ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 January ojú ìwé 32
  • Máa Fojú Inú Wo Ohun Tó Ò Ń Kà Nínú Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fojú Inú Wo Ohun Tó Ò Ń Kà Nínú Bíbélì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ibo Ni Mo Ti Fẹ́ Bẹ̀rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?—Apá 3: Túbọ̀ Jàǹfààní Púpọ̀ Bó o Ṣe Ń Ka Bíbélì
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àwòrán Ń Jẹ́ Ká Rántí Ohun Tá A Kọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 January ojú ìwé 32

OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́

Máa Fojú Inú Wo Ohun Tó Ò Ń Kà Nínú Bíbélì

Ọ̀pọ̀ ìtàn tó kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì ló kún inú Bíbélì. Tá a bá ń fojú inú wo àwọn ìtàn yìí bá a ṣe ń kà á, á jẹ́ kó túbọ̀ yé wa, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú wọn. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára nǹkan tá a lè ṣe táá jẹ́ ká lè máa fojú inú wo ohun tá a bá ń kà nínú Bíbélì.

  • Máa kà á sókè. Tó o bá ń ka Bíbélì sókè, ìyẹn á jẹ́ kó o lè túbọ̀ máa fojú inú wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Tẹ́ ẹ bá sì ń ka Bíbélì pa pọ̀ nínú ìdílé, ẹ lè ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan ka ọ̀rọ̀ ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà nínú ìtàn náà, ìyẹn á jẹ́ kó dà bíi pé ẹ wà níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

  • Máa fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Gbìyànjú láti mọ ohun táwọn tó ò ń kà nípa wọn ń rò àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, bi ara ẹ pé: ‘Kí nìdí tẹ́ni náà fi ṣe ohun tó ṣe tàbí sọ ohun tó sọ? Ká sọ pé èmi nirú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, báwo lọ̀rọ̀ yẹn ì bá ṣe rí lára mi àti pé kí ló ṣeé ṣe kí n máa rò?’

  • Yàwòrán ohun tó ò ń kà. Tó o bá yàwòrán ohun tó ò ń kà, á jẹ́ kó o lè fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀, kó o rántí àwọn ẹ̀kọ́ ibẹ̀ dáadáa, kódà tí àwòrán náà ò bá tiẹ̀ rẹwà.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́