4 Mósè wá sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Tó bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ọ̀gànjọ́ òru, màá lọ sí àárín Íjíbítì,+ 5 gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì yóò sì kú,+ látorí àkọ́bí Fáráò tó wà lórí ìtẹ́ dórí àkọ́bí ẹrúbìnrin tó ń lọ nǹkan lórí ọlọ àti gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn.+