-
Léfítíkù 3:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Kó mú ọ̀rá látinú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kó fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.+ Kó gé ìrù rẹ̀ tó lọ́ràá nítòsí eegun ẹ̀yìn kúrò lódindi, ọ̀rá tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká,
-
-
Léfítíkù 4:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “‘Lẹ́yìn náà, kó yọ gbogbo ọ̀rá tó wà lára akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, títí kan ọ̀rá tó bo ìfun àti ọ̀rá tó yí ìfun ká 9 àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú. Kó yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ rẹ̀.
-
-
Léfítíkù 8:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ó mú àgbò tó fẹ́ fi rú ẹbọ sísun náà wá sí tòsí, Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ lé orí àgbò náà.+
-
-
Léfítíkù 8:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, Mósè sì mú kí orí àgbò náà, àwọn ègé rẹ̀ àti ọ̀rá rẹ̀ líle* rú èéfín.
-