọ́ wo ni obìnrin ará Foníṣíà náà ní, kí nìyẹn sì mú kí Jésù ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

5 Obìnrin ará Foníṣíà náà nírẹ̀lẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kò bínú nígbà tí Jésù sọ àpèjúwe kan tó mú kó dà bíi pé ó fi obìnrin náà wé àwọn ajá kéékèèké, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹranko táwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì máa ń sìn nílé. Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Jésù sọ bẹ́ẹ̀ fún, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Ṣé o ò ní wò ó pé ṣe ló kàn ẹ́ lábùkù, tí ò sì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́? Kì í ṣe ohun tí obìnrin ará Foníṣíà náà ṣe nìyẹn o. Yàtọ̀ sí pé ó nírẹ̀lẹ̀, kò tún jẹ́ kọ́rọ̀ náà sú òun. Ìyẹn ló jẹ́ kó máa bẹ Jésù léraléra pé kó ran òun lọ́wọ́. Kí nìdí tí obìnrin náà fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé obìnrin náà nígbàgbọ́ nínú Jésù. Kódà, nígbà tí Jésù rí bí ìgbàgbọ́ obìnrin yìí ṣe lágbára tó, ó pinnu pé òun máa ràn án lọ́wọ́. Òótọ́ ni pé Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún obìnrin yìí pé “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù” la rán òun sí, síbẹ̀ ó pinnu láti wo ọmọ obìnrin náà sàn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé obìnrin náà kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì.

Obìnrin ará Foníṣíà náà kúnlẹ̀ síwájú Jésù, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ran òun lọ́wọ́. Jésù àti mẹ́ta lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ jókòó sídìí tábìlì oúnjẹ, wọ́n sì ń tẹ́tí sí obìnrin náà.

Obìnrin ará Foníṣíà náà nírẹ̀lẹ̀, kò jẹ́ kọ́rọ̀ náà sú òun, ó sì nígbàgbọ́ pé Jésù máa ran òun lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 5)


6. Kí la rí kọ́ nínú ìtàn obìnrin ará Foníṣíà?

6 Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ wa sọ́nà, ó yẹ ká fìwà jọ obìnrin ará Foníṣíà. Ó yẹ ká nírẹ̀lẹ̀, ká má jẹ́ kí nǹkan tètè máa sú wa, ká sì nígbàgbọ́ tó lágbára. Ẹni tó bá nírẹ̀lẹ̀ lá máa bẹ Ọlọ́run léraléra pé kó ran òun lọ́wọ́. Ó tún yẹ ká nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jésù Kristi àtàwọn tó yàn pé kó máa bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. (Mát. 24:45-47) Tá a bá láwọn ànímọ́ yìí, inú Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ máa dùn sí wa, wọ́n máa tọ́ wa sọ́nà, wọ́n á sì ràn wá lọ́wọ́. (Fi wé Jémíìsì 1:5-7.) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa ń tọ́ wa sọ́nà, bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa hùwà táá múnú ẹ̀ dùn àti bó ṣe ń dáàbò bò wá. Ká lè jàǹfààní àwọn nǹkan pàtàkì tí Jèhófà ń ṣe fún wa yìí, a máa wo ohun tá a lè kọ́ lára àpọ́sítélì Pétérù, Pọ́ọ̀lù àti Ọba Dáfídì.

BÍI PÉTÉRÙ, MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

7. Iṣẹ́ wo ni Jésù gbé fún Pétérù, kí ló sì yẹ kó ṣe? Ṣàlàyé. (Hébérù 5:14–6:1)

7 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pétérù. Ó wà lára àwọn Júù tó kọ́kọ́ mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà, ìyẹn ẹni tí Jèhófà yàn pé kó máa sọ “àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun” fáwọn èèyàn ẹ̀. (Jòh. 6:66-68) Kí Jésù tó lọ sọ́run lẹ́yìn tó jíǹde, ó sọ fún Pétérù pé: “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” (Jòh. 21:17) Pétérù sì ṣe ohun tí Jésù sọ yìí lóòótọ́, kódà Jèhófà jẹ́ kó kọ méjì lára àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́, ó ṣì yẹ kí Pétérù máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ, àwọn lẹ́tà yìí sì wà lára Ìwé Mímọ́. Pétérù gbà pé àwọn kan lára ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ “ṣòroó lóye.” (2 Pét. 3:15, 16) Àmọ́ Pétérù ò jẹ́ kó sú òun, ó nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́ kí “oúnjẹ líle,” ìyẹn ọ̀rọ̀ tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí Pọ́ọ̀lù láti kọ lè yé òun, kóun sì lè fi wọ́n sílò.—Ka Hébérù 5:14–6:1.

