ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 13:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Jèhófà sọ fún Ábúrámù lẹ́yìn tí Lọ́ọ̀tì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́ gbójú sókè níbi tí o wà, kí o sì wo àríwá àti gúúsù, ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, 15 torí gbogbo ilẹ̀ tí o rí yìí ni màá fún ìwọ àti ọmọ* rẹ, yóò sì di ohun ìní yín títí láé.+

  • Jẹ́nẹ́sísì 15:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Lẹ́yìn èyí, Jèhófà sọ fún Ábúrámù nínú ìran pé: “Ábúrámù, má bẹ̀rù.+ Apata ni mo jẹ́ fún ọ.+ Èrè rẹ yóò pọ̀ gan-an.”+

  • Jẹ́nẹ́sísì 15:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Ó wá fi kún un pé: “Èmi ni Jèhófà, ẹni tó mú ọ kúrò ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí kó lè di ohun ìní+ rẹ.”

  • Jẹ́nẹ́sísì 17:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Nígbà tí Ábúrámù pé ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99), Jèhófà fara han Ábúrámù, ó sì sọ fún un pé: “Èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè. Máa bá mi rìn,* kí o sì fi hàn pé o jẹ́ aláìlẹ́bi.*

  • Jẹ́nẹ́sísì 17:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Màá fún ìwọ àti ọmọ* rẹ ní ilẹ̀ tí o gbé nígbà tí o jẹ́ àjèjì,+ ìyẹn gbogbo ilẹ̀ Kénáánì, yóò jẹ́ ohun ìní wọn títí láé, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run+ wọn.”

  • Diutarónómì 34:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Jèhófà sọ fún un pé: “Ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù nìyí pé, ‘Ọmọ* rẹ ni èmi yóò fún.’+ Mo ti jẹ́ kí o fi ojú ara rẹ rí i, àmọ́ o ò ní sọdá sí ibẹ̀.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́