29 Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún wọn pé: “Wọn ò ní pẹ́ kó mi jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn mi.+ Torí náà, kí ẹ sin mí pẹ̀lú àwọn bàbá mi sínú ihò tó wà lórí ilẹ̀ Éfúrónì ọmọ Hétì,+ 30 ihò tó wà lórí ilẹ̀ Mákípẹ́là níwájú Mámúrè ní ilẹ̀ Kénáánì, ilẹ̀ tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ Éfúrónì ọmọ Hétì tó fi ṣe ibi ìsìnkú.