8. Kí ni Pétérù ṣe nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà ní kó ṣe àwọn àyípadà kan?

8 Torí pé Pétérù nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, ìyẹn ló jẹ́ kó ṣe ohun tí Jèhófà sọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Pétérù wà ní Jópà, ó rí ìran kan. Nínú ìran náà, áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún un pé kó máa pa àwọn ẹran kan kó sì máa jẹ wọ́n. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, aláìmọ́ làwọn ẹran náà bí Òfin Mósè ṣe sọ. Kò sí Júù kan tó máa fẹ́ ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀ láé! Torí náà Pétérù kọ́kọ́ fèsì pé: “Rárá o, Olúwa, mi ò jẹ ohunkóhun tó jẹ́ ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́ rí.” Áńgẹ́lì náà wá sọ fún un pé: “Yéé pe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.” (Ìṣe 10:9-15) Ọ̀rọ̀ náà yé Pétérù, ó sì yí èrò ẹ̀ pa dà. Báwo la ṣe mọ̀? Kò pẹ́ lẹ́yìn tó rí ìran náà, àwọn ọkùnrin mẹ́ta kan wá látọ̀dọ̀ Kọ̀nílíù tó jẹ́ Kèfèrí. Wọ́n sọ fún Pétérù pé Kọ̀nílíù, ọ̀gá àwọn sọ pé kó wá wàásù fún òun. Ká ní kì í ṣe ti ìran tí Pétérù rí ni, kò jẹ́ wọ ilé Kèfèrí láé! Ìdí ni pé àwọn Júù gbà pé aláìmọ́ làwọn Kèfèrí. (Ìṣe 10:28, 29) Àmọ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Pétérù gbà láti fara mọ́ òye tuntun tó ní nípa ohun tí Jèhófà sọ. (Òwe 4:18) Torí náà, Pétérù wàásù fún Kọ̀nílíù àti agbo ilé ẹ̀, inú ẹ̀ sì dùn bó ṣe rí i pé wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́, wọ́n gba ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi.—Ìṣe 10:44-48.

9. Ọ̀nà méjì wo la lè gbà jàǹfààní tá a bá ń jẹ́ kó wù wá láti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì tó jinlẹ̀?

9 Bíi Pétérù, ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ tá a kọ́kọ́ mọ̀ tó dà bíi wàrà nìkan ló yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀. Ó tún yẹ ká jẹ́ kó wù wá láti máa kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀, ìyẹn àwọn oúnjẹ líle tó ṣòro lóye tó wà nínú Bíbélì. Ó yẹ ká máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ tó wà nínú ẹ̀. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká sọ ọ̀nà méjì tó máa gbà ṣe wá láǹfààní tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, a máa mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà tó máa jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Ìkejì, á jẹ́ kó túbọ̀ yá wa lára láti sọ àwọn ohun àgbàyanu tá a kọ́ nípa Jèhófà Baba wa ọ̀run fáwọn èèyàn. (Róòmù 11:33; Ìfi. 4:11) Bákan náà, ohun míì wà tá a lè kọ́ lára Pétérù. Tí ètò Ọlọ́run bá ṣàtúnṣe òye tá a ní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó yẹ ká tètè yí èrò wa pa dà, ká sì ṣàtúnṣe tó yẹ. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, àá sì wúlò fún un.

BÍI PỌ́Ọ̀LÙ, MÁA HÙWÀ TÓ Ń MÚNÚ ỌLỌ́RUN DÙN

10. Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ máa hùwà táá múnú Ọlọ́run dùn? (Kólósè 3:8-10)

10 Tá a bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn, ó yẹ ká máa jàǹfààní ohun míì tó ń pèsè fún wa, ìyẹn bó ṣe ń kọ́ wa ká lè máa hùwà tó dáa. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ká “bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀,” ká sì fi “ìwà tuntun” wọ ara wa láṣọ. (Ka Kólósè 3:8-10.) Ó máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá ká tó lè máa hùwà táá múnú Ọlọ́run dùn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù. Láti kékeré ló ti ń sapá kó lè múnú Ọlọ́run dùn. (Gál. 1:14; Fílí. 3:4, 5) Àmọ́ kò ní ìmọ̀ tó péye nípa bó ṣe lè sin Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ “aláfojúdi” torí pé kò mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Jésù fi kọ́ àwọn èèyàn, ó sì tún jẹ́ agbéraga. Àwọn nǹkan yìí ni ò jẹ́ kó lè hùwà táá múnú Ọlọ́run dùn.—1 Tím. 1:13.

11. Ìwà wo ló yẹ kí Pọ́ọ̀lù jáwọ́ nínú ẹ̀? Ṣàlàyé.

