8 Ní ti àmùrè* tí wọ́n hun,+ èyí tó wà lára éfódì náà láti dì í mú kó lè dúró dáadáa, ohun kan náà ni kí wọ́n fi ṣe é, kí wọ́n lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa.
7 Lẹ́yìn náà, ó wọ aṣọ+ fún un, ó de ọ̀já+ mọ́ ọn, ó wọ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá+ fún un, ó wọ éfódì+ fún un, ó sì fi àmùrè éfódì tí wọ́n hun pọ̀*+ dè é mọ́ ọn pinpin.