-
Ẹ́kísódù 7:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ó sì dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà+ nígbà tí mo bá na ọwọ́ mi láti bá Íjíbítì jà, tí mo sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò láàárín wọn.”
-
-
Ẹ́kísódù 7:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ohun tí wàá fi mọ̀ pé èmi ni Jèhófà+ nìyí. Màá fi ọ̀pá ọwọ́ mi lu omi odò Náílì, á sì di ẹ̀jẹ̀.
-
-
Ẹ́kísódù 8:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Mósè sọ fún Fáráò pé: “Mo fún ọ láǹfààní láti sọ ìgbà tí o fẹ́ kí n bẹ̀bẹ̀ pé kí àwọn àkèré náà kúrò lọ́dọ̀ rẹ, ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn èèyàn rẹ àti nínú àwọn ilé rẹ. Inú odò Náílì nìkan ni wọ́n á ṣẹ́ kù sí.” 10 Ó fèsì pé: “Ní ọ̀la.” Ó wá sọ pé: “Bí o ṣe sọ ló máa rí, kí o lè mọ̀ pé kò sẹ́ni tó dà bíi Jèhófà Ọlọ́run wa.+
-
-
Sáàmù 24:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Jèhófà ló ni ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀,+
Ilẹ̀ tó ń méso jáde àti àwọn tó ń gbé orí rẹ̀.
-