11 Kí Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, ó tètè máa ń bínú. Ìwé Ìṣe sọ pé ìgbà kan wà tí Pọ́ọ̀lù bínú gan-an sáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù débi pé ‘inú ẹ̀ ru, ó sì ń fikú halẹ̀ mọ́’ wọn. (Ìṣe 9:1) Àmọ́ lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù di Kristẹni, kò sí àní-àní pé ó máa ṣiṣẹ́ kára kó lè bọ́ ìwà àtijọ́ yìí sílẹ̀. (Éfé. 4:22, 31) Síbẹ̀, ó tún pa dà ṣàṣìṣe yìí torí nígbà tí òun àti Bánábà ní èdèkòyédè, Bíbélì sọ pé ó “gbaná jẹ.” (Ìṣe 15:37-39) Ká sòótọ́, ó máa dun Pọ́ọ̀lù pé òun ò tíì borí ìwà yìí, àmọ́ kò jẹ́ kó sú òun. Ṣe ló ‘ń lu ara ẹ̀ kíkankíkan,’ tó ń ṣiṣẹ́ kára kó lè jáwọ́ nínú ìwà tó ń hù yìí, kó sì máa hùwà táá múnú Jèhófà dùn.—1 Kọ́r. 9:27.

12. Kí ló jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù lè jáwọ́ nínú ìwà tí ò dáa?

12 Ohun tó jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò dáa tó sì ń hùwà táá múnú Ọlọ́run dùn ni pé ó nírẹ̀lẹ̀, kò sì gbára lé okun tiẹ̀. (Fílí. 4:13) Bíi ti Pétérù, Pọ́ọ̀lù náà “gbára lé okun tí Ọlọ́run ń fúnni.” (1 Pét. 4:11) Àmọ́, láwọn ìgbà míì Pọ́ọ̀lù máa ń ṣàṣìṣe, ìyẹn sì máa ń mú kó rẹ̀wẹ̀sì. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ó máa ń rántí àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún un, ìyẹn ló sì ń jẹ́ kó sapá láti máa hùwà táá múnú Ọlọ́run dùn.—Róòmù 7:21-25.

13. Báwo la ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù?

13 A lè fara wé Pọ́ọ̀lù tá a bá ń jàǹfààní nínú bí Jèhófà ṣe ń kọ́ wa ká lè máa hùwà táá múnú ẹ̀ dùn. Bó ti wù kó pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà, ó yẹ ká máa ṣiṣẹ́ kára ká lè jáwọ́ nínú ìwà tí ò dáa, ká sì máa hùwà tó dáa. Àmọ́ tá a bá ṣàṣìṣe, bóyá ṣe la gbaná jẹ tàbí tá a sọ̀rọ̀ tí ò dáa sẹ́nì kan, kò yẹ ká ronú pé ọ̀rọ̀ wa ti kọjá àtúnṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká túbọ̀ sapá ká lè máa ronú bó ṣe tọ́, ká sì máa hùwà tó yẹ. (Róòmù 12:1, 2; Éfé. 4:24) Ohun pàtàkì kan wà tó yẹ ká máa rántí, ìyẹn ni pé tá a bá wọ aṣọ kan, tí aṣọ náà sì tóbi lára wa, a lè tún un ṣe kó lè ṣe rẹ́gí. Àmọ́ tó bá kan àwọn ìwà tó ń múnú Ọlọ́run dùn tá a fẹ́ gbé wọ̀ bí aṣọ, a ò lè yí àwọn ìwà náà pa dà, kàkà bẹ́ẹ̀ àwa la máa ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ, ká lè gbé àwọn ìwà náà wọ̀ bí aṣọ.

BÍI DÁFÍDÌ, JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ DÁÀBÒ BÒ Ẹ́

14-15. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwa èèyàn ẹ̀? (Sáàmù 27:5) (Tún wo àwòrán.)

14 Tá a bá fẹ́ máa láyọ̀, ó yẹ ká máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ká sì máa hùwà táá jẹ́ kínú ẹ̀ dùn sí wa. Àmọ́ ìyẹn nìkan ò tó, ó tún ṣe pàtàkì ká jẹ́ kí Jèhófà máa dáàbò bò wá. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà dáàbò bò wá?

15 Ó dá Ọba Dáfídì lójú pé Jèhófà máa dáàbò bo òun nígbà ìṣòro. (Ka Sáàmù 27:5.) Ohun kan náà ni Jèhófà ń ṣe fáwa ìránṣẹ́ ẹ̀ lónìí. Kò ní gbà kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni ba àjọṣe àwa àti òun jẹ́. Ó ṣèlérí pé táwọn èèyàn bá gbéjà kò wá, wọn ò ní ṣàṣeyọrí. (Sm. 34:7; Àìsá. 54:17) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù títí kan àwọn èèyàn tó ń lò láti ta kò wá lágbára, wọ́n sì lè pa wá lára, wọn ò lágbára tó Jèhófà. Tí wọ́n bá tiẹ̀ pa wá, Jèhófà máa jí wa dìde. (1 Kọ́r. 15:55-57; Ìfi. 21:3, 4) Nígbà míì, àníyàn wa lè pọ̀ débi pé a lè má fẹ́ sin Jèhófà mọ́, àmọ́ nírú àsìkò bẹ́ẹ̀ Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí ẹ̀. (Òwe 12:25; Mát. 6:27-29) Bákan náà, Jèhófà tún fi àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kẹ́ wa, ó sì fún wa láwọn alàgbà tó ń fìfẹ́ bójú tó wa. (Àìsá. 32:1, 2) Tá a bá wà nípàdé, wọ́n máa ń rán wa létí àwọn nǹkan tá a lè ṣe kí Jèhófà lè máa dáàbò bò wá.—Héb. 10:24, 25.

