-
Jẹ́nẹ́sísì 7:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ní ọjọ́ yẹn gan-an, Nóà wọ inú áàkì pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì,+ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.+ 14 Wọ́n wọlé, pẹ̀lú gbogbo ẹran inú igbó ní irú tiwọn, gbogbo ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn, gbogbo ẹran tó ń rákò ní ayé ní irú tiwọn, gbogbo ẹ̀dá tó ń fò ní irú tiwọn, títí kan gbogbo ẹyẹ àti gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́.
-