-
Jẹ́nẹ́sísì 22:15-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Áńgẹ́lì Jèhófà tún pe Ábúráhámù lẹ́ẹ̀kejì láti ọ̀run, 16 ó sọ pé: “‘Mo fi ara mi búra pé torí ohun tí o ṣe yìí,’ ni Jèhófà+ wí, ‘tí o kò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ, ọ̀kan ṣoṣo+ tí o ní, 17 ó dájú pé màá bù kún ọ, ó sì dájú pé màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti iyanrìn etí òkun,+ ọmọ* rẹ yóò sì gba ẹnubodè* àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ lọ́wọ́ wọn.
-
-
Jẹ́nẹ́sísì 35:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ọlọ́run sọ fún un pé: “Jékọ́bù+ ni orúkọ rẹ. Àmọ́, o ò ní máa jẹ́ Jékọ́bù mọ́, Ísírẹ́lì ni wàá máa jẹ́.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Ísírẹ́lì.+ 11 Ọlọ́run tún sọ fún un pé: “Èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè.+ Máa bímọ, kí o sì di púpọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè àti àwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè yóò tinú rẹ jáde,+ àwọn ọba yóò sì ti ara rẹ jáde.*+
-