-
Léfítíkù 7:23-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá+ èyíkéyìí láti ara akọ màlúù tàbí ọmọ àgbò tàbí ewúrẹ́. 24 Ẹ lè fi ọ̀rá òkú ẹran àti ọ̀rá ẹran tí ẹranko míì pa ṣe nǹkan míì, àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́.+ 25 Tí ẹnikẹ́ni bá jẹ ọ̀rá ẹran tó mú wá láti fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, kí ẹ pa onítọ̀hún kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.
-
-
1 Àwọn Ọba 8:64Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
64 Ní ọjọ́ yẹn, ọba ní láti ya àárín àgbàlá tó wà níwájú ilé Jèhófà sí mímọ́, torí ibẹ̀ ló ti máa rú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà pẹ̀lú àwọn apá tó lọ́ràá lára àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀, nítorí pé pẹpẹ bàbà+ tó wà níwájú Jèhófà kéré ju ohun tó lè gba àwọn ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà pẹ̀lú àwọn apá tó lọ́ràá+ lára àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀.
-