24 ‘Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, o ti ń fi títóbi rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ han ìránṣẹ́ rẹ,+ àbí ọlọ́run wo ní ọ̀run tàbí ní ayé ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ àrà bíi tìrẹ?+
22 Ìdí nìyẹn tí o fi tóbi gan-an,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. Kò sí ẹni tó dà bí rẹ,+ kò sì sí Ọlọ́run kankan àfi ìwọ;+ gbogbo ohun tí a ti fi etí wa gbọ́ jẹ́rìí sí i.