ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 27:9-15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 “Kí o ṣe àgbàlá+ àgọ́ ìjọsìn náà. Ní apá gúúsù tó dojú kọ gúúsù, kí àgbàlá náà ní àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa ṣe, èyí tí wọ́n máa ta, kí gígùn ẹ̀gbẹ́ kan jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́.+ 10 Kí ó ní ogún (20) òpó pẹ̀lú ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò tí wọ́n fi bàbà ṣe. Kí o fi fàdákà ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 11 Kí gígùn àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n máa ta sí apá àríwá náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́, kí àwọn òpó rẹ̀ jẹ́ ogún (20) àti ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò tí wọ́n fi bàbà ṣe, pẹ̀lú ìkọ́ àwọn òpó náà àti ohun tó so wọ́n pọ̀* tí wọ́n fi fàdákà ṣe. 12 Kí àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n máa ta sí ẹ̀gbẹ́ àgbàlá náà lápá ìwọ̀ oòrùn jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wàá tó ní ihò. 13 Kí fífẹ̀ àgbàlá náà ní apá ìlà oòrùn tí oòrùn ti ń yọ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́. 14 Kí àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) wà ní ẹ̀gbẹ́ kan, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́ta tó ní ihò.+ 15 Kí àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́ta tó ní ihò.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́