13 Ó wá sọ fún Ábúrámù pé: “Mọ̀ dájú pé àwọn ọmọ rẹ máa di àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, àwọn èèyàn ibẹ̀ á fi wọ́n ṣe ẹrú, wọ́n á sì fìyà jẹ wọ́n fún ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún.+ 14 Àmọ́ màá dá orílẹ̀-èdè tí wọn yóò sìn+ lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà, wọ́n á kó ọ̀pọ̀ ẹrù+ jáde.