21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Tí o bá dé Íjíbítì, rí i pé gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí mo fún ọ lágbára láti ṣe lo ṣe níwájú Fáráò.+ Àmọ́, màá jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ le,+ kò sì ní jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lọ.+
4 Màá jẹ́ kí ọkàn Fáráò le,+ ó máa lépa wọn, màá sì ṣe ara mi lógo nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀.+ Ó dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”+ Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn.