22 Rúbẹ́nì sọ fún wọn pé: “Ẹ má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ Ẹ jù ú sínú kòtò omi yìí nínú aginjù, àmọ́ ẹ má ṣe é léṣe.”*+ Ó ní in lọ́kàn láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn kó lè dá a pa dà sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀.
3 “Rúbẹ́nì,+ ìwọ ni àkọ́bí+ mi, okun mi, ìbẹ̀rẹ̀ agbára ìbímọ mi, iyì àti okun rẹ ta yọ. 4 Torí ara rẹ kò balẹ̀ bí omi tó ń ru gùdù, o ò ní ta yọ, torí pé o gun ibùsùn+ bàbá rẹ. O sọ ibùsùn mi di ẹlẹ́gbin* nígbà yẹn. Ó gun orí rẹ̀!
5Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì,+ àkọ́bí Ísírẹ́lì nìyí. Òun ni àkọ́bí, àmọ́ torí pé ó kó ẹ̀gàn bá ibùsùn bàbá rẹ̀,*+ ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí ni a fún àwọn ọmọ Jósẹ́fù+ ọmọ Ísírẹ́lì, torí náà, wọn ò kọ orúkọ rẹ̀ sínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn pé òun ni àkọ́bí.