-
Jẹ́nẹ́sísì 37:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ó ṣẹlẹ̀ pé à ń di ìtí ọkà ní àárín oko, ni ìtí tèmi bá dìde, ó nàró, àwọn ìtí tiyín sì tò yí ìtí tèmi ká, wọ́n sì tẹrí ba fún un.”+ 8 Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sọ fún un pé: “Ṣé o wá fẹ́ jọba lé wa lórí ni, kí o wá máa pàṣẹ fún wa?”+ Ìyẹn wá mú kí wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀, torí àwọn àlá tó lá àti ohun tó sọ.
9 Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún lá àlá míì, ó sì rọ́ ọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, ó ní: “Mo tún lá àlá míì. Lọ́tẹ̀ yìí, oòrùn àti òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá (11) ń tẹrí ba fún mi.”+
-