-
Nọ́ńbà 13:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ Mósè àti Áárónì àti gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù Páránì, ní Kádéṣì.+ Wọ́n jábọ̀ fún gbogbo àpéjọ náà, wọ́n sì fi àwọn èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. 27 Ohun tí wọ́n ròyìn fún Mósè ni pé: “A dé ilẹ̀ tí o rán wa lọ, wàrà àti oyin+ sì ń ṣàn níbẹ̀ lóòótọ́, àwọn èso+ ibẹ̀ nìyí.
-
-
Diutarónómì 27:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Kí ẹ wá kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí sára wọn tí ẹ bá ti sọdá, kí ẹ lè wọ ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn, bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ṣe ṣèlérí fún yín gẹ́lẹ́.+
-