-
Léfítíkù 14:44, 45Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
44 kí àlùfáà wọlé lọ yẹ̀ ẹ́ wò. Tí àrùn náà bá ti ràn nínú ilé náà, á jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ tó le gan-an+ ló wà nínú ilé náà. Ilé náà ti di aláìmọ́. 45 Lẹ́yìn náà, kó ní kí wọ́n wó ilé náà lulẹ̀, tòun ti àwọn òkúta rẹ̀, àwọn ẹ̀là gẹdú àti gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà àti àpòrọ́ rẹ̀, kó sì ní kí wọ́n kó o lọ sí ẹ̀yìn ìlú, níbi àìmọ́.+
-