11 Wọ́n wá yan àwọn ọ̀gá* lé wọn lórí láti máa fipá kó wọn ṣiṣẹ́ àṣekára.+ Wọ́n sì kọ́ àwọn ìlú tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí fún Fáráò. Orúkọ àwọn ìlú náà ni Pítómù àti Rámísésì.+
7 Jèhófà sì sọ pé: “Mo ti rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn mi ní Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ igbe wọn torí àwọn tó ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́; mo mọ̀ dáadáa pé wọ́n ń jẹ̀rora.+