-
Ẹ́kísódù 1:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Torí náà, àwọn ará Íjíbítì sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú, wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n gan-an.+ 14 Wọ́n ni wọ́n lára gidigidi bí wọ́n ṣe ń mú wọn ṣiṣẹ́ àṣekára, wọ́n ń fi àpòrọ́ alámọ̀ àti bíríkì ṣiṣẹ́, wọ́n sì ń mú wọn ṣe onírúurú iṣẹ́ nínú oko bí ẹrú. Kódà, wọ́n lò wọ́n nílòkulò bí ẹrú láti ṣe onírúurú iṣẹ́ àṣekára.+
-
-
Ìṣe 7:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run sọ fún un pé àwọn ọmọ* rẹ̀ máa di àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, àwọn èèyàn ibẹ̀ á fi wọ́n ṣe ẹrú, wọ́n á sì fìyà jẹ wọ́n* fún ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún.+ 7 ‘Màá dá orílẹ̀-èdè tí wọ́n máa ṣẹrú fún lẹ́jọ́,’+ ni Ọlọ́run wí, ‘lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, wọ́n á jáde, wọ́n á sì ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún mi ní ibí yìí.’+
-