-
Léfítíkù 6:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Tó bá ti ṣẹ̀, tó sì jẹ̀bi, kó dá ohun tó jí pa dà àti ohun tó fipá gbà, ohun tó fi jìbìtì gbà, ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ rẹ̀ tàbí ohun tó sọ nù tí ó rí, 5 tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí, kó sì san gbogbo rẹ̀ pa dà,+ kó tún fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un. Kó fún ẹni tó ni ín lọ́jọ́ tí wọ́n bá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ̀bi.
-
-
Léfítíkù 22:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “‘Tí ẹnì kan bá ṣèèṣì jẹ ohun mímọ́, kó fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un, kó sì fún àlùfáà ní ọrẹ mímọ́ náà.+
-
-
Nọ́ńbà 5:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá dá èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn èèyàn ń dá, tó sì hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà, ẹni* náà ti jẹ̀bi.+ 7 Ó* gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́+ ẹ̀ṣẹ̀ tó* dá, kó san ohun tó jẹ̀bi rẹ̀ pa dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, kó sì fi ìdá márùn-ún rẹ̀+ kún un; kó fún ẹni tó ṣe àìdáa sí.
-