34 Máa lọ báyìí, darí àwọn èèyàn náà lọ síbi tí mo bá ọ sọ. Wò ó! Áńgẹ́lì mi yóò ṣáájú rẹ.+ Lọ́jọ́ tí mo bá sì fẹ́ ṣèdájọ́, èmi yóò fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”
16 Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, a ké pe Jèhófà,+ ó gbọ́ wa, ó sì rán áńgẹ́lì+ kan láti mú wa kúrò ní Íjíbítì, a ti wá dé Kádéṣì báyìí, ìlú tó wà ní ààlà ilẹ̀ rẹ.
9 Kódà nígbà tí Máíkẹ́lì+ olú áńgẹ́lì+ ń bá Èṣù fa ọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń jiyàn nípa òkú Mósè,+ kò jẹ́ dá a lẹ́jọ́, kò sì sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí i,+ àmọ́ ó sọ fún un pé: “Kí Jèhófà* bá ọ wí.”+