ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 6:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Ìtàn Nóà nìyí.

      Olódodo ni Nóà.+ Ó fi hàn pé òun jẹ́ aláìlẹ́bi* láàárín àwọn tí wọ́n jọ gbé láyé.* Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́+ rìn.

  • Diutarónómì 8:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 “Torí náà, o gbọ́dọ̀ máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, nípa rírìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì máa bẹ̀rù rẹ̀.

  • Diutarónómì 13:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ máa tọ̀ lẹ́yìn, òun ni kí ẹ máa bẹ̀rù, àwọn àṣẹ rẹ̀ ni kí ẹ máa pa mọ́, ohùn rẹ̀ sì ni kí ẹ máa fetí sí; òun ni kí ẹ máa sìn, òun sì ni kí ẹ rọ̀ mọ́.+

  • 3 Jòhánù 4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Kò sí ohun tó ń mú inú mi dùn* bíi kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.+

  • Júùdù 14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Kódà, Énọ́kù+ tó jẹ́ ẹnì keje nínú ìran Ádámù tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn pé: “Wò ó! Jèhófà* dé pẹ̀lú ọ̀kẹ́ àìmọye* àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,+ 15 láti ṣe ìdájọ́ gbogbo èèyàn+ àti láti dá gbogbo àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi torí gbogbo ìwà búburú wọn àti gbogbo ọ̀rọ̀ tó burú jáì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ti sọ sí i.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́