-
Ẹ́kísódù 7:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ó sì dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà+ nígbà tí mo bá na ọwọ́ mi láti bá Íjíbítì jà, tí mo sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò láàárín wọn.”
-
-
Ẹ́kísódù 8:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Mósè sọ fún Fáráò pé: “Mo fún ọ láǹfààní láti sọ ìgbà tí o fẹ́ kí n bẹ̀bẹ̀ pé kí àwọn àkèré náà kúrò lọ́dọ̀ rẹ, ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn èèyàn rẹ àti nínú àwọn ilé rẹ. Inú odò Náílì nìkan ni wọ́n á ṣẹ́ kù sí.” 10 Ó fèsì pé: “Ní ọ̀la.” Ó wá sọ pé: “Bí o ṣe sọ ló máa rí, kí o lè mọ̀ pé kò sẹ́ni tó dà bíi Jèhófà Ọlọ́run wa.+
-
-
Ẹ́kísódù 9:29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Mósè wá sọ fún un pé: “Gbàrà tí mo bá ti kúrò nílùú, màá tẹ́wọ́ síwájú Jèhófà. Ààrá náà yóò dáwọ́ dúró, yìnyín náà ò sì ní rọ̀ mọ́, kí o lè mọ̀ pé Jèhófà ló ni ayé.+
-