22 Ìdí nìyẹn tí o fi tóbi gan-an,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. Kò sí ẹni tó dà bí rẹ,+ kò sì sí Ọlọ́run kankan àfi ìwọ;+ gbogbo ohun tí a ti fi etí wa gbọ́ jẹ́rìí sí i.
23 ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tó dà bí rẹ+ ní ọ̀run lókè tàbí lórí ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀, ò ń pa májẹ̀mú mọ́, o sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀+ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tó ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ.+