ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 10:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Áárónì, Nádábù àti Ábíhù,+ mú ìkóná wọn, kálukú fi iná sínú rẹ̀, wọ́n sì fi tùràrí+ sórí rẹ̀. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í rú ẹbọ tí kò yẹ+ níwájú Jèhófà, ohun tí kò pa láṣẹ fún wọn.

  • 2 Kíróníkà 26:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Wọ́n kojú Ọba Ùsáyà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ùsáyà, kò tọ́ sí ọ láti sun tùràrí sí Jèhófà!+ Àwọn àlùfáà nìkan ló yẹ kó máa sun tùràrí, torí àwọn ni àtọmọdọ́mọ Áárónì,+ àwọn tí a ti yà sí mímọ́. Jáde kúrò ní ibi mímọ́, nítorí o ti hùwà àìṣòótọ́, o ò sì ní rí ògo kankan gbà lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run nítorí èyí.”

  • Ìsíkíẹ́lì 8:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Àádọ́rin (70) ọkùnrin lára àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì dúró níwájú wọn, Jasanáyà ọmọ Ṣáfánì+ sì wà lára wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mú àwo tùràrí rẹ̀ dání, èéfín tùràrí tó ní òórùn dídùn sì ń gòkè lọ.+ 12 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì ń ṣe nínú òkùnkùn, kálukú nínú yàrá inú tó kó* àwọn ère rẹ̀ sí? Wọ́n ń sọ pé, ‘Jèhófà ò rí wa. Jèhófà ti fi ilẹ̀ wa sílẹ̀.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́