-
Léfítíkù 5:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Tí ẹnì* kan bá hùwà àìṣòótọ́, ní ti pé ó ṣèèṣì ṣẹ̀ sí àwọn ohun mímọ́ Jèhófà,+ kó mú àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún Jèhófà látinú agbo ẹran, kó fi rú ẹbọ ẹ̀bi;+ ṣékélì ibi mímọ́*+ ni kí wọ́n fi díwọ̀n iye ṣékélì* fàdákà rẹ̀. 16 Kó san nǹkan kan dípò ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ sí ibi mímọ́, kó sì fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un.+ Kó fún àlùfáà, kí àlùfáà lè fi àgbò ẹbọ ẹ̀bi ṣe ètùtù+ fún un, yóò sì rí ìdáríjì.+
-
-
Nọ́ńbà 5:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá dá èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn èèyàn ń dá, tó sì hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà, ẹni* náà ti jẹ̀bi.+ 7 Ó* gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́+ ẹ̀ṣẹ̀ tó* dá, kó san ohun tó jẹ̀bi rẹ̀ pa dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, kó sì fi ìdá márùn-ún rẹ̀+ kún un; kó fún ẹni tó ṣe àìdáa sí.
-