4 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Màá rọ̀jò oúnjẹ fún yín láti ọ̀run,+ kí kálukú máa jáde lọ kó iye tó máa tó o lójoojúmọ́,+ kí n lè dán wọn wò, kí n sì rí i bóyá wọ́n á pa òfin mi mọ́ tàbí wọn ò ní pa á mọ́.+
2 Máa rántí ọ̀nà jíjìn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ mú ọ rìn ní aginjù fún ogójì (40) ọdún yìí,+ kó lè rẹ̀ ọ́ sílẹ̀, kó sì dán ọ wò,+ kó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ,+ bóyá wàá pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ tàbí o ò ní pa wọ́n mọ́.