Arábìnrin kan nawọ́ kó lè dáhùn nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ “Ilé Ìṣọ́.” Àwọn ará mí ì náà nawọ́.

Arábìnrin kan wà nípàdé pẹ̀lú àwọn ará, ìyẹn fi hàn pé ó fẹ́ kí Jèhófà dáàbò bo òun (Wo ìpínrọ̀ 14-15)


16. Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo Dáfídì?

16 Nígbà tí Dáfídì ṣègbọràn sí Jèhófà, ó dáàbò bò ó, kò sì jẹ́ kó jìyà táwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ máa ń jẹ. (Fi wé Òwe 5:1, 2.) Àmọ́ nígbà tí Dáfídì ṣàìgbọràn, Jèhófà ò gbà á sílẹ̀, ó sì jẹ́ kó jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀. (2 Sám. 12:9, 10) Àwọn ìgbà kan wà tí Dáfídì jìyà bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ṣẹ̀. Kí ni Jèhófà ṣe lásìkò yẹn? Dáfídì gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà, Jèhófà tù ú nínú, ó sì jẹ́ kó dá a lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an, òun sì máa bójú tó o.—Sm. 23:1-6.

17. Báwo la ṣe lè fara wé Dáfídì?

17 A lè fara wé Dáfídì tá a bá jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà ká tó ṣèpinnu. Ó yẹ ká rántí pé àwọn ìgbà míì wà tá a lè jìyà torí pé a ṣèpinnu tí ò tọ́. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kò yẹ ká ronú pé Jèhófà ò dáàbò bò wá. (Gál. 6:7, 8) Àwọn ìgbà míì sì wà tá a lè jìyà bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò ṣe ohun tí ò dáa. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé á tù wá nínú, á sì fìfẹ́ bójú tó wa.—Fílí. 4:6, 7.

MÁA ṢE OHUN TÁÁ JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ TỌ́ Ẹ SỌ́NÀ

18. Ìṣòro wo làwọn èèyàn ní lónìí, kí la sì lè ṣe kí Jèhófà lè máa tọ́ wa sọ́nà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

18 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2026 sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.” Àsìkò yìí gan-an ló yẹ ká jẹ́ kí Jèhófà túbọ̀ máa tọ́ wa sọ́nà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn tó yí wa ká ni ò gbà pé àwọn nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Àwọn kan gba Ọlọ́run gbọ́, àmọ́ wọn ò jọ́sìn ẹ̀ bó ṣe fẹ́. Ní tàwọn míì, ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn bíi tiwọn ni wọ́n ti máa ń gba ìtọ́sọ́nà, abájọ tí gbogbo wọn ò fi láyọ̀. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ fìwà jọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́? Ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ká máa hùwà tínú Ọlọ́run dùn sí, ká sì máa ṣègbọràn sí Jèhófà kó lè máa dáàbò bò wá.

Fọ́tò: Arábìnrin tó wà nínú àwòrán iwájú ìwé ń ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé ó ń wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà. 1. Ó ń kẹ́kọ̀ọ́ “Ilé Ìṣọ́” tá a máa kà nípàdé. 2. Ó gbé oúnjẹ wá fún tọkọtaya kan nílé wọn. Ọkọ náà jókòó sórí àga, wọ́n fi báńdééjì wé e lórí, wọ́n sì ń fa omi sí i lára. 3. Arákùnrin méjì wá ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ ẹ̀, ó sì ń tẹ́tí sí wọn.

Ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ká máa hùwà tó dáa, ká sì jẹ́ kí Jèhófà máa dáàbò bò wá (Wo ìpínrọ̀ 18)a

KÍ LA LÈ ṢE . . .

  • ká lè máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà?

  • ká lè máa hùwà táá múnú Jèhófà dùn?

  • kí Jèhófà lè máa dáàbò bò wá?

ORIN 162 Mo Fẹ́ Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run

a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arábìnrin náà ń kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ torí ó fẹ́ kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà, ó ń ṣoore fáwọn èèyàn torí ó fẹ́ múnú Jèhófà dùn, ó sì jẹ́ káwọn alàgbà ran òun lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bẹ̀ ẹ́ wò.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́