-
Ẹ́kísódù 18:25, 26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Mósè yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n nínú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn èèyàn náà, ó fi wọ́n ṣe olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta àti olórí àwọn mẹ́wàá-mẹ́wàá. 26 Wọ́n ń bá àwọn èèyàn náà dá ẹjọ́ tí wọ́n bá gbé wá. Wọ́n máa ń gbé ẹjọ́ tó bá ṣòroó dá lọ sọ́dọ̀ Mósè,+ àmọ́ wọ́n máa ń dá àwọn ẹjọ́ tí kò tó nǹkan.
-
-
Nọ́ńbà 27:1-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Àwọn ọmọ Sélóféhádì+ wá sí tòsí, Sélóféhádì yìí ni ọmọ Héfà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírù, ọmọ Mánásè, látọ̀dọ̀ àwọn ìdílé Mánásè ọmọ Jósẹ́fù. Orúkọ àwọn ọmọ Sélóféhádì ni Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà. 2 Wọ́n dúró síwájú Mósè, àlùfáà Élíásárì, àwọn ìjòyè+ àti gbogbo àpéjọ náà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, wọ́n sì sọ pé: 3 “Bàbá wa ti kú ní aginjù, àmọ́ kò sí lára àwọn tó gbìmọ̀ pọ̀ láti ta ko Jèhófà, àwọn tó ti Kórà+ lẹ́yìn. Torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ló ṣe kú, kò sì ní ọmọkùnrin kankan. 4 Kí ló dé tí orúkọ bàbá wa fi máa pa rẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ torí pé kò bímọ ọkùnrin? Fún wa ní ohun ìní láàárín àwọn arákùnrin bàbá wa.” 5 Mósè wá mú ọ̀rọ̀ wọn tọ Jèhófà+ lọ.
-