-
Diutarónómì 2:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Tí o bá ti sún mọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, má yọ wọ́n lẹ́nu, má sì múnú bí wọn, torí mi ò ní fún ọ ní ìkankan lára ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì kó lè di tìrẹ, nítorí mo ti fún àwọn àtọmọdọ́mọ Lọ́ọ̀tì kó lè di tiwọn.+
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 11:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Nígbà tó ṣe díẹ̀, àwọn ọmọ Ámónì bá Ísírẹ́lì jà.+
-
-
Sefanáyà 2:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Nítorí náà, bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí,
“Móábù máa dà bíi Sódómù gẹ́lẹ́,+
Àti àwọn ọmọ Ámónì bíi Gòmórà,+
Ibi tí èsìsì wà, tí kòtò iyọ̀ wà, tó sì ti di ahoro títí láé.+
Àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn mi á kó wọn lọ,
Àwọn tó ṣẹ́ kù nínú orílẹ̀-èdè mi á sì gba tọwọ́ wọn.
-