ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Málákì 2:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Torí mo kórìíra* ìkọ̀sílẹ̀,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, “mo sì kórìíra ẹni tí ìwà ipá ti wọ̀ lẹ́wù,”* ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. “Ẹ ṣọ́ ẹ̀mí tó ń darí yín, ẹ má sì hùwà àìṣòótọ́.+

  • Mátíù 19:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 ó sì sọ pé, ‘Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́ ìyàwó rẹ̀, àwọn méjèèjì á sì di ara kan’?+

  • Máàkù 10:7, 8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀,+ 8 àwọn méjèèjì á sì di ara kan,’+ tó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, àmọ́ wọ́n jẹ́ ara kan.

  • Róòmù 7:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Bí àpẹẹrẹ, òfin de obìnrin tí a gbé níyàwó mọ́ ọkọ rẹ̀ nígbà tí ọkùnrin náà bá wà láàyè; àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ bá kú, a dá a sílẹ̀ kúrò lábẹ́ òfin ọkọ rẹ̀.+

  • 1 Kọ́ríńtì 6:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ẹni tó bá ní àṣepọ̀ pẹ̀lú aṣẹ́wó á di ara kan pẹ̀lú rẹ̀ ni? Nítorí Ọlọ́run sọ pé “àwọn méjèèjì á sì di ara kan.”+

  • Éfésù 5:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 “Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́* ìyàwó rẹ̀, àwọn méjèèjì á sì di ara kan.”+

  • Hébérù 13:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo èèyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó má sì ní ẹ̀gbin,+ torí Ọlọ́run máa dá àwọn oníṣekúṣe* àti àwọn alágbèrè lẹ́jọ́.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́